Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Tó Ń Gbèjà Òtítọ́

Àwọn Tó Ń Gbèjà Òtítọ́

Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Kọkànléláàádóje Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Àwọn Tó Ń Gbèjà Òtítọ́

ỌJỌ́ pàtàkì ni MARCH 10, 2012 jẹ́ ní ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Patterson, ní New York. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tó múra dáadáa, títí kan àwọn àlejò tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè, kóra jọ síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kejìléláàádóje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ọ̀pọ̀ nínú wọn wá sínú gbọ̀ngàn àpéjọ tó wà ní Patterson; àwọn míì sì pé jọ láti wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lórí ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n láwọn ibòmíì ní Bẹ́tẹ́lì. Àpapọ̀ iye àwọn tó wá síbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án ó lé méjìlélógójì [9,042].

Ojú àwọn èèyàn ti wà lọ́nà fún bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣe máa rí. Àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege lọ́tẹ̀ yìí kò dà bí àwọn tó ti ń wá sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì látẹ̀yìn wá, torí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ti ọ̀tẹ̀ yìí ló ti wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún kí wọ́n tó wá. Lára wọn jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tàbí alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí míṣọ́nnárì tàbí ẹni tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò tíì lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Kí ni wọ́n wá fẹ́ sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run yìí?

Kò pẹ́ púpọ̀ kí àwùjọ tó wà níbẹ̀ tó mọ ìdáhùn. Arákùnrin Gerrit Lösch tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, òun ló sì sọ ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́. Ó béèrè ìbéèrè kan tó ń múni ronú jinlẹ̀, ó ní: “Ṣé Olùgbèjà Òtítọ́ Ni Ọ́?” Ó ṣàlàyé pé àwa Kristẹni jẹ́ olùgbèjà òtítọ́, pé a máa ń gbèjà gbogbo ẹ̀kọ́ Kristẹni lápapọ̀. Gbígbé ẹ̀kọ́ òtítọ́ lárugẹ kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ kíkọ́ni ní òtítọ́ nìkan, ó tún ní nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè dẹni tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.

Arákùnrin Lösch wá béèrè pé: “Báwo ni a ṣe mọ̀ pé a ní òtítọ́?” Ó ní kì í ṣe bí iye àwọn tó tẹ́wọ́ gbà á ṣe pọ̀ tó la fi lè mọ̀. Lóòótọ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́ lóde òní, ṣùgbọ́n nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, wọn kò ju ìwọ̀nba díẹ̀ lọ. Ó mẹ́nu kan ọ̀nà márùn-ún tí a fi mọ̀ pé a ní òtítọ́. Ó ní: (1) A dúró nínú ẹ̀kọ́ Jésù, (2) a nífẹ̀ẹ́ ara wa, (3) a rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà ìwà rere títayọ tí Ọlọ́run fi lélẹ̀, (4) a kì í dá sí àwọn àríyànjiyàn láàárín aráyé, àti pé (5) à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run.

“Máa Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni àti Ìtọ́sọ́nà”

Ṣe ni àwùjọ bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n rí Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó gbé àpótí aṣọ kan dání bó ṣe ń bọ̀ nídìí tábìlì ìsọ̀rọ̀! Àkòrí àsọyé rẹ̀ ni “Máa Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni àti Ìtọ́sọ́nà.” Ó dá lórí ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 50:5 tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi. Ó ní Jésù yóò sọ pé: “Èmi, ní tèmi, kò sì ya ọlọ̀tẹ̀. Èmi kò yí padà sí òdì-kejì.”

Arákùnrin Jackson rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n máa wà lójúfò sí ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń fún wọn nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ètò rẹ̀ àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nínú àkàwé nípa tálẹ́ńtì tí Jésù sọ nínú Mátíù 25:14-30, a lè sọ pé iye kan náà ni àwọn ẹrú náà gbà, torí ohun tí wọ́n fún ẹrú kọ̀ọ̀kan jẹ́ bí agbára rẹ̀ ṣe mọ. Ṣe ni ọ̀gá wọn retí pé kí kálukú wọn ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe. Nígbà tó yá, ó yin ẹrú méjì, ó sì pe àwọn méjèèjì ní “ẹrú rere àti olùṣòtítọ́.” Nítorí náà, kì í ṣe bí àṣeyọrí èèyàn ṣe pọ̀ tó nìkan la fi ń mọ̀ bóyá ó jẹ́ olùṣòtítọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, bí èèyàn ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà tó ni.

Ọ̀gá àwọn ẹrú náà pe ẹrú kẹta ní “ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra” àti “ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun.” Kí ló fà á? Ṣe ni ẹrú yìí wa ilẹ̀, ó sì ri tálẹ́ńtì rẹ̀ mọ́ ibẹ̀. Tálẹ́ńtì kì í ṣe owó, iye ìwọ̀n nǹkan ni, tó jẹ́ dédé ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] owó dínárì, èyí tó wúwo tó ogún kìlógíráàmù, ìyẹn ni pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó ìlàjì àpò sìmẹ́ǹtì kan. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ iye ìwọ̀n àpótí aṣọ tí wọ́n gbà kéèyàn máa gbé lọ́fẹ̀ẹ́ tó bá fẹ́ wọ ọkọ̀ òfuurufú láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Ó gba ìsapá kéèyàn tó lè ri ohun tó tóbi tó àpótí aṣọ mọ́lẹ̀. Nítorí náà, ẹrú náà kò ṣaláì ṣe nǹkan kan, ó ri tálẹ́ńtì náà mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìtọ́ni tí ọ̀gá rẹ̀ fún un nìyẹn. Bákan náà, ọwọ́ míṣọ́nnárì kan lè dí, ṣùgbọ́n fún kí ni? Bóyá ó ń kọ lẹ́tà ìròyìn, tàbí ó jókòó ti Íńtánẹ́ẹ̀tì ó ń yẹ ìsọfúnni wò kiri ṣáá, tàbí ó lọ ń kí àwọn èèyàn káàkiri tàbí ó ń ṣòwò. Ó lè rẹ onítọ̀hún tẹnutẹnu nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú nítorí nǹkan tó ṣe o, àmọ́ ohun tí wọ́n ní kó ṣe kọ́ ló ṣe. Arákùnrin Jackson wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé ìtọ́ni!”

“Má Fàyè Gba Iyè Méjì”

Ìyẹn ni àkòrí àsọyé Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ó sọ pé “kò síbi tí Bíbélì ti fi hàn pé àjọṣe kankan wà láàárín ìgbàgbọ́ àti iyè méjì.” Ó ní “ìgbàgbọ́ kì í fàyè gba iyè méjì.” Sátánì gbin iyè méjì sí ọkàn Éfà tó jẹ́ ẹni pípé, torí náà ó lè gbin iyè méjì sí àwa náà lọ́kàn. Arákùnrin Morris wá sọ pé: “Máa fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, wàá sì bọ́ lọ́wọ́ iyè méjì.” Ó tọ́ka sí bí Pétérù ṣe kọ́kọ́ “rìn lórí omi,” àmọ́ nígbà tí ó ‘wo ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà,’ ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ni Jésù bá dì í mú, ó sì wá bí i pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì?” (Mátíù 14:29-31) Arákùnrin Morris ní: “Ọwọ́ ẹ̀yin míṣọ́nnárì yóò dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún, débi pé ohun tí ẹ̀ ń ṣe lè jọ àwọn èèyàn lójú gan-an bíi pé ẹ̀ ń rìn lórí omi, àmọ́ tí ìjì bá dé, ẹ má ṣe ṣiyè méjì.”

Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé nígbà tí ìjì ìṣòro bá ń jà, ó máa ń nira gan-an, àmọ́ tó bá yá ìjì náà máa rọlẹ̀. Ó wá gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé nígbà ìṣòro, kí wọ́n ronú lórí ohun tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣe nígbà tí wọ́n wà ní àtìmọ́lé ní ìlú Fílípì. Ìwé Ìṣe 16:25 sọ pé: “Ní nǹkan bí àárín òru, Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń gbàdúrà, wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbọ́ wọn.” Ó ní kí wọ́n kíyè sí kókó kan, pé: Kì í ṣe pé wọ́n kàn gbàdúrà nìkan, wọ́n tún kọrin. Orin wọn sì ròkè débi pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń gbọ́. Arákùnrin Morris wá sọ pé lóòótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ni kò fi bẹ́ẹ̀ lóhùn orin, síbẹ̀ a kò gbọ́dọ̀ máa lọ́ra láti kọrin, pàápàá nígbà tí a bá wà nínú ìṣòro. Ó wá ka ọ̀rọ̀ inú orin tí àkòrí rẹ̀ sọ pé “Fífara Dà Á Dópin,” ìyẹn Orin 135 nínú ìwé orin wa Kọrin sí Jèhófà, láti fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìyànjú Míì

Arákùnrin Robert Luccioni tó wà ní Ẹ̀ka Ìrajà sọ àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Ǹjẹ́ O Nífẹ̀ẹ́ Ọjọ́ Púpọ̀?” Inú ọ̀rọ̀ Dáfídì Ọba, èyí tó wà ní ìwé Sáàmù 34:12, ló ti fa àkòrí náà yọ. Arákùnrin Luccioni sọ̀rọ̀ nípa ohun tí èèyàn lè ṣe nígbà ìṣòro tí àjọṣe dáadáa tó wà láàárín òun àti Jèhófà kò sì ní bà jẹ́. Ó ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè kọ́ nínú ìwé Sámúẹ́lì kìíní, orí ọgbọ̀n. Nígbà tí Dáfídì, àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ àti àwọn ìdílé wọn ń sá fún Sọ́ọ̀lù Ọba, wọ́n fìgbà kan gbé ní Síkílágì bí ìgbèkùn. Nígbà tí àwọn onísùnmọ̀mí tó jẹ́ ará Ámálékì wá kó àwọn ìdílé wọn lẹ́rú, Dáfídì ni àwọn ọkùnrin náà dá lẹ́bi fún ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yẹn, wọ́n sì fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta. Kí ni Dáfídì wá ṣe? Kò jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló “bẹ̀rẹ̀ sí fún ara rẹ̀ lókun nípasẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 30:6) Ó béèrè ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ Jèhófà, ó tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jèhófà fún un, ìyẹn sì jẹ́ kó lè gba àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú náà pa dà. Arákùnrin Luccioni wá fi dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lójú pé, tí àwọn náà bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀, wọn yóò nífẹ̀ẹ́ ọjọ́ púpọ̀ débi pé wọ́n á rí ohun rere, ìyẹn ni pé ìgbé ayé wọn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nárì yóò dùn bí oyin.

Arákùnrin Michael Burnett tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ẹ Fọkàn sí Ọjọ́ Ọ̀la Aláyọ̀ Tí Yóò Tẹ̀ Lé Òru Ayé Yìí.” Ó ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín àkókò tó wà láàárín ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ títí di òwúrọ̀ sí ìṣọ́ mẹ́ta, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ jẹ́ wákàtí mẹ́rin. Ìṣọ́ tó gbẹ̀yìn, ìyẹn láti aago méjì òru sí aago mẹ́fà àárọ̀ ló máa ń ṣókùnkùn jù, ìgbà yẹn ni òtútù máa ń mú jù, ìgbà yẹn sì ni oorun máa ń kunni jù. Onísáàmù náà jẹ́ kí àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà gba òun lọ́kàn kí oorun má bàa gbé òun lọ nígbà ìṣọ́ tó kẹ́yìn ní òru. (Sáàmù 119:148) Arákùnrin Burnett wá sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé, “Ẹ rí i dájú pé ẹ wà lójúfò.” Ó ní: “Nígbà míì, ẹ máa ní ìṣòro tó lè múni rẹ̀wẹ̀sì, ẹ sì máa rí ìnira nínú ayé aláìnífẹ̀ẹ́ yìí, bí ìgbà tí onísáàmù yẹn wà ní òru tó ṣókùnkùn biribiri tó sì tutù nini. Àmọ́ ṣe ni kí ẹ pinnu ohun tí ẹ máa ṣe ṣáájú.” Ó wá rán wọn létí pé kí wọ́n rí i dájú pé àwọn ń kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ kí wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Ó ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí, ó ní: “Lójoojúmọ́, ẹ máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run nítorí pé ẹ fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ńṣe ni kí ẹ̀yin náà jẹ́ kí Jèhófà tó jẹ́ ọ̀rẹ́ yín máa bá ẹ̀yin náà sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ látinú Bíbélì. Òru ayé yìí ti lọ jìnnà, ojú sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́. Nítorí náà, ẹ máa ronú nípa àwọn nǹkan tí ẹ máa ṣe nígbà àkókò aláyọ̀ tó ń bọ̀, ìyẹn á lè jẹ́ kí ẹ fọkàn sí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tí yóò tẹ̀ lé òru ayé yìí.”

Ohun tí Arákùnrin Mark Noumair, tí òun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, fi ṣe àkòrí àsọyé rẹ̀ ni: “Ẹ Ti Gba Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Nítorí Kí Ẹ Lè Ṣe Iṣẹ́ Tí Ń Bẹ Níwájú.” Orí 1 Pétérù 5:10 ló sì gbé e kà. Ó bi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Níwọ̀n bí ẹ ti wà lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run tipẹ́tipẹ́, kí nìdí tí a tún fi pè yín wá sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower?” Ó ní: “Ìdí ni pé ẹ mọ iṣẹ́ yín dunjú. Ọ̀pọ̀ àwọn tó mọ iṣẹ́ wọn dunjú sì máa ń wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i kí wọ́n lè túbọ̀ jáfáfá. Nínú oṣù márùn-ún tí ẹ lò yìí, ṣe ni Jèhófà ń fi ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ tí ẹ kọ́ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípa ètò rẹ̀ sọ yín di “alágbára” àti ẹni tó ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,’ kí ẹ bàa lè bójú tó àwọn ojúṣe ńlá tó já lé yín léjìká. Ó dájú pé òpó ilé tó dúró sán-ún, kì í yẹ̀, kì í tẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í yọ dà nù lábẹ́ ẹrù tó wà lórí rẹ̀. Nígbà tí ẹ bá ń bá àwọn arákùnrin àti arábìnrin yín ṣiṣẹ́ pọ̀, ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ yóò máa hàn. Ṣé ẹ máa wá jẹ́ kí ojúṣe tó já lé yín léjìká mú kí ẹ yà kúrò nínú àwọn ìlànà Ọlọ́run, tàbí ṣe ni ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀ kúrò nínú ohun tí ẹ kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ohun tó bá lágbára ló máa ń lè gbé ẹrù. Ohun tó sì máa ń jẹ́ kí òpó igi lágbára ni pé inú rẹ̀ máa ń le. Bákan náà, àwọn ìwà dáadáa tí ẹ ní ló máa mú kí ẹ jẹ́ alágbára. Ṣe ni Jèhófà mú yín wá síbí láti lè sọ yín di alágbára, ẹni tó ṣeé gbára lé àti ẹni tó ṣeé fọkàn tán tó máa lè ṣe iṣẹ́ tó wà níwájú. Ọlọ́run ti ṣe ipa tirẹ̀, nítorí náà àdúrà wa ni pé kí ẹ̀yin náà ṣe ipa tiyín, kí ẹ wá jẹ́ kí Jèhófà ‘Olùkọ́ni yín Atóbilọ́lá’ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín.”

Àwọn Ìrírí àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

Ó máa ń dùn mọ́ni gan-an láti gbọ́rọ̀ látẹnu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fúnra wọn nígbà ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, bí ti ọ̀tẹ̀ yìí sì ṣe rí náà nìyẹn. Nínú apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àṣefihàn ìrírí tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ ìwàásù lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí tọkọtaya kan láti ilẹ̀ Faransé ń bọ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n dúró de ọkọ̀ òfuurufú fún wákàtí mẹ́fà ní pápákọ̀ òfuurufú kan. Nígbà tí wọ́n wà ní ilé oúnjẹ tó wà níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọkùnrin méjì kan tí àwọn náà ń dúró de ọkọ̀ òfuurufú fọ̀rọ̀ wérọ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà sọ pé orílẹ̀-èdè Màláwì ni òun ti wá, ni tọkọtaya náà bá sọ èdè Chichewa tó jẹ́ èdè ilẹ̀ Màláwì sí i. Èyí ya ọkùnrin náà lẹ́nu, ó wá bi wọ́n pé báwo ni wọ́n ṣe gbọ́ èdè òun? Wọ́n sì sọ fún un pé àwọn ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Màláwì. Nígbà tí ọkùnrin kejì sọ pé orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ni òun ti wá, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un nígbà tí tọkọtaya yìí tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè Faransé sí i. Àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí sọ ohun tó dára nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tọkọtaya tó jẹ́ míṣọ́nnárì yìí sì wàásù fún wọn.

Arákùnrin Nicholas Ahladis tó wà ní Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀ fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu tọkọtaya méjì tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́. Ilẹ̀ Ọsirélíà ni ọ̀kan lára tọkọtaya méjì náà ti kó kúrò lọ sí orílẹ̀-èdè East Timor tí ogun ti ń lọ lọ́tùn-ún lósì láti lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Orílẹ̀-èdè Korea ni tọkọtaya kejì ti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Hong Kong láti lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì níbẹ̀. Ojú tọkọtaya méjèèjì sì ti wà lọ́nà láti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn nílẹ̀ òkèèrè tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, láti lọ lo ohun tí wọ́n kọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì.

Lẹ́yìn tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà wọn, akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ṣojú fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù ka lẹ́tà ìdúpẹ́ tí wọ́n kọ láti fi dúpẹ́ fún àwọn ìtọ́ni tí wọ́n rí gbà. Nígbà tí Arákùnrin Lösch wá ń sọ ọ̀rọ̀ ìparí, ó lo àwọn àkànlò èdè tó lárinrin. Ó sọ pé òtítọ́ dà bí òṣùmàrè ẹlẹ́wà, ó dà bí ìsun omi nínú aṣálẹ̀, àti bí ìdákọ̀ró nínú ìjì líle lójú òkun. Ó ní: “Ìbùkún gbáà ló jẹ́ láti mọ òtítọ́.” Ó sì rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ jẹ́ olùgbèjà òtítọ́, ẹ sì ran àwọn míì lọ́wọ́ kí àwọn náà lè di olùgbèjà òtítọ́.”

[Àtẹ ìsọfúnni/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 31]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

12 iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá

36 ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn

20 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti ṣèrìbọmi

15 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

A rán àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nísàlẹ̀ yìí:

IBI TÍ A RÁN ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ LỌ

BELIZE

BENIN

CAPE VERDE

CÔTE D’IVOIRE

DOMINICAN REPUBLIC

EAST TIMOR

ECUADOR

GABON

GEORGIA

GUINEA

HONG KONG

KAMẸRÚÙNÙ

KÀǸBÓDÍÀ

LÀÌBÉRÍÀ

MÀLÁWÌ

PERU

MADAGÁSÍKÀ

ORILẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

SAMOA

SÃO TOMÉ AND PRÍNCIPE

SÌǸBÁBÚWÈ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kíláàsì Kejìléláàádóje Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Nínú ìlà àwọn orúkọ tó wà nísàlẹ̀ yìí, a to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì lọ sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Iap, R.; Iap, J.; Ng, T.; Ng, P.; Laurino, F.; Laurino, B.; Won, S.; Won, S.

(2) Morales, N.; Morales, M.; Zanutto, J.; Zanutto, M.; Rumph, I.; Rumph, J.; Germain, D.; Germain, N.

(3) Atchadé, Y.; Atchadé, Y.; Thomas, C.; Thomas, E.; Estigène, C.; Estigène, P.

(4) Ehrman, D.; Ehrman, A.; Bray, J.; Bray, A.; Amorim, M.; Amorim, D.; Seo, Y.; Seo, Y.

(5) Simon, J.; Simon, C.; Seale, C.; Seale, D.; Erickson, J.; Erickson, R.

(6) McCluskey, D.; McCluskey, T.; Brown, A.; Brown, V.; Mariano, D.; Mariano, C.; Loyola, Y.; Loyola, C.

(7) Rutgers, P.; Rutgers, N.; Foucault, P.; Foucault, C.; Wunjah, J.; Wunjah, E.