Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Nǹkan Kan Wà Tí Kò Ṣeé Ṣe?

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Nǹkan Kan Wà Tí Kò Ṣeé Ṣe?

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Nǹkan Kan Wà Tí Kò Ṣeé Ṣe?

ỌKỌ̀ òkun tí wọ́n pè ní Titanic, èyí tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lò fúngbà àkọ́kọ́ lọ́dún 1912 ni ọkọ̀ òkun tó tóbi jù, tí wọ́n sì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jù láyé ìgbà yẹn. Torí pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ta yọ ni wọ́n fi ṣe gbogbo nǹkan ọkọ̀ òkun náà, àwọn tó ṣe é gbà pé “kò sóhunkóhun tó lè ri ọkọ̀ náà.” Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Ìgbà ìrìn àjò àkọ́kọ́ tó máa rìn lójú òkun ló kọ lu òkìtì yìnyín kan nínú òkun Àtìláńtíìkì ti Àríwá, tó sì rì sínú agbami tòun ti nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] lára àwọn èrò tó ń kó lọ. Bí ọkọ̀ òkun tí wọ́n sọ pé ohunkóhun kò lè rì ṣe pa rẹ́ mọ́ ìsàlẹ̀ òkun láàárín wákàtí mélòó kan péré nìyẹn.

Ìdí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ń mú kí kálukú ronú pé nǹkan kan “kò lè ṣeé ṣe.” A lè sọ pé ohun kan kò ṣeé ṣe nítorí a ti gbà pé nǹkan yẹn kọjá ohun tí a lè fara dà, tàbí pé ó kọjá agbára wa, tàbí ó ré kọjá òye wa. Ọ̀pọ̀ àṣeyọrí tí àwọn èèyàn ń fi ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣe lóde òní jẹ́ ohun tí àwọn èèyàn gbà pé kó ṣeé ṣe láyé ìgbà kan. Ìdí sì ni pé láyé ìgbà yẹn, wọ́n ré kọjá ohun tí aráyé lè ṣe tàbí èyí tí wọ́n tiẹ̀ lè máa gbèrò rẹ̀ fún ọjọ́ iwájú. Àwọn nǹkan míì tí aráyé ti lè máa sọ pé kò ṣeé ṣe àní títí di àádọ́ta [50] ọdún péré sẹ́yìn, ló ti ń wáyé báyìí. Irú bíi fífi ọkọ̀ gbangba òfuurufú gbé èèyàn lọ sójú òṣùpá, rírán irú ọkọ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sí iyànníyàn pílánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ń pè ní Máàsì, kí wọ́n sì máa darí ọkọ̀ náà láti orí ilẹ̀ ayé, ṣíṣàlàyé gbogbo èròjà tó pilẹ̀ àbùdá èèyàn àti fífojú rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ lápá ibòmíì ní ìlú tàbí ní ọ̀kẹ́ àìmọye ibùsọ̀ láyé. Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ rí, ìyẹn Ronald Reagan, sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí ní ṣókí, nígbà tó ń bá àwọn ògbóǹkangí nínú onírúurú ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ̀rọ̀. Ó ní: “Ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ òléwájú nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ti sọ àwọn ohun tí aráyé sọ pé kò lè ṣeé ṣe láyé àná di nǹkan tí gbogbo èèyàn ń lò lóde òní.”

Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n John Broberck wo àwọn ohun àrà tí aráyé ń gbé ṣe báyìí, ó ní: “Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kankan kò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ohun kan kò ṣeé ṣe mọ́. Ohun tó kàn lè sọ ni pé kò dájú pé ó lè ṣẹlẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ó lè sọ pé ohun kan kò ṣeé ṣàlàyé níbi tí òye ṣì dé báyìí.” Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí sọ pé tí ohun kan bá dà bíi pé kò ṣeé ṣe lójú tiwa, “ohun kan tó yẹ ká máa ṣírò mọ́ ọ̀rọ̀ náà ni pé níwọ̀n ibi tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì wa nípa ẹ̀dá abẹ̀mí àti ohun aláìlẹ́mìí ṣì dé, orísun agbára kan wà tí a kò mọ́. Ìwé Mímọ́ wa sì fi hàn pé agbára Ọlọ́run ni orísun agbára yìí.”

Ohun Gbogbo Ló Ṣeé Ṣe Lọ́dọ̀ Ọlọ́run

Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí Ọ̀jọ̀gbọ́n Brobeck tó sọ ọ̀rọ̀ tá a fà yọ níṣàájú yìí ni Jésù ará Násárétì, táwọn èèyàn sọ pé ó jẹ́ ọkùnrin tó tóbi lọ́lá jù láyé yìí, ti sọ pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún ènìyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 18:27) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni ipá tó lágbára jù lọ ní ayé àtọ̀run. A kò lè fi ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tàbí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì díwọ̀n rẹ̀ rárá. Ẹ̀mí mímọ́ yìí lè mú kí á ṣe àwọn ohun tó ré kọjá agbára wa láti ṣe.

Àwa ẹ̀dá èèyàn sábà máa ń bá ara wa ní àwọn ipò tó lè dà bíi pé kò ṣeé ṣe fún wa láti borí. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn wa kan lè kú tàbí kí wàhálà pọ̀ nínú ìdílé wa débi tí yóò fi dà bíi pé a kò lè máa fara dà á mọ́. Irú ìgbé ayé tí à ń gbé sì ti lè kó ìbànújẹ́ tó lé kenkà bá wa débi pé a ro ara wa pin. Tí ọ̀rọ̀ náà bá wá pin wá lẹ́mìí, tí ayé sì sú wa pátápátá, kí la lè ṣe?

Bíbélì sọ fún wa pé, tí èèyàn bá nígbàgbọ́ nínú Olódùmarè, tó sì ń gbàdúrà pé kó fún òun ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tí òun alára sì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, ó lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà tí yóò fi lè borí àwọn ohun tó dà bí òkè ìṣòro tó kọjá agbára rẹ̀. Wo ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tí Jésù sọ, ó ní: “Lóòótọ́ ní mo wí fún yín pé ẹnì yòówù tí ó bá sọ fún òkè ńlá yìí pé, ‘Gbéra sọ sínú òkun,’ tí kò sì ṣiyèméjì nínú ọkàn-àyà rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó ní ìgbàgbọ́ pé ohun tí òun sọ yóò ṣẹlẹ̀, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.” (Máàkù 11:23) Kò sí ipò téèyàn ò lè fara dà tàbí èyí téèyàn ò lè máa bá yí, tí a bá jẹ́ kí agbára Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ máa darí ayé wa.

Wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tí àrùn jẹjẹrẹ pa aya rẹ̀ tí wọ́n ti jọ wà fún ọdún méjìdínlógójì [38]. Oró ńlá ni ikú aya rẹ̀ jẹ́ fún un. Ó gbà pé ìbànújẹ́ yẹn ti pọ̀ ju èyí tí òun lè máa fara dà lọ. Ó sọ pé àwọn ìgbà kan wà tó ń ṣe òun bíi pé ó sàn kí òun kú ju kí òun máa dá gbé ayé láìsí aya òun. Ó ní ayé kò nítumọ̀ fún òun mọ́, pé ṣe ló kàn máa ń dà bíi pé òun wà nínú àfonífojì ibú òjìji. Nígbà tó ronú nípa bí nǹkan ṣe rí fún un lásìkò ìgbà yẹn, ó gbà pé àdúrà tí òun gbà tomijé-tomijé àti Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ àti bí òun ṣe ń fi tọkàntọkàn wá ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí Ọlọ́run, ló ran òun lọ́wọ́ tí òun fi lè fara da ohun tí òun ti rò pé kò ṣeé ṣe.

Àárín tọkọtaya kan ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dà rú. Ọkọ rẹ̀ máa ń bínú sódì, ìwàkiwà míì sì pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ayé wá sú aya rẹ̀ pátápátá, ó sì gbìyànjú láti pa ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ mú kó jáwọ́ nínú àwọn ìwàkiwà rẹ̀, kò sì bínú sódì mọ́. Ó ya aya rẹ̀ lẹ́nu gan-an láti rí àwọn àyípadà tí ọkọ rẹ̀ ṣe yìí, torí obìnrin náà ti rò ó tẹ́lẹ̀ pé àyípadà yẹn kò ṣeé ṣe láé.

Ọkùnrin míì sọ pé lílo oògùn olóró àti ìṣekúṣe ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bayé òun jẹ́ pátápátá. Ó ní: “Mo di ìdàkudà.” Ó wá gbàdúrà tọkàntọkàn sí Ọlọ́run pé: “Olúwa, mo mọ̀ pé o wà. Jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́!” Ọlọ́run gbọ́ àdúrà rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí mú kó ṣe àwọn àyípadà tó ti dà bí pé kò lè ṣeé ṣe láé. Ó ní: “Tẹ́lẹ̀, ṣe ni mo máa ń kábàámọ̀ ṣáá, màá sì máa rò ó pé ayé mi ti bà jẹ́ pátápátá. Nígbà míì, ìbànújẹ́ á kàn dorí mi kodò. Ṣùgbọ́n, Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ kí n lè gbógun ti èròkerò wọ̀nyẹn. Tí mi ò bá rí oorun sùn lóru, màá bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo ti mọ̀ sórí. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo fi ń pàrònú rẹ́ yìí jẹ́ kí n bọ́ lọ́wọ́ èròkerò.” Ó ti dẹni tó ní ìyàwó tí wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ tayọ̀tayọ̀ báyìí. Òun àti aya rẹ̀ sì ń ṣakitiyan láti mú kí àwọn èèyàn mọ̀ dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ranni lọ́wọ́ gidigidi. Nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò lójútùú, àwọn ìgbà kan wà tó ti lè máa rò pé kò lè ṣeé ṣe fún òun láti gbé irú ìgbé ayé tó dára tí òun ń gbé báyìí.

Àwọn ìrírí yìí fi hàn pé Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára púpọ̀ àti pé ẹ̀mí Ọlọ́run lè ṣe àwọn nǹkan tá a ti lè máa rò pé kò lè ṣeé ṣe nínú ayé wa. Àmọ́, o lè sọ pé, “Ìyẹn gba ìgbàgbọ́ gidi!” Òdodo ọ̀rọ̀ nìyẹn. Ká sòótọ́, Bíbélì gan-an sọ pé “láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù [Ọlọ́run] dáadáa.” (Hébérù 11:6) Ṣùgbọ́n rò ó wò ná: Ká ní ọ̀rẹ́ rẹ àtàtà kan, bóyá tó jẹ́ ọ̀gá ilé iṣẹ́ báńkì kan, tàbí ọlọ́lá kan, sọ fún ọ pé: “Ọ̀rẹ́, fọkàn balẹ̀, má ṣèyọnu mọ́. Tí o bá nílò ohunkóhun, ṣáà wá sọ́dọ̀ mi.” Ó dájú pé irú ìlérí bẹ́ẹ̀ máa fi ọkàn rẹ balẹ̀. Àmọ́ ṣá, ó dunni pé ẹ̀dá èèyàn sábà máa ń jáni kulẹ̀. Nǹkan lè yí pa dà fún ọ̀rẹ́ rẹ yìí kó má lè mú ohun tó ń wù ú láti ṣe fún ọ yìí ṣẹ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, tí ọ̀rẹ́ yẹn bá kú, gbogbo nǹkan dáadáa tó ní lọ́kàn láti ṣe àti agbára rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ dópin láìròtẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ Ọlọ́run kò dà bí àwa èèyàn, kò sí nǹkan kan tó lè ṣàdédé yí pa dà fún un, tí kò fi ní lè mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Kò sí ohun ti Ọlọrun kò le è ṣe.”Lúùkù 1:37, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

“Ìwọ Ha Gba Èyí Gbọ́ Bí?”

Àìmọye ìṣẹ̀lẹ̀ ló wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì tó fi hàn pé òótọ́ ni pé “kò sí ohun tí Ọlọrun kò le è ṣe.” Wo àwọn àpẹẹrẹ kan.

Obìnrin ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún kan tó ń jẹ́ Sárà rẹ́rìn-ín nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un pé yóò bí ọmọkùnrin kan. Àmọ́ ó bímọ ọ̀hún lóòótọ́, ìran ọmọ náà ló sì di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó wà títí dòní. Ẹja ńlá kan gbé ọkùnrin kan mì fún odindi ọjọ́ mẹ́ta, àmọ́ ọkùnrin náà là á já ó sì wá kọ ìrírí ara rẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Jónà lorúkọ ọkùnrin yẹn. Lúùkù tó jẹ́ dókítà, tó mọ ìyàtọ̀ láàárín kí èèyàn kàn dá kú àti kí èèyàn kú pátápátá, kọ̀wé nípa bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì ṣe ṣubú láti ojú fèrèsé àjà kẹta ilé kan tó sì kú, àmọ́ tí wọ́n jí i dìde pa dà. Gbogbo ìwọ̀nyí kì í ṣe ìtàn àròsọ o. Téèyàn bá fara bálẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀kọ̀ọ̀kan ìtàn náà, èèyàn máa rí ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ ló ṣẹlẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 18:10-14; 21:1, 2; Jónà 1:17; 2:1, 10; Ìṣe 20:9-12.

Jésù sọ ọ̀rọ̀ tó yani lẹ́nu yìí fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Màtá, ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.” Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìlérí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bí ohun tí kò lè ṣeé ṣe yìí, ó wá béèrè ìbéèrè tó ń múni ronú yìí, ó ní: “Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” Ìbéèrè tó ṣì yẹ kéèyàn fara balẹ̀ ronú lé lóde òní ni.—Jòhánù 11:26.

Ìwàláàyè Títí Láé Lórí Ilẹ̀ Ayé, Ǹjẹ́ Ohun Tí Kò Lè Ṣeé Ṣe Ni?

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan kọ̀wé lẹ́yìn ìwádìí kan tí wọ́n ṣe, pé: “Ó lè máà pẹ́ mọ́ tí yóò fi ṣeé ṣe fún wa láti máa pẹ́ láyé ju ti ìsinsìnyí lọ, táá fi jẹ́ pé a óò fẹ́rẹ̀ẹ́ máa wà láàyè títí láé.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan ṣàlàyé pé kì í ṣe pé àwọn sẹ́ẹ̀lì tín-tìn-tín ara wa máa ń bà jẹ́ tàbí pé a lò wọ́n gbó tàbí pé nǹkan míì ṣe wọ́n ló ń fà á tí a fi ń kú, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jọ pé nǹkan kan tá ò mọ̀ ló máa ń dédé da iṣẹ́ àwọn ẹ̀yà inú ara wa rú tí kò fi ní ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ tàbí kó kàn paná pi. * (The New Encyclopædia Britannica) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó ń mú kí olúkúlùkù wa darúgbó ni pé, nǹkan kan wà tó máa ń bà jẹ́ nínú ibi tí àwọn ẹ̀yà ara ti ń gba ìsọfúnni tó ń darí gbogbo ètò ìṣiṣẹ́ wọn.”

Lóòótọ́ àlàyé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí dùn, àmọ́ ìdí tí Bíbélì sọ fún wa tí a fi lè gbà gbọ́ pé èèyàn lè wà láàyè títí láé, lágbára ju àlàyé èyíkéyìí látinú ọgbọ́n orí èèyàn tàbí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ. Ìdí náà ni pé Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Orísun ìwàláàyè wa, ṣèlérí pé “òun yóò gbé ikú mì títí láé.” (Sáàmù 36:9; Aísáyà 25:8) Ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́? Jèhófà ló ṣe ìlérí yìí, kò sì lè purọ́.—Títù 1:2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó o bá fẹ́ rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ẹ̀mí gígùn àti ohun tó ń fa ọjọ́ ogbó, wo àwọn àpilẹ̀kọ kan tó dá lórí rẹ̀ ní ojú ìwé 19 sí 25 nínú ìtẹ̀jáde Jí! July–September 2006. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

“Àwọn ohun tí aráyé sọ pé kò lè ṣeé ṣe láyé àná [ti] di nǹkan tí gbogbo èèyàn ń lò lóde òní.” —RONALD REAGAN

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]

Tí a bá wà nínú ipò kan tó dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ, ta ni a máa ké pè?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]

Fọ́tò NASA