Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Àwọn Tó Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?

Ǹjẹ́ Àwọn Tó Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Àwọn Tó Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?

▪ Kí Jésù tó pa dà sí ọ̀run, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn, àmọ́ kò mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ nípa ìṣèlú. (Mátíù 28:18-20) Torí náà, ìlànà tí Jésù ti fún wọn ṣáájú ìgbà yẹn ni wọ́n ń tẹ̀ lé, ó ní: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Máàkù 12:17.

Báwo ni títẹ̀lé ìlànà yìí ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lè máa gbé ayé, àmọ́ tí wọn kì í ṣe apá kan rẹ̀? Báwo ni wọ́n ṣe máa mọ àwọn ohun tó jẹ́ ti Ìlú tàbí ti Késárì yàtọ̀ sí àwọn ohun tó jẹ́ ti Ọlọ́run?

Ojú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi wo ọ̀rọ̀ yìí ni pé ẹni tó bá ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú kò tẹ̀ lé ìlànà tí Jésù fi lélẹ̀. Ìwé kan tó sọ nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ ìṣèlú, ìyẹn Beyond Good Intentions—A Biblical View of Politics, sọ pé: “Pọ́ọ̀lù lo ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú Róòmù láti fi béèrè pé kí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ òun lábẹ́ òfin, àmọ́ kò lọ́wọ́ sí àwọn ọ̀ràn tó jẹ́ ti ìlú nígbà ayé rẹ̀.”

Ìlànà wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni? Ìwé náà sọ pé: “Àwọn lẹ́tà tó kọ sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láwọn ìlú pàtàkì bíi Kọ́ríńtì, Éfésù àti Róòmù pàápàá fi hàn pé kò lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìṣèlú nígbà ayé rẹ̀.” Ìwé náà tún sọ síwájú sí i pé, Pọ́ọ̀lù “sọ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa tẹrí ba fún ìjọba, àmọ́ nínú gbogbo àwọn lẹ́tà tó kọ, kò sọ ohunkóhun tó jẹ mọ́ pé kí ṣọ́ọ̀ṣì máa lọ́wọ́ nínú ìṣèlú.”—Róòmù 12:18; 13:1, 5-7.

Àwọn Kristẹni tí wọ́n gbé láyé ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù kú pàápàá kò da ojúṣe wọn sí Ọlọ́run pọ̀ mọ́ ti Ìjọba. Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ, àmọ́ wọn kì í bá wọn dá sí ọ̀ràn ìṣèlú. Ìwé Beyond Good Intentions tún sọ nípa àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni gbà pé àwọn ní láti bọ̀wọ̀ fún àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso, síbẹ̀ wọ́n gbà pé kò yẹ káwọn máa lọ́wọ́ sí àwọn ọ̀ràn ìṣèlú.”

Àmọ́ ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn tí Jésù kú, nǹkan yí pa dà. Ọ̀gbẹ́ni Charles Villa-Vicencio, tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, sọ nínú ìwé Between Christ and Caesar, pé: “Nígbà tí ètò ìṣèlú yí pa dà lábẹ́ àkóso Constantine, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló lọ́wọ́ sí àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nílùú, wọ́n wọṣẹ́ ológun, wọ́n sì lọ́wọ́ nínú ìṣàkóso ìṣèlú.” Ibo ni ọ̀rọ̀ náà wá já sí? Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin fi máa parí, àjọṣe tó wà láàárín àwọn onísìn àtàwọn olóṣèlú ti wá di ohun tí gbogbo ìlú tẹ́wọ́ gbà ní gbogbo abẹ́ àkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n ń pe ara wọn ní ọmọlẹ́yìn Kristi ṣì máa ń sọ fún àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣèlú. Àmọ́, àwọn ẹ̀sìn yìí kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni.