Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀. Jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Jèhófà Ọlọ́run àti Mósè
Àkópọ̀: Jèhófà yan Mósè pé kí ó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.
1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA Ẹ́KÍSÓDÙ 3:1-14; 4:1-17.
Ṣàpèjúwe bí iná tó ń jó igi kékeré náà ṣe rí lójú tìrẹ.
․․․․․
Kí lo rò pé Mósè ṣe, báwo sì ni ojú rẹ̀ àti ohùn rẹ̀ ṣe rí, nígbà tó gbọ́ ohùn Ọlọ́run tó ń pè é, bó ṣe wà nínú Ẹ́kísódù 3:4?
․․․․․
Báwo ni ohùn Mósè ṣe rí nígbà tó ń béèrè àwọn ìbéèrè tó wà nínú Ẹ́kísódù 3:11, 13 àti 4:1, 10 lọ́wọ́ Jèhófà?
․․․․․
2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Lo àwọn ìwé ìwádìí míì tó o mọ̀ láti fi ṣèwádìí síwájú sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ̀rọ̀ yẹn láti fi dáhùn ìbéèrè tí Mósè béèrè nípa orúkọ Ọlọ́run? *
․․․․․
Kí lo rò pé ó fà á tí Mósè kò fi fẹ́ láti lọ sọ́dọ̀ Fáráò? (Ojútùú: Ka․․․․․
Kí lo rò pé ó fà á tí Mósè kò fi fẹ́ láti lọ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀?
․․․․․
3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀rù sábà máa ń ba èèyàn nígbà tó bá fẹ́ ṣe ohun kan tí yóò wá dà bíi pé òun kò ní lè ṣe é.
․․․․․
Bó ṣe dá Jèhófà lójú pé o lè ṣe àwọn nǹkan tó bá sọ pé kó o ṣe.
․․․․․
ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.
Àwọn nǹkan wo ló máa ń bà ọ́ lẹ́rù pé o kò ní lè ṣe nígbà tó o bá fẹ́ ṣe é?
․․․․․
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan lo lè ṣe, àwọn nǹkan wo ni Jèhófà Ọlọ́run lè sọ pé kó o ṣe?
․․․․․
4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÀWỌN ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․
Tí o bá fẹ́ ka àpilẹ̀kọ yìí tàbí o fẹ́ tẹ̀ ẹ́ jáde, lọ sí orí ìkànnì wa www.pr418.com
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org àti www.pr418.com
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ńlá àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ jáde tí o lè fi ṣèwádìí jinlẹ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀. Tí o bá fẹ́ mọ̀ sí i, gbìyànjú láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí.