Coverdale Ẹni Tó Túmọ̀ Bíbélì Odindi Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Tẹ̀ Lédè Gẹ̀ẹ́sì
Coverdale Ẹni Tó Túmọ̀ Bíbélì Odindi Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Tẹ̀ Lédè Gẹ̀ẹ́sì
KÒ SÍ orúkọ ẹni tó túmọ̀ Bíbélì odindi tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì nínú Bíbélì náà. Ẹni náà ni Miles Coverdale, Bíbélì tó túmọ̀ náà sì jáde lọ́dún 1535. Nígbà yẹn, ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ń jẹ́ William Tyndale wà lẹ́wọ̀n nítorí iṣẹ́ ribiribi tó ṣe lórí títúmọ̀ Bíbélì. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni wọ́n pa ọ̀gbẹ́ni Tyndale.
Bíbélì tí ọ̀gbẹ́ni Tyndale túmọ̀ ni Coverdale wò láti fi ṣe apá kan lára Bíbélì tó túmọ̀. Ọgbọ́n wo ni ọ̀gbẹ́ni Coverdale wá dá tó fi rí Bíbélì tó túmọ̀ tẹ̀ jáde láìjẹ́ pé wọ́n pa á, nígbà tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n gbẹ̀mí àwọn atúmọ̀ Bíbélì yòókù torí pé wọ́n túmọ̀ Bíbélì? Iṣẹ́ takuntakun wo ni Coverdale ṣe?
Wọ́n Gbin Ẹ̀mí Wíwá Àtúnṣe sí I Lọ́kàn
Ìlú Yorkshire tó wà lórílẹ̀-èdè England ni wọ́n bí ọ̀gbẹ́ni Miles Coverdale sí, bóyá lọ́dún 1488. Ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì ti Cambridge ló ti gboyè jáde, wọ́n sì fi jẹ àlùfáà ìjọ Kátólíìkì lọ́dún 1514. Ọ̀gbẹ́ni Robert Barnes tó jẹ́ olùkọ́ Coverdale ló gbin ẹ̀mí wíwá àtúnṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì sí i lọ́kàn. Àmọ́ ṣe ni Barnes sá kúrò ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1528. Ọdún méjìlá lẹ́yìn náà, àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì dáná sun ọ̀gbẹ́ni Barnes tó jẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn yìí lórí òpó igi kan.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1528, Coverdale ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pé àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu bíi jíjúbà ère, ààtò ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti Gbígba Ara Olúwa, tí ẹ̀sìn Kátólíìkì ń ṣe lòdì. Torí pé ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu, ó kúrò ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó lọ gbé apá ibòmíì nílẹ̀ Yúróòpù fún ọdún méje.
Ọ̀dọ̀ William Tyndale nílùú Hamburg tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì, ni ọ̀gbẹ́ni Coverdale ń gbé. Wọ́n sì jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ torí pé àwọn méjèèjì fẹ́ láti túmọ̀ Bíbélì tí àwọn aráàlú máa lè kà. Láàárín àkókó yìí, Coverdale kọ́ béèyàn ṣe lè ṣe ìtumọ̀ Bíbélì lọ́dọ̀ Tyndale.
Àkókò Ìyípadà Tó
Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan ti bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Lọ́dún 1534, Ọba Henry Kẹjọ tàpá sí àṣẹ póòpù ìjọ Kátólíìkì tó wà ní ìlú Róòmù láì fi bò rárá. Ọba yìí náà nífẹ̀ẹ́ sí i pé kí Bíbélì wà lédè Gẹ̀ẹ́sì, kí àwọn èèyàn lè máa kà á. Kò sì pẹ́ tí Coverdale fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ńlá náà. Ọ̀gá ni Coverdale nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì, àmọ́ kò ní òye ìtumọ̀ èdè bíi ti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Tyndale tó ń tọ́ ọ sọ́nà, ẹni tí èdè Hébérù àti Gíríìkì yọ̀ mọ́ lẹ́nu dáadáa. Coverdale lo ẹ̀dà Bíbélì tó wà lédè Látìn àti Jámánì láti fi ṣe àtúnṣe Bíbélì tí Tyndale túmọ̀.
Lọ́dún kan ṣáájú kí wọ́n tó pa ọ̀gbẹ́ni Tyndale, ìyẹn ní ọdún 1535, wọ́n tẹ ìtumọ̀ Bíbélì tí Coverdale ṣe jáde ní ilẹ̀ Yúróòpù. Ó kọ ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ tó wúni lórí gan-an nípa Henry Ọba pé òun fi ìtumọ̀ Bíbélì náà júbà rẹ̀. Coverdale fi dá ọba yẹn lójú pé àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tí Tyndale ṣe kò sí nínú Bíbélì yẹn, torí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé yẹn ń dá wàhálà sílẹ̀, pàápàá bó ṣe tọ́ka sí àwọn ẹ̀kọ́ ìjọ Kátólíìkì tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ni Henry bá fọwọ́ sí i pé kí wọ́n tẹ Bíbélì náà jáde. Bó ṣe di pé àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà nìyẹn.
Lọ́dún 1537, wọ́n tẹ Bíbélì tí Coverdale ṣe jáde ní oríṣi ẹ̀dà méjì lórílẹ̀-èdè England. Lọ́dún yẹn kan náà, Henry Ọba tún fún wọn láṣẹ láti ṣe ẹ̀dà tí wọ́n pè ní Bíbélì ti Mátíù (Matthew’s Bible), èyí tí wọ́n tẹ̀ nílùú Antwerp, ìtumọ̀
Bíbélì tí Tyndale àti èyí tí Coverdale ṣe ni wọ́n sì kó pa pọ̀ sínú rẹ̀.Ọ̀gbẹ́ni Thomas Cromwell, tó jẹ́ bọ́bajíròrò pàtàkì, rí ìdí pàtàkì tó fi yẹ kí wọ́n tún ẹ̀dà Bíbélì Mátíù yẹn ṣe, ọ̀gbẹ́ni Cranmer tó jẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti ìlú Canterbury sì ti èrò náà lẹ́yìn. Ni ọ̀gbẹ́ni Thomas Cromwell bá tún rọ Coverdale pé kó ṣe àtúnṣe gbogbo ìwé ìtumọ̀ Bíbélì tó ṣe yẹn látòkè délẹ̀. Henry Ọba fàṣẹ sí ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì tuntun náà lọ́dún 1539, ó sì ní kí wọ́n kó lára rẹ̀ sínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kí àwọn èèyàn lè máa kà á. Torí bí Bíbélì náà ṣe tóbi tó, wọ́n ń pè é ní Great Bible, ìyẹn Bíbélì Ńlá. Tayọ̀tayọ̀ làwọn èèyàn jákèjádò ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi tẹ́wọ́ gba Bíbélì náà.
Ogún Tí Coverdale Fi Sílẹ̀
Lẹ́yìn tí Henry Ọba Kẹjọ kú, tí Edward Ọba Kẹfà gorí ìtẹ́, wọ́n fi Coverdale jẹ Bíṣọ́ọ̀bù ti ilé ìjọsìn ti Exeter lọ́dún 1551. Àmọ́, lọ́dún 1553 tí Ọbabìnrin Mary ti ìjọ Kátólíìkì jọba lẹ́yìn Edward Ọba, Coverdale ní láti sá lọ sí orílẹ̀-èdè Denmark. Nígbà tó yá, ó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Switzerland, ó ń bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó níbẹ̀. Ó tẹ oríṣi ẹ̀dà mẹ́ta apá ibi táwọn èèyàn ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun nínú Bíbélì, jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó sì fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lédè Látìn sínú rẹ̀ kí àwọn àlùfáà lè máa lò ó fún ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn.
Ohun tó yani lẹ́nu nínú Bíbélì tí Coverdale ṣe ni pé kò lo ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà,” tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run nínú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Tyndale lo orúkọ Ọlọ́run níbi tó ju ogún [20] lọ nínú ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tó ṣe. Ohun tí ọ̀gbẹ́ni J. F. Mozley sọ nínú ìwé náà Coverdale and His Bibles, ni pé: “Lọ́dún 1535, Coverdale kò fara mọ́ lílo ọ̀rọ̀ náà [Jèhófà] rárá.” Àmọ́ ṣá, ó pa dà wá lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta nínú Bíbélì rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Great Bible, ìyẹn Bíbélì Ńlá.
Ṣùgbọ́n Bíbélì tí Coverdale túmọ̀ ni Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tó kọ́kọ́ lo lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù, ní òkè ojú ìwé tí wọ́n ń kọ àkọlé ìwé sí. Nǹkan pàtàkì míì sì tún ni pé inú Bíbélì yẹn ni wọ́n ti kọ́kọ́ kó gbogbo ìwé Àpókírífà pa pọ̀ sí àfikún ẹ̀yìn ìwé dípò tó fi máa wà káàkiri láàárín àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.
Àwọn atúmọ̀ èdè míì lẹ́yìn Coverdale ti lo àwọn àkànlò ọ̀rọ̀ tó lò nínú ìtumọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lo gbólóhùn náà “àfonífojì òjìji ikú” tó wà nínú Sáàmù 23:4. Ọ̀jọ̀gbọ́n S. L. Greenslade sọ pé ọ̀rọ̀ náà “inú rere onífẹ̀ẹ́” tó wà ní ẹsẹ kẹfà jẹ́ “àkànlò ọ̀rọ̀ kan tó lò láti fi ìyàtọ̀ sí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí àwọn èèyàn rẹ̀ àti ìfẹ́ tó ní sí àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò àti pé ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ọlọ́run ní yìí yàtọ̀ sí àánú.” Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures—With References lo inú rere onífẹ̀ẹ́ náà, wọ́n wá fi àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé síbẹ̀ pé: “Tàbí, ‘ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.’”
Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn Bíbélì tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè England sọ pé Bíbélì Great Bible tí Coverdale túmọ̀ ni àbájáde gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe láti lè gbé Bíbélì jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì . . . bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tí Tyndale ti dáwọ́ lé ṣíṣe ìtumọ̀ Májẹ̀mú Tuntun. (The Bibles of England) Ká sòótọ́, ìtumọ̀ Bíbélì tí Coverdale ṣe ló jẹ́ kí àwọn èèyàn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ìgbà ayé rẹ̀ lè rí Bíbélì kà lédè wọn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù rèé lápá òsì, ó wà ní ojú ìwé tí wọ́n kọ àkọlé ìwé sí nínú Bíbélì tí wọ́n tẹ̀ lọ́dún 1537
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
Láti inú ìwé kan tí wọ́n pè ní Our English Bible: Its Translations and Translators
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]
Ibi tí a ti rí fọ́tò tá a lò: The Holy Scriptures of the Olde and Newe Testamente With the Apocripha láti ọwọ́ Myles Coverdale