Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì​—Apẹja

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì​—Apẹja

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì​—Apẹja

“Bí ó ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Gálílì, ó [Jésù] rí arákùnrin méjì, Símónì tí a ń pè ní Pétérù àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n ń rọ àwọ̀n ìpẹja sínú òkun, nítorí wọ́n jẹ́ apẹja. Ó sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ṣe ni èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.’”—MÁTÍÙ 4:18, 19.

Ọ̀PỌ̀ ìgbà ni àwọn ìwé Ìhìn Rere tó wà nínú Bíbélì, ìyẹn Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa ẹja, iṣẹ́ ẹja pípa àti àwọn apẹja. Kódà, Jésù lo ọ̀pọ̀ àpèjúwe tó dá lórí iṣẹ́ ẹja pípa. Èyí kò sì yani lẹ́nu, torí pé etí Òkun Gálílì tàbí ìtòsí rẹ̀ ló ti sábà máa ń kọ́ àwọn èèyàn. (Mátíù 4:13; 13:1, 2; Máàkù 3:7, 8) Adágún omi tí kò ní iyọ̀, tó wà níbi tó dára yìí, gùn tó kìlómítà mọ́kànlélógún, fífẹ̀ rẹ̀ sì lé ní kìlómítà mọ́kànlá. Nínú àwọn àpọ́sítélì Jésù, àwọn tó ṣeé ṣe kó jẹ́ apẹja tó méje. Àwọn bíi: Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù, Jòhánù, Fílípì, Tọ́másì, àti Nàtáníẹ́lì.—Jòhánù 21:2, 3.

Báwo ni iṣẹ́ àwọn apẹja ṣe rí nígbà ayé Jésù? Ó máa dára kó o mọ̀ díẹ̀ nípa àwọn apẹja náà àti iṣẹ́ wọn. Ìyẹn yóò jẹ́ kí òye rẹ nípa àwọn àpèjúwe Jésù àti àwọn ohun tí Jésù ṣe túbọ̀ kún sí i, wàá sì túbọ̀ mọyì àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Jẹ́ ká kọ́kọ́ wo bí iṣẹ́ àwọn apẹja ṣe máa ń rí lójú Òkun Gálílì.

“Ìrugùdù Ńlá Kan Dìde Nínú Òkun”

Inú àfonífojì ńlá kan ni Òkun Gálílì wà, ó sì fi igba mítà ó lé mẹ́wàá [210] rẹlẹ̀ sí ìtẹ́jú òkun. Àwọn òkè olókùúta tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ló yí etí òkun náà ká, Òkè Hámónì tó fani mọ́ra gan-an sì yọ sókè ní ọ̀kánkán lápá àríwá ibẹ̀. Nígbà míì lásìkò òtútù, ẹ̀fúùfù tó tutù nini lè fẹ́ lu ojú agbami òkun kó sì mú kí ìgbì òkun máa ru sókè. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, atẹ́gùn gbígbóná máa ń wà lórí omi òkun náà. Ìjì líle sì máa ń ṣàdédé fẹ́ wá láti orí àwọn òkè tó yí òkun náà ká, táá wá dá wàhálà sílẹ̀ fún àwọn atukọ̀ tó bá ń lọ lórí òkun. Irú ìjì líle yìí tiẹ̀ ti bá Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lórí òkun náà rí.—Mátíù 8:23-27.

Ọkọ̀ òbèlè tí àwọn apẹja náà ń lò máa ń gùn tó nǹkan bíi mítà mẹ́jọ, ibi tó fẹ̀ jù lára rẹ̀ sì máa ń lé díẹ̀ ní mítà méjì. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọkọ̀ wọn máa ń ní òpó ìgbòkun àti ibi kékeré tó dà bíi yàrá ní ìsàlẹ̀ ọwọ́ ẹ̀yìn ọkọ̀ náà. (Máàkù 4:35-41) Ọkọ̀ ojú omi tó lágbára àmọ́ tí kò lè sáré púpọ̀ yìí máa ń gba ìnira ẹ̀fúùfù tó ń fẹ́ lu ìgbòkun àti òpó ọkọ̀ sára lápá kan, àwọ̀n tó wúwo á sì tún máa fà á lápá kejì.

Àwọn apẹja máa ń lo àjẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ọkọ̀ láti fi darí rẹ̀ sí ibi tí wọ́n bá fẹ́ kó kọrí sí. Apẹja mẹ́fà lè jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ nínú ọkọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà tàbí kí wọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Máàkù 1:20) Yàtọ̀ síyẹn, ohun ìgbọ́kọ̀sáré àti àwọn ohun èlò míì lè wà nínú ọkọ̀ náà. Irú bíi: aṣọ ìgbòkun (1), okùn (2), àwọn àjẹ̀ (3), òkúta ìdákọ̀ró (4), àwọn aṣọ tó móoru tí ó sì gbẹ (5), oúnjẹ (Máàkù 8:14) (6), àwọn apẹ̀rẹ̀ (7), ìrọ̀rí (Máàkù 4:38) (8), àti àwọ̀n (9). Ó sì tún lè kó ìléfòó míì yàtọ̀ sí ti ara àwọ̀n (10), àti ọ̀rìn (11), irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń tún nǹkan ṣe (12), àti ògùṣọ̀ (13).

“Wọ́n Kó Ògìdìgbó Ńlá Ẹja”

Ibi tí àwọn odò ti ṣàn wọnú Òkun Gálílì ni àwọn apẹja ti máa ń rí ẹja pa jù lóde òní, bó sì ṣe rí nìyẹn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ìdí ni pé ibẹ̀ ni pàǹtírí koríko máa ń gbà ṣàn wá sínú òkun yẹn, àwọn ẹja sì máa ń torí ìyẹn wá síbẹ̀ dáadáa. Nígbà ayé Jésù, àwọn apẹja sábà máa ń ṣiṣẹ́ ní alẹ́ kí wọ́n lè rí ẹja pa, wọ́n máa ń lo ògùṣọ̀ láti fi ríran. Ìgbà kan wà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi gbogbo òru wá ẹja, síbẹ̀ wọn kò rí ẹja pa. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, nígbà tí Jésù ní kí wọ́n tún ju àwọ̀n wọn sínú òkun, wọ́n rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja kó débi pé díẹ̀ ló kù kí ọkọ̀ wọ́n rì.—Lúùkù 5:6, 7.

Nígbà míì, àwọn apẹja máa ń tukọ̀ lọ sí apá ibi tí òkun ti jìn gan-an. Ọkọ̀ ojú omi méjì yóò sì jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní àwọn ibi tí wọ́n ti máa pẹja. Àwọn apẹja náà yóò na àwọ̀n kan sí àárín ọkọ̀ méjèèjì; wọ́n á wá máa sáré wakọ̀ wọn lọ sápá òdìkejì ara wọn, wọ́n á máa tú àwọ̀n wọn sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ láti fi ká àwọn ẹja tó bá wà níbẹ̀ mọ́. Tí àwọn ọkọ̀ náà bá ti yí po tí wọ́n sì pàdé ara wọn, wọ́n á pa àwọ̀n náà dé. Wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í fa okùn tó wà ní etí àwọ̀n náà láti wọ́ ẹja tó bá kó wá sínú ọkọ̀. Ó ṣeé ṣe kí àwọ̀n tí wọ́n ń lò gùn tó ọgbọ̀n mítà, ó sì lè jinnú tó mítà méjì àtààbọ̀ tí wọ́n bá jù ú sínú omi, èyí tó lè kó ọ̀wọ́ ẹja kan pọ̀. Wọ́n máa ń so àwọn ìléfòó mọ́ apá òkè àwọ̀n náà kí òkè rẹ̀ lè léfòó, wọ́n sì máa ń so àwọn ọ̀rìn mọ́ apá ìsàlẹ̀ rẹ̀ kí ibẹ̀ lè rì sínú omi. Bí àwọn apẹja bá ti kó ẹja inú àwọ̀n tán wọ́n á tún na àwọ̀n náà pa dà sínú òkun, bí wọ́n á sì ṣe máa ṣe nìyẹn títí dìgbà tí wọ́n á fi kúrò níbẹ̀.

Ọ̀nà míì tó yàtọ̀ ni àwọn apẹja máa ń lò tí wọ́n bá fẹ́ pa ẹja nínú omi tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn. Wọ́n máa ń na àwọ̀n ńlá láti etí òkun lọ sí àárín òkun bí wọ́n ṣe ń tukọ̀ lọ, wọ́n á lọ yí po láti lè fi àwọ̀n náà ká àwọn ẹja mọ́ títí wọ́n á fi pa dà sí etí òkun níbi tí ọkọ̀ náà ti gbéra. Àwọn apẹja tó wà létí òkun á wá fa àwọ̀n náà wá sí orí ilẹ̀, ibẹ̀ ni wọ́n á ti ṣa àwọn ẹja inú àwọ̀n náà. Wọ́n á kó àwọn tó dára sínú apẹ̀rẹ̀. Wọ́n á tà lára wọn ní tútù níbẹ̀. Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù ni wọ́n máa ń fi iyọ̀ sí tí wọ́n á sì sá a gbẹ, tàbí kí wọ́n kó o sínú ọtí kíkan. Lẹ́yìn náà wọ́n á tọ́jú wọn sínú àwọn ìkòkò oníga méjì, wọ́n á wá kó o ránṣẹ́ sí Jerúsálẹ́mù tàbí ilẹ̀ òkèèrè míì. Wọ́n máa ń da àwọn ẹ̀dá inú omi tí kò ní ìpẹ́ tàbí lẹ́bẹ́, irú bí ẹja àdàgbá, tó bá wà nínú àwọ̀n náà nù, nítorí wọ́n kà wọ́n sí aláìmọ́. (Léfítíkù 11:9-12) Irú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà pẹja yìí ni Jésù mẹ́nu kàn nígbà tó ń fi “ìjọba ọ̀run” wé àwọ̀n ńlá kan, tó sì fi oríṣiríṣi ẹja wé àwọn èèyàn rere àti èèyàn búburú.—Mátíù 13:47-50.

Apẹja tó bá ń dá ṣiṣẹ́ lè lo ìwọ̀ tó so okùn mọ́, tó sì ti fi ìjẹ̀ sí láti fi pa ẹja. Ó sì lè lo àwọ̀n kékeré kan. Láti ta àwọ̀n náà, yóò rìn wọnú omi, yóò wá ju àwọ̀n náà síwájú láti ta á sójú omi. Àwọ̀n tó tẹ́ sójú omi náà á wá lọ sí ìsàlẹ̀ omi. Àwọ̀n náà lè kó ẹja mélòó kan bí apẹja náà ṣe ń fi okùn rẹ̀ fà á pa dà.

Owó gọbọi ni wọ́n ń ta àwọ̀n nígbà yẹn, iṣẹ́ kékeré kọ́ sì ni wọ́n máa ń ṣe láti tọ́jú rẹ̀, nítorí náà tìṣọ́ratìṣọ́ra ni wọ́n fi ń lò ó. Àwọn apẹja máa ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn láti fi tún àwọ̀n wọn ṣe, láti fọ̀ ọ́, àti láti sá a gbẹ. Bí wọ́n sì ṣe máa ń ṣe nìyí ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá dé láti ibi tí wọ́n ti lọ pa ẹja. (Lúùkù 5:2) Kí Jákọ́bù àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ tó di àpọ́sítélì, inú ọkọ̀ wọn ni wọ́n wà tí wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe nígbà tí Jésù pè wọ́n pé kí wọ́n wá di ọmọ ẹ̀yìn òun.—Máàkù 1:19.

Lára irú ẹja tí àwọn apẹja ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń wá ni ẹja èpìyà tó wọ́pọ̀ gan-an nígbà yẹn. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn tó wà ní Gálílì ló sábà máa ń fi ẹja yìí se oúnjẹ. Ó ṣeé ṣe kí Jésù náà jẹ ẹja tó máa ń dùn gan-an yìí. Ó lè jẹ́ ẹja èpìyà tí wọ́n ti fi iyọ̀ sí tí wọ́n sì sá gbẹ ni ẹja méjì tí Jésù lò nígbà tó ṣe iṣẹ́ ìyanu tó fi bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. (Mátíù 14:16, 17; Lúùkù 24:41-43) Ẹja èpìyà sábà máa ń kó ọmọ rẹ̀ sí ẹnu tó bá ń lọ nínú omi. Ṣùgbọ́n, tí kò bá kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí ẹnu, ó lè gbé òkúta kékeré kan tàbí owó ẹyọ tó bá wà ní ìsàlẹ̀ òkun sí ẹnu.—Mátíù 17:27.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn apẹja tó ń rí ẹja pa dáadáa máa ń jẹ́ onísùúrù, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì ṣe tán láti fara da ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ kí wọ́n bàa lè rí èrè púpọ̀. Irú ẹ̀mí tó yẹ kí àwọn tó bá tẹ́wọ́ gba ìkésíni Jésù pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ní nìyẹn tí wọ́n bá máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ “apẹja ènìyàn.”—Mátíù 28:19, 20.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

(Lọ wo ẹ̀dà tí a tẹ̀)