Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọ́run Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ

Ọlọ́run Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Ọlọ́run Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀. Jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Áhábù, Jésíbẹ́lì, Nábótì àti Èlíjà

Àkópọ̀: Jésíbẹ́lì mú kí Áhábù Ọba pa ẹnì kan kó lè sọ ọgbà àjàrà ẹni náà di tirẹ̀.

1 KA ÀWỌN ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA 1 ÀWỌN ỌBA 21:1-26.

Sọ bí o ṣe rò pé àwọn èèyàn mẹ́rin tí ìtàn yìí dárúkọ ṣe rí?

Áhábù ․․․․․

Jésíbẹ́lì ․․․․․

Nábótì ․․․․․

Èlíjà ․․․․․

Bí ó ṣe ń ka ẹsẹ 5 sí 7 lọ, irú ohùn wo lo rò pé Jésíbẹ́lì máa fi sọ̀rọ̀ nígbà tó ń bá Áhábù sọ̀rọ̀, irú ohùn wo sì ni Áhábù máa fi bá Jésíbẹ́lì sọ̀rọ̀?

․․․․․

Ṣàpèjúwe wàhálà tí o rò pé ó ṣẹlẹ̀ nínú ẹsẹ 13 tó o kà.

Ṣé ohùn líle tàbí ohùn pẹ̀lẹ́ ni Èlíjà àti Áhábù fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹsẹ 20 sí 26?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Irú ìwà wo ni Jésíbẹ́lì hù nínú ẹsẹ 7 àti 25 tó o kà?

․․․․․

Irú ìwà wo ni Áhábù hù nínú ẹsẹ 4?

․․․․․

Ta ni Áhábù tún pa torí kí ó lè gba ọgbà àjàrà Nábótì? (Ka 2 Àwọn Ọba 9:24-26.)

․․․․․

Irú èèyàn wo lo rò pé Jèhófà ka Áhábù sí? (Tún ka ẹsẹ 25 àti 26. Tún wo 1 Àwọn Ọba 16:30-33.)

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà mọ gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀.

․․․․․

Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ ṣe ń dun Jèhófà.

․․․․․

Bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo. (Ka Diutarónómì 32:4.)

․․․․․

4 ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Báwo ni àwọn èèyàn lónìí ṣe ń hu irú ìwà tí Jésíbẹ́lì hù? (Ka Ìṣípayá 2:18-21.)

․․․․․

Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa yẹ kí ìwọ náà fi hàn pé o jẹ́ onígboyà bíi ti Èlíjà?

․․․․․

Tí ó bá rí i pé àwọn èèyàn hùwà ìrẹ́jẹ tàbí tí wọ́n rẹ́ ìwọ náà jẹ, kí ló yẹ kó o máa rántí?

․․․․․

5 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Àbá kan rèé: Kọ ìtàn yìí bíi pé o ń sọ ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀. Kọ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà bó ṣe ṣẹlẹ̀, kó o sì tún kọ apá tó máa jẹ́ kó dà bíi pé ó tún béèrè ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn àti àwọn tó ṣẹlẹ̀ lójú wọn.

Lọ sí orí ìkànnì www.pr418.com

Ka Bíbélì lórí ìkànnì íńtánẹ́ẹ̀tì

Wa àpilẹ̀kọ yìí jáde tàbí kó o tẹ̀ ẹ́