Ǹjẹ́ Bíbélì Yàtọ̀ sí Àwọn Ìwé Yòókù?
Ǹjẹ́ Bíbélì Yàtọ̀ sí Àwọn Ìwé Yòókù?
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní . . . , kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” —2 TÍMÓTÌ 3:16, 17.
GBOGBO èèyàn kọ́ ló fara mọ́ ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ nípa Bíbélì. Ìwọ ńkọ́? Èwo nínú àwọn gbólóhùn tó wà nísàlẹ̀ yìí ló bá èrò tìrẹ nípa Bíbélì mu?
• Ìwé àkàgbádùn tó gbayì ni
• Ọ̀kan lára àwọn ìwé tí àwọn èèyàn gbà pé ó jẹ́ ìwé mímọ́ ni
• Ìwé ìtàn àlọ́ tó ń kọ́ni níwà ọmọlúwàbí ni
• Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni
Ìbéèrè kan tó jẹ mọ́ èyí ni pé, Ṣé ohun tó bá ṣáà ti wuni léèyàn lè gbà gbọ́ nípa Bíbélì? Wo ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ, ó ní: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ ni pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí wọ́n dìídì ṣe láti fi fún wa ní ìtọ́ni, láti fi tù wá nínú àti láti mú kí á lè ní ìrètí.
Ṣùgbọ́n tí Bíbélì bá jẹ́ ìwé àkàgbádùn lásán, tàbí tó kàn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tí àwọn èèyàn kà sí ìwé mímọ́, ǹjẹ́ wàá lè gbára lé àwọn ìtọ́ni inú rẹ̀ kó o sì máa lò ó láti fi tọ́ ìdílé rẹ sọ́nà, pàápàá tí ohun tó sọ bá yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ìwọ rò pé ó tọ́ láti ṣe? Tí Bíbélì bá jẹ́ ìwé ìtàn àròsọ lásán, ṣé àwọn ìlérí inú rẹ̀ á máa tù ọ́ nínú, táá sì jẹ́ kó o lè ní ìrètí?
Àmọ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà gbọ́ dájú pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé ó yàtọ̀ gédégbé sí gbogbo ìwé yòókù. Kí ló jẹ́ kí wọ́n gbà bẹ́ẹ̀? Kí ni Bíbélì fi yàtọ̀ sí gbogbo ìwé yòókù? A rọ̀ ọ́ pé kí o wo nǹkan márùn-ún lára ohun tí Bíbélì fi yàtọ̀ gédégbé sí àwọn ìwé yòókù, èyí tí a sọ nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.