Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

Kí nìdí tí wọ́n fi ń fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì ṣe erùpẹ̀ àpòrọ́ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó kọ́ ilé gogoro Bábélì ni pé “bíríkì jẹ́ òkúta fún wọn, ṣùgbọ́n ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì jẹ́ erùpẹ̀ àpòrọ́ fún wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 11:3.

Inú ilẹ̀ ni ọ̀dà bítúmẹ́nì ti máa ń sun jáde. Epo rọ̀bì abẹ́ ilẹ̀ ló máa ń sun ún jáde, ó sì pọ̀ káàkiri ilẹ̀ Mesopotámíà. Ìgbà tó bá sun jáde tó sì dì ló máa ń di ọ̀dà bítúmẹ́nì. Ayé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ni àwọn èèyàn ti mọ̀ pé ó wúlò torí pé ó máa ń gan mọ́ nǹkan. Ìwé ìwádìí kan sọ pé ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì “wúlò gan-an níbi tí wọ́n bá ti ń fi bíríkì kọ́ ilé.”

Àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n gbé jáde nínú ìwé ìròyìn tí wọ́n ń pè ní Archeology ṣàpèjúwe ohun tí àwọn èèyàn rí nígbà tí wọ́n lọ wo àwókù ilé gogoro aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ kan tó wà ní ìlú Úrì àtijọ́ ní ilẹ̀ Mesopotámíà. Ẹni tó kọ̀wé yẹn sọ pé: “Èèyàn ṣì lè rí ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì láàárín àwọn bíríkì tí wọ́n fi mọ láyé ìgbà yẹn. Ó jẹ́ ara àwọn nǹkan tí àwọn èèyàn àtijọ́ kọ́kọ́ ń lò látinú ilẹ̀ epo rọ̀bì tó lọ salalu ní gúúsù ilẹ̀ Ìráàkì. Ọ̀dà dídì tó dúdú tó ń lẹ̀ mọ́ nǹkan yìí, èyí tó ń dá wàhálà àti rògbòdìyàn sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn àgbègbè náà lóde òní, ti fìgbà kan rí jẹ́ ohun tó so wọ́n pọ̀. Ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì tí wọ́n ń lò láti fi ṣe erùpẹ̀ àpòrọ́, tí wọ́n sì tún fi ń ṣe ojú títì kì í jẹ́ kí omi lè ba bíríkì àwọn ará ilẹ̀ Súmà tí kì í lágbára jẹ́. Ohun tí wọ́n bá sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì ṣe máa ń wà fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún.”

Irú “pépà” wo ló wà láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

Ọ̀rọ̀ kan tí Jòhánù, ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì, sọ ló fa ìbéèrè yìí. Ó sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní ohun púpọ̀ láti kọ̀wé rẹ̀ sí yín, èmi kò fẹ́ láti fi pépà àti yíǹkì kọ ọ́.”—2 Jòhánù 12.

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà kharʹtes, tí wọ́n tú sí “pépà” níhìn-ín, ń tọ́ka sí ìwé tí wọ́n ṣe láti ara ewéko òrépèté tó máa ń hù létí odò. Ìwé ìwádìí kan sọ bí wọ́n ṣe máa ń fi pòròpórò òrépèté ṣe abala ìwé, ó ní: “Wọ́n á kọ́kọ́ bó èèpo ara pòròpórò rẹ̀, èyí tó máa ń gùn tó mítà mẹ́ta nígbà míì, wọ́n á wá là wọ́n pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ, lẹ́yìn náà, wọ́n á lẹ̀ wọ́n pọ̀ mọ́ra, wọ́n á sì wá tó abala kọ̀ọ̀kan lé orí ara wọn, wọ́n á fi dábùú ara wọn ní igun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀; wọ́n á wá fi òòlù lù wọ́n di fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kí wọ́n tó wá fi nǹkan fá ojú rẹ̀ dán kó lè ṣeé kọ̀wé sí.”

Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí ọ̀pọ̀ àwọn ìwé òrépèté àtijọ́ ní ilẹ̀ Íjíbítì àti ní àgbègbè ibi tí Òkun Òkú wà. Kódà àwọn kan lára ìwé òrépèté tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sí tí wọ́n rí níbẹ̀ ti wà láti ìgbà ayé Jésù tàbí ṣáájú ìgbà yẹn pàápàá. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú pépà yìí ni wọ́n fi kọ àwọn ìwé kan nínú Bíbélì, irú bí àwọn ìwé tí àwọn àpọ́sítélì kọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Spectrumphotofile/ photographersdirect.com

© FLPA/David Hosking/age fotostock