‘Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!’
‘Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!’
Àpéjọ Àgbègbè Ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ FRIDAY
“Ní Ti Jèhófà, Ó Ń Wo Ohun Tí Ọkàn-Àyà Jẹ́”—1 SÁMÚẸ́LÌ 16:7.
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ SATURDAY
“Lára Ọ̀pọ̀ Yanturu Tí Ń Bẹ Nínú Ọkàn-Àyà Ni Ẹnu Ń Sọ” —MÁTÍÙ 12:34.
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ SUNDAY
“Fi Ọkàn-Àyà Pípé Pérépéré Sin Jèhófà”—1 KÍRÓNÍKÀ 28:9.
Ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ìgbà tí Bíbélì sọ nípa ọkàn. Lọ́pọ̀ ìgbà, Ìwé Mímọ́ máa ń sọ nípa ọkàn ìṣàpẹẹrẹ, kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ nípa ọkàn téèyàn lè fojú rí. Kí ni ọkàn ìṣàpẹẹrẹ? Ó lè tọ́ka sí ohun tí ẹni kan jẹ́ ní inú, ìyẹn ohun tí ẹnì kan ń rò, bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ̀ àti ohun tó fẹ́.
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa? Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì Ọba láti sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Bí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa ṣe rí máa ń nípa lórí irú ìgbésí ayé tí à ń gbé nísinsìnyí àti lórí bí a ṣe máa rí ìyè lọ́jọ́ iwájú. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Ọlọ́run rí ohun tó wà nínú ọkàn wa. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Irú èèyàn tá a jẹ́ ní inú, ìyẹn “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà,” ló máa pinnu ojú tí Ọlọ́run máa fi wò wá.—1 Pétérù 3:4.
Báwo la ṣe lè máa ṣọ́ ọkàn wa? A má dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó yéni yékéyéké ní àwọn àpéjọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe kárí ayé, tó máa bẹ̀rẹ̀ ní oṣù yìí. A pè ọ́ tayọ̀tayọ̀ láti wà níbẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọ yìí. * Ohun tó o máa kọ́ níbẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa hùwà lọ́nà tí yóò máa mú ọkàn Jèhófà Ọlọ́run yọ̀.—Òwe 27:11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Láti mọ ibi tó sún mọ́ ẹ jù lọ tá a ti máa ṣe àpéjọ náà, jọ̀wọ́ lọ wo ìkànnì wa www.pr418.com. O tún lè béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Fọ́tò apá ọ̀tún: Aus dem Fundus der MÜNCHNER OLYMPIAPARK GMBH, München