Ta Ni Olùgbọ́ Àdúrà?
Ta Ni Olùgbọ́ Àdúrà?
TÍ ẸNÌ kan bá wà lóòótọ́ tó jẹ́ Olùgbọ́ àdúrà, a jẹ́ pé òun náà ni Ẹlẹ́dàá. Àbí, yàtọ̀ sí Ẹni tó dá ọpọlọ àwa èèyàn, ta ló tún lè mọ ohun tí ò ń rò? Àbí yàtọ̀ sí òun, ta ni ì bá tún lè máa dáhùn àdúrà kí ó sì máa ṣe ìrànlọ́wọ́ tí ọmọ aráyé ń fẹ́? Àmọ́ ṣá, o lè máa rò ó pé: ‘Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó dá ohun gbogbo?’
Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé téèyàn bá ti lè gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, a jẹ́ pé onítọ̀hún kò gba ẹ̀rí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní gbọ́ nìyẹn. Ṣùgbọ́n èrò àwọn kan pé ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kò bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu kì í ṣòótọ́ rárá. Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí.
◼ Láìpẹ́ yìí, wọ́n ṣe ìwádìí kan láàárín ẹgbẹ̀rún kan àti òjì-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà [1,646] àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó wà ní yunifásítì mọ́kànlélógún [21] tó dára jù ní Amẹ́ríkà. Ìdá mẹ́ta péré nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yẹn ló sọ nínú àlàyé wọn pé àwọn kò gbà pé Ọlọ́run wà.
Ní kúkúrú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló ṣì gbà pé Ọlọ́run wà.
Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Ẹlẹ́dàá Wà
Ṣé kéèyàn kàn ṣáà gbà pé Olùgbọ́ àdúrà wà ni láìsí ẹ̀rí kankan tó fi hàn bẹ́ẹ̀? Rárá o. Àṣìṣe gbáà ló máa jẹ́ téèyàn bá rò pé ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣáà gba nǹkan gbọ́ láìjẹ́ pé ẹ̀rí kankan wà. Ohun tí Bíbélì sọ pé ìgbàgbọ́ jẹ́ ni “ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé ìgbàgbọ́ jẹ mọ́ níní “ẹ̀rí tí ó dájú nípa àwọn ohun tí a kò rí.” (Ìròhìn Ayọ̀) Bí àpẹẹrẹ, a kò lè fojú rí afẹ́fẹ́, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ó wà torí pé ó máa ń fẹ́ sí wa lára, a sì ń rí àwọn nǹkan tó ń ṣe. Bákan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fojú rí Olùgbọ́ àdúrà, tí a bá gbé àwọn ẹ̀rí tó wà yẹ̀ wò, ìyẹn máa jẹ́ kó dá wa lójú pé Olùgbọ́ àdúrà wà lóòótọ́.
Ibo la ti lè rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà? Tí a bá wo àyíká wa, a óò rí wọn. Bíbélì ṣàlàyé pé: Hébérù 3:4) Ǹjẹ́ o gbà pé ohun tí Bíbélì sọ yìí bọ́gbọ́n mu? Bóyá tó o bá ronú lórí bí àwọn nǹkan tó wà ní ilẹ̀ ayé àti ojú sánmà ṣe wà létòlétò tàbí bó ṣe di pé àwọn nǹkan abẹ̀mí wà àti bí ọpọlọ èèyàn tó jẹ́ ohun tó díjú jù lọ láyé ṣe ń ṣiṣẹ́, wàá gbà pé ẹnì kan tí ọgbọ́n àti agbára rẹ̀ ju ti ẹ̀dá èèyàn ní láti wà. *
“Dájúdájú, olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Àmọ́ kì í ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run ni a lè rí kọ́ láti ara àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run láti ara àwọn ohun tó dá, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn wà nínú ilé tó sì ń gbúròó ẹsẹ̀ ẹnì kan tó ń bọ̀ lẹ́yìn ilẹ̀kùn. Wàá mọ̀ pé ẹnì kan ń bọ̀ o, àmọ́ o kò ní mọ onítọ̀hún. Láti lè mọ ẹni náà, wàá ní láti ṣí ilẹ̀kùn náà. Irú ohun kan náà la máa ṣe ká tó lè mọ Ẹni tó dá ohun gbogbo.
Bíbélì ló dà bí ilẹ̀kùn àbáwọlé sínú ìmọ̀ nípa Ọlọ́run. Tó o bá ṣí ilẹ̀kùn yẹn, tó o ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ àti bí wọ́n ṣe ṣẹ, wàá rí ẹ̀rí pé Ọlọ́run wà. * Yàtọ̀ sí ìyẹn, ìtàn nípa bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò jẹ́ ká mọ ìwà Ọlọ́run tó jẹ́ Olùgbọ́ àdúrà.
Irú Ẹni Wo Ni Olùgbọ́ Àdúrà Jẹ́?
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni gidi kan ni Olùgbọ́ àdúrà àti pé a lè mọ̀ ọ́n. Ẹni gidi kan ló lè gbọ́ ohun tí èèyàn bá ń sọ ní àgbọ́yé. Bíbélì sọ̀rọ̀ tó dùn mọ́ni yìí, pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní Sáàmù 65:2) Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àwọn tó bá fi ìgbàgbọ́ ké pè é. Ó sì ní orúkọ. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú, ṣùgbọ́n àdúrà àwọn olódodo ni ó máa ń gbọ́.”—Òwe 15:29.
ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.” (Jèhófà máa ń mọ nǹkan lára. Òun ni “Ọlọ́run ìfẹ́,” Bíbélì sì tún pè é ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 13:11; 1 Tímótì 1:11) Nígbà kan tí ìwà ibi pọ̀ gan-an ní ayé, Bíbélì sọ bó ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: ‘Ó dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6) Ohun tí àwọn kan máa ń sọ, pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ àwọn èèyàn láti fi dán wọn wò, kì í ṣe òótọ́. Bíbélì sọ pé: “Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú.” (Jóòbù 34:10) Ṣùgbọ́n o lè máa rò ó pé, ‘Tí Ọlọ́run bá jẹ́ Ẹlẹ́dàá àti Olódùmarè, kí nìdí tó fi jẹ́ kí ìjìyà máa bá a nìṣó?’
Jèhófà fún àwa ọmọ aráyé ní òmìnira láti máa fúnra wa yan ohun tí ó wù wá, ìyẹn sì jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ wa pé a ní òmìnira láti yan bí a ṣe fẹ́ gbé ìgbé ayé wa? Àmọ́ ó dunni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣi òmìnira wọn lò, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ kó ara wọn àti àwọn ẹlòmíì sí ìyọnu. Wàyí o, ìbéèrè kan rèé, tó yẹ kéèyàn ronú jinlẹ̀ lé lórí, ìyẹn: Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú ìjìyà kúrò láìjẹ́ pé ó gba òmìnira tó fún ọmọ aráyé kúrò lọ́wọ́ wọn? A máa wá ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Tó o bá fẹ́ rí àlàyé púpọ̀ sí i nípa ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, wo Ilé Ìṣọ́ June 1, 2004, ojú ìwé 9 sí 14; Jí! October 2006, ojú ìwé 20 sí 22; ìwé pẹlẹbẹ náà The Origin of Life—Five Questions Worth Asking àti ìwé Is There a Creator Who Cares About You? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe wọn.
^ Ìwé pẹlẹbẹ náà Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn jẹ́ ara ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe kí o lè fi ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Bíbélì ní ìmísí Ọlọ́run.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ṣé Àwọn Àìdáa Inú Ẹ̀sìn Ló Ń Mú Ọ Ṣiyè Méjì?
Ó dunni gan-an pé ẹ̀sìn ló ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣiyè méjì pé bóyá ni Ọlọ́run aláàánú tó jẹ́ Olùgbọ́ àdúrà wà. Torí bí ìsìn ṣe ń kópa nínú ogun àti ìpániláyà, àti bí wọ́n ṣe fàyè gba ìwà bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, ọ̀pọ̀ àwọn tó tiẹ̀ fẹ́ràn àdúrà gbígbà ti sọ pé, “Èmi ò gba Ọlọ́run gbọ́.”
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀sìn la sábà máa ń bá nídìí àwọn láabi tó máa ń ṣẹlẹ̀? Ní kúkúrú, àwọn ẹni ibi ló kàn ń fi ẹ̀sìn bojú láti ṣe iṣẹ́ ibi. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwọn kan yóò máa lo ẹ̀sìn Kristẹni láti fi ṣe ibi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn alábòójútó tó jẹ́ Kristẹni pé: “Láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.”—Ìṣe 20:29, 30.
Ọlọ́run ka ìsìn èké sí ohun ìríra. Kódà Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ìsìn èké ló jẹ̀bi “ẹ̀jẹ̀ . . . gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 18:24) Nítorí pé ìsìn èké kùnà láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run tòótọ́ tó ń fi ìfẹ́ ṣe gbogbo nǹkan rẹ̀, ìsìn èké jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lójú Ọlọ́run.—1 Jòhánù 4:8.
Ó ń dun Olùgbọ́ àdúrà gan-an bó ṣe ń rí àwọn tí ìsìn ń fojú wọn gbolẹ̀. Láìpẹ́, ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí aráyé máa mú kó lo Jésù láti dá gbogbo àgàbàgebè ẹ̀sìn lẹ́jọ́. Jésù sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.”—Mátíù 7:22, 23.