Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Wúlò Fún Wa Lóde Òní

Bíbélì Wúlò Fún Wa Lóde Òní

Bíbélì Wúlò Fún Wa Lóde Òní

“Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.”—SÁÀMÙ 119:105.

KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Ìwé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lè jẹ́ ìwé tó fakọ yọ, àmọ́ ìyẹn ò fi hàn pé wọ́n lè tọ́ni sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ ìwà rere. Ó sì jẹ́ dandan láti máa ṣe àwọn àyípadà sí àwọn ìwé atọ́nà òde òní látìgbàdégbà. Àmọ́ Bíbélì sọ ní tiẹ̀ pé: “Ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa.”—Róòmù 15:4.

ÀPẸẸRẸ: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé tó dá lórí ìmọ̀ ìṣègùn, àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an lórí béèyàn ṣe lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìlera tó dáa wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Bíbélì sì tún kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Àmọ́ ó wá sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

OHUN TÍ ÌWÁDÌÍ FI HÀN: Ẹ̀mí sùúrù, níní àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa, àti jíjẹ́ ọ̀làwọ́, lè mú kí ìlera ẹni túbọ̀ dáa. Ìwé ìròyìn Journal of the American Medical Association sọ pé: “Àwọn ọkùnrin tó máa ń bínú gan-an máa ń tètè ní àrùn rọpárọsẹ̀ ju àwọn tí kì í tètè bínú lọ.” Ìwádìí tí àwọn kan ṣe fún ọdún mẹ́wàá ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà fi hàn pé àwọn àgbàlagbà tó bá ní “àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ ń kàn síra àti alábàárò tí wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ lọ̀” sábà máa ń pẹ́ díẹ̀ láyé. Lọ́dún 2008, àwọn olùṣèwádìí kan ní orílẹ̀-èdè Kánádà àti Amẹ́ríkà rí i pé “téèyàn bá ń fi owó rẹ̀ ṣoore fún àwọn èèyàn, ìyẹn máa ń fúnni ní ayọ̀ ju kéèyàn kàn máa ná an sórí ara rẹ̀ lọ.”

KÍ LÈRÒ RẸ? Yàtọ̀ sí Bíbélì, ṣé wàá lè fi gbogbo ara gbára lé ìmọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìlera tó bá wà nínú ìwé kan tó o mọ̀ pé wọ́n ti kọ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún-ún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

“Mo fẹ́ràn Bíbélì gan-an . . . torí ó ní àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò gidigidi lórí ọ̀rọ̀ ìṣègùn.”​—HOWARD KELLY, M.D., Ọ̀KAN NÍNÚ ÀWỌN TÓ JẸ́ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀTI OLÙDÁSÍLẸ̀ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌṢÈGÙN TI THE JOHNS HOPKINS UNIVERSITY SCHOOL OF MEDICINE