Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Pàṣẹ fún Àwọn Olùjọsìn Rẹ̀ Láti Fẹ́ Kìkì Àwọn Tí Wọ́n Jọ Ń Jọ́sìn Òun?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Pàṣẹ fún Àwọn Olùjọsìn Rẹ̀ Láti Fẹ́ Kìkì Àwọn Tí Wọ́n Jọ Ń Jọ́sìn Òun?
▪ Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó pa àṣẹ kan fún wọn nípa àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká pé: “Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ bá wọn dána. Ọmọbìnrin rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi fún ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sì ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú fún ọmọkùnrin rẹ.” (Diutarónómì 7:3, 4) Kí nìdí tó fi ka irú nǹkan yìí léèwọ̀ fún wọn?
Jèhófà mọ̀ pé Sátánì fẹ́ ba ìjọsìn àwọn èèyàn òun jẹ́ lápapọ̀, kó sọ orílẹ̀-èdè náà di abọ̀rìṣà. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi kìlọ̀ fún wọn síwájú sí i pé àwọn abọ̀rìṣà náà “yóò yí ọmọ rẹ padà láti má ṣe tọ̀ mí lẹ́yìn, dájúdájú, wọn yóò sì máa sin àwọn ọlọ́run mìíràn.” Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wé mọ́ ọ̀rọ̀ yìí o. Tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bá lọ bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà pẹ́nrẹ́n, wọ́n yóò pàdánù ojú rere Ọlọ́run àti ààbò rẹ̀ lórí wọn, ṣìnkún ni ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn á sì tẹ̀ wọ́n. Tó bá sì lọ rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí kò ní lè wá láti orílẹ̀-èdè náà mọ́ nìyẹn. Abájọ tí Sátánì yóò fi fẹ́ láti tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n lè máa fẹ́ ẹni tí kì í ṣe olùjọsìn Ọlọ́run bíi tiwọn.
Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó yẹ ká máa rántí pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ Ọlọ́run lógún. Ó mọ̀ pé àyàfi tí olúkúlùkù wọn bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun tó jẹ́ Ọlọ́run wọn nìkan ni wọ́n tó lè láyọ̀ tí nǹkan á sì máa lọ dáadáa fún wọn. Ṣé òótọ́ ni ìkìlọ̀ tí Jèhófà ń fún wọn yìí, pé tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà, yóò ṣe àkóbá fún un? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ti Sólómọ́nì Ọba. Ó mọ ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún wọn lórí ọ̀rọ̀ fífẹ́ aya tí kì í ṣe olùjọsìn rẹ̀, pé: “Wọn yóò tẹ ọkàn-àyà yín láti tọ àwọn ọlọ́run wọn lẹ́yìn.” Bóyá torí pé ọgbọ́n rẹ̀ pọ̀ jọjọ, ó rò pé ìkìlọ̀ yẹn kò kan òun rárá, pé òun ti kọjá irú ẹni tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fún ní ìkìlọ̀. Ó wá kọ etí ikún sí i. Ibo lọ̀rọ̀ rẹ̀ wá já sí? Bíbélì sọ pé: “Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn aya rẹ̀ tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ . . . láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.” Ẹ ò rí pé ìyẹn burú jáì! Sólómọ́nì wá pàdánù ojúure Jèhófà, àìṣòótọ́ rẹ̀ yìí sì fa ìpínyà burúkú bá àwọn èèyàn rẹ̀.—1 Àwọn Ọba 11:2-4, 9-13.
Àwọn míì lè rò pé gbogbo èèyàn kọ́ ni ìtọ́ni yẹn kàn. Bí àpẹẹrẹ, Málónì tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ṣáà fẹ́ Rúùtù obìnrin ọmọ Móábù, tí Rúùtù sì wá di ojúlówó olùjọsìn Ọlọ́run. Àmọ́ ṣe ni ẹni tó bá fẹ́ obìnrin ọmọ Móábù fi ara rẹ̀ sínú ewu ńlá. Bíbélì kò sì sọ ohun dáadáa nípa Málónì bí ó ṣe fẹ́ ọmọ Móábù, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni Málónì ṣẹ́kú, ó sì ṣeé ṣe kó tiẹ̀ ti kú ṣáájú kí Rúùtù pàápàá tó di olùjọsìn Jèhófà. Kílíónì tó jẹ́ arákùnrin Málónì fẹ́ Ópà obìnrin ọmọ Móábù, ẹni tí kò jáwọ́ nínú bíbọ àwọn òòṣà tó jẹ́ “àwọn ọlọ́run rẹ̀.” Àmọ́ ẹ̀yìn ìgbà tí Rúùtù di olùjọsìn Jèhófà ni Bóásì ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ṣe aya ní tiẹ̀. Kódà, nígbà tó yá, àwọn Júù ka Rúùtù sí “ojúlówó aláwọ̀ṣe.” Ìbùkún ni ìgbéyàwó Bóásì àti Rúùtù já sí fún àwọn méjèèjì.—Rúùtù 1:4, 5, 15-17; 4:13-17.
Ǹjẹ́ ó wá bọ́gbọ́n mu láti máa fi àpẹẹrẹ bí Málónì ṣe lọ fẹ́ Rúùtù yìí ṣe àwáwí pé kò fi bẹ́ẹ̀ burú téèyàn kò bá tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà pé ká fẹ́ kìkì àwọn tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà bíi tiwa? Ká sòótọ́, téèyàn bá lọ ní irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn, ṣé kò ní dà bí ìgbà téèyàn ń tọ́ka sí ẹnì kan tó ta tẹ́tẹ́ tó sì jẹ owó ńlá láti fi ṣe àlàyé pé tẹ́tẹ́ títa jẹ́ iṣẹ́ tó dáa láti ṣe jẹun?
Bíbélì rọ àwọn Kristẹni òde òní pé kí wọ́n gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” Ó sì kìlọ̀ pé kéèyàn má ṣe fi “àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” Àwọn Kristẹni tòótọ́ tó ṣì ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ ni ìtọ́ni yìí kàn gbọ̀ngbọ̀n. Àmọ́ ṣá, Bíbélì pèsè ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an fún àwọn tó ti fẹ́ ẹni tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nípa ohun tí wọ́n lè ṣe nínú ipò tí kò rọrùn tí wọ́n wà yẹn. (1 Kọ́ríńtì 7:12-16, 39; 2 Kọ́ríńtì 6:14) Gbogbo irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà ń fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀ ń fẹ́ kí àwa tó ń sìn ín máa láyọ̀ yálà a jẹ́ àpọ́n tàbí ẹni tó ti ṣègbéyàwó.