Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ẹnì Kan Wà Tó Ń Gbọ́ Àdúrà?

Ǹjẹ́ Ẹnì Kan Wà Tó Ń Gbọ́ Àdúrà?

Ǹjẹ́ Ẹnì Kan Wà Tó Ń Gbọ́ Àdúrà?

“Tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Ọlọ́run wà. Síbẹ̀, nígbà míì màá kàn ṣáà gbàdúrà. Kò dá mi lójú pé ẹnì kan wà tó ń gbọ́ àdúrà mi, àmọ́ ká sòótọ́, ó wù mí kí ẹnì kan wà tó ń gbọ́. Mi ò láyọ̀, ìgbésí ayé mi ò sì yé mi. Ẹ̀rù ń bà mí láti gbà pé Ọlọ́run wà, torí mo rò pé àwọn aláìríkan-ṣèkan ló ń gbà pé Ọlọ́run wà.”​—PATRICIA, * LÁTI ILẸ̀ IRELAND.

ÀWỌN ẹlòmíì náà máa ń ní irú èrò tí Patricia ní yìí. Wọn kò fi gbogbo ara gbà pé Ọlọ́run wà, síbẹ̀ wọ́n ṣì máa ń gbàdúrà. Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí.

◼ Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín ẹgbàá ó lé igba [2,200] èèyàn ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, nǹkan bí ìdá márùn-ún péré nínú wọn ló gbà pé Ọlọ́run kan wà tó dá ayé tó sì ń gbọ́ àdúrà. Síbẹ̀ nǹkan bí ìdajì àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò yìí ló máa ń gbàdúrà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

◼ Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè, wọ́n rí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìdá mẹ́ta nínú wọn tó sọ pé àwọn kò gbà pé Ọlọ́run wà ló máa ń gbàdúrà.

Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣiyè Méjì?

Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Allan sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, mo máa ń sọ pé mi ò gbà pé Ọlọ́run wà torí mo rò pé ṣe ni wọ́n kàn dọ́gbọ́n dá ẹ̀sìn sílẹ̀ láti máa fi darí àwọn èèyàn àti láti máa fi pa owó. Mo sì tún rò pé, tí Ọlọ́run bá wà, ìwà ìrẹ́jẹ kò ní pọ̀ tó bó ṣe pọ̀ láyé báyìí. Síbẹ̀, nígbà míì màá dá jókòó jẹ́ẹ́ màá sì máa sọ ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn síta bíi pé ‘nǹkan kan’ wà níbì kan tí mò ń sọ fún. Mo tún máa ń bi ara mi pé: ‘Báwo ni mo tiẹ̀ ṣe dẹni tó wà láàyè?’”

Ó ní ìdí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èèyàn tó ní irú èrò yìí fi ń ṣiyè méjì nípa bóyá ẹnì kan wà tó ń dáhùn àdúrà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè jẹ́ pé àìrí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọn ló fa iyè méjì náà, irú bí àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:

◼ Ǹjẹ́ ẹnì kan wà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá?

◼ Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀sìn sábà máa ń wà nídìí àwọn láabi tó ń ṣẹlẹ̀?

◼ Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà?

Tó o bá lè mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ṣé yóò túbọ̀ yá ọ lára láti máa gbàdúrà?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí.