Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ

Jèhófà Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Jèhófà Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ

“ÈNÌYÀN ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí, tí wọ́n kọ sílẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò tí à ń gbé yìí mu gan-an ni. Àwọn èèyàn sábà máa ń ṣi agbára wọn lò, láìka irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tàbí ibi tí wọ́n ń gbé sí. Bákan náà, wọ́n sábà máa ń ni àwọn aláìní àti àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ lára. Báwo ni irú ìwà ìrẹ́jẹ bẹ́ẹ̀ ṣe máa ń rí lára Jèhófà? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú Ìsíkíẹ́lì 22:6, 7, 31.—Kà á.

Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ ọ́ kedere pé àwọn tó wà nípò àṣẹ kò gbọ́dọ̀ ṣi agbára wọn lò. Kí orílẹ̀-èdè náà tó lè rí ìbùkún Ọlọ́run, àwọn aṣáájú wọn gbọ́dọ̀ máa ṣàánú àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àti àwọn òtòṣì kí wọ́n sì máa gba tiwọn rò. (Diutarónómì 27:19; 28:15, 45) Àmọ́ nígbà ayé wòlíì Ìsíkíẹ́lì, ṣe ni àwọn ìjòyè ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà ń lo agbára wọn lọ́nà ìkà. Kí ni wọ́n ń ṣe?

Ṣe ni àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì ń lo ‘apá wọn fún ète títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.’ (Ẹsẹ 6) Ọ̀rọ̀ náà “apá” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ṣàpẹẹrẹ agbára tàbí àṣẹ. Ìyẹn ni ìtumọ̀ Bíbélì míì fi sọ pé: “Awọn ọmọ-alade Ísraeli, olukuluku ninu agbara rẹ̀ wà ninu rẹ lati ta ẹjẹ silẹ.” Báwo ni ìwà ìrẹ́jẹ kò ṣe ní wà nígbà tí àwọn aṣáájú tó yẹ kó máa gbé òfin ró, kí wọ́n sì mú kí àwọn èèyàn hùwà tó bófin mu ń ṣi agbára wọn lò, tí wọ́n sì ń pa àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀?

Lẹ́yìn èyí, Ìsíkíẹ́lì wá sọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn aṣáájú àti àwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣàìgbọràn sí Òfin Jèhófà. Ìsíkíẹ́lì sọ pé: “Wọ́n ti fojú tín-ín-rín baba àti ìyá.” (Ẹsẹ 7) Bí wọ́n ṣe ń fojú tín-ínrín àwọn òbí, ṣe ni wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fọ́ ìpìlẹ̀ tó gbé àwùjọ wọn ró, ìyẹn ìdílé.—Ẹ́kísódù 20:12.

Àwọn ọ̀bàyéjẹ́ náà ń rẹ́ àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ tó wà láàárín wọn jẹ. Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá rúfin, ṣe ni wọ́n ń ṣàì ka ìdí tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin náà sí, ìdí náà sì ni pé kí ìfẹ́ lè gbilẹ̀ láàárín wọn. Bí àpẹẹrẹ, Òfin Ọlọ́run sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rí i dájú pé wọ́n gba ti àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó ń gbé láàárín wọn rò. (Ẹ́kísódù 22:21; 23:9; Léfítíkù 19:33, 34) Ṣùgbọ́n ṣe ni àwọn èèyàn náà ń “lu àtìpó ní jìbìtì.”—Ẹsẹ 7.

Àwọn èèyàn náà tún ń hùwà ìkà sí àwọn “ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó” tó jẹ́ pé wọn kò ní olùgbèjà. (Ẹsẹ 7) Jèhófà kì í fi ọ̀rọ̀ àwọn tí òbí wọn tàbí àwọn tí ọkọ àbí aya wọn kú ṣeré rárá. Nítorí náà, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun fúnra òun ló máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọ́n ń ṣẹ́ ọmọ tí kò ní olùrànlọ́wọ́ tàbí opó níṣẹ̀ẹ́.—Ẹ́kísódù 22:22-24.

Ọ̀nà báwọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Ìsíkíẹ́lì gbà rú Òfin Ọlọ́run, tí wọ́n sì tẹ́ńbẹ́lú ẹ̀mí ìfẹ́ tí Òfin yẹn ì bá mú kó gbilẹ̀ láàárín wọn. Kí ni Jèhófà wá ṣe? Ó ṣèlérí pé: “Èmi yóò da ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lé wọn lórí.” (Ẹsẹ 31) Jèhófà sì ṣe ohun tó sọ lóòótọ́, ó jẹ́ kí àwọn ará Bábílónì wá pa Jerúsálẹ́mù run, kí wọ́n sì kó àwọn èèyàn inú rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Ọ̀rọ̀ Ìsíkíẹ́lì yìí kọ́ wa ní ohun méjì nípa irú ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwà ìrẹ́jẹ: Àkọ́kọ́, ó kórìíra rẹ̀; ìkejì, ó máa ń ṣàánú àwọn aláìṣẹ̀ tí wọ́n bá rẹ́ jẹ. Ọlọ́run kò sì tíì yí pa dà. (Málákì 3:6) Ó ṣèlérí pé òun máa mú ìwà ìrẹ́jẹ àti àwọn tó ń rẹ́ni jẹ kúrò láìpẹ́. (Òwe 2:21, 22) O ò ṣe túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run tó jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo,” kí o sì mọ bí o ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ ọn.—Sáàmù 37:28.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún August:

Ìsíkíẹ́lì 21-38

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

Jèhófà sọ ọ́ kedere pé àwọn tó wà nípò àṣẹ kò gbọ́dọ̀ ṣi agbára wọn lò