Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ A Lè Gbà Pé Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu inú Bíbélì Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?

Ǹjẹ́ A Lè Gbà Pé Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu inú Bíbélì Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?

Ǹjẹ́ A Lè Gbà Pé Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu inú Bíbélì Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?

TÍ ẸNÌ kan bá sọ ìtàn kan tó yani lẹ́nu fún ẹ, ó dájú pé wàá ronú nípa irú èèyàn tó sọ ọ́ kó o tó mọ̀ bóyá wàá gbà á gbọ́. Ara ohun tó o sì máa wò mọ́ onítọ̀hún ni ọ̀nà tó gbà sọ ọ́ àti bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí látẹ̀yìn wá kó o tó gbà pé òótọ́ ni ohun tó sọ. Ó ṣe tán, tó bá ti pẹ́ tó o ti mọ̀ ọ́n pé ó máa ń sọ òótọ́, tí kò sì parọ́ fún ẹ rí, wàá fẹ́ gba ohun tó sọ yìí gbọ́.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tó wà nínú Bíbélì ṣe rí. Kò sí ìkankan nínú wa láyé nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn wáyé. Ṣùgbọ́n a lè mọ̀ bóyá àwọn ìtàn inú Bíbélì yẹn ṣeé gbà gbọ́, pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni. Báwo la ṣe lè mọ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mélòó kan tá a fi lè gbà pé àwọn iṣẹ́ ìyanu inú Bíbélì ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.

Gbangba ni ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn ti wáyé. Nígbà míì, àwọn iṣẹ́ ìyanu náà máa ń ṣojú ẹgbẹẹgbẹ̀rún tàbí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn. (Ẹ́kísódù 14:21-31; 19:16-19) Gbangba ni wọ́n ti ṣẹlẹ̀ kì í ṣe níkọ̀kọ̀.

Iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn máa ń ṣẹlẹ̀ láìsí afẹfẹyẹ̀yẹ̀ kankan. Ṣe ni wọ́n máa ń wáyé láìsí àkànṣe ètò tàbí àṣehàn tàbí bojúbojú kankan. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu inú Bíbélì ló jẹ́ pé ṣe ni ẹni tó ṣe é kàn ṣe kòńgẹ́ ipò tó mú kó ṣe é tàbí àwọn tó bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe é. (Máàkù 5:25-29; Lúùkù 7:11-16) Ní irú àwọn ipò yẹn, kò lè jẹ́ pé ẹni tó ṣe iṣẹ́ ìyanu náà dìídì ṣètò pé kí àwọn kan díbọ́n bí ẹni tí nǹkan ṣe láti fi tan àwọn èèyàn jẹ.

Àwọn tó ṣe iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn kò ṣe é láti fi gba ògo, láti di olókìkí tàbí ọlọ́rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe é kí àwọn èèyàn lè máa yín Ọlọ́run lógo ni. (Jòhánù 11:1-4, 15, 40) Kódà, wọ́n máa ń bínú sí ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti fi agbára iṣẹ́ ìyanu wá ọrọ̀.—2 Àwọn Ọba 5:15, 16, 20, 25-27; Ìṣe 8:18-23.

Onírúurú iṣẹ́ ìyanu tó wà nínú Bíbélì fi hàn pé wọn ò kàn lè jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé omi di wáìnì, wọ́n mú kí òkun àti ẹ̀fúùfù pa rọ́rọ́, wọ́n mú kí ọ̀dá wà, wọ́n sì mú kí òjò tún bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, wọ́n mú aláìsàn lára dá, wọ́n sì la ojú afọ́jú. Gbogbo iṣẹ́ ìyanu yìí àti àwọn míì tó wà nínú Bíbélì fi hàn pé agbára tó ju ti ẹ̀dá èèyàn lọ, tó sì lágbára láti darí ohunkóhun bó ṣe fẹ́, ló wà lẹ́yìn àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn.—1 Àwọn Ọba 17:1-7; 18:41-45; Mátíù 8:24-27; Lúùkù 17:11-19; Jòhánù 2:1-11; 9:1-7.

Àwọn alátakò tí iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn ṣojú wọn kò jiyàn pé wọ́n ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Nígbà tí Jésù jí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde, àwọn olórí ìsìn tó ń ta ko Jésù kò jiyàn pé Lásárù kú. Wọn ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Torí pé ó ti tó ọjọ́ mẹ́rin tí wọ́n ti sin òkú Lásárù. (Jòhánù 11:45-48; 12:9-11) Kódà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn tó kọ ìwé Támọ́dì àwọn Júù ṣì ń sọ pé Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu. Orísun agbára rẹ̀ ni wọ́n kàn ń jiyàn lé lórí. Bákan náà, nígbà tí wọ́n mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá síwájú ilé ẹjọ́ àwọn Júù, wọn ò bi wọ́n pé “Ǹjẹ́ ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu?” Ohun tí wọ́n bi wọ́n ni pé: “Agbára wo tàbí orúkọ ta ni ẹ fi ṣe èyí?”—Ìṣe 4:1-13.

Torí náà, ǹjẹ́ a lè gbà pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa iṣẹ́ ìyanu? Bẹ́ẹ̀ ni. Gbogbo ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn iṣẹ́ ìyanu tó wà nínú Bíbélì ní àwọn ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé wọ́n ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Àwọn ìdí míì tún wà tá a fi lè gbà pé òótọ́ ni àwọn ohun tí Bíbélì sọ. Bí àpẹẹrẹ, tí Bíbélì bá sọ ìtàn kan, ó máa ń sọ àkókò tó ṣẹlẹ̀, ibi tó ti ṣẹlẹ̀ àti orúkọ àwọn tí ọ̀ràn náà kàn. Kódà bí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn tó wà nínú Bíbélì ṣe péye tó máa ń jọ àwọn alátakò Bíbélì lójú. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ti ní ìmúṣẹ, títí kan gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ inú rẹ̀. Àti pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ràn ló wà nínú Bíbélì nípa bí àwọn èèyàn ṣe lè máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà, àwọn ìmọ̀ràn náà sì ti ran onírúurú èèyàn, lọ́mọdé lágbà, lọ́wọ́. Kò tún sí ibòmíì tí a ti lè rí ìmọ̀ràn nípa bí àlàáfíà ṣe lè wà láàárín àwọn èèyàn tó lè dà bíi ti inú Bíbélì.

Tí kò bá tíì dá ẹ lójú pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, o ò ṣe wáyè láti túbọ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ̀ dáadáa? Bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ Bíbélì sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. (Jòhánù 17:17) Wàá rí i pé o lè gba ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn gbọ́. Tó o bá sì ti gbà pé òótọ́ ni àwọn ìtàn náà, wàá lè gbà pé òótọ́ ni àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn alátakò Jésù kò jiyàn pé Lásárù kú