Báwo Ni Ìwà Ìbàjẹ́ Ṣe Gbilẹ̀ Tó?
“Ilé iṣẹ́ wa máa ń bá ìjọba ìbílẹ̀ kan ṣiṣẹ́. Ó sì sábà máa ń tó oṣù méjì tàbí mẹ́ta kí wọ́n tó san owó iṣẹ́ tí a bá ṣe. Àmọ́ láìpẹ́ yìí, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba náà pè mí lórí fóònù, pé òun lè bá wa ṣe é kí á tètè máa rí owó gbà tí ẹ̀gúnjẹ bá ti lè máa yọ fún òun.”—JOHN. *
ǸJẸ́ wọ́n ti ṣe ohun tó jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ sí ọ rí? Àfàìmọ̀ ni àwọn oníwà ìbàjẹ́ ò ti ní ṣe àkóbá kan fún ọ rí, bí kò bá tiẹ̀ jẹ́ irú èyí tí a mẹ́nu kàn yìí.
Àtẹ ìwádìí kan tí àjọ tí wọ́n ń pè ní Transparency International ṣe lọ́dún tó kọjá, láti fi ṣe àlàyé bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe gbilẹ̀ tó láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ìyẹn 2011 Corruption Perceptions Index, fi hàn pé, ‘èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè àti àgbègbè mẹ́tàlélọ́gọ́sàn-án [183] tí wọ́n gbé yẹ̀ wò ni ìwà ìbàjẹ́ ti mù dé ọrùn pátápátá, tí wọ́n sì ń yíràá nínú rẹ̀.’ Ní ọdún méjì ṣáájú ìyẹn, àjọ yìí sọ pé ìròyìn ọdọọdún tí àwọn ṣe ní ọdún 2009 fi hàn pé ìwà ìbàjẹ́ wọ́pọ̀ níbi gbogbo kárí ayé, ó ní: “Ó hàn gbangba pé kò sí ibì kankan nínú ayé tó bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro tí ìwà ìbàjẹ́ ń fà.”
“Ìwà ìbàjẹ́ wé mọ́ lílo agbára tó wà níkàáwọ́ ẹni láti máa fi wá èrè sí àpò ara ẹni. Ó máa ń ṣèpalára fún gbogbo ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀, àtijẹ-àtimu rẹ̀ àti ayọ̀ rẹ̀ sinmi lórí jíjẹ́ tí àwọn tó wà nípò àṣẹ bá jẹ́ olóòótọ́.”—ÀJỌ TRANSPARENCY INTERNATIONAL
Nígbà míì pàápàá, àkóbá tí ìwà ìbàjẹ́ ń ṣe máa ń burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Time sọ pé “ìwà ìbàjẹ́ àti àìka-nǹkan-sí” wà lára àwọn nǹkan tó jẹ́ kí iye ẹ̀mí tó ṣòfò pọ̀ gan-an nígbà tí
ìmìtìtì ilẹ̀ ńlá wáyé ní orílẹ̀-èdè Haiti lọ́dún 2010. Ó wá fi kún un pé: “Àwọn èèyàn máa ń kọ́ ilé láìgba ìtọ́sọ́nà tó yẹ lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ tó ń bójú tó ilé kíkọ́, torí àwọn olùbẹ̀wò tó yẹ kó máa ṣojú fún ìjọba ti máa ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀gúnjẹ lọ́wọ́ wọn.”Ǹjẹ́ ìwà ìbàjẹ́ tó gbòde kan yìí tiẹ̀ lè kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yìí, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ àwọn ohun tó ń fa ìwà ìbàjẹ́. A ó ṣàyẹ̀wò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
^ A ti yí orúkọ náà pa dà.
“Ìwà ìbàjẹ́ wé mọ́ lílo agbára tó wà níkàáwọ́ ẹni láti máa fi wá èrè sí àpò ara ẹni. Ó máa ń ṣèpalára fún gbogbo ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀, àtijẹ-àtimu rẹ̀ àti ayọ̀ rẹ̀ sinmi lórí jíjẹ́ tí àwọn tó wà nípò àṣẹ bá jẹ́ olóòótọ́.”—ÀJỌ TRANSPARENCY INTERNATIONAL