Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì—Àgbẹ̀
Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì—Àgbẹ̀
“[Jésù] wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.’”—MÁTÍÙ 9:37, 38.
JÉSÙ sábà máa ń lo iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ohun èlò iṣẹ́ àgbẹ̀ láti fi ṣe àpèjúwe àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. (Mátíù 11:28-30; Máàkù 4:3-9; Lúùkù 13:6-9) Kí nìdí? Ìdí ni pé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ̀ ń ṣe. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ ló jẹ́ pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ látọjọ́ pípẹ́ ni wọ́n ṣì ń lò. Wọ́n mọyì bó ṣe máa ń pàfiyèsí sí nǹkan tí wọ́n ń ṣe lójoojúmọ́. Ó mọ bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára wọn, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì máa ń wọ̀ wọ́n lọ́kàn.—Mátíù 7:28.
A lè túbọ̀ mọyì àwọn àpèjúwe Jésù àtàwọn ìtàn míì nínú Bíbélì tá a bá mọ díẹ̀ nípa àgbẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn irè oko tó ń gbìn, irin iṣẹ́ tó ń lò àtàwọn ìṣòro tó ń bá pàdé.
Máa fojú inú wo bí àgbẹ̀ kan ṣe ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ta a yàn sínú àpilẹ̀kọ yìí, kó o sì wo ohun tó o máa rí kọ́.
Ìgbà Gbígbìn
Bí oòrùn ṣe tàn yòò láàárọ̀, àgbẹ̀ fọwọ́ bo òkè ojú, ó dúró lẹ́nu ọ̀nà, afẹ́fẹ́ tó tutù sì ń fẹ́ lóló. Òjò ti sọ ojú ilẹ̀ tó le di rírọ̀. Àkókò ti tó láti túlẹ̀. Ó gbé ohun èlò ìtúlẹ̀ fífúyẹ́ tí wọ́n fi igi ṣe lé èjìká rẹ̀, ó sì gba oko rẹ̀ lọ.
Nígbà tó dé oko, ó ko àwọn màlúù rẹ̀ jọ, ó fi àjàgà sí wọn lọ́rùn, ó sì fi ọ̀pá kẹ́sẹ́ darí wọn Lúùkù 9:62) Kì í kọjá ẹnu ààlà oko rẹ̀, ó sì máa ń lo ilẹ̀ rẹ̀ dáadáa.
lọ ṣiṣẹ́. Ohun èlò ìtúlẹ̀ tó ní irin lẹ́nu dá ẹnu lé ilẹ̀ olókùúta. Kò lè tú ilẹ̀ náà, ó kàn họ ọ́ lórí ni, ó ń kọ pooro sáàárín ebè (1). Bí àgbẹ̀ náà ṣe ń du ohun èlò ìtúlẹ̀ náà sọ́tùn-ún sósì kí ìlà tó ń kọ náà bàa lè tọ́, kì í wo ẹ̀yìn kí ìlà náà má bàa wọ́. (Nígbà tó ti túlẹ̀ náà dáadáa tó sì ní pooro, ó wá kan gbígbìn nǹkan sí i. Ó fi ọwọ́ kan gbé àpò ọkà báálì, ó sì fi ọwọ́ kejì fọ́n irúgbìn náà sọ́tùn-ún sósì (2). Àwọn ipa ọ̀nà táwọn èèyàn lè gbà wà láàárín oko náà, nítorí náà, ó rí sí i pé àwọn irúgbìn náà bọ́ sórí “erùpẹ̀ rere.”—Lúùkù 8:5, 8.
Lẹ́yìn tí àgbẹ̀ náà ti gbin irúgbìn, ó wá kan fífọ́ àwọn yẹ̀pẹ̀ tó ti dì. Ó so ẹ̀ka igi ṣóńṣó mọ́ màlúù rẹ̀, ó sì fi igi náà tú àwọn yẹ̀pẹ̀ náà ká sínú oko. Àwọn ẹyẹ máa ń ké tí wọ́n á sì máa ṣa àwọn irúgbìn jẹ kí erùpẹ̀ tó bò ó. Lẹ́yìn náà, ó mú jígà (3) láti fi tú ilẹ̀ àti láti hu àwọn èpò kúrò kí wọ́n má bàa fún irúgbìn náà pa kí wọ́n tó dàgbà.—Mátíù 13:7.
Ìgbà Ìkórè
Ọ̀pọ̀ oṣù ti kọjá. Òjò ti rọ̀. Orí ọkà báálì tó ti pọ́n ń mì lògbòlògbò nínú oòrùn, pápá náà ti funfun.—Jòhánù 4:35.
Ọwọ́ àgbẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ máa ń dí gan-an nígbà ìkórè. Ẹni tó ń kórè fọwọ́ òsì di ṣírí ọkà mú, ó sì fi dòjé tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún gé e (4). Àwọn ẹlòmíì kó o jọ, wọ́n sì dì í sí ìtí-ìtí (5), wọ́n kó o sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí kẹ̀kẹ́ ẹrù (6) tó máa gbé e lọ síbi tí wọ́n ti ń pakà ní abúlé.
Oòrùn ti mú ganrínganrín, ojú ọ̀run sì mọ́ roro. Ìdílé àgbẹ̀ jókòó sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ fúngbà díẹ̀. Wọ́n ń sọ̀rọ̀, wọ́n ń rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń jẹ àwọn oúnjẹ, bíi búrẹ́dì, ọkà gbígbẹ́, ólífì, ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ́ àti èso àjàrà. Wọ́n wá mu omi lé e lórí.—Diutarónómì 8:7.
Ní oko tó wà nítòsí, àwọn tó ń pèéṣẹ́ ń kó àwọn ọkà tó ṣẹ́ kù (7). Àwọn kan jẹ́ tálákà, wọ́n kò sì ní ilẹ̀.— Diutarónómì 24:19-21.
Lẹ́yìn náà, àgbẹ̀ náà sá àwọn ìtí sórí ilẹ̀ ìpakà tó wà ní abúlé náà. Màlúù ń fa ohun èlò Diutarónómì 25:4) Àwọn òkúta wẹẹrẹ àti ègé irin mímú wà lójú ohun èlò ìpakà náà ó sì gé àwọn ṣírí ọkà sí wẹ́wẹ́.
ìpakà tó wúwo yípo yípo (8). (Àgbẹ̀ náà dúró títí dìgbà tí afẹ́fẹ́ ìrọ̀lẹ́ dé. (Rúùtù 3:2) Ní ìrọ̀lẹ́, ó mú àmúga ẹlẹ́nu ṣóṣóró tí wọ́n fi igi ṣe tàbí “ṣọ́bìrì ìfẹ́kà” (9), ó kì í bọ abẹ́ ìtí ọkà tó ti pa, ó sì ń gbé e sókè kí afẹ́fẹ́ lè fẹ́ ẹ. (Mátíù 3:12) Àwọn ọkà náà bọ́ sórí ilẹ̀, àwọn pòròpórò náà sì fẹ́ dà nù. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fi àmúga náà gbé ọkà àti pòròpórò náà sókè títí tó fi fẹ́ gbogbo ọkà náà tán.
Nígbà tí oòrùn wọ̀, ìyàwó àgbẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sẹ́ ìdọ̀tí kúrò lára ọkà (10). Wọ́n bu ọkà tí wọ́n ti pa sínú asẹ́ láti gbọn òkúta ara rẹ̀ kúrò. Wọ́n kó àwọn ọkà báálì náà sínú apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì kó àwọn ìdọ̀tí yẹn dànù. Irè oko náà so dáadáa. Àwọn tó ń kórè náà kó díẹ̀ lára àwọn ọkà náà sínú àwọn ìkòkò kan (11). Wọ́n máa kó ìyókù síbi ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí.
Àgbẹ̀ náà na ẹ̀yìn àtàwọn iṣan rẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà, ó sì wo gbogbo oko tó wà yíká abúlé náà. Inú rẹ̀ ń dùn bó ṣe ń wo àwọn oko tó kún fún pòròpórò tí wọ́n ti gé ọkà rẹ̀ kúrò, èyí jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n ti ṣiṣẹ́ àṣekára fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Ó ń wo àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń bójú tó ọgbà àjàrà àti ólífì, pómégíránétì àti igi ọ̀pọ̀tọ́. Ẹnì kan tó ń gbẹ́lẹ̀ nínú ọgbà kékeré kan nítòsí juwọ́ sí i. Ilẹ̀ oko ibẹ̀ máa so apálá, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, ẹ̀wà, ewébẹ̀ líìkì, èso chick-pea àti àlùbọ́sà. Àgbẹ̀ náà dúró, ó gbórí sókè, ó ń wo ọ̀run, ó sì gbàdúrà ráńpẹ́ látọkànwá, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ẹ̀bùn rere tó fún òun.—Sáàmù 65:9-11.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28-30]
(Lọ wo ẹ̀dà tí a tẹ̀)