“Èyí Túmọ̀ Sí Ìyè Àìnípẹ̀kun”
“Èyí Túmọ̀ Sí Ìyè Àìnípẹ̀kun”
“Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—JÒHÁNÙ 17:3.
ÌMỌ̀ lè gba ẹ̀mí èèyàn là. Nígbà tí àìsàn kọ lu Nouhou ọmọ oṣù mẹ́wàá ní orílẹ̀-èdè Niger, màmá rẹ̀ tó jẹ́ olùtọ́jú àwọn aláìsàn mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Ó fún un ní àpòpọ̀ omi tó mọ́, iyọ̀ àti ṣúgà tó máa ń jẹ́ kí omi pa dà sínú ara. Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè Fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) sọ pé, bí obìnrin náà “ṣe tara ṣàṣà wá nǹkan ṣe, tí ọmọ rẹ̀ sì gba ìtọ́jú tó yẹ, ló jẹ́ kí ara ọmọ náà tètè yá.”
Ìmọ̀ Bíbélì náà lè gbẹ̀mí èèyàn là. Ẹni tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ Bíbélì, ìyẹn Mósè, sọ pé: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí fún yín, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí ìwàláàyè yín, àti pé nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni ẹ̀yin yóò mú ọjọ́ yín gùn.” (Diutarónómì 32:47) Ṣé Bíbélì lè jẹ́ kí ẹ̀mí èèyàn gùn lóòótọ́? Báwo ló ṣe túmọ̀ sí ìwàláàyè wa?
Àpilẹ̀kọ márààrún tó ṣáájú èyí nínú ìwé ìròyìn yìí ti fi hàn pé Bíbélì jẹ́ ìwé tó fakọ yọ nítorí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣeé gbára lé, ìtàn inú rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó jẹ mọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì péye, àwọn ìwé inú rẹ̀ wà níṣọ̀kan láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, àwọn ìtọ́sọ́nà inú rẹ̀ sì múná dóko. Èyí jẹ́ kó dá wa lójú ṣáká pé Bíbélì yàtọ̀ gédégbé sí àwọn ìwé yòókù. Nítorí náà, bí Bíbélì ṣe sọ pé ọ̀rọ̀ òun lè jẹ́ kí èèyàn ní ẹ̀mí gígùn, ìyẹn ìyè ayérayé, ǹjẹ́ kò ní dáa kó o fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tá a ti gbé yẹ̀ wò?
A rọ̀ ọ́ pé kí o kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí níní ìmọ̀ Bíbélì lọ́nà tó péye ṣe máa jẹ́ kó o lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn nísinsìnyí àti ayọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti jẹ́ kó o mọ bí o ṣe lè ní ìmọ̀ yìí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Bíbélì tún ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti pé òun nìkan ló dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tí àwa èèyàn sábà máa ń béèrè, lọ́nà tó ń tẹ́ni lọ́rùn. Irú ìbéèrè bíi:
• Kí nìdí tí a fi wà ní ayé?
• Kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?
• Ǹjẹ́ ìrètí kankan tiẹ̀ wà fún àwọn èèyàn mi tó ti kú?
O lè rí bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.