Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Ti Àpókírífà—Ǹjẹ́ Ìtàn Jésù Tí Bíbélì Kò Sọ Ni Lóòótọ́?
Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Ti Àpókírífà—Ǹjẹ́ Ìtàn Jésù Tí Bíbélì Kò Sọ Ni Lóòótọ́?
“ÈYÍ kàmàmà. Ó máa bí ọ̀pọ̀ èèyàn nínú gan-an.” “Ó yí ohun tá a mọ̀ nípa ẹ̀sìn Kristẹni ìpilẹ̀ṣẹ̀ pa dà.” Àwọn gbólóhùn ńláńlá yìí ló ń jáde lẹ́nu àwọn ọ̀mọ̀wé tí inú wọn dùn sí ìwé kan tí wọ́n pè ní “Ìhìn Rere Júdásì.” Ó jẹ́ ìwé kan tí wọ́n rò pé ó ti sọ nù láti ohun tó lé ní ẹgbẹ̀jọ ọdún sẹ́yìn (àwòrán rẹ̀ ló wà lókè yìí).
Ní báyìí, àwọn èèyàn tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí irú àwọn ìwé ìhìn rere inú ìwé àpókírífà bẹ́ẹ̀. Àwọn kan sọ pé ọ̀rọ̀ inú ìwé yẹn tú àṣírí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó wáyé àti àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tí Jésù kọ́ni nígbà ayé rẹ̀ táwọn èèyàn ti bò mọ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́. Ṣùgbọ́n, irú ìwé wo tiẹ̀ ni àwọn ìwé ìhìn rere ti àpókírífà? Ṣé a lè rí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Jésù àti ẹ̀sìn Kristẹni nínú wọn, tó jẹ́ pé kò sí nínú Bíbélì?
Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Tí Ọlọ́run Mí Sí àti Ayédèrú Ìhìn Rere Ti Àpókírífà
Láàárín ọdún kọkànlélógójì [41] sí ìkejìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] Sànmánì Kristẹni ni Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù kọ “ọ̀rọ̀ ìtàn nípa Jésù Kristi” sílẹ̀. (Mátíù 1:1) Nígbà míì, wọ́n tún máa ń pe àwọn ìwé tí wọ́n kọ yìí ní ìwé ìhìn rere, èyí tó túmọ̀ sí “ìhìn rere” nípa Jésù Kristi.—Máàkù 1:1.
Lóòótọ́ àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu míì àti àwọn ìwé míì lè wà tó sọ̀rọ̀ nípa Jésù, àmọ́ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin yìí nìkan làwọn ará ìgbàanì gbà pé Ọlọ́run mí sí, tó sì kúnjú òṣùwọ̀n èyí tí a fi lè kà á mọ́ ara Ìwé Mímọ́, èyí tó ń fúnni ní “ìdánilójú àwọn ohun” tó jẹ mọ́ ìgbé ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ni. (Lúùkù 1:1-4; Ìṣe 1:1, 2; 2 Tímótì 3:16, 17) Wọ́n dárúkọ àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí nínú gbogbo ibi tí wọ́n to àwọn àkọsílẹ̀ ìwé tí ó para pọ̀ jẹ́ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí láyé àtijọ́. Kò sídìí láti ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣiyè méjì pé wọ́n wà lára àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí, tó wà nínú Bíbélì.
Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn kan tún gbé àwọn ìwé míì jáde tí wọ́n tún ń sọ pé ó jẹ́ ìwé ìhìn rere bákan náà. Ni àwọn èèyàn bá ka àwọn ìwé ìhìn rere yẹn mọ́ ará ìwé tí wọ́n ń pè ní àpókírífà. *
Ọ̀gbẹ́ni Irenaus Lyon tó gbé ayé ní apá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì kọ̀wé pé àwọn tí ó pẹ̀yìn dà kúrò nínú ẹ̀sìn Kristẹni “ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé àpókírífà àti ayédèrú ìwé, títí kan àwọn ìwé ìhìn rere kan tí àwọn fúnra wọn kọ láti ṣi àwọn aláìmọ̀kan lọ́nà.” Nítorí náà, ìwé tó léwu fúnni láti ní tàbí láti kà ni wọ́n ka àwọn ìwé ìhìn rere ti àpókírífà sí.
Àmọ́, ní ìgbà ojú dúdú, àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé àti àwọn adàwékọ kan wá ń da àwọn ìwé náà kọ, èyí tí kò jẹ́ kí àwọn ìwé yẹn pa rẹ́. Nígbà tó di ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, àwọn èèyàn kan bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ nípa ìwé àpókírífà gan-an, wọ́n wá ọ̀pọ̀ irú ìwé bẹ́ẹ̀ kàn, títí kan àwọn èyí tí àwọn ọ̀mọ̀wé fi àlàyé sí, àti àwọn tí wọ́n pè ní ìwé
ìhìn rere. Lóde òní, onírúurú ẹ̀dà ìwé yẹn ni wọ́n sì ti tẹ̀ jáde ní àwọn ìsọ̀rí èdè pàtàkì tó wà láyé.Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Ti Àpókírífà: Ìtàn Tó Jọ Pé Wọ́n Hùmọ̀ Nípa Jésù Ni
Ọ̀rọ̀ àwọn ìwé ìhìn rere ti àpókírífà sábà máa ń dá lórí àwọn ẹni tí àwọn ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì kàn mẹ́nu bà fẹ́rẹ́ tàbí tí wọn ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn rárá. Nígbà míì sì rèé, wọ́n lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun kan tí wọ́n gbà pé Jésù ṣe ní ìgbà kékeré rẹ̀. Wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan.
◼ Ìwé ìhìn rere tí àwọn kan sọ pé Jákọ́bù kọ, èyí tí wọ́n tún ń pè ní “Ìbí Màríà,” ṣàlàyé bí wọ́n ṣe bí Màríà àti ìgbà kékeré rẹ̀ àti bó ṣe di pé ó fẹ́ Jósẹ́fù. Àwọn tó mọ ìwé náà pè é ní ìtàn àròsọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu tó jẹ mọ́ ti ìsìn, bó sì ṣe jẹ́ nìyẹn. Ohun tí ìwé yẹn fẹ́ gbìn sí àwọn èèyàn lọ́kàn ni pé Màríà wà ní ipò wúńdíá jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, ó sì hàn gbangba pé ṣe ni wọ́n kọ ìwé náà láti fi gbógo fún Màríà.—Mátíù 1:24, 25; 13:55, 56.
◼ Ayédèrú ìwé ìhìn rere tí wọ́n pè ní “Ìhìn Rere Ìgbà Ọmọdé ti Tọ́másì” dá lórí ìgbà tí Jésù ṣì wà lọ́mọdé, ìyẹn láàárín ọmọ ọdún márùn-ún sí méjìlá. Ìwé náà sọ pé ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu kan tó jẹ́ pé kò lè jóòótọ́. (Wo Jòhánù 2:11.) Wọ́n fi Jésù hàn bí ọmọ burúkú, tó máa ń tètè bínú, tí kì í sì í dárí jini àti pé ó máa ń fi agbára iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbẹ̀san lára àwọn olùkọ́ rẹ̀, aládùúgbò rẹ̀ àti àwọn ọmọ míì. Wọ́n ní ó sọ ẹlòmíì di afọ́jú, arọ tàbí pé ó pa àwọn míì.
◼ Àwọn ìwé ìhìn rere ti àpókírífà míì irú bíi “Ìhìn Rere ti Pétérù,” sọ̀rọ̀ nípa ìgbẹ́jọ́ Jésù, bó ṣe kú àti bó ṣe jíǹde. Àwọn ìwé míì bí “Ìṣe Pílátù,” èyí tí ó jẹ́ ara ìwé “Ìhìn Rere ti Nikodémù,” sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tó wà ní ibi tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ti ṣẹlẹ̀. Ìtàn irọ́ àti orúkọ irọ́ tó kún inú àwọn ìwé náà fi hàn pé ayédèrú ìwé ni wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ìwé “Ìhìn Rere ti Pétérù” fẹ́ dọ́gbọ́n fi hàn pé Pọ́ńtíù Pílátù jàre ohun tó ṣe, ó sì tún ṣàpèjúwe àjíǹde Jésù lọ́nà tó fi dà bí ohun àsọdùn lásán.
Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Ti Àpókírífà àti Ìpẹ̀yìndà Kúrò Nínú Ẹ̀sìn Kristẹni
Lóṣù December ọdún 1945, nítòsí abúlé kan tó ń jẹ́ Nag Hammadi ní ilẹ̀ Íjíbítì Òkè, àwọn ara oko kan ṣàdédé rí ìwé àfọwọ́kọ mẹ́tàlá tí wọ́n fi òrépèté ṣe, tó ní gbólóhùn méjìléláàádọ́ta nínú. Ìwádìí sọ pé àwọn ìwé yìí tó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni náà jẹ́ ti àwọn ẹ̀ya ìsìn kan tí wọ́n gbé ka ọgbọ́n orí, èyí tí wọ́n ń pè ní Onímọ̀ Awo [Gnosticism]. Ẹ̀ya ìsìn yí pa iṣẹ́ awo pọ̀ mọ́ ìbọ̀rìṣà, ìmọ̀ ọgbọ́n orí ti àwọn Gíríìkì, ẹ̀sìn àwọn Júù àti ẹ̀sìn Kristẹni, nítorí náà ó kó àwọn kan tó sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni ṣìnà.—1 Tímótì 6:20, 21.
Àwọn ìwé bí “Ìhìn Rere ti Tọ́másì,” “Ìhìn Rere ti Fílípì” àti “Ìhìn Rere Òtítọ́,” tó jẹ́ ara ìwé mẹ́tàlá tá a sọ lókè yìí, èyí tí wọ́n rí nítòsí ìlú Nag Hammadi, gbé èrò ìkọ̀kọ̀ ti àwọn ẹ̀ya ìsìn Onímọ̀ Awo kalẹ̀ bíi pé Jésù ló sọ wọ́n. Ọ̀kan lára ìwé ìhìn rere àwọn Onímọ̀ Awo yẹn ni wọ́n sì sọ pé ìwé “Ìhìn Rere ti Júdásì,” tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí lẹ́nu àìpẹ́ yìí jẹ́. Ìwé yìí fi Júdásì hàn bí èèyàn dáadáa àti pé òun nìkan ni àpọ́sítélì tó mọ ìwà Jésù dáadáa. Olùṣèwádìí kan tó mọ tìfun-tẹ̀dọ̀ ìwé ìhìn rere yìí sọ pé kò ṣàpèjúwe Jésù bí “olùgbàlà tó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló pè é ní olùkọ́ àti ẹni tó ń ṣí ọgbọ́n àti ìmọ̀ payá.” Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ìwé Ìhìn Rere tí Ọlọ́run mí sí, ohun tí wọ́n fi kọ́ni ni pé Jésù kú láti fi ara rẹ̀ ṣe ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. (Mátíù 20:28; 26:28; 1 Jòhánù 2:1, 2) Ẹ ò rí i pé ṣe ni wọ́n fẹ́ fi àwọn ìwé ìhìn rere ti àwọn Onímọ̀ Awo yìí jin ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn nínú Bíbélì lẹ́sẹ̀, dípò tí wọ́n á fi mú kéèyàn túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Ìṣe 20:30.
Bí Àwọn Ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì Ṣe Ta Wọ́n Yọ
Àyẹ̀wò fínnífínní fi hàn pé àwọn ìwé ìhìn rere ti àpókírífà jẹ́ ìwé irọ́ pátápátá. Téèyàn bá fi wọ́n wé àwọn ìwé Ìhìn Rere ti inú Bíbélì, ó máa ń hàn gbangba pé àwọn ìwé ìhìn rere ti àpókírífà kò ní ìmísí Ọlọrun. (2 Tímótì 1:13) Ìgbà tó sì ti jẹ́ pé àwọn tí kò tiẹ̀ mọ Jésù tàbí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ rárá ló kọ wọ́n, kò sí òtítọ́ tó fara sin kankan nípa Jésù tàbí ẹ̀sìn Kristẹni tí wọ́n fi hàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n kún fún ìtàn irọ́, èyí tí wọ́n hùmọ̀ àti àwọn àsọdùn tí kò lè mú kéèyàn túbọ̀ mọ̀ nípa Jésù àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ni.—1 Tímótì 4:1, 2.
Ṣùgbọ́n ní ti Mátíù àti Jòhánù, wọ́n jẹ́ ara àwọn àpọ́sítélì méjìlá, nígbà tí Máàkù àti Lúùkù sì bá àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù rìn dáadáa. Ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí wọn nígbà tí wọ́n kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere wọn. (2 Tímótì 3:14-17) Fún ìdí èyí, àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ní gbogbo ohun tó yẹ kí èèyàn mọ̀ téèyàn á fi lè gbà gbọ́ pé “Jésù ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run.”—Jòhánù 20:31.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Ọ̀rọ̀ náà “àpókírífà” jẹ́ ọ̀rọ̀ kan lédè Gíríìkì tó túmọ̀ sí “fi pa mọ́ sí ìkọ̀kọ̀.” Ohun tí wọ́n kọ́kọ́ ń lo ọ̀rọ̀ náà fún látijọ́ ni ìwé ìkọ̀kọ̀ kan tó wà fún kìkì àwọn tó jọ ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìkọ̀kọ̀ yẹn, wọn kì í sì í jẹ́ kí ọ̀gbẹ̀rì tí kò bá sí nínú ẹgbẹ́ wọn rí i sójú rárá. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi orúkọ yẹn pe àwọn ìwé kan tí wọn kò kà mọ́ ara àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú Bíbélì.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Kenneth Garrett/National Geographic Stock