Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Lo Lè Ṣe Tí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Á Fi Dára?

Kí Lo Lè Ṣe Tí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Á Fi Dára?

Kí Lo Lè Ṣe Tí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Á Fi Dára?

KÍ LO lè ṣe tí ìgbésí ayé rẹ á fi dára? Ọ̀nà kan ni pé kó o lo ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún ẹ láti ronú nípa bí àwọn ìpinnu tó o bá ṣe nísinsìnyí ṣe máa nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀ títí lọ.

Òótọ́ ni pé, ó lè má rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn ìpinnu tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé àǹfààní ojú ẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wá. Bí àpẹẹrẹ, o lè mọ̀ pé títẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì lè mú kí ìrẹ́pọ̀ wà nínú ìdílé rẹ. (Éfésù 5:22–6:4) Àmọ́, èyí gba pé kó o máa lo àkókò pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, kí o má sì jẹ́ kí iṣẹ́, eré ìdárayá tàbí eré ìnàjú gbà ẹ́ lọ́kàn jù. Bíi ti àwọn nǹkan mìíràn ní ìgbésí ayé, o gbọ́dọ̀ pinnu yálà àǹfààní ojú ẹsẹ̀ lo fẹ́ ni tàbí àṣeyọrí tó máa wà títí lọ. Kí ló máa jẹ́ kó o lè ṣe ohun tó tọ́? Ṣe àwọn nǹkan mẹ́rin wọ̀nyí.

1 Máa Ronú Nípa Àbájáde Àwọn Ìpinnu Rẹ

Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu, ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde rẹ̀. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Tó o bá fòótọ́ inú ronú nípa àbájáde ìpinnu tó o fẹ́ ṣe, ó lè jẹ́ kó o yẹra fún ohun tó lè pa ẹ́ lára. Bákan náà, tó o bá ronú nípa àwọn àǹfààní tó wà pẹ́ títí tó o máa rí tó o bá ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu, ìyẹn máa jẹ́ kó o túbọ̀ fẹ́ ṣe ohun tó tọ́.

Bi ara rẹ pé: ‘Kí ló máa jẹ́ àbájáde ìpinnu mi lẹ́yìn ọdún kan, lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tàbí ogun ọdún pàápàá? Ipa wo ló máa ní lórí èrò àti ìlera mi? Ipa wo ni ohun tí mo bá ṣe máa ní lórí ọmọ àti ìyàwó mi àti àwọn tí mo fẹ́ràn?’ Ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù kó o bi ara rẹ ni pé: ‘Ṣé inú Ọlọ́run máa dùn sí ìpinnu tí mo bá ṣe? Ipa wo ló máa ní lórí àjọṣe mi pẹ̀lú rẹ̀?’ Nítorí Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì, ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó sì lè jẹ́ kó o rí àwọn ewu tí o kò kíyè sí.—Òwe 14:12; 2 Tímótì 3:16.

2 Gbé Ìpinnu Kọ̀ọ̀kan Yẹ̀ Wò Dáadáa

Dípò tí ọ̀pọ̀ á fi ṣèpinnu fúnra wọn, ńṣe ni wọ́n máa ń ṣe ohun tí wọ́n bá rí i pé àwọn míì ń ṣe. Àmọ́, pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ohun kan, ìyẹn ò sọ pé kí ó yọrí sí rere. Gbé ìpinnu kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò dáadáa. Wo àpẹẹrẹ Natalie. * Ó sọ pé: “Mo fẹ́ ní ọkọ rere. Àmọ́, mo rí i pé ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbésí ayé mi kò ní jẹ́ kó ṣeé ṣe. Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n gbọ́n féfé ni mò ń bá ṣọ̀rẹ́ ní iléèwé. Síbẹ̀, àwọn ìpinnu tí wọ́n ń ṣe kò dára. Ńṣe ni wọ́n kàn ń pààrọ̀ ọ̀rẹ́bìnrin tàbí ọ̀rẹ́kùnrin nígbà gbogbo. Bíi tiwọn, èmi náà ní àwọn ọ̀rẹ́kùnrin. Irú ìgbésí ayé yìí kó ìrora ọkàn tó pọ̀ bá mi.”

Natalie bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Mo rí i pé àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyọ̀, mo sì rí i pé ìgbéyàwó wọn ṣọ̀kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í yí àwọn ohun tí mo kà sí pàtàkì àti ọ̀nà ìgbésí ayé mi pa dà.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Natalie sọ pé: “Ẹni tí ìwà rẹ̀ wù mí gan-an ló wù mí láti fẹ́. Nígbà tó yá mo fẹ́ ọkùnrin kan tá a jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà. Mo gbà pé Ọlọ́run ti fún mi ní ìdílé tó dára ju ohun tí mo rò.”

3 Máa Ronú Nípa Àǹfààní Tó Máa Wà Títí Lọ

Tó o bá fẹ́ yẹra fún àǹfààní tí kò ní tọ́jọ́, ó yẹ kó o máa ronú nípa irú ọjọ́ ọ̀la tó o fẹ́ àti ohun tó o máa ṣe kí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́. (Òwe 21:5) Má ṣe máa ronú nípa àádọ́rin [70] tàbí ọgọ́rin [80] ọdún téèyàn sábà máa ń lò láyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa ronú nípa bó o ṣe máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Bíbélì ṣàlàyé pé nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù, Ọlọ́run ti ṣe ohun tó máa jẹ́ kí aráyé lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Mátíù 20:28; Róòmù 6:23) Ọlọ́run ṣèlérí pé láìpẹ́ ohun tí òun fẹ́ fún àwa èèyàn àti ayé yìí látìbẹ̀rẹ̀ máa ṣẹ. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa láǹfààní láti gbádùn ìwàláàyè títí láé nínú ayé ẹlẹ́wà tí Ọlọ́run mú bọ̀ sípò. (Sáàmù 37:11; Ìṣípayá 21:3-5) Wàá ní irú ọjọ́ ọ̀la yìí tó o bá ń ṣèpinnu tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó máa wà títí lọ.

4 Sapá Kí Ọwọ́ Rẹ Lè Tẹ Àfojúsùn Rẹ

Kí lo lè ṣe láti lè jàǹfààní nínú ìlérí ọjọ́ iwájú yẹn? Wàá kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. (John 17:3) Tó o bá ní ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì, ó máa jẹ́ kó o ní ìdánilójú pé ìlérí Ọlọ́run fún ọjọ́ iwájú máa ṣẹ. Ìdánilójú yìí máa jẹ́ kó o lè ṣe àwọn àyípadà tó bá yẹ kó o lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run.

Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Michael yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí àmujù, tí mo sì ń lo oògùn olóró. Mo wà nínú ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta kan, mo sì rò pé màá ti kú kí n tó pé ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún. Ìbínú àti ìjákulẹ̀ tí mo ní mú kí n gbìyànjú léraléra láti pa ara mi. Ó wù mí pé kí ìgbésí ayé túbọ̀ nítumọ̀, àmọ́ gbogbo ẹ̀ kò yé mi.” Nígbà tí Michael wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama, ẹnì kan tí wọ́n jọ wà nínú ẹgbẹ́ kan náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Michael pẹ̀lú gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́.

Ẹ̀kọ́ tí Michael kọ́ látinú Bíbélì mú kó yí ojú tó fi ń wo ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ pa dà. Ó sọ pé: “Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé lọ́jọ́ iwájú ayé máa pa dà di Párádísè àti pé àwọn èèyàn á máa gbé lálàáfíà, wọn kò sì ní ṣàníyàn mọ́. Mo sì wò ó pé bí ọjọ́ ọ̀la mi ṣe máa rí nìyẹn. Mó fi ṣe àfojúsùn mi láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Síbẹ̀ kò rọrùn fún mi. Kódà lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo mutí yó nígbà mélòó kan. Mo tiẹ̀ bá ọmọbìnrin kan sùn.”

Báwo ni Michael ṣe yanjú àwọn ìṣòro tó ní tó sì yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà? Ó sọ pé: “Ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà mí níyànjú pé kí n máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kí n sì máa bá àwọn tó fẹ́ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run rìn. Mo rí i pé àwọn ọ̀rẹ́ mi nínú ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta ṣì ń ṣàkóbá fún mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dà bí ìdílé mi, mi ò bá wọn ṣọ̀rẹ́ mọ́,”

Michael wá àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ rẹ̀ lè tètè tẹ̀, ó sì gbájú mọ́ àwọn ohun àkọ́múṣe tó máa mú kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ àfojúsùn rẹ̀ tó tóbi jù lọ, ìyẹn mímú ìgbésí ayé rẹ̀ bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣàkọsílẹ̀ àfojúsùn tó máa gba àkókò tó pọ̀ kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ̀ ẹ́ àti àwọn ohun tó o máa ṣe báyìí kí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́. Sọ àwọn àfojúsùn rẹ fún àwọn tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì ní kí wọ́n máa wo bó o ṣe ń ṣe sí.

Má ṣe sún kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti fifi àwọn ìtọ́ni rẹ̀ ṣèwàhù síwájú. Bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ẹni tó bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwàhù pé: “Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò . . . máa kẹ́sẹ járí.”—Sáàmù 1:1-3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.