Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan​—Ṣé Gbogbo Èèyàn Rere Ló Máa Lọ sí Ọ̀run?

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan​—Ṣé Gbogbo Èèyàn Rere Ló Máa Lọ sí Ọ̀run?

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan​—Ṣé Gbogbo Èèyàn Rere Ló Máa Lọ sí Ọ̀run?

INÚ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ máa ń dùn láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o ní ìbéèrè kan nínú Bíbélì tó ò ń ṣe kàyéfì nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀kan lára ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́ra láti béèrè ohun náà lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó o bá bá pàdé. Inú rẹ̀ yóò dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.

Irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Ṣẹ́gun lọ sí ilé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Báyọ̀.

Kí Ni Àwọn Tó Bá Lọ sí Ọ̀run Yóò Lọ Ṣe Níbẹ̀?

Ṣẹ́gun: Tó o bá ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la, ǹjẹ́ o máa ń rò pé nǹkan máa sàn sí i, àbí kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rere?

Báyọ̀: Mo rò pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. Ní ti àwọn èèyàn rere, mo retí pé a máa lọ sí ọ̀run lọ bá Jésù jọba.

Ṣẹ́gun: Ìrètí àgbàyanu nìyẹn. Bíbélì ṣe ọ̀pọ̀ àlàyé nípa bí ọ̀run ṣe rí àti àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ láti lọ síbẹ̀. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o ti ronú lórí ohun tí àwọn tí ó ń lọ sí ọ̀run máa ṣe níbẹ̀?

Báyọ̀: Ṣe ni a máa wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí a ó máa yìn ín títí láé.

Ṣẹ́gun: Ohun tó ń wù ẹ́ yẹn náà kò burú. Kódà, kì í ṣe àǹfààní tí àwọn tó ń lọ sí ọ̀run máa ní nìkan ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó tún sọ̀rọ̀ nípa ojúṣe pàtàkì tí wọ́n máa ṣe.

Báyọ̀: Irú ojúṣe wo nìyẹn?

Ṣẹ́gun: Ìwé Ìṣípayá 5:10 sọ ọ́. Ó ní: “O [Jésù] sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” Ǹjẹ́ o kíyè sí iṣẹ́ tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé wọ́n máa lọ ṣe níbẹ̀?

Báyọ̀: Bẹ́ẹ̀ ni, ẹsẹ yìí sọ pé wọ́n máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.

Ṣẹ́gun: O ṣeun, bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn.

Àwọn Wo Ni Wọn Yóò Ṣàkóso Lé Lórí?

Ṣẹ́gun: Àmọ́ tí àwọn tó ń lọ sí ọ̀run yìí bá máa jẹ́ ọba, ǹjẹ́ wọn kò ní láwọn tí wọ́n máa ṣàkóso lé lórí? Àbí báwo ni ìjọba kan ṣe máa wà tí kò ní sí àwọn tó máa ṣàkóso lé lórí?

Báyọ̀: Ó yẹ kí wọ́n ní àwọn tí wọ́n máa ṣàkóso lé lórí lóòótọ́.

Ṣẹ́gun: Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn wo lo rò pé wọ́n máa ṣàkóso lé lórí?

Báyọ̀: Mo rò pé àwọn èèyàn tó wà ní ayé, tí kò tíì kú kí wọ́n sì lọ sí ọ̀run la ó máa ṣàkóso lé.

Ṣẹ́gun: Ọ̀rọ̀ rẹ máa bá a mu dáadáa tó bá jẹ́ pé gbogbo èèyàn rere pátápátá ló ń lọ sí ọ̀run. Ṣùgbọ́n nǹkan míì tún wà, tó yẹ ká ronú nípa rẹ̀. Tó bá wá jẹ́ pé àwọn èèyàn rere kan wà tí kò ní lọ sí ọ̀run ńkọ́?

Báyọ̀: Àwọn èèyàn rere kan kò ní lọ sí ọ̀run kẹ̀? Èmi ò tíì gbọ́ kí Kristẹni kan sọ bẹ́ẹ̀ rí.

Ṣẹ́gun: Ohun tó wà nínú Sáàmù 37:29 ló mú kí n béèrè bẹ́ẹ̀. Jọ̀wọ́ ṣé wàá ka ẹsẹ Bíbélì yẹn?

Báyọ̀: Ó dáa, ó kà pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé. Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”

Ṣẹ́gun: O ṣeun. Ǹjẹ́ o kíyè sí ibi tó sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn rere máa gbé?

Báyọ̀: Ẹsẹ yẹn sọ pé wọn yóò gbé lórí ilẹ̀ ayé.

Ṣẹ́gun: Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, kò tiẹ̀ sọ pé fún ìgbà díẹ̀ pàápàá. Ohun tí ẹsẹ yẹn sọ ni pé: “Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”

Báyọ̀: Bóyá ṣe ni ìyẹn kàn ń fi hàn pé kò sí ìgbà tí èèyàn rere kò ní sí lórí ilẹ̀ ayé. Tí àwa ti ìsinsìnyí bá kú, tá a lọ sí ọ̀run, àwọn èèyàn rere míì tí wọ́n bá bí yóò rọ́pò wa.

Ṣẹ́gun: Ọ̀pọ̀ èèyàn náà máa rò pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí nìyẹn tí wọ́n bá kà á. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o mọ̀ pé ó lè túmọ̀ sí nǹkan míì? Ṣé kò lè jẹ́ pé àwọn ẹni rere yẹn gan-an ni ẹsẹ yìí ń sọ pé á máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé?

Báyọ̀: Ohun tí ò ń sọ ò tíì yé mi.

Párádísè Tó Máa Wà Lórí Ilẹ̀ Ayé

Ṣẹ́gun: Ó dáa, kíyè sí ohun tí ẹsẹ Bíbélì míì tún sọ nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Jẹ́ kí a ka Ìṣípayá 21:4. Ohun tó sọ nípa àwọn tí yóò gbé lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú ni pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ǹjẹ́ ìlérí yẹn kò fani mọ́ra?

Báyọ̀: Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n èmi rò pé bí nǹkan ṣe máa rí lọ́run ni ibí yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Ṣẹ́gun: Òótọ́ ni pé àwọn tó bá lọ sí ọ̀run máa jàǹfààní irú ìbùkún bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n tún wo ẹsẹ Bíbélì yẹn lẹ́ẹ̀kan sí i. Kí ló sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ikú?

Báyọ̀: Ó ní “ikú kì yóò sì sí mọ́.”

Ṣẹ́gun: Bó ṣe rí gan-an nìyẹn. Dájúdájú, wàá gbà pé, kó tó di pé ohun kan kò ní sí mọ́, ó ti wà rí nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Báyọ̀: Bẹ́ẹ̀ ni.

Ṣẹ́gun: Àmọ́, a ò tíì gbọ́ pé wọ́n ń kú ní ọ̀run rí, àbí o ti gbọ́ ọ rí? Orí ilẹ̀ ayé níbí nìkan làwọn èèyàn ti máa ń kú.

Báyọ̀: Òótọ́ ọ̀rọ̀ nìyẹn. Mo máa ní láti ronú lórí rẹ̀.

Ṣẹ́gun: Ṣé o rí i, Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn rere kan máa lọ sí ọ̀run, àmọ́ ó tún sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni yóò gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ó dájú pé wàá ti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí: “Alabukun-fun ni awọn ọlọ́kàn-tútù: nitori ti wọn o jogun ayé.”—Mátíù 5:5, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Báyọ̀: Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n máa ń kà á ní ṣọ́ọ̀ṣì wa.

Ṣẹ́gun: Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni àwọn ọlọ́kàn tútù máa jogún ayé, ǹjẹ́ ìyẹn ò fi hàn pé àwọn kan yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé? Àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé ló máa gbádùn àwọn ìbùkún tí ìwé Ìṣípayá tí a kà yẹn sọ. Wọ́n máa rí bí ìyípadà ńláǹlà ṣe máa dé bá ayé wa yìí, torí pé Ọlọ́run máa mú gbogbo ohun búburú kúrò, títí kan ikú pàápàá.

Báyọ̀: Ọ̀rọ̀ rẹ ń yé mi bọ̀ díẹ̀díẹ̀, àmọ́ mi ò gbà pé ẹsẹ Bíbélì méjì nìkan tó láti fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ.

Ṣẹ́gun: Òótọ́ ni, kì í ṣe ẹsẹ Bíbélì méjì yìí nìkan ló fi hàn bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ Bíbélì ló sọ̀rọ̀ nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Ǹjẹ́ mo ṣì lè sáré fi àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tí mo kíyè sí pé ó ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn hàn ẹ́ fún ìṣẹ́jú díẹ̀?

Báyọ̀: Bẹ́ẹ̀ ni.

“Ẹni Burúkú Kì Yóò sì Sí Mọ́”

Ṣẹ́gun: Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa, a ka Sáàmù 37:29. Ní báyìí, jẹ́ ká pa dà lọ ka ẹsẹ kẹwàá àti ìkọkànlá nínú Sáàmù yẹn. Jọ̀wọ́ kà á.

Báyọ̀: Ó ní: “Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”

Ṣẹ́gun: O ṣeun. Ǹjẹ́ o kíyè sí ibi tí ẹsẹ kọkànlá sọ pé “àwọn ọlọ́kàn tútù,” ìyẹn àwọn èèyàn rere, yóò máa gbé?

Báyọ̀: Ó ní àwọn ni “yóò ni ilẹ̀ ayé.” Ṣùgbọ́n, mo rò pé ẹsẹ Bíbélì yìí ń ṣẹ lọ́wọ́ báyìí; torí àwọn èèyàn rere ṣáà ń gbé nínú ayé lónìí.

Ṣẹ́gun: Òótọ́ ni. Ṣùgbọ́n tún kíyè sí i pé ẹsẹ yẹn sọ pé àwọn ẹni rere máa ní “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Kò fi bẹ́ẹ̀ sí àlàáfíà ní ayé báyìí, àbí ó wà?

Báyọ̀: Rárá, kò sí.

Ṣẹ́gun: Torí náà, báwo ni ìlérí yìí yóò ṣe ní ìmúṣẹ? Ká sọ pé o ní ilé ńlá kan. Àwọn kan lára àwọn èèyàn tó o gbà síbẹ̀ jẹ́ èèyàn dáadáa, wọ́n máa ń tọ́jú ilé, wọ́n sì máa ń ṣe dáadáa sí àwọn ará ilé yòókù. Inú rẹ sì dùn pé o gbà wọ́n sí ilé. Ṣùgbọ́n àwọn ayálégbé tó kù kò ṣe dáadáa; ṣe ni wọ́n máa ń ba nǹkan jẹ́, wọ́n sì máa ń mú ayé nira fún àwọn ará ilé yòókù. Tí àwọn ayálégbé yẹn bá kọ̀ láti yí ìwà búburú wọn pa dà, kí lo máa ṣe sí wọn?

Báyọ̀: Mo máa lé wọn jáde ni.

Ṣẹ́gun: Ohun tí Ọlọ́run máa ṣe gan-an nìyẹn sí àwọn èèyàn burúkú tó wà káàkiri ayé lónìí. Tún wo ẹsẹ kẹwàá. Ó ní: “Ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́.” Ìyẹn ni pé Ọlọ́run máa lé àwọn tó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún ọmọnìkejì wọn jáde, ní ti pé yóò pa wọ́n run. Nígbà náà, àwọn ẹni rere á lè máa gbé lórí ilẹ̀ ayé ní àlàáfíà. Mo mọ̀ pé àlàyé náà pé àwọn èèyàn rere máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé lè yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n ti ń kọ́ yín tẹ́lẹ̀.

Báyọ̀: Bẹ́ẹ̀ ni, mi ò gbọ́ irú rẹ̀ rí ní ṣọ́ọ̀ṣì wa.

Ṣẹ́gun: Gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ẹsẹ Bíbélì méjì nìkan kọ́ ló ṣàlàyé kókó yìí. Ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì látòkè délẹ̀ sọ nípa ọjọ́ ọ̀la àwọn èèyàn rere. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a ti kà lónìí, ǹjẹ́ o ronú pé ó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn rere kan lọ sí ọ̀run, kí àwọn èèyàn rere yòókù sì máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé?

Báyọ̀: Kò tíì dá mi lójú. Àmọ́ ó jọ pé ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí ń sọ nìyẹn. Màá fẹ́ túbọ̀ ronú dáadáa lórí ohun tí o sọ yìí ná.

Ṣẹ́gun: Bí o ṣe ń ronú lórí ọ̀rọ̀ tí a jọ sọ yìí, àwọn ìbéèrè kan lè wá sí ẹ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, o lè béèrè pé, àwọn ẹni rere tó ti gbé ayé ṣáájú ìgbà tiwa ńkọ́? Ṣé ọ̀run ni gbogbo wọn lọ? Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ibo ni wọ́n wà báyìí?

Báyọ̀: Àwọn ìbéèrè yìí dáa gan-an ni.

Ṣẹ́gun: Jẹ́ kí n ṣe nǹkan méjì kan. Màá kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó jẹ mọ́ ohun tá a jọ sọ yìí fún ẹ. * Màá sì tún fẹ́ pa dà wá ká jọ sọ̀rọ̀ nípa wọn lẹ́yìn tó o bá ti kà wọ́n tó o sì ti ronú lé wọn lórí. Ṣé o fẹ́ bẹ́ẹ̀?

Báyọ̀: Bẹ́ẹ̀ ni, o ṣeun gan-an ni.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]