Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Lo Ìfaradà

Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Lo Ìfaradà

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn

Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Lo Ìfaradà

JÓSẸ́FÙ tún gbé ẹrù míì sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Fojú inú wò ó bó ṣe yíjú wo abúlé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn, tó wá fọwọ́ gbá ìdí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n di ẹ̀rù lé náà pẹ́pẹ́, kí ó lè máa lọ. Ó dájú pé á máa ro bí ìrìn àjò wọn yìí ṣe jìnnà tó. Ilẹ̀ Íjíbítì lọ́hùn-ún! Á máa rò ó pé òun ń lọ sáàárín àwọn tí òun kò mọ̀ rí, tí èdè wọn àti àṣà wọn sì yàtọ̀. Báwo ni gbogbo àyípadà yẹn ṣe máa bá ìdílé òun kékeré yìí lára mu?

Kò rọrùn fún Jósẹ́fù láti sọ ìròyìn burúkú náà fún Màríà aya rẹ̀ àtàtà, àmọ́ Jósẹ́fù ṣọkàn akin, ó sì sọ ọ́. Ó sọ ohun tó rí nínú àlá fún un pé áńgẹ́lì kan wá jíṣẹ́ Ọlọ́run fún òun pé Hẹ́rọ́dù Ọba fẹ́ gbẹ̀mí Jésù, ọmọ wọn kékeré náà! Pé àfi kí wọ́n yáa jáde kúrò nínú ìlú yẹn kíákíá! (Mátíù 2:13, 14) Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá Màríà gan-an. Báwo lẹ́nì kan ṣe lè fẹ́ gbẹ̀mí ọmọ òun jòjòló tí kò tíì dá nǹkan kan mọ̀? Màríà àti Jósẹ́fù kò mọ ohun tó lè fà á. Àmọ́, wọ́n ṣáà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọ́n sì múra láti lọ.

Nígbà tí àwọn èèyàn ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣì ń sùn, láìmọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, Jósẹ́fù mú Màríà àti Jésù, wọ́n rọra yọ́ jáde kúrò nílùú ní òru. Bí Jósẹ́fù ṣe ń mú wọn lọ sí Íjíbítì ní ìhà gúúsù, tí ojú sì ń mọ́ bọ̀ ní ìlà-oòrùn, ó ṣeé ṣe kí ó máa ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí fún wọn lọ́hùn-ún. Á máa rò ó pé, ‘Báwo ni òun káfíńtà lásánlàsàn ṣe fẹ́ dàábò bo ìdílé òun kúrò lọ́wọ́ irú ọba alágbára yẹn? Ṣé òun máa lè pèsè fún ìdílé òun báyìí? Ṣé òun máa lè fara da gbogbo nǹkan tó máa jẹ́ kí òun lè ṣe iṣẹ́ ńlá tí Jèhófà Ọlọ́run gbé lé òun lọ́wọ́, pé kí òun bójú tó ọmọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí kí òun sì tọ́ ọ dàgbà?’ Ó dájú pé ojúṣe ńlá ń bẹ níwájú Jósẹ́fù láti ṣe. Bí a ṣe fẹ́ wo bí Jósẹ́fù ṣe borí àwọn ìpèníjà wọ̀nyí, gbogbo wa la máa rí ìdí tó fi yẹ kí àwọn bàbá àti gbogbo wa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù.

Jósẹ́fù Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀

Ní ohun tó ti lé lọ́dún kan sẹ́yìn ni ìgbésí ayé Jósẹ́fù ti yí pa dà pátápátá ní Násárétì ìlú rẹ̀, ní ìgbà tí òun àti Màríà ọmọ Hélì jọ ń fẹ́ra sọ́nà. Jósẹ́fù mọ̀ pé Màríà jẹ́ ọmọbìnrin tí kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì dúró sán-ún. Àfi bó ṣe wá gbọ́ pé ó ti lóyún! Jósẹ́fù fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́ kí àwọn èèyàn máa bàa kàn án lábùkù. * Àmọ́ áńgẹ́lì Jèhófà fara han Jósẹ́fù nínú àlá, ó sì ṣàlàyé fún un pé oyún tí Màríà ní jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Ó sì sọ fún un pé ọmọ tí Màríà máa bí ni yóò “gba àwọn èèyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Ó wá fi Jósẹ́fù lọ́kàn balẹ̀ pé: “Má fòyà láti mú Màríà aya rẹ sí ilé.”—Mátíù 1:18-21.

Ohun tí Jósẹ́fù ọkùnrin olódodo yìí sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ńláǹlà yìí, ìyẹn ni pé yóò máa bójú tó ọmọ tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀ yìí, àmọ́ tó jẹ́ àyànfẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò sì tọ́ ọ dàgbà. Nígbà tó yá, torí pé ó fẹ́ ṣe ìgbọràn sí àṣẹ ọba, ó mú ìyàwó rẹ̀ tó lóyún yìí wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kó lè wá forúkọ sílẹ̀. Bẹ́tílẹ́hẹ́mù yìí ló sì bí ọmọ rẹ̀ sí. *

Jósẹ́fù kò mú ìdílé rẹ̀ pa dà lọ sí Násárétì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n tẹ̀ dó sí, èyí tí kò ju ibùsọ̀ mélòó kan sí Jerúsálẹ́mù. Tálákà ni wọ́n, àmọ́ Jósẹ́fù ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti rí i pé ìyà kò jẹ Màríà àti Jésù. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé nínú ilé kékeré kan. Nígbà yẹn, Jésù kì í ṣe ìkókó mọ́, ó ṣeé ṣe kó ti pé ọmọ ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àkókò yìí gan-an ni ìgbésí ayé ṣàdédé yí pa dà fún wọn.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn ọkùnrin kan tó jẹ́ awòràwọ̀ láti ìlà oòrùn, bóyá láti ìyànníyàn Bábílónì, wá kí wọn. Ìràwọ̀ kan ló dárí wọn wá sílé Jósẹ́fù àti Màríà, wọ́n sì ní ọmọ kan tó máa di ọba àwọn Júù ni àwọn wá wò. Àwọn ọkùnrin yẹn sì bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún wọn.

Bóyá wọ́n mọ̀ àbí wọn kò mọ̀, ṣe ni àwọn awòràwọ̀ yẹn tipa bẹ́ẹ̀ kó Jésù ọmọ kékeré náà sínú ewu ńlá. Kàkà kí ìràwọ̀ tí wọ́n rí yẹn kọ́kọ́ darí wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Jerúsálẹ́mù ló darí wọn lọ. Ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ fún Hẹ́rọ́dù ọba búburú yẹn pé àwọn ń wá ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí tí yóò di ọba àwọn Júù, èyí tó mú kí orí òjòwú ọba yẹn kanrin.—Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . . Ta ló Rán ‘Ìràwọ̀’ Náà?” ní ojú ìwé  29.

Àmọ́, ó dùn mọ́ni pé agbára tó ju ti Hẹ́rọ́dù lọ ló ń darí ọ̀rọ̀ ọmọ náà, bí a ṣe máa rí i níwájú. Àwọn ọkùnrin yẹn kó àwọn ẹ̀bùn kalẹ̀ fún wọn, wọn kò sì béèrè ohunkóhun pa dà lọ́wọ́ ìdílé Jósẹ́fù. Ẹ ò rí i pé ó máa ya Jósẹ́fù àti Màríà lẹ́nu pé àwọn kàn dédé dẹni tó ní “wúrà àti oje igi tùràrí àti òjíá” tó jẹ́ àwọn nǹkan olówó iyebíye! Àwọn awòràwọ̀ náà ní in lọ́kàn láti pa dà lọ sọ ibi tí ọmọ náà wà fún Hẹ́rọ́dù Ọba. Ṣùgbọ́n, Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó pàṣẹ fún àwọn awòràwọ̀ yẹn lójú àlá pé kí wọ́n gba ọ̀nà míì pa dà máa lọ sí ilé wọn.—Mátíù 2:1-12.

Kété lẹ́yìn tí àwọn awòràwọ̀ náà kọrí sílé, áńgẹ́lì Jèhófà fara han Jósẹ́fù, ó sì kìlọ̀ fún un pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì sá lọ sí Íjíbítì, kí o sì dúró níbẹ̀ títí èmi yóò fi bá ọ sọ̀rọ̀; nítorí Hẹ́rọ́dù ti fẹ́ máa wá ọmọ kékeré náà káàkiri láti pa á run.” (Mátíù 2:13) Èyí ló jẹ́ kí Jósẹ́fù yára ṣègbọràn ní kíá, bí a ṣe sọ níṣàájú. Ààbò ọmọ rẹ̀ ló jẹ ẹ́ lógún jù, torí náà, ó kó ìdílé rẹ̀ gba ilẹ̀ Íjíbítì lọ. Nígbà tí àwọn awòràwọ̀ yẹn sì ti fún ìdílé rẹ̀ ní àwọn ẹ̀bùn tó ṣeyebíye, wọ́n ti ní àwọn ohun tí wọ́n lè lò ní ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n ń lọ.

Nígbà tó yá, àwọn tó kọ ìtàn àròṣọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu sínú ìwé àpókírífà ṣe àbùmọ́ lóríṣiríṣi nípa ìrìn àjò wọn lọ sí Íjíbítì yìí. Wọ́n ní Jésù ọmọ kékeré náà ṣe iṣẹ́ ìyanu tó mú kí ìrìn àjò náà kúrú sí i àti pé wọ́n pàdé àwọn ọlọ́ṣà lọ́nà, àmọ́ ó sọ agbára wọn dòfo, pé ó tiẹ̀ mú kí igi ọ̀pẹ déètì tẹrí wálẹ̀ kí ìyá rẹ̀ lé mú lára èso orí rẹ̀. * Lóòótọ́ , ìrìn àjò tí wọ́n rìn yẹn jìnnà, kò sì rọrùn àti pé wọn kò tiẹ̀ mọ ibi tí ìrìn àjò náà lè já sí.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni àwọn òbí lè rí kọ́ lára Jósẹ́fù. Kò lọ́ tìkọ̀ láti dáwọ́ iṣẹ́ tó ń ṣe dúró, ó sì tún pa ìdẹ̀ra tirẹ̀ tì láti lè dáàbò bo ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ ewu. Ó ṣe kedere pé ó ka ìdílé rẹ̀ sí ohun tí Jèhófà dìídì fi síkàáwọ́ òun láti bójú tó. Lónìí, inú ayé eléwu làwọn òbí tí ń tọ́ ọmọ wọn, ìyẹn ayé tó kún fún onírúurú àwọn nǹkan tó ń wu àwọn ọmọ léwu, tó fẹ́ kó ìwà ìbàjẹ́ ràn wọ́n tàbí kó tiẹ̀ bayé wọn jẹ́ pátápátá. Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa gan-an ni àwọn ìyá àti bàbá tí wọ́n tètè máa ń gbé ìgbésẹ̀ tó tọ́ bíi ti Jósẹ́fù ń ṣe, tí wọ́n sì máa ń sa gbogbo ipá wọn láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè pa wọ́n lára bẹ́ẹ̀!

Jósẹ́fù Pèsè fún Ìdílé Rẹ̀

Ó jọ pé ìdílé rẹ̀ kò dúró pẹ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì, torí pé kò pẹ́ tí áńgẹ́lì tún fi sọ fún Jósẹ́fù pé Hẹ́rọ́dù ti kú. Jósẹ́fù sì mú ìdílé rẹ̀ pa dà sí orílẹ̀-èdè wọn. Tipẹ́tipẹ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ kan ti sọ pé Jèhófà yóò pe ọmọkùnrin rẹ̀ “láti Íjíbítì.” (Mátíù 2:15) Jósẹ́fù kópa nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, àmọ́ ìlú wo ló máa wá kó ìdílé rẹ̀ lọ báyìí?

Jósẹ́fù jẹ́ ẹni tó máa ń kíyè sára gan-an. Ó bẹ̀rù ẹni tó jọba lẹ́yìn Hẹ́rọ́dù, ìyẹn Ákíláọ́sì, tí òun náà jẹ́ ìkà àti apànìyàn bíi ti Hẹ́rọ́dù. Ọlọ́run wá darí Jósẹ́fù kí ó kó ìdílé rẹ̀ pa dà lọ sí Násárétì ìlú rẹ̀ tó wà ní Gálílì, èyí tó jìnnà sí Jerúsálẹ́mù àti gbogbo wàhálà ibẹ̀. Ibẹ̀ ni òun àti Màríà ti tọ́ àwọn ọmọ wọn.—Mátíù 2:19-23.

Wọ́n jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn, àmọ́ nǹkan ò rọrùn. Nígbà tí Bíbélì pe Jósẹ́fù ní káfíńtà, ó lo ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí onírúurú iṣẹ́ tí wọ́n ń fi igi ṣe, irú bíi gígé igi gẹdú, gbígbé wọn lọ sí ibi tí wọ́n ti máa lò ó, títọ́jú rẹ̀ láti jẹ́ kó gbẹ lọ́nà tó fi máa ṣeé là àti lílo àwọn igi náà láti fi kọ́ ilé, láti fi ṣe ọkọ̀ ojú omi, afárá, kẹ̀kẹ́ ẹrù, àgbá kẹ̀kẹ́, àjàgà àti onírúurú àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ lóko. (Mátíù 13:55) Iṣẹ́ tó gba agbára gan-an ni iṣẹ́ yìí. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, káfíńtà sábà máa ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀bá ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀ tàbí ní ṣọ́ọ̀bù tó bá kọ́ síwájú ilé rẹ̀.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé oríṣiríṣi ohun èlò tí bàbá Jósẹ́fù fún un ló ń lò. Yóò lo àwọn irinṣẹ́ bí irin kọdọrọ, okùn ìwọ̀n, ẹfun láti fi fa ìlà, àáké tí wọ́n fi ń bó èèpo igi, ayùn, àáké, òòlù onírin, òòlù onígi, ohun tí wọ́n fi ń gbẹ́ nǹkan, irin tí wọ́n fi ń lu ihò sára igi, àti onírúurú àtè àti ìṣó.

Fojú inú wo bí Jésù tó jẹ́ ọmọdé yóò ṣe máa wo bàbá rẹ́ tó jẹ́ alágbàtọ́ yìí bó ṣe ń ṣiṣẹ́. Ṣe ló máa tẹjú mọ́ bí Jósẹ́fù ṣe ń ṣe àwọn nǹkan. Á ti kíyè sí i pé ẹni tó lágbára ni Jósẹ́fù, torí á máa wo apá rẹ̀ tó fẹ̀, tó sì ní iṣan tó lágbára, á sì tún ti kíyè sí bó ṣe ń fi ọwọ́ rẹ̀ dá àrà àti bó ṣe ń fi ojú ọnà wo nǹkan. Ó ṣeé ṣe kó ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọ rẹ̀ kékeré yìí ní bí yóò ṣe máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, irú bó ṣe lè fi awọ ẹja tó ti gbẹ ha ara igi títí igi náà fi máa dán. Ó ṣeé ṣe kó tún ti fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín oríṣiríṣi àwọn igi tó lè lò hàn án, irú bíi igi síkámórè, igi óákù àti igi ólífì.

Jésù yóò tún ti mọ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ alágbára yẹn tó ń lò láti fi gé àwọn igi, tó fi ń la igi, tó fi ń gbá igi wọnú ara wọn, náà ló ń lò láti fi gbá òun mọ́ra láti tu òun nínú, àti ìyá òun àti àwọn àbúrò òun. Nígbà tó yá, Jósẹ́fù àti Màríà ní ìdílé tó tóbi, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n bí ọmọ mẹ́fà míì yàtọ̀ sí Jésù. (Mátíù 13:55, 56) Ṣe ni Jósẹ́fù ní láti túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ kára láti lè bojú tó gbogbo wọ́n kó sì lè pèsè ohun tí wọ́n máa jẹ.

Àmọ́ ṣá o, Jósẹ́fù rí i pé bí òun ṣe máa pèsè fún ìdílé òun nípa tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù. Torí náà, ó ń lo àkókò láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn òfin rẹ̀. Òun àti Màríà tún máa ń mú àwọn ọmọ wọn lọ sí sínágọ́gù déédéé, ní ibi tí wọ́n ti máa gbọ́ bí wọ́n ṣe ń ka òfin Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣàlàyé rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni Jésù á máa béèrè tí wọ́n bá kúrò níbẹ̀, tí Jósẹ́fù á sì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun dáhùn gbogbo ohun tí ọmọ náà fẹ́ mọ̀ nípa ìjọsìn Ọlọ́run. Lọ́dọọdún, Jósẹ́fù tún máa ń mú ìdílé rẹ̀ lọ sí ibi àjọ̀dún ní Jerúsálẹ́mù. Ó lè gba Jósẹ́fù ní ọ̀sẹ̀ méjì kí òun àti ìdílé rẹ̀ tó lè rin ìrìn àjò tàlọ-tàbọ̀ tó jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà méjìléláàádọ́fà àti ààbọ̀ [112.65], kí wọ́n sì tún ṣe àjọ̀dún Ìrékọjá tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún yẹn.

Àwọn Kristẹni tó jẹ́ olórí ìdílé lónìí náà máa ń ṣe bákan náà. Wọ́n máa ń rí i pé àwọn ráyè gbọ́ tàwọn ọmọ wọn, bí wọ́n ṣe máa tọ́ wọn lọ́nà Ọlọ́run ni wọ́n máa ń fi ṣáájú ohun gbogbo, títí kan wíwá nǹkan amáyédẹrùn. Wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti rí i pé àwọn mú àwọn ọmọ lọ sí gbogbo ìpàdé Kristẹni, yálà àwọn ìpàdé ìjọ tàbí àwọn ìpàdé ńlá. Bíi ti Jósẹ́fù, wọ́n mọ̀ pé kó sì ohun míì tó tún lè ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní púpọ̀ tó ìyẹn.

“Nínú Ìdààmú-Ọkàn”

Nígbà tí Jésù wà ní ọmọ ọdún méjìlá, Jósẹ́fù mú ìdílé rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù bó ṣe sábà máa ń ṣe nígbà Ìrékọjá. Lákòókò àjọ̀dún yìí, ṣe ni àwọn ìdílé ńlá jọ máa ń wọ́ tìrí-tìrí lọ sí Jerúsálẹ́mù, lásìkò ìrúwé tí ewéko pápá máa ń tutù yọ̀yọ̀. Tí wọ́n bá dé àgbègbè ilẹ̀ gbígbẹ nítòsí ibi ìgòkè wọ ìlú Jerúsálẹ́mù tó wà níbi gíga, ọ̀pọ̀ nínú wọn á bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn orin ìgòkè tó wà nínú ìwé Sáàmù. (Sáàmù 120-134) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni ogunlọ́gọ̀ èrò máa ń rọ́ kún inú ìlú ńlá náà. Lẹ́yìn àjọ̀dún yẹn, àwọn ìdílé náà àti gbogbo èrò tí wọ́n jọ wá máa tún kọrí sọ́nà ìlú wọn pa dà. Bóyá ọ̀pọ̀ nǹkan míì gbàfiyèsí Jósẹ́fù àti Màríà, tí wọ́n sì ti rò pé Jésù ń bá àwọn èrò tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn rìn bọ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rin ìrìn àjò odindi ọjọ́ kan kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ wá rí i pé ọ̀ràn ńlá ti ṣẹlẹ̀, pé Jésù ti dàwátì!—Lúùkù 2:41-44.

Nínú ìdààmú, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tún rin gbogbo ibi tí wọ́n gbà kọjá pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Fojú inú wo bí gbogbo ìlú yẹn yóò ṣe dá páropáro lójú wọn bí wọ́n ṣe ń gba àárín ìgboro lọ, tí wọ́n sì ń pe orúkọ Jésù ọmọ wọn tí wọ́n ń wá. Wọ́n á máa rò ó pé ibo lọmọ náà lè wà? Nígbà tó máa fi di ọjọ́ kẹta tí wọ́n ti ń wá ọmọ yẹn, ṣé Jósẹ́fù kò ti ní máa rò ó pé kí la tí ń gbọ́ irú èyí sí, pé òun kò lè bójú tó ọmọ tí Jèhófà dìídì fi sí ìkáwọ́ òun? Níkẹyìn, wọ́n kọrí sí tẹ́ńpìlì. Wọ́n ń wá a kiri títí wọ́n fi kan yàrá kan tí àwọn ọ̀mọ̀wé, tó mọ tinú tòde Òfin Mósè kóra jọ sí, tí wọ́n sì rí Jésù láàárín wọn níbẹ̀! Ẹ wo bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe máa mí kanlẹ̀, tí ara á sì tù wọ́n!—Lúùkù 2:45, 46.

Jésù jókòó sáàárín wọn ní tiẹ̀, ó ń gbọ́ ohun tí àwọn ọ̀mọ̀wé yẹn ń sọ, ó sì ń béèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ wọn. Ẹnu ya àwọn ọkùnrin náà sí òye ọmọ yẹn àti àwọn ìdáhùn tó ń fún wọn. Ìyàlẹ́nu ńlá gbáà nìyẹn máa jẹ́ fún Màríà àti Jósẹ́fù. Nínú àkọsílẹ̀ yẹn, Jósẹ́fù kò sọ ohunkóhun. Ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ ló jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn àwọn méjèèjì. Ó ní: “Ọmọ, èé ṣe tí o fi hùwà sí wa lọ́nà yìí? Kíyè sí i, baba rẹ àti èmi ti ń wá ọ nínú ìdààmú-ọkàn.”—Lúùkù 2:47, 48.

Bí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fi ìwọ̀nba gbólóhùn mélòó kan wẹ́rẹ́ ṣàpèjúwe ohun tójú àwọn òbí máa ń rí lára ọmọ títọ́ nìyẹn. Wàhálà ọmọ títọ́ máa ń pọ̀ gan-an, kódà tí ọmọ yẹn bá jẹ́ ẹni pípé pàápàá! Ọmọ títọ́ nínú ayé eléwu tá a ń gbé lónìí lè fa “ìdààmú-ọkàn” tó pọ̀ fún àwọn òbí, àmọ́ ìtùnú ló máa jẹ́ fún àwọn bàbá àti ìyá tí wọ́n bá ń fi sọ́kàn pé Bíbélì náà ti fi hàn pé àwọn òbí máa ń ní irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀.

Ó dára tó jẹ́ pé Jésù wà níbì kan ṣoṣo láyé yìí tó ti lè mọ̀ ọ́n lára pé òun túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Baba òun tó wà lọ́run, tó sì ń kọ́ gbogbo ohun tó lè rí kọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi dá àwọn òbí rẹ̀ lóhùn bó ṣe rò gẹ́lẹ́ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ní láti máa wá mi? Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?”—Lúùkù 2:49.

Ó dájú pé Jósẹ́fù máa ro ọ̀rọ̀ yẹn lọ́pọ̀ ìgbà. Bóyá ni kò ní jẹ́ pé àwọn gbólóhùn tó jáde lẹ́nu Jésù yẹn máa wú u lórí gan-an. Ó ṣe tán, ó ti ṣe ọ̀pọ̀ akitiyan láti kọ́ ọmọ tó ń ṣe alágbàtọ́ rẹ̀ yìí kó lè ní irú èrò bẹ́ẹ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run. Nígbà yẹn tí Jésù ṣì wà lọ́mọdé, ó ti mọ bí ìfẹ́ “baba” ṣe máa ń rí sí ọmọ, pàápàá látinú ọwọ́ tí Jósẹ́fù fi mú ọ̀rọ̀ òun alára.

Tó bá jẹ́ pé bàbá ni ìwọ náà, o kò rí i pé àǹfààní ńlá lo ní láti kọ́ ọmọ rẹ kó lè lóye ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ bàbá onífẹ̀ẹ́ tó ń dáàbò bo ọmọ rẹ̀? Tó bá jẹ́ pé ìwọ kọ lo bí ọmọ tí ò ń tọ́ tàbí alágbàtọ́ ni ọ́, rántí àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, kó o mọ̀ pé ọmọ yàtọ̀ sí ọmọ, kí o sì ka olúkúlùkù wọn sí ọmọ àtàtà. Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba wọn ọ̀run.

Jósẹ́fù Lo Ìfaradà

Ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ni Bíbélì tún mẹ́nu kàn nípa ìgbésí ayé Jósẹ́fù, àmọ́ ó yẹ́ ká fún ohun tó sọ ní àfiyèsí gidigidi. A kà pé Jésù “sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn,” ìyẹn àwọn òbí rẹ̀. A tún rí i kà pé “Jésù sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n àti ní ìdàgbàsókè ti ara-ìyára àti ní níní ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.” (Lúùkù 2:51, 52) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀ nípa Jósẹ́fù? Ohun tó pọ̀ ni. A kẹ́kọ̀ọ́ pé Jósẹ́fù ń bá a lọ láti máa mú ipò iwájú ní agbo ilé rẹ̀, torí pé ọmọkùnrin rẹ̀ pípé bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ bàbá rẹ̀, ó sì fi ara rẹ̀ sábẹ́ rẹ̀.

A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù ń ní ìtẹ̀síwájú nínú ọgbọ́n. Ó dájú pé Jósẹ́fù á ti ṣe gudugudu méje nínú ìtẹ̀síwájú ọmọkùnrin rẹ̀ yìí. Láyé ìgbà yẹn, òwe kan ti wà tipẹ́tipẹ́ láàárín àwọn Júù. Wọ́n máa ń sọ pé àwọn ọkùnrin tí ayé bá dẹ̀ lọ́rùn ló lè di ọlọ́gbọ́n èèyàn, pé àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ bíi káfíńtà, àgbẹ̀, àti alágbẹ̀dẹ “kò lè mọ ẹ̀tọ́ àti ìdájọ́ òdodo; wọn kò sì gbọ́dọ̀ mí fín níbi tí àwọn èèyàn bá ti ń pòwe.” Nígbà tí Jésù dàgbà, ó fi hàn pé àṣìpa òwe gbáà ni òwe yẹn. Torí pé láti ìgbà tí Jésù ti wà ní kékeré ni ó ti ń gbọ́ tí bàbá tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀ ti ń kọ́ agbo ilé rẹ̀ nípa “ẹ̀tọ́ àti ìdájọ́ òdodo” Jèhófà lọ́nà tó jáfáfá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé káfíńtà lásán ni! Ó sì dájú pé á ti ṣe bẹ́ẹ̀ ní àìmọye ìgbà.

A tún ti rí ipa tí Jósẹ́fù kó nínú ìdàgbàsókè Jésù. Ó bọ́ Jésù dáadáa, ìyẹn ló jẹ́ kí ó dàgbà di géńdé ọkùnrin tí ara rẹ̀ le dáadáa. Síwájú sí í, Jósẹ́fù tún kọ́ ọmọ rẹ̀ ní iṣẹ́ ọwọ́ títí tó fi mọ iṣẹ́ náà dáadáa. Kì í ṣe ọmọ káfíńtà nìkan ni àwọn èèyàn mọ Jésù sí, wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí “káfíńtà náà.” (Máàkù 6:3) Torí náà, Jósẹ́fù tọ́ Jésù ní àtọ́yanjú. Ńṣe ló yẹ kí àwọn olórí ìdílé náà fara wé Jósẹ́fù, kí wọ́n pèsè fún àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì tọ́ wọn títí wọ́n á fi dẹni tó lè gbọ́ bùkátà ara wọn.

Tí a bá ka Bíbélì dé ibi tí Jésù ti ṣe ìrìbọmi ní ọmọ ọgbọ̀n ọdún, àá rí i pé Bíbélì kò tún sọ nǹkan kan míì mọ́ nípa Jósẹ́fù. Ẹ̀rí fi hàn pé Màríà ti di opó nígbà tí Jésù fi máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Wo àpótí náà “Ìgbà wo Ni Jósẹ́fù Kú?” ní ojú ìwé 27.) Síbẹ̀, Jósẹ́fù ti ṣe gudugudu méje, yààyàà mẹ́fà, ó ti fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ ní ti bí èèyàn ṣe ń jẹ́ bàbá tó dáàbò bo ìdílé rẹ̀, tó ń pèsè fún wọn, tó sì fi ìfaradà ṣe ojúṣe rẹ̀ dópin. Ohun tó ti dára jù ni pé kí gbogbo bàbá, olórí ìdílé, àní gbogbo Kristẹni pátá, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Láyé ìgbà yẹn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojú ẹni tó ti ṣègbéyàwó ni wọ́n máa fi ń wo àwọn tó bá ti di àfẹ́sọ́nà.

^ Bíbélì fi hàn pé ẹ̀yìn ìgbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi ló ṣe iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́. (Jòhánù 2:1-11) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ìwé ìhìn rere ti àpókírífà, wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Ti Àpókírífà, Ǹjẹ́ Ìtàn Jésù Tí Bíbélì Kò Sọ Ni Lóòótọ́?” ní ojú ìwé 18.

[Àpòtí tó wà ní ojú ìwé 27]

Ìgbà Wo Ni Jósẹ́fù Kú?

A mọ̀ pé Jósẹ́fù ṣì wà láàyè nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá. Ìgbà tí ọ̀pọ̀ ọmọ àwọn Júù bá wà ní ọjọ́ orí yẹn ni wọ́n sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ iṣẹ́ bàbá wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì fi máa di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, wọ́n á di ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ lábẹ́ bàbá wọn. Ó jọ pé Jósẹ́fù gbé ayé pẹ́ díẹ̀, débi tó fi lè kọ́ Jésù tí òun náà sì di káfíńtà. Ǹjẹ́ Jósẹ́fù ṣì wà láyé nígbà tí Jésù di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? Kò dájú rárá. Nítorí pé Bíbélì dárúkọ ìyá Jésù, àwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin àti àwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin, pé wọ́n wà láàyè ní gbogbo ìgbà yẹn, àmọ́ kò sọ nǹkan kan nípa Jósẹ́fù ní tiẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí àwọn kan pe Jésù ní “ọmọkùnrin Màríà,” tí wọn kò sọ pé ọmọkùnrin Jósẹ́fù. (Máàkù 6:3) Bíbélì tún sọ pé Màríà ṣe àwọn nǹkan kan, àti pé ó dá àwọn ìpinnu ṣe láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ lọ ọkọ kankan. (Jòhánù 2:1-5) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì obìnrin kì í sábà ṣe bẹ́ẹ̀, àyàfi tó bá jẹ́ opó. Paríparì rẹ̀ ni pé nígbà tí Jésù ń kú lọ, àpọ́sítélì Jòhánù ló fa ìyá rẹ̀ lé lọ́wọ́. (Jòhánù 19:26, 27) Kì bá má ti sí ìdí fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé Jósẹ́fù ṣì wà láyé. Èyí jẹ́ kó ṣe kedere pé ìgbà tí Jésù ṣì wà ní ọ̀dọ́kùnrin ni Jósẹ́fù ti kú. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Jésù ni ọmọkùnrin tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n nínú ìdílé wọn, ó dájú pé òun ni yóò máa bójú tó iṣẹ́ káfíńtà tí Jósẹ́fù ń ṣe, tí yóò sì máa tọ́jú ìdílé wọn títí tó fi ṣe ìrìbọmi.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Jósẹ́fù gbé ìgbésẹ̀, ó sì fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara rẹ̀ kó lè dáàbò bo ọmọ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Jósẹ́fù ṣiṣẹ́ kára láti lè pèsè fún ìdílé rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Jósẹ́fù máa ń mú ìdílé rẹ̀ lọ sí ibi ìjọsìn déédéé ní tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Jósẹ́fù kọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ láti di Káfíńtà