Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

KÍ LÓ mú kí ọkùnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì paraku, tí òun alára sì jẹ́ ògbóǹkangí adájọ́, di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kí ló mú kí apániláyà kan jáwọ́ nínú ìwà ipá, kó sì di ìránṣẹ́ Ọlọ́run? Gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.

“Mo wá ní òye tó jinlẹ̀ nípa ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́.”​—SEBASTIÃO ALVES JUNQUEIRA

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1946

ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: BRAZIL

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: KÁTÓLÍÌKÌ PARAKU

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìgbèríko ni ìdílé mi ń gbé. Ibẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà mẹ́fà sí ìlú Piquete. Àwọn òbí mi ní oko kékeré kan, ohun tí a ń kórè látinú oko la sì fi ń gbọ́ bùkátà. Ìlú Piquete ni ilé ìwé tí mo ń lọ wà, nítorí náà, mo ra àlòkù kẹ̀kẹ́ kan nígbà tó yá, èyí tó mú kó rọrùn fún mi láti máa lọ sí ìlú náà. Tálákà ni àwọn tó wà ní ìlú wa, ṣùgbọ́n ìlú náà mọ́ tónítóní, ìwà ọ̀daràn kò sì fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ níbẹ̀. Ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ohun ìjà fáwọn ológun ni ọ̀pọ̀ ọkùnrin tó wà ní ìlú náà ti ń ṣiṣẹ́.

Mo fojú sí ìwé mi gan-an, ìyẹn sì jẹ́ kí n lè wọ ilé ìwé àwọn ológun tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọkọ̀ òfuurufú, èyí tó wà ní ìlú kan tí kò jìnnà sí wa, mo sì gba oyè sájẹ́ǹtì jáde níbẹ̀ lọ́dún 1966. Lẹ́yìn ìyẹn mo tún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn amòfin mo sì gboyè jáde níbẹ̀. Nígbà tó yá, mo kọ̀wé pé mo fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ ọ̀gá ọlọ́pàá. Lọ́dún 1976, mo yege nínú ìdánwò kan tí ìjọba ṣe fún wa, wọ́n sì yàn mí kí n máa ṣe iṣẹ́ náà. Nígbà míì, iṣẹ́ mi máa ń gba pé kí n lọ ṣe alábòójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n. Láwọn ìgbà yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá gbàyè láti wàásù fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Wọ́n sì sábà máa ń wàásù fún èmi náà. Mo jẹ́ ẹni tó bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run gan-an ni. Torí náà, ó dùn mọ́ mi nínú nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé Ọlọ́run ní orúkọ, pé Jèhófà lorúkọ rẹ̀ àti pé èèyàn lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gòkè àgbà lẹ́nu iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìdájọ́. Lọ́dún 1981, mo yege nínú ìdánwò míì tí ìjọba ṣe fún wa, wọ́n sì sọ mí di adájọ́ ní ìpínlẹ̀ kan. Nígbà tó di ọdún 2005, mo di adájọ́ ní ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní kóòtù ìlú São Paulo.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Láìpẹ́ lẹ́yìn tí mo jáde ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn amòfin, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, èyí sì mú kí bí mo ṣe ń ronú yí pa dà. Kátólíìkì paraku ni mí. Nínú ìdílé wa, a ní àwọn tó jẹ́ àlùfáà, a ní ẹnì kan tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù, èmi náà sì máa ń ran àlùfáà lọ́wọ́ nígbà ààtò gbígba ara Olúwa. Kí àlùfáà tó bẹ̀rẹ̀ ìwàásù, èmi ni mo máa ń ṣe àyọkà látinú ìwé àdúrà. Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ka Bíbélì nínú ìdílé àwọn Kátólíìkì. Torí náà, nígbà tí màmá mi gbọ́ pé mò ń ka Bíbélì, inú bí i gidigidi. Ó fẹ́ kí n jáwọ́ nínú rẹ̀, ó ní tí mi ò bá yéé kà á ó lè yí mi lórí. Síbẹ̀ mo ṣì ń kà á lọ ní tèmi, torí mi ò rí ewu kankan nínú rẹ̀.

Ó jọ pé ẹ̀mí ìtọpinpin tí mo ní ló mú kí n tẹra mọ́ kíka Bíbélì. Mo fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn àlùfáà àti ojúṣe wọn nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé ẹ̀kọ́ ìsìn tó dá lórí ìjìjàgbara, àmọ́ èrò àwọn tó kọ ìwé náà àti àlàyé wọn kò bọ́gbọ́n mu rárá, mi ò sì rí nǹkan kan dì mú nínú rẹ̀.

Lásìkò náà ni dókítà tó ń tọ́jú eyín mi, tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà, fún mi ní ìwé kan tí ẹnì kan fún un. Orúkọ ìwé náà ni Did Man Get Here by Evolution or by Creation? * Mo gba ìwé náà pẹ̀lú èrò pé ó máa dáa gan-an kí n ka òun àti ìwé The Origin of Species, ìyẹn ìwé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tí Charles Darwin kọ. Ṣùgbọ́n àlàyé inú ìwé Did Man Get Here by Evolution or by Creation? wọni lọ́kàn gan-an, ó bọ́gbọ́n mu, ó sì yíni lérò pa dà. Ó wá dá mi lójú gbangba pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kò lẹ́sẹ̀-ńlẹ̀ rárá.

Ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá tí mo kà jẹ́ kí n túbọ̀ fẹ́ láti mọ̀ sí i. Ó wá ó ń wù mí láti ka àwọn ìwé míì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Wọ́n sọ fún mi pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ̀gbẹ́ni mẹkáníìkì kan tó wà ní ilé ìwé tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọkọ̀ òfuurufú. Mo bá a sọ̀rọ̀, ó sì fún mi ní àwọn ìwé kan tí mo lọ kà. Nígbà yẹn, mi ò gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo ronú pé mo lè dá kẹ́kọ̀ọ́ fúnra mi.

Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, mo pinnu pé níwọ̀n bí mo ti níyàwó, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí èmi àti ìdílé mi jọ máa kà á pa pọ̀. A wá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a jọ ń ka Bíbélì pa pọ̀. Nítorí ìdílé mi jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, gbogbo ohun tí a máa ń ṣe kò ju ohun tí àwọn àlùfáà àti àwọn bíṣọ́ọ̀bù bá sọ lọ. Torí náà, ohun kan tí mo kà nínú Jòhánù 14:6 jọ mí lójú gan-an. Ó ní: “Jésù wí fún [Tọ́másì ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀] pé: ‘Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.’” Lẹ́yìn tí mo fara balẹ̀ ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó wá dá mi lójú pé Jèhófà ló ń fúnni ní ìgbàlà nípasẹ̀ Jésù. Àmọ́ ohun tí wọ́n mú ká gbà gbọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì ni pé ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà la ti lè rí ìgbàlà.

Ẹsẹ Bíbélì méjì kan ló mú kí ọkàn mi ṣí kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni. Ọ̀kan nínú wọn ni ìwé Òwe 1:7, tó sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀. Ọgbọ́n àti ìbáwí ni àwọn òmùgọ̀ lásán-làsàn ti tẹ́ńbẹ́lú.” Ìkejì wà nínú Jákọ́bù 1:5, tó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” Òǹgbẹ ìmọ̀ àti ọgbọ́n ń gbẹ mí gidigidi, ṣùgbọ́n gbogbo bí mo ṣe ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, mi ò rí nǹkan kan tí màá fi pa òǹgbẹ náà. Bí mi ò ṣe lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ nìyẹn.

Lọ́dún 1980, àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìyàwó mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tí mo bá wà nílé, mo máa ń jókòó tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ ìyàwó mi lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, èmi náà jẹ́ kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, ó pẹ́ gan-an ká tó pinnu pé a máa ṣe ìrìbọmi láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọdún 1994 ni ìyàwó mi ṣe ìrìbọmi, èmi sì ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1998.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ọmọ mi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti jàǹfààní gan-an, torí àwọn ìlànà Jèhófà la fi tọ́ wọn dàgbà. (Éfésù 6:4) Méjì nínú wọn tó jẹ́ ọkùnrin ń ṣakitiyan láti bójú tó ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ìjọ wọn nílò nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì ń fi ìtara púpọ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. Ìyàwó mi ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lẹ́nu kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ Bíbélì, èmi náà sì ní àǹfààní láti máa sìn bí alàgbà nínú ìjọ tí mo wà.

Nígbà tí mo di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo wá ní òye tó jinlẹ̀ nípa ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Gẹ́gẹ́ bí adájọ́, mo máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nínú bí mo ṣe ń dá onírúurú ẹjọ́ ní kóòtù. Mo máa ń wo gbogbo ohun tó yí ẹjọ́ kan ká, màá sì wo bí mo ṣe lè dájọ́ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu àti bí mo ṣe lè lo ìyọ́nú nínú ẹjọ́ tó bá gbà pé kí n ṣe bẹ́ẹ̀.

Mo ti dá oríṣiríṣi ẹjọ́ àwọn oníwà ipá, àwọn ọ̀daràn, àwọn tó hùwà ìkà sí ọmọdé àti onírúurú ìwà ọ̀daràn tó le gan-an. Síbẹ̀, ìyẹn kò sọ mí di ẹni tí kò lójú àánú mọ́. Bí mo bá ń gbọ́ ìròyìn, tí mo sì ń rí bí ìwà burúkú àti ìwà ìbàjẹ́ ṣe gbilẹ̀ káàkiri, ó máa ń ká mi lára gan-an. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo ti wá mọ ìdí tí ìwà ọ̀daràn fi ń pọ̀ sí i, mo sì dúpẹ́ pé mo ní ìrètí pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa.

“Ọgbà ẹ̀wọ̀n kò mú mi yíwà pa dà.”​—KEITH WOODS

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1961

ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: NORTHERN IRELAND

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: APÁNILÁYÀ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ọdún 1961 ni wọ́n bí mi ní ìlú Portadown, ìyẹn ìlú kan tí èrò pọ̀ sí ní orílẹ̀-èdè Northern Ireland. Ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ni ìdílé mi ń ṣe, inú ọgbà ńlá kan tí àwọn ilé pọ̀ sí ni mo sì gbé dàgbà. Àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì la jọ ń gbé ládùúgbò. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìdílé tó ń gbé ibẹ̀ jẹ́ tálákà. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí owó lóde nígbà yẹn, gbogbo wa la sì jọ máa ń bára wa ṣe wọléwọ̀de.

Ìgbé ayé tí mò ń gbé nígbà yẹn kò tẹ́ èmi fúnra mi lọ́rùn. Ní ọdún 1974, mo kópa nínú ìjà tí wọ́n ń pè ní Rògbòdìyàn [Troubles], ìyẹn ìjà ẹ̀sìn àti ìṣèlú tó gbòde ní orílẹ̀-èdè Northern Ireland. Láàárín ìgbà yẹn, ìjà náà túbọ̀ ń le sí i ní gbogbo àgbègbè wa. Bí àpẹẹrẹ, lálẹ́ ọjọ́ kan, bàbá mi tó jẹ́ ọ̀gá ilé iṣẹ́ Ulster Carpet Factory, ìyẹn ilé iṣẹ́ ńlá kan tí wọ́n ti ń ṣe kápẹ́ẹ̀tì, wà lẹ́nu iṣẹ́ níbi tó ti ń kọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin méjì kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó ń gbé lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wa níṣẹ́. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí kan náà, ẹnì kan lọ ju bọ́ǹbù sínú ilé àwọn ọmọ náà láti ojú fèrèsé pálọ̀ wọn. Bọ́ǹbù náà sì pa bàbá wọn, ìyá wọn àti àbúrò wọn ọkùnrin mọ́lé.

Nígbà tó yá, wàhálà náà pọ̀ gan-an débi pé ó yọrí sí ogun. Wọ́n jó ilé àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì kí wọ́n lè lé wọn kúrò ní àgbègbè tí àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì wà, àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì náà sì fojú àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì han èèmọ̀ ní àgbègbè tí àwọn náà wà. Bó ṣe di pé àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì nìkan ló kù sínú ọgbà wa nìyẹn. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí àwọn agbófinró fi mú mi, tí wọ́n sì rán mi lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta torí bọ́ǹbù tí mò ń jù kiri.

Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, mo di ọ̀rẹ́ ọkùnrin ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n mọ̀ dáadáa nínú ẹgbẹ́ àwọn tí kò fara mọ́ ìpínyà láàárín ilẹ̀ Northern Ireland àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Àwa méjèèjì wá ń ṣe bíi tẹ̀gbọ́n tàbúrò, èmi ni mo sì ṣe ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀. Fífi tí wọ́n fi mí sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kò mú mi yíwà pa dà, kò sì mú òun náà yíwà pa dà. Bí a ṣe jáde kúrò ní ẹ̀wọ̀n, ṣe la tún pa dà sí ìdí ìgbòkègbodò ìṣèlú tí à ń ṣe tẹ́lẹ̀, ti ọ̀tẹ̀ yìí tiẹ̀ tún le ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ni ọ̀rẹ́ mi bá tún dèrò ẹ̀wọ̀n pa dà. Ibẹ̀ ni wọ́n sì ti pa á.

Àwọn ọ̀tá dájú sọ èmi náà, débi pé nígbà kan, wọ́n fi bọ́ǹbù fọ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi dà nù. Síbẹ̀, kàkà kó rọ̀ lára ewé àgbọn mi líle ló ń le sí i. Ṣe ni mo túbọ̀ tara bọ ìjà tí mo gbà pé mo ń jà lórúkọ Ọlọ́run àti ilẹ̀ Ulster, ìyẹn ìjà tí mo ń fi ìtara ẹ̀sìn jà fún ilẹ̀ Northern Ireland.

Ní àkókò yẹn, mo kópa nínú fídíò kan tó dá lórí Rògbòdìyàn tó gbòde nígbà yẹn, èyí tí wọ́n gbé sáfẹ́fẹ́ ní ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n British TV. Fídíò tá a ṣe yìí tún wá dá kún wàhálà mi. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí mo délé lálẹ́ ọjọ́ kan mo rí i pé ìyàwó mi ti kó jáde nílé. Láìpẹ́ sí ìgbà yẹn, àjọ kan tó ń rí sí ọ̀ràn ìdílé gba ọmọkùnrin mi lọ́wọ́ mi, torí fídíò tí wọ́n gbé sáfẹ́fẹ́ yẹn ti mú kí wọ́n gbà pé mi ò ní lè tọ́jú ọmọ náà. Mo rántí pé mo wo ara mi nínú dígí mo sì sọ pé, “Ọlọ́run, tí o bá wà lóòótọ́, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́.”

Lọ́jọ́ Sátidé tó tẹ̀ lé e, mo pàdé ojúlùmọ̀ mi kan tó ń jẹ́ Paul, tó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi sọ ọ̀rọ̀ látinú Bíbélì. Lọ́jọ́ kẹta lẹ́yìn náà, Paul fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kan ránṣẹ́ sí mi. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn náà tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 18:36. Ó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” Ọ̀rọ̀ Jésù yìí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ọjọ́ yẹn ni ìgbésí ayé mi sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Paul bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, Ẹlẹ́rìí míì tó ń jẹ́ Bill wá ń kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì yẹn nìṣó. Mo mọ̀ pé mo ṣòro kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, torí mo máa ń béèrè ìbéèrè gan-an! Mo tún máa ń pe àwọn olórí ìsìn wá sí ilé mi kí wọ́n lè fi hàn pé Bill kò tọ̀nà. Ṣùgbọ́n níkẹyìn, mo rí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kedere.

Mo rántí pé lọ́jọ́ kan mo sọ fún Bill pé kó máà wá kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ torí pé wọ́n ti gbé igi dí àwọn ọ̀nà tó wọnú àdúgbò wa, àti pé tó bá wá wọ́n máa gba ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ wọ́n á sì dáná sun ún. Síbẹ̀ náà, Bill wá láti kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì bó ṣe máa ń wá tẹ́lẹ̀. Ó fi ọkọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ nílé, ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wá. Àbí ta ló máa fẹ́ gba kẹ̀kẹ́ lásán lọ́wọ́ rẹ̀? Ìgbà kan tún wà tí Bill ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ nínú ilé mi, àwọn ọlọ́pàá àti àwọn sójà sì wá mú mi. Bí wọ́n ṣe ń fà mí lọ, Bill sọ fún mi pé kí n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní àwọn àsìkò yẹn ní ipa tó jinlẹ̀ gan-an lórí mi.

Nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó ní láti ya ọ̀pọ̀ nínú wọn lẹ́nu láti rí mi. Mo ní irun gígùn, mo wọ yẹtí, mo sì tún wọ ẹ̀wù tí wọ́n fi awọ ṣe, tó jẹ́ ti ẹgbẹ́ òṣèlú tí mo wà nígbà yẹn. Àmọ́ ẹnu yà mí bí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ṣe gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀. Inú rere tí wọ́n fi hàn sí mi wú mi lórí gan-an ni.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo ṣì ń bá àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ rìn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, òtítọ́ tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì túbọ̀ ń wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Mo wá rí i pé, tí mo bá fẹ́ sin Jèhófà, mo gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìṣèlú àti àwọn ẹgbẹ́ tí mò ń kó. Ìyẹn kò sì rọrùn fún mi láti ṣe. Ṣùgbọ́n bí mo ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Jèhófà fún mi ní agbára tí mo fi lè ṣe ìyípadà tó yẹ. Mo gé irun mi, mi ò wọ yẹtí mọ, mo sì ra kóòtù kan. Ohun tí mò ń kọ́ tún jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tó dáa sí àwọn èèyàn.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ìgbé ayé ọ̀daràn àti apániláyà ni mo ń gbé tẹ́lẹ̀. Àwọn agbófinró àgbègbè wa lónírúurú dá mi mọ̀ dáadáa. Àmọ́ nǹkan ti yàtọ̀ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà àkọ́kọ́ tí mo lọ sí àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣe ní ìlú Navan ní ilẹ̀ Ireland, àwọn agbófinró tẹ̀ lé mi lọ, wọ́n tún tẹ̀ lé mi pa dà sí ilẹ̀ Northern Ireland kí n má bàa fa wàhálà. Àmọ́ ní báyìí tí wọ́n ti mọ̀ pé mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọn kò tẹ̀ lé mi kiri mọ́. Bákan náà, ní báyìí, èmi àti àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù bíi Paul, Bill àti àwọn ará yòókù nínú ìjọ ni a jọ máa ń jáde lọ sí òde ìwàásù fàlàlà.

Bí mo ṣe yí pa dà, tí mo di èèyàn rere, mo wá di ara ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo pàdé Ẹlẹ́rìí kan níbẹ̀ tó ń jẹ́ Louise, a sì ṣègbéyàwó. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn aláṣẹ tún jẹ́ kí ọmọ mi ọkùnrin pa dà sọ́dọ̀ mi.

Tí mo bá ronú nípa ìgbésí ayé tí mo ń gbé tẹ́lẹ̀, mo máa ń kábàámọ̀ pé mo ṣe ìpalára fún àwọn èèyàn, mo sì kó ìbànújẹ́ bá wọn. Ṣùgbọ́n mo lè fi ìdánilójú sọ pé Bíbélì máa ń yí àwọn èèyàn bíi tèmi pa dà kúrò nínú ìgbé ayé ẹni tí a ṣì lọ́nà, ó sì máa ń sọ wọ́n di ẹni tó ń gbé ìgbé ayé rere àti ẹni tó nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

Nígbà tí màmá mi gbọ́ pé mò ń ka Bíbélì, inú bí i gidigidi