Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Olùgbọ́ Àdúrà Fi Fàyè Gba Ìjìyà?

Kí Nìdí Tí Olùgbọ́ Àdúrà Fi Fàyè Gba Ìjìyà?

Kí Nìdí Tí Olùgbọ́ Àdúrà Fi Fàyè Gba Ìjìyà?

ÀWỌN èèyàn kan máa ń gbàdúrà, àmọ́ wọ́n ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Ọlọ́run wà. Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣiyè méjì? Bóyá nítorí wọ́n ń rí i pé ìyà ti pọ̀ jù nínú ayé yìí. Ǹjẹ́ ìwọ náà ti rò ó rí pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run ló dìídì dá àwa èèyàn ní aláìpé ká sì máa jìyà? Tó bá jẹ́ pé òun ló dá wa bẹ́ẹ̀, ó máa ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fún irú ọlọ́run bẹ́ẹ̀ tó dìídì fẹ́ kí àwa èèyàn máa jìyà. Ṣùgbọ́n rò ó wò ná: Ká ní o rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun kan tó dára gan-an, àmọ́ nígbà tí o wò ó, o rí ibì kan lára rẹ̀ tó bà jẹ́, ṣé wàá rò pé bí ilé iṣẹ́ tó ṣe ọkọ̀ yẹn ṣe ṣe é jáde nìyẹn? Rárá o! Ṣe ni wàá gbà pé agánrán ni ọkọ̀ náà nígbà tó jáde, pé ó ní láti jẹ́ ẹnì kan tàbí nǹkan kan ló ba ara ọkọ̀ yẹn jẹ́.

Bákan náà, bí a ṣe ń rí àwọn iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé àti ojú sánmà àti bí gbogbo rẹ̀ ṣe wà létòlétò, àmọ́ tí a sì tún wá rí bí ìdàrúdàpọ̀ àti ìwà ìbàjẹ́ ṣe gbòde kan láàárín ìran èèyàn, kí ló yẹ kó jẹ́ èrò wa? Bíbélì kọ́ni pé pípé ni Ọlọ́run dá tọkọtaya àkọ́kọ́ sí ayé, àmọ́ àwọn fúnra wọn ló fa àbùkù tó dé bá wọn. (Diutarónómì 32:4, 5) Ìròyìn ayọ̀ kan tí a ní ni pé Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa mú àbùkù yẹn kúrò, ìyẹn ni pé òun máa sọ àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn nínú aráyé di pípé pa dà. Kí wá nìdí tí kò fi tíì ṣe é títí di báyìí?

Kí Nìdí Tí Kò Fi Tíì Ṣe É Títí Di Báyìí?

Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ dá lórí ọ̀rọ̀ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso aráyé. Látilẹ̀ wá, Jèhófà kò ní in lọ́kàn pé kí ẹ̀dá èèyàn máa ṣàkóso ara wọn. Òun ló fẹ́ máa ṣàkóso wọn. Bíbélì gan-an sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ó ṣeni láàánú pé àwọn èèyàn tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso Ọlọ́run. Ìwà àìlófin wọn ló sọ wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀. (1 Jòhánù 3:4) Èyí ló fà á tí wọ́n fi pàdánù ipò pípé tí wọ́n wà, tí wọ́n sì wá kó àbùkù bá ara wọn àti àwọn ọmọ wọn.

Jèhófà ti gba àwọn èèyàn láyè láti máa ṣàkóso ara wọn láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá, ìtàn ohun tó sì ti ń ṣẹlẹ̀ fi hàn pé ẹ̀dá èèyàn kò lè ṣàkóso ara wọn. Ó tún jẹ́ ká rí i pé gbogbo ìjọba èèyàn ló ń fa ìjìyà. Kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó mú ogun, ìwà ọ̀daràn, ìwà ìrẹ́jẹ tàbí àìsàn kúrò.

Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Máa Ṣàtúnṣe Ohun Tó Ti Bà Jẹ́?

Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run máa tó mú ayé tuntun òdodo wá. (2 Pétérù 3:13) Kìkì àwọn tó bá fúnra wọn yàn láti nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn àti Ọlọ́run, ni Ọlọ́run máa jẹ́ kó wà níbẹ̀.—Diutarónómì 30:15, 16, 19, 20.

Bíbélì tún sọ pé nígbà “ọjọ́ ìdájọ́” tó dé tán yìí, Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìjìyà kúrò pátápátá àti àwọn tó ń fà á. (2 Pétérù 3:7) Lẹ́yìn náà, Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba tí Ọlọ́run yàn, yóò máa ṣàkóso àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Jésù? Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.

Jésù, Ọba tó ń ṣàkóso láti ọ̀run yóò mú gbogbo ìbàjẹ́ tó wáyé nítorí ìṣọ̀tẹ̀ àwọn èèyàn sí Jèhófà “orísun ìyè,” kúrò pátápátá, yóò sì mú àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú kúrò. (Sáàmù 36:9) Jésù yóò mú gbogbo àwọn tó bá fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ lára dá. Àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe yìí yóò sì ṣẹ lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. Irú ìlérí bíi:

◼ “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ Àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ àwọn tí a ti dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.”—Aísáyà 33:24.

◼ “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

Ǹjẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa mú gbogbo ìjìyà kúrò yóò ṣẹ láìpẹ́ kò tù wá nínú? Àmọ́ ní báyìí ná, ẹ má ṣe jẹ́ ká rò pé níwọ̀n bí Ọlọ́run ti fàyè gba ìjìyà lọ́wọ́lọ́wọ́, kì í gbọ́ àdúrà mọ́.

Ọlọ́run wà o. Ó sì ń gbọ́ gbogbo ohun tó o bá ń sọ fún un, títí kan ẹ̀dùn ọkàn àti ìrora rẹ. Ó sì ń fẹ́ kó o gbádùn ayé rẹ ní ìgbà tí gbogbo ìrora àti àwọn ohun tó ń fa iyè méjì rẹ kò ní sí mọ́.