Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ibo ni wọ́n ti rí àwọn òkúta iyebíye tó wà lára aṣọ ìgbàyà àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì?

Ẹ̀yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì tí wọ́n dé inú aginjù ni Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe aṣọ ìgbàyà yìí. (Ẹ́kísódù 28:15-21) Àwọn òkúta tó wà lára aṣọ ìgbàyà náà ni rúbì, tópásì, émírádì, tọ́kọ́ásì, sàfáyà, jásípérì, léṣémù, ágétì, ámétísì, kírísóláítì, ónísì àti jéèdì. * Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tiẹ̀ lè rí àwọn òkúta iyebíye yìí?

Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ohun pàtàkì ni wọ́n ka àwọn òkúta iyebíye sí, wọ́n sì máa ń tà wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Íjíbítì àtijọ́ máa ń wá àwọn òkúta iyebíye yẹn dé ibi tó jìnnà gan-an, irú bí àwọn orílẹ̀-èdè tí a wá mọ̀ sí Ìráànì, Afghanistan, àti bóyá títí dé Íńdíà. Oríṣiríṣi òkúta iyebíye ni àwọn ará Íjíbítì máa ń rí níbi tí wọ́n ti ń wa kùsà. Àwọn ọba Íjíbítì nìkan ló sì ní àṣẹ lórí wíwa àwọn òkúta iyebíye jáde ní àgbègbè abẹ àṣẹ wọn. Baba ńlá náà Jóòbù sọ bí àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ ṣe ń gba ojú ihò abẹ́lẹ̀ àti ojú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ láti lọ wá àwọn òkúta iyebíye. Jóòbù mẹ́nu ba sàfáyà àti tópásì ní pàtó, pé wọ́n wà lára àwọn ìṣúra tí wọ́n máa ń wà jáde látinú ilẹ̀.—Jóòbù 28:1-11, 19.

Ìwé Ẹ́kísódù sọ pé nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, “wọ́n . . . gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì,” ìyẹn ni pé wọ́n gba àwọn nǹkan olówó iyebíye lọ́wọ́ wọn. (Ẹ́kísódù 12:35, 36) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilẹ̀ Íjíbítì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti rí àwọn òkúta tó wà lára aṣọ ìgbàyà àlùfáà àgbà.

Kí nìdí tí wọ́n fi ń lo wáìnì gẹ́gẹ́ bí oògùn láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

Nínú àkàwé kan, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tí àwọn ọlọ́ṣà nà. Jésù sọ pé ará Samáríà kan ló ràn án lọ́wọ́ tó bá a di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, tó sì da “òróró àti wáìnì sórí wọn.” (Lúùkù 10:30-34) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí Tímótì ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó gbà á níyànjú pé: “Má mu omi mọ́, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí àpòlúkù rẹ àti ọ̀ràn àìsàn rẹ tí ó ṣe lemọ́lemọ́.” (1 Tímótì 5:23) Ǹjẹ́ ohun tí Jésù sọ pé ará Samáríà yẹn lò láti fi ṣe ìwòsàn àti ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì bá ìlànà ìṣègùn mu?

Ìwé náà Ancient Wine sọ pé wáìnì jẹ́ “apàrora, apakòkòrò, kódà a lè pè é ní gbogboǹṣe.” Láyé àtijọ́, àwọn ará Íjíbítì, Mesopotámíà àti Síríà máa ń lo wáìnì gan-an fún ṣíṣe ìwòsàn. Ìwé The Oxford Companion to Wine sọ pé wáìnì ni “ohun tó ti wà ní àkọsílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ jù lọ, pé wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí oògùn.” Ní ti ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba Tímótì, ìwé The Origins and Ancient History of Wine sọ pé: “Àyẹ̀wò ti fi hàn pé tí wọ́n bá da kòkòrò tó ń fa ibà jẹ̀funjẹ̀fun àti àwọn kòkòrò àrùn burúkú míì sínú ọtí wáìnì, kíá ni wọ́n ń kú.” Ìwádìí òde òní sì ti jẹ́rìí sí i pé àwọn kan lára èròjà tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] tó wà nínú ọtí wáìnì lè pa kòkòrò àrùn lọ́nà bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wúlò gan-an fún ọ̀pọ̀ nǹkan míì nínú ìṣègùn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Kì í ṣe gbogbo òkúta wọ̀nyí la mọ orúkọ tí wọ́n ń pè wọ́n lóde òní.

[[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwòrán àwọn àgbẹ̀ tó ń tẹ àjàrà níbi ìfúntí wáìnì, tó wà lára ibojì Nakht ní Tíbésì, nílẹ̀ Íjíbítì

[Credit Line]

Gianni Dagli Orti/The Art Archive at Art Resource, NY