Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Wo Ni Jésù Di Ọba?

Ìgbà Wo Ni Jésù Di Ọba?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ìgbà Wo Ni Jésù Di Ọba?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.

1. Ìjọba Wo Ni Ọlọ́run Ṣèlérí fún Jésù?

Ọlọ́run ṣèlérí pé ọ̀kan nínú àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba yóò jókòó lórí ìtẹ́ òun fún àkókò tí ó lọ kánrin. Jésù ni àtọmọdọ́mọ Dáfídì tí Ọlọ́run ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, ó sì ti ń ṣàkóso ní ọ̀run báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 89:4; Lúùkù 1:32, 33.

Nígbà tí Dáfídì ṣì wà lọ́mọdé, Ọlọ́run yàn án pé ó máa di ọba lórí àwọn èèyàn Jèhófà, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí Dáfídì Ọba kú, Sólómọ́nì, ẹni tí Jèhófà ti yàn ṣe ọba, wá jókòó sórí “ìtẹ́ Jèhófà.” (1 Kíróníkà 28:4, 5; 29:23) Lẹ́yìn ikú Sólómọ́nì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọba ló jẹ ní Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n èyí tó pọ̀ jù nínú wọn jẹ́ aláìṣòótọ́. Ní ìkẹyìn, Jèhófà jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run, kí wọ́n sì mú ọba tó wà lórí oyè nígbà náà kúrò. Ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni [Ṣ.S.K.] ni ìyẹn ṣẹlẹ̀. Látìgbà yẹn wá, kò sí ọba kankan láti ìlà ìdílé Dáfídì tó jọba ní ìlú Jerúsálẹ́mù ti orí ilẹ̀ ayé.—Ka Ìsíkíẹ́lì 21:27.

2. Ọdún mélòó ni kò fi sí ọba kankan tó ń ṣojú fún Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé láti ìlà ìdílé Dáfídì?

Láìpẹ́ lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù, Jèhófà sọ fún wòlíì rẹ̀ Dáníẹ́lì pé òun yóò yan ọba kan tí yóò ṣàkóso láti ọ̀run wá. Ìgbà wo ni ọba náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?—Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14.

Dáníẹ́lì túmọ̀ ìran kan. Nínú ìran náà Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n gé igi arabarìbì kan lulẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ pé kí wọ́n mú ìjọba tó wà ní Jerúsálẹ́mù kúrò, kí wọ́n sì pa á run. Ṣùgbọ́n ó ní kí wọ́n fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ nínú ilẹ̀ kí ó lè dàgbà pa dà lẹ́yìn tí “ìgbà méje” bá ti kọjá lórí rẹ̀. Bíbélì fi hàn pé “ìgbà” mẹ́tà àti ààbọ̀ jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́. Torí náà “ìgbà méje” yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọjọ́. (Ìṣípayá 12:6, 14) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ọjọ́ sábà máa ń dúró fún ọdún. (Númérì 14:34) Nítorí náà, ìyẹn fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run kò ní ní aṣojú tó ń ṣàkóso lórí ilẹ̀-ayé fún ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọdún.—Ka Dáníẹ́lì 4:10-17.

3. Ìgbà wo ni Ọlọ́run fi Jésù jẹ Ọba?

Ọlọ́run fi Jésù jẹ Ọba ní ọ̀run ní ọdún 1914 Sànmánì Kristẹni [S.K.], ìyẹn sì jẹ́ dédé ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọdún lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù. Ohun àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe lẹ́yìn tó di Ọba ni pé ó lé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. (Ìṣípayá 12:7-10) Àwọn èèyàn kò lè fojú rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àmọ́ ó yọrí sí wàhálà tí aráyé lè fojú rí. (Ìṣípayá 12:12) Àwọn nǹkan tó ti ń ṣẹlẹ̀ láti ọdún 1914 fi hàn pé ọdún yẹn gan-an ni Jésù di Ọba.—Ka Mátíù 24:14; Lúùkù 21:10, 11, 31.

4. Àǹfààní wo ni ìṣàkóso Jésù máa ṣe fún ọ?

Níwọ̀n bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ìṣàkóso Jésù ti ní ìmúṣẹ, ìyẹn fi hàn pé o lè gbára lé Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Láìpẹ́, Jésù máa lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba láti gba gbogbo aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ìjìyà.—Ka Sáàmù 72:8, 12, 13; Dáníẹ́lì 2:44.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka ojú ìwé 215 sí 218 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 17]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

October October

607 Ṣ.S.K. 1914 S.K.

← 2,520 ọdún →

1000 Ṣ.S.K. 1 Ṣ.S.K. 1 S.K. 1000 S.K. 2000 S.K.

← 606 ọdún àti oṣú mẹ́ta →← 1,913 ọdún àti oṣù mẹ́sàn-án →

Wọ́n pa ìjọba Ṣe ìṣirò yìí: Ọlọ́run fi Jésù jẹ Ọba

tó wà ní 606 ọdún àti oṣú mẹ́ta tó ní àṣẹ lórí

Jerúsálẹ́mù run + 1,913 ọdún àti oṣù mẹ́sàn-án gbogbo orílẹ̀-èdè

= 2,520 ọdún