Kí Nìdí Tí Ìwà Ìbàjẹ́ Kò Fi Kásẹ̀ Nílẹ̀?
“Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—ONÍWÀÁSÙ 8:9.
Ọ̀RỌ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí sọ bí ìjọba èèyàn ṣe rí gẹ́lẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ títí di báyìí. Ìjọba èèyàn ló ń fa ìyà àti ìpọ́njú tó lé kenkà bá aráyé. Látìgbà láéláé ló ti jẹ́ pé gbogbo ìgbà tí àwọn tí wọ́n ní ọkàn tó dáa bá ń gbìyànjú láti mú kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ ni ìwọra àti ìwà ìbàjẹ́ kì í jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí. Kí nìdí tó fi ń rí bẹ́ẹ̀? Kí ló fà á tí ìwà ìbàjẹ́ kò fi tíì kásẹ̀ nílẹ̀? Ní pàtàkì, ohun búburú mẹ́ta kan ló ń fà á.
1. Ipa tí ẹ̀ṣẹ̀ ń ní lórí ẹni.
Bíbélì sọ ọ́ ní tààràtà pé ‘gbogbo wa wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’ (Róòmù 3:9) Ṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ wà nínú ẹ̀jẹ̀ wa bí àrùn ìdílé tí kò ṣeé wò sàn, torí inú wa ló “ń gbé.” Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni ẹ̀ṣẹ̀ ti ń “ṣàkóso” bí ọba lórí aráyé. Gbogbo ìgbà ni “òfin ẹ̀ṣẹ̀” ń ṣiṣẹ́ nínú wa. Ẹran ara wa tó máa ń fẹ́ láti dẹ́ṣẹ̀ yìí ló ń sún ọ̀pọ̀ èèyàn débi pé ire tara wọn ni wọ́n máa ń jìjàdù tàbí kí wọ́n máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn wá ọrọ̀ tàbí ipò ńlá kódà tó bá tiẹ̀ máa kó ìnira bá àwọn míì.—Róòmù 5:21; 7:17, 20, 23, 25.
2. Ipa tí ayé burúkú tí à ń gbé yìí ń ní lórí ẹni.
Ìwọra àti ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ló gba ayé kan. Ìwà wọ̀nyí sì ni àwọn míì máa ń hù. Torí pé wọ́n ṣáà fẹ́ wà ní ipò ọlá, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í wá agbára lójú méjèèjì. Wọ́n á máa kó owó àti ọrọ̀ jọ ṣáá, láìjẹ́ pé wọ́n fi bẹ́ẹ̀ nílò rẹ̀. Ibi tó sì wá burú sí ni pé, kò sí ọ̀nà burúkú tí wọn kì í gbà kí ọwọ́ wọn ṣáà ti lè tẹ nǹkan wọ̀nyẹn. Dípò tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á fi máa yàgò fún ìwàkiwà, ṣe ni wọ́n máa ń “tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi.”—Ẹ́kísódù 23:2.
3. Ipa tí Sátánì Èṣù ń ní lórí ẹni.
Sátánì, ẹ̀dá ẹ̀mí ọlọ̀tẹ̀ tí a kò lè fojú rí, ló “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Ó sì máa ń dùn mọ́ ọn pé kó máa sún àwọn èèyàn ṣe ohun tó bá wù ú. Tó bá ti rí ẹni tó fẹ́ràn owó àti àwọn nǹkan amáyédẹrùn, ó lè fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ti onítọ̀hún débi tó fi máa hùwà àìṣòótọ́.
Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé bó bá ṣe wu Sátánì ló kàn ṣe lè máa dárí wa, láìsí ohunkóhun tí a lè ṣe? A óò rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.