Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Iṣẹ́ Ìyanu Ń Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?—Ohun Mẹ́ta Táwọn Èèyàn Fi Ń Ta Ko Iṣẹ́ Ìyanu

Ǹjẹ́ Iṣẹ́ Ìyanu Ń Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?—Ohun Mẹ́ta Táwọn Èèyàn Fi Ń Ta Ko Iṣẹ́ Ìyanu

Ǹjẹ́ Iṣẹ́ Ìyanu Ń Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?—Ohun Mẹ́ta Táwọn Èèyàn Fi Ń Ta Ko Iṣẹ́ Ìyanu

ÀTAKÒ KÌÍNÍ: Iṣẹ́ ìyanu ò lè wáyé torí wọ́n ta ko àwọn ìlànà tó ń darí bí àwọn nǹkan ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ látọjọ́ táláyé ti dáyé. Gbogbo ohun tá a mọ̀ nípa àwọn ìlànà tó ń darí bí nǹkan ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé dá lórí ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kíyè sí pé ó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wa. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo nǹkan tó jẹ mọ́ àwọn ìlànà yìí ni àwa èèyàn mọ̀. Ńṣe ni àwọn ìlànà yẹn dà bí ìlànà gírámà èdè tí a ń sọ. Nígbà míì àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan máa ń wà tí kì í sábà tẹ̀ lé ìlànà gírámà èdè náà. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwa èèyàn ṣì mọ̀ nípa àwọn ìlànà tó ń darí bí nǹkan ṣe ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. (Jóòbù 38:4) Bí àpẹẹrẹ, ògbóǹkangí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan lè ti fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀kan nínú àwọn ìlànà tó ń darí bí nǹkan ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. Àmọ́ tí ohun kan bá wá ṣẹlẹ̀ tí kò tẹ̀ lé ìlànà tó ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ yẹn, ṣe ló máa tún òye rẹ̀ nípa ìlànà náà gbé yẹ̀ wò. Nítorí òwe kan sọ pé òjò ọjọ́ kan ṣoṣo ló ń ṣẹ́gun ẹgbàá ọ̀dá.

Ìtàn apanilẹ́rìn-ín kan jẹ́ ká rí bó ṣe rọrùn tó pé kéèyàn gbé èrò rẹ̀ karí òye tí kò kún tó. Ọ̀gbẹ́ni John Locke (tó gbé ayé láàárín ọdún 1632 sí 1704) sọ ìtàn kan nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ikọ̀ orílẹ̀-èdè Holland, ìyẹn Netherlands báyìí, àti ọba ilẹ̀ Siam, ìyẹn orílẹ̀-èdè Thailand ìsinsìnyí. Ó sọ pé, nígbà tí ikọ̀ yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè rẹ̀ fún ọba yẹn, ó ní ìgbà míì máa ń wà tí erin lè rìn lórí omi. Ọba yẹn sọ pé irọ́ ni ikọ̀ náà ń pa fún òun, pé kò lè ṣẹlẹ̀. Àmọ́ ohun tí ọba yẹn kò tíì mọ̀ ni ikọ̀ yẹn wulẹ̀ ń sọ fún un. Ọba náà kò mọ́ pé tí omi bá dì gbagidi, erin lè rìn lórí rẹ̀. Lójú ọba yìí, kò ṣeé ṣe torí pé òye rẹ̀ nípa omi kò débẹ̀.

Wo àwọn nǹkan tí àwọn èèyàn ti gbé ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àmọ́ tó jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn èèyàn lè máa rò pé kò ṣeé ṣe:

● Ọkọ̀ òfuurufú kan lè gbé èrò tó lé ní ẹgbẹ̀rin (800) fò láti ìlú New York ní Amẹ́ríkà lọ sí ìlú Singapore ní ilẹ̀ Éṣíà láìdúró, kó sì máa sáré tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] kìlómítà láàárín wákátì kan.

● Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé kan wà tó ń jẹ́ kí àwọn tó wà ní ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé lè máa rí ara wọn bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀.

● Èèyàn lè gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún orin sórí ẹ̀rọ kékeré kan tí kò tó páálí ìṣáná.

● Àwọn dókítà oníṣẹ́ abẹ lè pààrọ̀ ọkàn aláìsàn kan tàbí ẹ̀yà míì ní ara rẹ̀, kí wọ́n fi èyí tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa síbẹ̀, kí aláìsàn náà sì máa gbé ayé rẹ̀ lọ.

Kí la rí fà yọ látinú gbogbo ohun tí a ti gbé yẹ̀ wò yìí? Òun ni pé: Tí ẹ̀dá èèyàn lásán bá lè ṣe irú nǹkan wọ̀nyí, èyí tí àwọn èèyàn gbà pé kò lè ṣeé ṣe lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn, ó dájú pé Ọlọ́run tó dá ayé àtọ̀run àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn, lè ṣe àwọn ohun àgbàyanu tí àwa èèyàn kò tíì lóye ní kíkún tàbí tí a kò tíì lè ṣe irú rẹ̀. *Jẹ́nẹ́sísì 18:14; Mátíù 19:26.

ÀTAKÒ KEJÌ: Tí kò bá sí ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìyanu nínú Bíbélì àwọn èèyàn kò ní fẹ́ gba ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ gbọ́. Bíbélì pàápàá kò sọ pé ká máa gba gbogbo iṣẹ́ ìyanu gbọ́. Kódà ohun tó yàtọ̀ pátápátá síyẹn ni Bíbélì sọ. Ó kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra tó bá dọ̀rọ̀ gbígba iṣẹ́ ìyanu àti àwọn àmì àgbàyanu gbọ́. Kíyè sí ìkìlọ̀ Bíbélì tó ṣe kedere yìí: “Ani [ẹni ẹ̀ṣẹ̀ náà], ẹni ti wiwa rẹ̀ yoo ri gẹgẹ bi iṣẹ Satani pẹlu agbara gbogbo ati àmì ati iṣẹ-iyanu èké. Ati pẹlu ìtànjẹ àìṣododo gbogbo.”​—2 Tẹsalóníkà 2:9, 10, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Jésù Kristi náà kìlọ̀ fún wa pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa pe ara wọn ní ọmọlẹ́yìn òun àmọ́ wọn kì í ṣe ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó ní àwọn kan tiẹ̀ máa sọ pé: “Olúwa, Olúwa, a kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní orúkọ rẹ; a lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde ní orúkọ rẹ; a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ rẹ.” (Mátíù 7:22, Ìròhìn Ayọ̀) Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé òun kò ní gbà pé àwọn èèyàn yẹn jẹ́ ọmọ ẹ̀yin òun. (Mátíù 7:23) Nítorí náà, Jésù kò fi kọ́ni pé gbogbo iṣẹ́ ìyanu tó wáyé ló jẹ́ nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run.

Ọlọ́run kò sọ pé orí iṣẹ́ ìyanu ni kí àwọn tó ń sin òun gbé ìgbàgbọ́ wọn kà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé e karí àwọn ẹ̀rí tó dájú.—Hébérù 11:1.

Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa nínú Bíbélì, ìyẹn àjíǹde Jésù Kristi. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn àjíǹde Jésù, àwọn Kristẹni kan ní ìlú Kọ́ríńtì bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn pé Jésù kò jíǹde. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe láti ran àwọn Kristẹni yẹn lọ́wọ́? Ṣé ohun tó kàn sọ fún wọn ni pé, “Ẹ lọ ní ìgbàgbọ́ sí i?” Rárá o. Ṣe ló rán wọn létí àwọn ẹ̀rí tó dájú nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀. Ó ní: “A sin [Jésù], bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé ó fara han Kéfà, lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, púpọ̀ jù lọ nínú àwọn tí wọ́n ṣì wà títí di ìsinsìnyí.”—1 Kọ́ríńtì 15:4-8.

Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni yẹn gbà pé iṣẹ́ ìyanu yẹn ṣẹlẹ̀ lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o. Torí Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí a kò bá tíì gbé Kristi dìde, dájúdájú, asán ni ìwàásù wa, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa.” (1 Kọ́ríńtì 15:14) Ohun pàtàkì ni Pọ́ọ̀lù ka ọ̀rọ̀ náà sí. Torí pé orí àjíǹde Jésù tó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu yìí ni ìgbàgbọ́ wọn dá lé. Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé òótọ́ pọ́ńbélé ni, nítorí ẹ̀rí wà látọ̀dọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn tí àjíǹde yìí ṣojú wọn, tí wọ́n ṣì wà láàyè nígbà yẹn. Kódà, àwọn ẹlẹ́rìí yìí gbà láti kú dípò tí wọ́n á fi sẹ́ pé àjíǹde Jésù tó ṣojú wọn kò ṣẹlẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:17-19.

ÀTAKÒ KẸTA: Àwọn nǹkan tó kàn máa ń dédé ṣẹlẹ̀ fúnra wọn ni àwọn aláìmọ̀kan máa ń pè ní iṣẹ́ ìyanu. Bí àwọn ọ̀mọ̀wé kan ṣe máa ń ṣàlàyé àwọn iṣẹ́ ìyanu tó wà nínú Bíbélì ni pé wọ́n wulẹ̀ jẹ́ àwọn nǹkan tó máa ń dédé ṣẹlẹ̀ fúnra wọn, láìsí pé ọwọ́ Ọlọ́run wà níbẹ̀. Wọ́n ronú pé irú àlàyé yìí ló máa jẹ́ kí àwọn èèyàn lè gba Bíbélì gbọ́. Lóòótọ́ àwọn nǹkan tó máa ń dédé ṣẹlẹ̀ fúnra wọn, irú bí ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn àti kí òkè ya lulẹ̀, lè wà lára àwọn iṣẹ́ ìyanu míì, ṣùgbọ́n nǹkan kan wà tí àwọn ọ̀mọ̀wé yìí máa ń gbójú fò nínú àlàyé wọn. Wọ́n máa ń gbójú fo àkókò tí Bíbélì sọ pé àwọn iṣẹ́ ìyanu náà wáyé.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan sọ pé àwọn kò gbà pé Odò Náílì di ẹ̀jẹ̀ nígbà ìyọnu àkọ́kọ́ tó wáyé ní ilẹ̀ Íjíbítì. Wọ́n ní amọ̀ pupa lásán tó dà pọ̀ mọ́ àwọn kòkòrò pupa kan tí wọ́n ń pè ní flagellate, ló ṣàn wá sínú odò náà. Ṣùgbọ́n ohun tí Bíbélì sọ ni pé odò náà di ẹ̀jẹ̀, kò sọ pé ó di amọ̀ pupa. Tí a bá fara balẹ̀ ka Ẹ́kísódù 7:14-21, a máa rí i pé àkókò tí Mósè ní kí Áárónì fi ọ̀pá rẹ̀ lu Odò Náílì gẹ́lẹ́ ni iṣẹ́ ìyanu yẹn ṣẹlẹ̀. Kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan míì ló kàn jẹ́ kí odò náà dédé pupa wá fúnra rẹ̀, bó ṣe bọ́ sí àkókó tí Áárónì fi ọ̀pá lu odò yẹn gẹ́lẹ́ tó iṣẹ́ ìyanu lọ́tọ̀!

Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ míì tó fi hàn pé àkókò tí iṣẹ́ ìyanu kan wáyé ṣe pàtàkì, ìyẹn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Odò Jọ́dánì tó kún àkúnya dí wọn lọ́nà. Bíbélì wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa, ó ní: “Ní kété tí àwọn olùru Àpótí náà ti lọ títí dé Jọ́dánì, tí àwọn àlùfáà tí ó ru Àpótí náà sì tẹ ẹsẹ̀ wọn bọ etí omi náà . . . , ìgbà náà ni omi tí ń ṣàn wálẹ̀ láti òkè bẹ̀rẹ̀ sí dúró jẹ́ẹ́. Ó dìde dúró bí ìsédò kan tí ó jìnnà réré gan-an ní Ádámù, ìlú ńlá tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sárétánì.” (Jóṣúà 3:15, 16) Ṣé ìmìtìtì ilẹ̀ ló fà á àbí ilẹ̀ ló kàn dédé ya dí ojú odò yẹn? Ìtàn Bíbélì yẹn kò sọ fún wa. Àmọ́ àkókó tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé jẹ́ ohun ìyanu. Àkókò tí Jèhófà sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ gan-an náà ló ṣẹlẹ̀.—Jóṣúà 3:7, 8, 13.

Torí náà, ǹjẹ́ a lè sọ pé iṣẹ́ ìyanu wà lóòótọ́? Bíbélì sọ pé wọ́n wà. Ohun tó sọ fún wa sì fi hàn pé wọn kì í ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ tó kàn ṣàdédé ṣẹlẹ̀ fúnra wọn. Nígbà náà, ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé iṣẹ́ ìyanu kì í ṣẹlẹ̀, kìkì nítorí pé wọn kì í wáyé lójoojúmọ́?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó o bá fẹ́ rí ẹ̀rí síwájú sí i tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, jọ̀wọ́ ka ìwé pẹlẹbẹ náà Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti Was Life Created? tàbí kó o béèrè ìsọfúnni síwájú sí i lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó fún ẹ ní ìwé ìròyìn yìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn lè máa rò pé kò lè ṣeé ṣe kí èèyàn fò lójú òfuurufú, kó máa sáré tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà láàárín wákátì kan