Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Sún Mọ́ Olùgbọ́ Àdúrà

Sún Mọ́ Olùgbọ́ Àdúrà

Sún Mọ́ Olùgbọ́ Àdúrà

Ọ̀PỌ̀ àwọn tó sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́ ni kò lè sọ ìdí pàtó tí wọ́n fi gbà á gbọ́. Wọ́n kò sì lè ṣàlàyé ìdí tí ìsìn fi sábà máa ń ṣe aburú tàbí ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà. Ohun tí wọ́n kàn mọ̀ ni pé kí wọ́n ṣáà ti gbàdúrà sí Ọlọ́run, ẹni tí wọn kò tiẹ̀ lóye bó ṣe jẹ́.

Àmọ́, ìwọ lè sún mọ́ Ọlọ́run jù bẹ́ẹ̀ lọ. O lè dẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ dá lórí pé o mọ Ọlọ́run gan-an débi pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, o sì mọyì rẹ̀. Ojúlówó ìgbàgbọ́ máa ń ní ẹ̀rí tó tì í lẹ́yìn. (Hébérù 11:1) Tí o bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, ó lè mọ Ọlọ́run débi pé wàá máa bá a sọ̀rọ̀ bí ẹní bá ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀. Wo ìrírí àwọn kan tó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀, wọ́n máa ń gbàdúrà bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣiyè méjì pé Ọlọ́run wà.

Obìnrin tó ń jẹ́ Patricia, tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ nínú ìwé ìròyìn yìí, sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi bíi mẹ́wàá jọ wà pa pọ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn. Ó ṣẹlẹ̀ pé mo ti sọ fún wọn pé mo jáde kúrò nílé kí n má bàa dá sí ìjíròrò kan tó ń lọ lọ́wọ́ láàárín bàbá mi tí kò gbà pé Ọlọ́run wà àti Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó wá sílé wa. Ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi bá sọ pé: ‘Ó sì lè jóòótọ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ o.’

“Òmíràn tún sọ pé: ‘Ẹ ò ṣe jẹ́ ká kúkú lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé wọn láti lọ ṣe ìwádìí.’ Ohun tá a sì ṣe gan-an nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ṣì ń ṣiyè méjì lórí ohun tí a gbọ́, àwa kan kò ṣíwọ́ lílọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́yìn náà nítorí pé ara wọn yọ̀ mọ́ èèyàn dáadáa.

“Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ Sunday kan, mo gbọ́ ohun kan tó yí ìwà mi pa dà. Ẹni tó ń sọ̀rọ̀ lórí Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí èèyàn fi ń jìyà. Mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ẹni pípé ni Ọlọ́run dá èèyàn ní ìbẹ̀rẹ̀, àti pé ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ni ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti bẹ̀rẹ̀, tó sì wá ran gbogbo ìran èèyàn. Ẹni tó ń sọ àsọyé náà tún ṣàlàyé ìdí tí Jésù fi ní láti kú kí aráyé tó lè rí ohun tí ọkùnrin àkọ́kọ́ pàdánù gbà pa dà. * (Róòmù 5:12, 18, 19) Àfi bíi pé wọ́n ṣí ìbòjú lójú mi, òye gbogbo nǹkan yẹn wá yé mi wàyí. Mo wá sọ fún ara mi pé, ‘Ọlọ́run kan tó bìkítà nípa wa wà lóòótọ́ o.’ Mo tẹra mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi, kò sì pẹ́ tí mo fi rí i pé, fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi, mo lè gbàdúrà sí ẹni gidi kan tí mo mọ̀ pé ó wà.”

Ọ̀gbẹ́ni Allan, tí a mẹ́nu kàn bákan náà nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, sọ pé: “Lọ́jọ́ kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ilé wa, ìyàwó mi ló dá wọn lóhùn, ọ̀rọ̀ tí wọ́n sì sọ fún un pé ó ṣeé ṣe láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé wù ú, ló bá ní kí wọ́n wọlé. Inú bí mi. Torí náà mo fi wọ́n sílẹ̀ ní pálọ̀, mo wá pe ìyàwó mi sí ilé ìdáná, mo sọ fún un pé, ‘O jẹ́ má sọ ara ẹ di òmùgọ̀. Kò yẹ kó o máa gba irú nǹkan wọ̀nyẹn gbọ́!’

“Ni ìyàwó mi bá fèsì pé: ‘Kò burú, tó o bá mọ̀ pé irọ́ ni wọ́n pa, lọ bá wọn, kó o já wọn nírọ́.’

“Láìfọ̀rọ̀ gùn, kò sí ohun tí mo rí fà yọ pé ó jẹ́ irọ́ nínú ọ̀rọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n wọn kò bínú, ńṣe ni wọ́n tún fún mi ní ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀, bóyá láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá kan ni àbí ó kàn ṣèèṣì wà bí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe wí. Àlàyé ìwé yẹn ṣe kedere, wọ́n sì fi ẹ̀rí tì í lẹ́yìn dáadáa èyí tó mú mi pinnu pé ó yẹ kí n túbọ̀ mọ̀ sí i nípa Ọlọ́run. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì pẹ́ tí mo fi rí i pé ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo ohun tó jẹ́ èrò ọkàn mi nípa ẹ̀sìn. Mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí i lọ́nà tó túbọ̀ ṣe pàtó. Mo ń hu àwọn ìwà kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ dára, torí náà mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́. Ó sì dá mi lójú dáadáa pé Jèhófà gbọ́ àdúrà mi.”

Ọ̀gbẹ́ni Andrew tó ń gbé ní ilẹ̀ England, sọ pé: “Mo jẹ́ ẹni tó máa ń rọ̀ mọ́ ohun tí mo bá gbà pé ó jóòótọ́, mo sì fẹ́ràn sáyẹ́ǹsì gan-an, àmọ́ ohun tó mú mi gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ kò ju pé àwọn èèyàn máa ń sọ pé ẹ̀rí tó dájú wà pé ẹ̀kọ́ náà jóòótọ́. Àwọn nǹkan aburú tí mo rí pé ó ń ṣẹlẹ̀ láyé ni kò sì jẹ́ kí n nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run mọ́.

“Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà míì mo máa ń ronú pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run wà lókè lóòótọ́, màá fẹ́ mọ ìdí tí gbogbo nǹkan fi wá rí bó ṣe rí yìí. Àbí kí nìdí tí ìwà ọ̀daràn àti ogun fi pọ̀ tó báyìí?’ Bí mo bá ní ìṣòro, nígbà míì, màá gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́, àmọ́ mi ò mọ ẹni tí mò ń gbàdúrà sí.

“Ẹnì kan wá fún ìyàwó mi ní ìwé àṣàrò kúkúrú tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Ayé Yii Yoo Ha Làájá Bi? Ó sì jẹ́ ìbéèrè tí èmi gan-an ti máa ń ronú lé lórí. Ohun tí mo kà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú yẹn jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa Bíbélì pé, ‘Àbí èèyàn tiẹ̀ lè rí àwọn ìdáhùn tó jóòótọ́ nínú rẹ̀?’ Lẹ́yìn náà, nígbà tí mo wà ní ọlidé, ẹnì kan wá fún mi ní ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn The Bible—God’s Word or Man’s? * Bí mo ṣe wá rí i pé ohun tí Bíbélì sọ bá ojúlówó ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, mo gbà pé ó máa dáa kí n túbọ̀ mọ̀ sí i nípa Bíbélì. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sọ pé òun fẹ́ máa kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì, mo gbà. Bí mo sì ṣe wá mọ ohun tó jẹ́ ète Jèhófà, mo wá mọ̀ dájú látọkàn wá pé ẹni gidi kan ni Ọlọ́run, ìyẹn ẹni tí mo lè máa gbàdúrà sí fàlàlà.”

Obìnrin tó ń jẹ́ Jan, tí wọ́n fi ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tọ́ dàgbà ní ìlú London sọ pé: “Àgàbàgebè tó wà nínú ẹ̀sìn àti bí ìyà ṣe pọ̀ nínú ayé ló jẹ́ kí n pa ẹ̀sìn tì. Mo sì tún pa ilé ìwé tì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin, mo sì ń ta gìtá jẹun. Ìgbà yẹn ni èmi àti ọmọkùnrin tó ń jẹ́ Pat bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra. Ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì ni wọ́n fi tọ́ ọ dàgbà, àmọ́ òun náà ti di aláìgbàgbọ́ bíi tèmi.

“Ilé kan tí àwọn oní-ǹkan ti pa tì ni a ń gbé, àwa àti àwọn míì tó ti pa ilé ìwé tì, àmọ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn àwọn ará Ìlà-oòrùn. A máa ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí sọ̀rọ̀ títí wọ ààjìn òru nípa ìdí tá a fi wà láàyè. Èmi àti Pat kò gbà pé Ọlọ́run wà, síbẹ̀ a gbà pé ‘ohun àìrí kan’ ní láti wà tó dá àwọn ohun abẹ̀mí.

“Nígbà tí a wá kó lọ sí àríwá ilẹ̀ England láti wá iṣẹ́ orin kíkọ, a bí ọmọkùnrin kan. Ní òru ọjọ́ kan, ọmọ náà ṣàìsàn, mi ò mọ ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Ọlọ́run tí mi ò gbà gbọ́. Láìpẹ́ sí ìgbà yẹn, àárín èmi àti Pat dà rú, mo bá kó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, mo sì gbé ọmọ wa dání lọ. Mo kàn ṣáà tún gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́, a kì í bàá mọ̀ ẹnì kan lè wà lóòótọ́ tó ń gbọ́ àdúrà. Àṣé Pat náà gbàdúrà níbi tó wà lọ́hùn-ún, èmi ò sì mọ̀.

“Nígbà tó ṣe díẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan ilẹ̀kùn yàrá Pat, wọ́n sì fi bí àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì ṣe wúlò tó hàn án. Ni Pat bá pè mí lórí fóònù pé ṣé máa jẹ́ ká jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kò sì pẹ́ tá a fi kẹ́kọ̀ọ́ pé tá a bá fẹ́ kí inú Ọlọ́run dùn sí wa, a ní láti lọ fìdí ìgbéyàwó wa múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Ó dà bí ohun tó máa ṣòro gan-an torí pé àárín àwa méjèèjì kò gún.

“A fẹ́ mọ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe máa ṣẹ, ìdí tí àwa èèyàn fi ń jìyà àti ohun tí Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ṣe kedere sí wa pé ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún, àwa náà sì fẹ́ ṣe ohun tó sọ. Ni a bá ṣègbéyàwó wa lábẹ́ òfin. Ọgbọ́n tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ti ràn wá lọ́wọ́, tí a fi lè tọ́ ọmọ mẹ́ta tá a ní yanjú. Ó dá wa lójú ṣáká pé Jèhófà gbọ́ àdúrà wa.”

Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ẹ̀rí Náà Fúnra Rẹ

Àwọn tí a sọ ìrírí wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí kò jẹ́ kí ẹ̀sìn èké tan àwọn jẹ, wọ́n sì dẹni tó mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà. Bákan náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tàn àwọn onísìn èké. Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ìgbà tí àwọn èèyàn yìí ní ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì ni wọ́n tó mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà lóòótọ́?

Ṣé wàá fẹ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà lóòótọ́? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́, tí wàá fi mọ òtítọ́ nípa Jèhófà àti bí o ṣe lè sún mọ́ “Olùgbọ́ àdúrà.”—Sáàmù 65:2.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí ikú Jésù ṣe rà wá pa dà, ka orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

“Bí mo sì ṣe wá mọ ohun tó jẹ́ ète Jèhófà, mo wá dájú látọkàn wá pé ẹni gidi kan ni Ọlọ́run, ìyẹn ẹni tí mo lè máa gbàdúrà sí fàlàlà”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Kéèyàn tó lè ní ojúlówó ìgbàgbọ́, ẹ̀rí tó tì í lẹ́yìn ní láti wà, èèyàn sì gbọ́dọ̀ fẹ́ láti mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run