Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Ẹ̀kọ́ Tí Àwọn Kristẹni Fi Ń Kọ́ni Ṣe Ń Ṣe Àwọn Ará Ìlú Láǹfààní?

Báwo Ni Ẹ̀kọ́ Tí Àwọn Kristẹni Fi Ń Kọ́ni Ṣe Ń Ṣe Àwọn Ará Ìlú Láǹfààní?

Báwo Ni Ẹ̀kọ́ Tí Àwọn Kristẹni Fi Ń Kọ́ni Ṣe Ń Ṣe Àwọn Ará Ìlú Láǹfààní?

NÍNÚ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a ti jíròrò ìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Àmọ́, báwo ni àwọn Kristẹni ṣe lè jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí ìdàgbàsókè ibi tí wọ́n ń gbé? Ọ̀nà kan tí wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n máa ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ, pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.

Àṣẹ tí Jésù pa pé kí wọ́n ‘sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn’ jọ ìtọ́ni tó fún wọn pé kí wọ́n dà bí iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ayé. (Mátíù 5:13, 14) Báwo ni wọ́n ṣe jọra? Àǹfààní wo ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe máa ṣe fún àwọn èèyàn?

Iṣẹ́ Tí Kristi Rán Wa Ń Dáàbò Boni, Ó sì Ń Lani Lóye

A máa ń fi iyọ̀ pa àwọn oúnjẹ kan àti àwọn nǹkan míì kí wọ́n má bàa bà jẹ́. Bákan náà, iṣẹ́ tí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ fún àwọn èèyàn tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè máa dáàbò bo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ìdíbàjẹ́. Àwọn tó bá tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ Jésù tí wọ́n sì fi ẹ̀kọ́ náà sílò máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìwà tó ń sọni dìbàjẹ́ lóde òní. Lọ́nà wo? Wọ́n máa mọ bí wọ́n ṣe lè yẹra fún àwọn àṣà tó ń ba ìlera jẹ́, bíi mímu sìgá tàbí àwọn nǹkan míì, ó sì máa mú kí wọ́n dẹni tó ní àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere àti ìwà rere. (Gálátíà 5:22, 23) Àwọn ànímọ́ yìí máa mú kí wọ́n dẹni tó wúlò láwùjọ. Ohun ribiribi ni àwọn Kristẹni tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ tó ń dáàbò bo àwọn èèyàn lọ́nà bẹ́ẹ̀ ń ṣe fún àgbègbè tí wọ́n ń gbé.

Kí nìdí tí Jésù tún ṣe fi àwọn Kristẹni wé ìmọ́lẹ̀? Bí òṣùpá ṣe ń gbé ìmọ́lẹ̀ tó wá látara oòrùn yọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ṣe ń gbé “ìmọ́lẹ̀” Jèhófà Ọlọ́run yọ. Wọ́n ń gbé ìmọ́lẹ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà yọ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wọn àti iṣẹ́ rere tí wọ́n ń ṣe.—1 Pétérù 2:12.

Jésù túbọ̀ tẹnu mọ́ ìjọra tó wà láàárín kéèyàn dà bí ìmọ́lẹ̀ àti kéèyàn di ọmọ ẹ̀yìn nígbà tó sọ pé: “Àwọn ènìyàn a tan fìtílà, wọn a sì gbé e kalẹ̀, kì í ṣe sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, a sì tàn sára gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn.” Kedere ni gbogbo àwọn tó bá wà nítòsí máa rí fìtílà tó ń jó tó wà lórí ọ̀pá fìtílà. Lọ́nà kan náà, kedere ló yẹ kí àwọn tó ń gbé ní àgbègbè ibi tí àwọn Kristẹni ń gbé máa rí iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ rere tí àwọn Kristẹni wọ̀nyí ń ṣe. Kí nìdí? Jésù sọ pé àwọn tó ń rí iṣẹ́ rere tí àwọn Kristẹni yìí ń ṣe máa fi ògo fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún àwọn Kristẹni náà.—Mátíù 5:14-16.

Ojúṣe Gbogbo Wa Ni

Nígbà tí Jésù sọ pé, “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé” àti pé “kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn,” gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pátá ló ń bá sọ̀rọ̀. Kì í ṣe àwọn èèyàn mélòó kan tó wà káàkiri nínú onírúurú ìsìn ló máa ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo onígbàgbọ́ ni “ìmọ́lẹ̀.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù méje, tí wọ́n ń gbé ní igba ó lè márùndínlógójì [235] ilẹ̀, gbà pé ojúṣe gbogbo àwọn lápapọ̀ ni láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn, kí wọ́n sì jíṣẹ́ tí Kristi rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fún wọn.

Kí ni ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá lé? Nígbà tí Jésù ń rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ wàásù, kò sọ fún wọn pé kí wọ́n máa wàásù nípa àtúntò ètò ìṣèlú tàbí ti àwùjọ, àjọṣe tó yẹ kó wà láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba, tàbí èròǹgbà míì táwọn èèyàn ń gbé lárugẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni lónìí ń ṣègbọràn sí ìtọ́ni Jésù ní ti pé wọ́n ń bá a nìṣó láti máa bá àwọn aládùúgbò wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìjọba kan ṣoṣo tó lè mú ètò búburú Sátánì wá sí òpin, tí yóò sì mú ayé tuntun òdodo wá.

Ní ti gidi, tá a bá ń ka àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere, a ó rí i pé ohun méjì ló ṣe kedere nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tó ń nípa lórí iṣẹ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí. A máa jíròrò méjèèjì nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Báwo ni ìwàásù àwọn Kristẹni ṣe dà bí iyọ̀?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Báwo ni ìwàásù Kristi ṣe dà bíi fìtílà níbi tó ṣókùnkùn?