Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan​—Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run?

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan​—Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run?

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan​—Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run?

INÚ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o ní ìbéèrè kan nínú Bíbélì tó ò ń ṣe kàyéfì nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀kan lára ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́ra láti béèrè ohun náà lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó o bá bá pàdé. Inú rẹ̀ yóò dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.

Irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Kẹ́mi ni orúkọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lọ sí ilé obìnrin kan tó ń jẹ́ Ṣadé.

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Ẹ Kò Gba Jésù Gbọ́?

Sadé: Pásítọ̀ wa sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gba Jésù gbọ́. N gbọ́ ṣé òótọ́ ni?

Kẹ́mi: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba Jésù gbọ́ dáadáa. Kódà, a gbà gbọ́ pé téèyàn kò bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, kò lè rí ìgbàlà.

Sadé: Ohun tí èmi náà gbà gbọ́ nìyẹn.

Kẹ́mi: A jẹ́ pé àwa méjèèjì ló jọ gba ìyẹn gbọ́. Jẹ́ kí n sọ orúkọ mi ná. Kẹ́mi lorúkọ mi. Jọ̀ọ́, kí ni orúkọ tìrẹ?

Sadé: Sadé ni. Inú mi dùn láti rí ẹ.

Kẹ́mi: Inú tèmi náà dùn láti mọ̀ ẹ́ Sadé. O lè máa rò ó pé ‘Tó bá jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba Jésù gbọ́ lóòótọ́, kí ló dé tí àwọn èèyàn fi ń sọ pé a ò gba Jésù gbọ́?’

Sadé: Bẹ́ẹ̀ ni, ó ya èmi náà lẹ́nu, kí ló fà á ná?

Kẹ́mi: Ní kúkúrú, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jésù, àmọ́, kì í ṣe gbogbo ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nípa rẹ̀ la gbà gbọ́.

Sadé: Ṣé lóòótọ́? Ṣé ẹ lè fún mi ní àpẹẹrẹ kan?

Kẹ́mi: Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé o rí i, àwọn èèyàn kan máa ń sọ pé ẹni rere lásán ni Jésù kàn jẹ́. Àmọ́, àwa ò gbà bẹ́ẹ̀.

Sadé: Èmi náà ò gbà bẹ́ẹ̀.

Kẹ́mi: Ìyẹn tún jẹ́ nǹkan míì tí àwa méjèèjì kò jọ gbà gbọ́. Àpẹẹrẹ kejì ni pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbà gbọ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí ó ta ko ohun tí Jésù sọ fún wa nípa àjọṣe tó wà láàárín òun àti Baba rẹ̀.

Sadé: Kí lo ní lọ́kàn?

Kẹ́mi: Ọ̀pọ̀ ìsìn ló ń kọ́ni pé Jésù ni Ọlọ́run. Bóyá ohun ti wọ́n ti kọ ìwọ náà nìyẹn.

Sadé: Bẹ́ẹ̀ ni, pásítọ̀ wa sọ pé ẹnì kan náà ni Ọlọ́run àti Jésù.

Kẹ́mi: Ṣé o gbà pé ọ̀nà tó dáa jù láti mọ ohun tó jóòótọ́ ni pé kéèyàn fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù fúnra rẹ̀ sọ?

Sadé: Bẹ́ẹ̀ ni, mo gbà bẹ́ẹ̀.

Kí Ni Jésù Sọ?

Kẹ́mi: Jẹ́ ká wo ẹsẹ Bíbélì kan tó ṣàlàyé kókó yìí dáadáa. Jọ̀wọ́, wo ohun tí ìwé Jòhánù 6:38 sọ. Jésù sọ pé: “Nítorí pé èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” Ní báyìí, ṣé o rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn máa fẹ́ ta kókó tó bá jẹ́ pé Jésù fúnra rẹ̀ ni Ọlọ́run.

Sadé: Kí lo ní lọ́kàn?

Kẹ́mi: Ó dáa, ṣé o kíyè sí i pé Jésù kò sọ pé òun sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run láti ṣe ìfẹ́ ara òun.

Sadé: Òótọ́ ni, ó ní òun wá láti ṣe ìfẹ́ Ẹni tí ó rán òun.

Kẹ́mi: Àmọ́, tó bá jẹ́ Jésù ni Ọlọ́run, ta ló tún rán an wá láti ọ̀run? Kí ló dé tí Jésù sì fi gbà láti ṣe ìfẹ́ Ẹni yẹn?

Sadé: Mo ti mọ ibi tó ò ń bọ́rọ̀ lọ. Ṣùgbọ́n kò jọ pé ẹsẹ Bíbélì yìí nìkan ṣoṣo fi hàn pé Jésù kọ́ ni Ọlọ́run.

Kẹ́mi: Jẹ́ ká wo ohun tí Jésù tún sọ. Ó sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú ìwé Jòhánù orí keje. Jọ̀wọ́ ṣé o lè ka Jòhánù 7:16?

Sadé: Màá kà á. “Jésù, ẹ̀wẹ̀, dá wọn lóhùn, ó sì wí pé: ‘Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.’”

Kẹ́mi: O ṣeun gan-an ni, Sadé. Nínú ohun tí o kà yìí, ǹjẹ́ èrò orí ara rẹ̀ ni Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn?

Sadé: Rárá o, ó ní ohun tí òun ń kọ́ àwọn èèyàn jẹ́ ti ẹni tó rán òun.

Kẹ́mi: Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. A lè máa wá bi ara wa pé, ‘Ta ni ẹni tó rán Jésù? Àti pé ta ló kọ́ ọ ní òtítọ́ tó fi ń kọ́ àwọn èèyàn?’ Ó dájú pé ẹni yẹn ní láti ju Jésù lọ, àbí? Ó ṣe tán ẹni bá juni lọ ló ń ránni níṣẹ́.

Sadé: Èyí jọ mí lójú gan-an ni. Mi ò tíì ka ẹsẹ Bíbélì yìí rí.

Kẹ́mi: Jẹ́ ká tún wo ohun tí Jésù sọ nínú ìwé Jòhánù 14:28. Ó ní: “Ẹ gbọ́ tí mo sọ fún yín pé, Èmi ń lọ, èmi sì ń padà bọ̀ sọ́dọ̀ yín. Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ ó yọ̀ pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí pé Baba tóbi jù mí lọ.” Nínú ohun tí a kà yìí, irú ojú wo lo rò pé Jésù fi ń wo ara rẹ̀ àti Baba rẹ̀?

Sadé: Ó ní Baba òun tóbi ju òun lọ. Ohun tí mo sì rò pé ó ń sọ ni pé Ọlọ́run tóbi ju òun lọ.

Kẹ́mi: O ṣeun. Bí àpẹẹrẹ, tún wo ohun tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú ìwé Mátíù 28:18. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Ǹjẹ́ Jésù sọ pé òun lòun fún ara òun ní gbogbo ọlá àṣẹ?

Sadé: Rára o, ó sọ pé ẹnì kan ló fún òun ní ọlá àṣẹ.

Kẹ́mi: Àmọ́, tó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́run, báwo lẹ́nì kan ṣe tún lè fún un ní ọlá àṣẹ? Ta lẹni tó sì fún un ní ọlá àṣẹ yẹn?

Sadé: Àfi kí n kọ́kọ́ ronú lórí ìyẹn ná.

Ta Ló Ń Bá Sọ̀rọ̀?

Kẹ́mi: Àmọ́ ohun míì tún wà tó máa ṣeni ní kàyéfì tó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́run lóòótọ́.

Sadé: Kí nìyẹn?

Kẹ́mi: Ìyẹn ni ohun tá a kà nípa ìrìbọmi tí Jésù ṣe. Wo ohun tó wà nínú Lúùkù 3:21, 22. Jọ̀wọ́ ṣé wàá ka ẹsẹ Bíbélì yẹn?

Sadé: “Wàyí o, nígbà tí a batisí gbogbo ènìyàn, a batisí Jésù pẹ̀lú, bí ó sì ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ní ìrí ti ara bí àdàbà bà lé e, ohùn kan sì jáde wá láti inú ọ̀run pé: ‘Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.’”

Kẹ́mi: Ǹjẹ́ o kíyè sí ohun tí Jésù ń ṣe nígbà tó ń ṣe ìrìbọmi?

Sadé: Ó ń gbàdúrà.

Kẹ́mi: Bẹ́ẹ̀ ni. A lè wá bi ara wa pé ‘Tó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́run lóòótọ́, ta ló wá ń gbàdúrà sí?’

Sadé: Ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání nìyẹn. Àfi kí n béèrè lọ́wọ́ pásítọ̀ wa.

Kẹ́mi: Bákàn náà, ṣé o kíyè sí i pé nígbà tí Jésù jáde nínú omi, ẹnì kan bá a sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Kí ni ẹni yẹn sọ?

Sadé: Ó ní Jésù ni Ọmọ òun, pé òun fẹ́ràn rẹ̀ àti pé òun tẹ́wọ́ gbà á.

Kẹ́mi: O ṣeun. Àmọ́ tó bá ṣe pé Jésù ni Ọlọ́run, ta ló sọ ọ̀rọ̀ yẹn láti ọ̀run?

Sadé: Mi ò tiẹ̀ ronú lọ síbẹ̀ rí o.

Kí ni ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ “Baba” tí Jésù sì jẹ́ “Ọmọ”?

Kẹ́mi: Ohun míì tún nìyí tó yẹ ká jọ ronú lé lórí. A kà á nínú Bíbélì lẹ́ẹ̀kan pé Jésù pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀. Nígbà tí Jésù sì ṣe ìrìbọmi, ohùn kan láti ọ̀run sọ pé Jésù ni Ọmọ òun. Kódà, Jésù tiẹ̀ pe ara rẹ̀ ní Ọmọ Ọlọ́run. Wàyí o, ká sọ pé o fẹ́ kọ́ mi pé àwọn méjì kan jọ jẹ́ ẹgbẹ́, àpẹẹrẹ àwọn wo nínú ìdílé ni wàá lò?

Sadé: Màá lo àpẹẹrẹ àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì.

Kẹ́mi: O ṣé gan-an, bóyá ká tiẹ̀ kúkú sọ pé àwọn ìbejì tó jọra wọn. Ṣùgbọ́n, Jésù pe Ọlọ́run ní Baba, ó sì pe ara rẹ̀ ní Ọmọ. Kí lo rò pé Jésù ń dọ́gbọ́n sọ fún wa yẹn?

Sadé: Ọ̀rọ̀ rẹ yé mi wàyí. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé ẹnì kan ju ẹnì kejì, ó sì ní ọlá àṣẹ ju ẹnì kejì.

Kẹ́mi: Bọ́rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Rò ó wò ná: O lo àpẹẹrẹ àwọn ìbejì kan láti fi ṣàpèjúwe àwọn méjì tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́. Tó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́run, ṣé o kò rò pé á ti ronú nípa àpẹẹrẹ tí o mú wá yẹn tàbí èyí tó tún dára ju ìyẹn lọ lórí ọ̀rọ̀ àwọn méjì tó jọ jẹ́ ẹgbẹ́, òun ṣáà ni Olùkọ́ Ńlá náà?

Sadé: Òótọ́ ni.

Kẹ́mi: Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Baba” àti “Ọmọ” ló máa ń lò láti fi ṣàpèjúwe bí òun àti Ọlọ́run ṣe jẹ́ síra.

Sadé: Òdodo ọ̀rọ̀ lo sọ yẹn o.

Kí Ni Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Ìgbàanì Sọ?

Kẹ́mi: Tí o bá ṣì ní ìṣẹ́jú díẹ̀ sí i, kí ń tó máa lọ, màá fẹ́ láti sọ nǹkan míì fún ẹ lórí kókó yìí.

Sadé: Bẹ́ẹ̀ ni, mo ṣì ní ìṣẹ́jú díẹ̀.

Kẹ́mi: Tó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́run lóòótọ́, ǹjẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò ti ní sọ bẹ́ẹ̀ ní tààràtà?

Sadé: Wọ́n á ti sọ bẹ́ẹ̀.

Kẹ́mi: Síbẹ̀, kò sí ibì kankan tó wà nínú ìwé Mímọ́ pé wọ́n sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wo ohun tí ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìgbàanì, ìyẹn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sílẹ̀. Nínú ìwé Fílípì 2:9, ó sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe lẹ́yìn tí Jésù kú àti lẹ́yìn tó jíǹde. Ó sọ pé: ‘Ọlọ́run gbé Jésù sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.’ Nínú ohun tí a kà yìí, kí ni Ọlọ́run ṣe fún Jésù?

Sadé: Ibẹ̀ sọ pé Ọlọ́run gbé e sí ipò gíga.

Kẹ́mi: Bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ tó bá ṣe pé Jésù àti Ọlọ́run dọ́gba kí ó tó kú, tí Ọlọ́run sì tún wá gbé e sí ipò gíga, ṣé ìyẹn ò ní gbé Jésù ga ju Ọlọ́run lọ? Ǹjẹ́ o rò pé ẹnikẹ́ni wà tó ju Ọlọ́run lọ?

Sadé: Kò sí. Kò tiẹ̀ lè ṣeé ṣe.

Kẹ́mi: Èmi náà gbà bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí wọ̀nyí, ṣé a wá lè sọ pé Bíbélì fi kọ́ni pé Jésù ni Ọlọ́run?

Sadé: Rárá o, kò rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé Ọmọ Ọlọ́run ni.

Kẹ́mi: Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Sadé, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ipò ọ̀wọ̀ tó ga gan-an ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé Jésù sí. A gbà gbọ́ pé bó ṣe kú gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún gbogbo àwọn olódodo èèyàn láti rí ìgbàlà.

Sadé: Èmi náà gbà bẹ́ẹ̀.

Kẹ́mi: Nígbà náà, o lè máa wá rò ó pé, ‘Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a mọrírì bí Jésù ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa?’ *

Sadé: Èmi náà ti ń ro ọ̀rọ̀ yẹn.

Kẹ́mi: Bóyá mo lè pa dà wá fi ìdáhùn rẹ̀ nínú Bíbélì hàn ẹ́. Ṣé wàá wà nílé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀?

Sadé: Bẹ́ẹ̀ ni, màá wà nílé.

Kẹ́mi: Ó dára bẹ́ẹ̀. Màá pa dà wá sọ́dọ̀ rẹ. Ó dàbọ̀ o.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?