Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Iṣẹ́ Ìyanu?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Iṣẹ́ Ìyanu?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Iṣẹ́ Ìyanu?

“Ohun tá a bá pè ní iṣẹ́ ìyanu kì í bá àwọn ìlànà tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ń tẹ̀ lé mu rárá.”​—RICHARD DAWKINS, ẸNI TÓ FÌGBÀ KAN JẸ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N NÍNÚ BÍ ÀWỌN ÈÈYÀN ṢE LÓYE ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ.

“Téèyàn bá gbà gbọ́ pé iṣẹ́ ìyanu wà, ó bọ́gbọ́n mu. Kò lòdì sí ohun tí ẹ̀sìn fi ń kọ́ni rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àmì pé Ọlọ́run fẹ́ràn ìṣẹ̀dá àti pé ó ṣì ń fi ọwọ́ agbára rẹ̀ hàn nínú ìṣẹ̀dá.”​—ROBERT A. LARMER, Ọ̀JỌ̀GBỌ́N NÍNÚ ÌMỌ̀ ỌGBỌ́N ORÍ.

“ǸJẸ́ o gbà pé iṣẹ́ ìyanu wà?” Bá a ṣe rí i nínú ohun tí àwọn èèyàn sọ lókè yìí, èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ní nípa iṣẹ́ ìyanu. Ìwọ ńkọ́, kí ni ìdáhùn tìrẹ?

Ó lè máà yá ẹ lára láti sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo gbà.” O lè máa rò pé tó o bá dáhùn bẹ́ẹ̀, á fi ẹ́ hàn bí ẹni tó máa ń gba irọ́ gbọ́ tàbí aláìmọ̀kan. Ọ̀pọ̀ èèyàn náà máa ń rò bẹ́ẹ̀.

O sì lè jẹ́ ẹni tó dá lójú pé iṣẹ́ ìyanu ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. O lè gbà pé òótọ́ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu inú Bíbélì ṣẹlẹ̀, irú bí Mósè ṣe pín Òkun Pupa níyà. O tún lè gbà pé iṣẹ́ ìyanu ṣì ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò tiwa yìí. Kódà, ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé “ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn tó wà ní ilẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ló gbà pé iṣẹ́ ìyanu ṣì ń ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí a bá rí èèyàn mẹ́rin ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mẹ́ta nínú wọn máa gbà pé iṣẹ́ ìyanu ń ṣẹlẹ̀. Bákan náà, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, nǹkan bí ìdajì àwọn èèyàn ibẹ̀ gbà pé iṣẹ́ ìyanu ṣì ń ṣẹlẹ̀.” (The Cambridge Companion to Miracles, tí Graham H. Twelftree ṣe àtúnṣe rẹ̀) Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe àwọn Kristẹni nìkan ló nígbàgbọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé ‘ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀sìn ló gbà gbọ́ pé iṣẹ́ ìyanu ń ṣẹlẹ̀.’—Britannica Encyclopedia of World Religions.

Ó sì lè jẹ́ pé o wà lára àwọn tó máa dáhùn pé: “Èmi ò mọ̀ bóyá ó ń ṣẹlẹ̀ o, mi ò sì fẹ́ mọ̀ rárá! Iṣẹ́ ìyanu kì í ṣẹlẹ̀ láyé tèmi!” Àmọ́, kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ̀ nípa iṣẹ́ ìyanu?

Fojú inú wo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ná: Jẹ́ ká sọ pé ẹnì kan ní àrùn kògbóògùn. Ó wá ka àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn àwọn oníṣègùn kan tó ṣeé gbà gbọ́, tó sọ nípa oògùn kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tó lè wo àrùn tó ń ṣe é, ǹjẹ́ kò ní dára kó wáyè láti ṣèwádìí díẹ̀ nípa ohun tí ìwé ìròyìn yẹn sọ? Lọ́nà kan náà, Bíbélì sọ pé àwọn iṣẹ́ ìyanu tó kàmàmà yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Wọ́n máa ní ipa rere lórí gbogbo ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ kò ní dára kí o wáyè láti ṣèwádìí bóyá àwọn ìlérí yẹn ṣeé gbára lé?

Àmọ́, ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Bíbélì ṣèlérí yẹn, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun mẹ́ta tí àwọn èèyàn fi ń ta ko iṣẹ́ ìyanu.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

KÍ NI IṢẸ́ ÌYANU?

Iṣẹ́ ìyanu jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ré kọjá agbára èèyàn tàbí agbára tá a mọ̀ látinú ìṣẹ̀dá, àwọn èèyàn sì sábà máa ń sọ pé agbára àrà ọ̀tọ̀ kan ló wà lẹ́yìn irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.