Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé sì Jókòó”
BÍBÉLÌ sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” (Jòhánù 1:18) Ògo Ọlọ́run pọ̀ jọjọ débi pé kò sí ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀ tó lè rí i kó sì tún wà láàyè. (Ẹ́kísódù 33:20) Àmọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan fi hàn pé Jèhófà mú kí àwọn kan tó yàn rí ìran nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run. Ọ̀kan nínú irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni wòlíì Dáníẹ́lì. Ohun àgbàyanu tó rí mú kí ó túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún Jèhófà lọ́nà tó jinlẹ̀ gan-an, bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe yẹ kó rí fún àwa náà. Wo bí Dáníẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe ohun tí Ọlọ́run mú kó rí nínú ìran. *—Ka Dáníẹ́lì 7:9, 10.
“Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé.” Dáníẹ́lì nìkan ni ó lo orúkọ oyè náà “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” ṣe ló sì fi ń tọ́ka pé ó jẹ́ “àgbàlagbà ọlọ́jọ́ orí tó ti wà tipẹ́tipẹ́.” (Dáníẹ́lì 7:9, 13, 22) Báwo ló ṣe pẹ́ tó tí Jèhófà ti wà? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni “Ọba ayérayé,” ó ti wà láti ayérayé, yóò sì máa wà títí láé ni. (1 Tímótì 1:17; Júúdà 25) Bí Ọlọ́run ti ṣe wà látayébáyé jẹ́ kó dá wa lójú pé ọgbọ́n rẹ̀ kò lópin, torí Bíbélì fi hàn pé bí ọgbọ́n ẹni ṣe tó wé mọ́ ọjọ́ orí ẹni. (Jóòbù 12:12) Lóòótọ́, bó ṣe jẹ́ pé Ọlọ́run ti wà láti ayérayé àti pé yóò máa wà títí ayérayé kò lè yé àwa èèyàn torí pé ó níbi tí òye wa mọ. Àmọ́, ṣé ó yẹ ká máa retí pé a lè ní òye kíkún nípa gbogbo bí Ọlọ́run tí ọgbọ́n rẹ̀ kò láfiwé ṣe jẹ́?—Róòmù 11:33, 34.
Kíyè sí i pé Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé náà “jókòó.” Kí nìdí? Àwọn ẹsẹ míì nínú orí yẹn sọ àwọn nǹkan kan tó jẹ́ ká mọ ìdí rẹ̀. Wọ́n mẹ́nu kan “Kóòtù” àti pé wọ́n “ṣèdájọ́.” (Dáníẹ́lì 7:10, 22, 26) Nítorí náà nínú ìran yìí, ṣe ni Jèhófà jókòó bí Adájọ́. Ìdájọ́ ta ló fẹ́ ṣe? Àwọn orílẹ̀-èdè ayé ni, èyí tí wọ́n ti kọ́kọ́ fi wé àwọn ẹranko ẹhànnà nínú ìran tí Dáníẹ́lì rí. * (Dáníẹ́lì 7:1-8) Irú Adájọ́ wo ni Jèhófà?
“Aṣọ rẹ̀ funfun bí ìrì dídì gẹ́lẹ́, irun orí rẹ̀ sì dà bí irun àgùntàn tí ó mọ́.” Àwọ̀ funfun máa ń dúró fún òdodo àti àìlábààwọ́n. Irun àgùntàn sì sábà máa ń jẹ́ funfun látilẹ̀ wá. Torí náà, ṣe ni irun tí wọ́n bá fi wé irun àgùntàn máa funfun nini. Ṣé ìwọ náà ti wá ń fojú inú rí ohun tí Dáníẹ́lì rí? Ǹjẹ́ ìwọ náà ń fojú inú rí Adájọ́ kan tí irun orí rẹ̀ funfun, bóyá tí aṣọ rẹ̀ funfun gbòò bíi yìnyín? Ṣe ni èdè àpèjúwe tó lò yìí ń jẹ́ kó dá wa lójú pé ìdájọ́ òdodo àti ti ọgbọ́n ni àwọn ìdájọ́ Jèhófà. Irú Adájọ́ bíi tirẹ̀ ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé, ká sì bọ̀wọ̀ fún lọ́nà tó jinlẹ̀ jù lọ.
Irú Adájọ́ bíi tirẹ̀ ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé, ká sì bọ̀wọ̀ fún lọ́nà tó jinlẹ̀ jù lọ
“Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀ gangan.” Àwọn wo ni ó ń ṣe ìránṣẹ́ ní ọ̀run yìí? Bíbélì pe àwọn áńgẹ́lì ní “àwọn òjíṣẹ́ [Ọlọ́run].” (Sáàmù 104:4) Iye àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù, síbẹ̀ ẹnu iṣẹ́ pẹrẹu ni wọ́n wà bí wọ́n ṣe “ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́,” tí wọ́n sì “ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 103:20, 21) Ǹjẹ́ ìyẹn kì í ṣe ẹ̀rí mìíràn tó fi hàn pé ọgbọ́n Ọlọ́run kò lópin? Yàtọ̀ sí Jèhófà, ta ló tún lè ṣètò ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ogun ọ̀run yìí, lọ́nà tí ọwọ́ gbogbo wọn fi dí pẹrẹu lẹ́nu iṣẹ́ láti ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún títí di báyìí?
Ìran tí Dáníẹ́lì rí ń mú ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà, Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé nì. Ìdájọ́ rẹ̀ jẹ́ òdodo, ọgbọ́n rẹ̀ sì ṣeé fọkàn tán. O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bó o ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run ọba ọgbọ́n yìí?
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún October:
^ Dáníẹ́lì kò rí Ọlọ́run ní ti gidi. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni Ọlọ́run mú kó rí àwọn ohun kan kedere lójú ìran. Nígbà tí Dáníẹ́lì wá ń ṣàpèjúwe ohun tí ó rí, ó lo àwọn ẹ̀yà ara èèyàn àti ìṣe èèyàn láti fi ṣàpèjúwe irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Irú àwọn èdè àpèjúwe bẹ́ẹ̀ mú kí á lè ní òye irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, àmọ́ kì í ṣe pé kí a máa wá rò pé bí ìrísí Ọlọ́run ṣe rí gẹ́lẹ́ náà nìyẹn.
^ Fún àlàyé kíkún nípa ìran tí Dáníẹ́lì ti rí àwọn ẹranko ẹhànnà, ka orí 9 nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.