Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tí mo bá ń mu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe ǹjẹ́ ó tiẹ̀ kan Ọlọ́run?

Tí mo bá ń mu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe ǹjẹ́ ó tiẹ̀ kan Ọlọ́run?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Tí mo bá ń mu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe ǹjẹ́ ó tiẹ̀ kan Ọlọ́run?

▪ Ẹnì kan lè fi òótọ́ inú béèrè ìbéèrè yẹn níwọ̀n bí kò ti sí òfin inú Bíbélì tó mẹ́nu kan mímu sìgá tàbí tábà, tàbí lílo àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ó ṣòro láti fòye mọ èrò Ọlọ́run lórí kókó yìí? Rárá o.

Bíbélì sọ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Àwọn ìlànà àti àlàyé tó ṣe kedere tó jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká tọ́jú ara wa wà nínú Ìwé Mímọ́. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tí àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí nípa bí mímu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe, ṣe máa ń ṣàkóbá fún ìlera èèyàn. A ó tún wá wo bí ohun tí wọ́n ṣàwárí ṣe bá àwọn ìlànà Bíbélì mu.

Sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe máa ń ṣàkóbá fún ìlera àwọn tó ń mu ún, ó sì wà lára ohun tó ń fi ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò jù. Ní Amẹ́ríkà, ẹ̀rí fi hàn pé téèyàn márùn-ún bá kú, ọ̀kan nínú wọn máa jẹ́ ẹni tí májèlé sìgá tàbí ohun tí wọ́n fi tábà ṣe pa. Àjọ Tó Ń Rí Sí Ìlòkulò Oògùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé lọ́dọọdún ní Amẹ́ríkà, sìgá mímu àti àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe máa ń pa ọ̀pọ̀ èèyàn ju àpapọ̀ àwọn tó ń tipa “ọtí líle, oògùn olóró, ìpànìyàn, pípa ara ẹni, jàǹbá ọkọ̀ àti àrùn éèdì” kú lọ.

Àwọn tó ń mu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe máa ń ṣe ìpalára fún àwọn ẹlòmíì. Kò sí ìwọ̀n èéfín sìgá téèyàn fà símú tí kò léwu. Àwọn tí kì í mu sìgá àmọ́ tí wọ́n ń fa èéfín sìgá tí àwọn míì ń mu símú lè tipa bẹ́ẹ̀ ní àrùn ọkàn àti àrùn jẹjẹrẹ tó ń ba ẹ̀dọ̀ fóró jẹ́. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn dókítà ṣàwárí ewu mìíràn, ìyẹn ni pé èèyàn lè kó májèlé láti ara èròjà olóró tó wà nínú eérú sìgá tó máa ń ṣẹ́ kù sára aṣọ, kápẹ́ẹ̀tì tàbí ibòmíì lẹ́yìn tí èéfín sìgá téèyàn lè fojú rí bá ti lọ tán.” Ìlera àwọn ọmọdé ni àwọn èròjà olóró yìí máa ń ṣàkóbá fún jù, ó sì lè sọ wọ́n dẹni tí nǹkan kì í tètè yé.

Sìgá tàbí ohun tí wọ́n fi tábà ṣe máa ń di bárakú. Ṣe ni ó máa ń sọ ẹni tó bá ń lò ó di ẹrú àṣà tó ń pani lára. Kódà, àwọn tó ń ṣèwádìí gbà pé èròjà nicotine wà lára ohun tó máa ń ṣòro jù láti fi sílẹ̀ tó bá ti di bárakú. Ó sì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èròjà olóró inú sìgá àti àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe.

Báwo ni àwọn ohun tí wọ́n sọ yìí ṣe wá bá àwọn ìlànà Bíbélì mu? Kíyè sí àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí:

Ọlọ́run fẹ́ ká bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí èèyàn. Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó bá fẹ́ rí ojú rere òun gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí èèyàn. (Diutarónómì 5:17) Òfin yẹn sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe ìgbátí sí etí gbogbo òrùlé wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé òrùlé pẹrẹsẹ ni ilé wọn máa ń ní, àwọn ará ilé sì máa ń lò síbẹ̀ dáadáa. Ìgbátí yìí kò ní jẹ́ kí àwọn ará ilé náà tàbí àwọn mìíràn já bọ́ láti orí òrùlé, kí wọ́n sì fi ara pa tàbí kí wọ́n kú pàápàá. (Diutarónómì 22:8) Bákan náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn ẹranko wọn ò ṣèpalára fún àwọn èèyàn. (Ẹ́kísódù 21:28, 29) Ẹni tó bá ń mu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe, ń tàpá sí ìlànà tó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún òfin yẹn. Ó ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣèpalára fún ara rẹ̀. Yàtọ̀ sí èyí, sìgá tàbí tábà tó ń mu tún ń ṣàkóbá fún ìlera àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀.

Ọlọ́run fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òun àti ọmọnìkejì wa. Jésù Kristi sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun gbọ́dọ̀ pa òfin méjì tó tóbi jù lọ mọ́. Ìyẹn ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wọn, ọkàn wọn, èrò-inú wọn àti gbogbo okun wọn, kí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn gẹ́gẹ́ bí ara wọn. (Máàkù 12:28-31) Ẹ̀mí wa jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, torí náà, ẹni tí ó bá ń mu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe kò ka ẹ̀mí tó jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún un sí, ìyẹn sì fi hàn pé kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣe 17:26-28) Ohun tó ti di bárakú fún onítọ̀hún yìí lè ṣe ìpalára gan-an fún àwọn ẹlòmíì, torí náà kò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé òun fẹ́ràn ọmọnìkejì òun.

Ọlọ́run sọ pé ká yàgò fún àwọn ìwà àìmọ́. Bíbélì sọ pé kí gbogbo Kristẹni wẹ ara wọn mọ́ “kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ó dájú pé mímu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe máa ń sọni di ẹlẹ́gbin. Lóòótọ́ kì í sábà rọrùn fún àwọn tó bá fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, ìyẹn ni pé kí wọ́n jáwọ́ nínú mímu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe. Àmọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, wọ́n lè jáwọ́ pátápátá kúrò nínú ohun asọnidi-ẹlẹ́gbin tó ń di bárakú yìí.