Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ran Agbo Ilé Kan Tó Ń ṣe Ẹ̀sìn Híńdù Lọ́wọ́
MI Ò ní gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí gbogbo ìdílé wa jọ wà pa pọ̀ níbi oúnjẹ àárọ̀ ní Monday ọjọ́ kejìlélógún nínú oṣù August, ọdún 2005. Ó ṣẹlẹ̀ pé mo ní kókó ọlọ́yún ńlá kan nínú ọpọlọ mi, àwọn oníṣègùn sì fẹ́ yọ ọ́ kúrò. Torí náà bí màá kú bí màá yè ni o, ẹnì kan ò lè sọ. Ọkọ mi Krishna gbàdúrà, lẹ́yìn náà mo bá gbogbo ìdílé wa sọ̀rọ̀.
Mo ṣàlàyé fún wọn pé: “Mò ń lọ sí ilé ìwòsàn kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ abẹ kan tó gbẹgẹ́ lára mi, ó sì lè la ẹ̀mí lọ. Nítorí náà kí gbogbo yín ṣe ọkàn gírí torí mi ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Mo ti ṣètò bí wọ́n ṣe máa sin mí, tó bá ṣẹlẹ̀ pé mi ò yè é. Ẹ̀yin tí ẹ ti ń sin Jèhófà, ẹ jọ̀ọ́, ẹ má bojú wẹ̀yìn. Ẹ̀yin tó kù, ẹ jọ̀ọ́, mo bẹ̀ yín pé kí ẹ jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ yín lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ẹ sì máa lọ sí ìpàdé ìjọ wọn. Kí ẹ̀yin náà lè ní irú ìgbàgbọ́ tí mo ní, pé ayé tuntun kan ń bọ̀, níbi tí àwọn tó ń sin Ọlọ́run lóòótọ́ ti máa wà láàyè títí láé, nínú ìlera pípé, ní Párádísè orí ilẹ̀ ayé.”
Kí n tó sọ ibi tí iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe fún mi yọrí sí, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ bí mo ṣe jẹ́, bí wọ́n ṣe tọ́ mi dàgbà àti bí mo ṣe dẹni tó mọ Ọlọ́run tòótọ́.
Bí Wọ́n Ṣe Tọ́ Mi Dàgbà Nínú Ẹ̀sìn Híńdù
Inú ilé ńlá kan tí wọ́n fi igi àti irin kọ́ ni agbo ilé wa ń gbé. Ilé náà wà ní orí òkè kan ní ìlú Durban tó wà ní etíkun ní orílẹ̀-èdè South Africa. Ká tó lè dé géètì tó wà ní iwájú ilé wa lókè, a máa ní láti gun ibi àtẹ̀gùn márùndínláàádóje [125] láti ojú ọ̀nà tó wà ní àfonífojì nísàlẹ̀. A óò wá gba ọ̀nà kékeré kan tó ní igbó láti ibi àtẹ̀gùn yìí dé ibi géètì onírin kan. Ìyá bàbá mi ní ojúbọ kan sí ẹ̀gbẹ́ géètì náà, tí wọ́n kó àwọn àwòrán àti ère àwọn òrìṣà ẹ̀sìn Híńdù sí rẹpẹtẹ. Ìyá bàbá mi yìí sọ fún mi pé “ọmọ ojúbọ” ni mí (ìyẹn mandir kī baccā, lédè Híńdì) àti pé àwọn òrìṣà tí à ń sìn ló fi mí ta àwọn òbí mi lọ́rẹ. Àtẹ̀gùn pupa kan wà ní iwájú ojúbọ yìí tó jáde sí ibi ilẹ̀kùn iwájú ilé wa. Ilé náà tóbi, ó ní ọ̀ọ̀dẹ̀ kan tó gùn, ilé ìdáná ńlá kan wà níbẹ̀ tá a ti máa ń fi àdògán dáná, ó ní yàrá méje yàtọ̀ sí ilé oníyàrá kan tí wọ́n kọ́ sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́. Àwa mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] ló jọ ń gbé inú ilé yìí, ìyẹn àwọn òbí wa àgbà, bàbá mi, àwọn àbúrò wọn mẹ́ta tó jẹ́ ọkùnrin, àbúrò wọn obìnrin àti àwọn ìdílé wọn.
Kò rọrùn láti máa gbọ́ bùkátà irú agbo ilé ńlá bẹ́ẹ̀. Àmọ́ bí gbogbo wa ṣe jọ ń gbé pọ̀, a wà ní ìṣọ̀kan, àjọgbé wa sì lárinrin. Ṣe ni àwọn ìyàwó ilé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìyẹn màmá mi Gargee Devi àti àwọn mẹ́ta yòókù, jọ máa ń pín iṣẹ́ ilé láàárín ara wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ní ìgbà tí iná dídá àti iṣẹ́ ìmọ́tótó ilé máa ń yí kàn án. Bàbá bàbá mi ni olórí ilé, àwọn ni wọ́n sì máa ń ra oúnjẹ gbogbo agbo ilé wa. Ọjọọjọ́ Wednesday ni àwọn òbí mi àgbà máa ń lọ sí ọjà lọ ra ẹran, èso àti àwọn nǹkan bíi ewébẹ̀, tí a máa ń lò fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Abẹ́ igi ahóyaya kan tó wà ní bèbè ibi tí a ti lè máa wo àfonífojì tó wà nísàlẹ̀ ni a máa ń jókòó sí nígbà tí a bá ń dúró pé kí wọ́n dé láti ọjà. Bí a bá ti rí i pé wọ́n dé tí wọ́n sì ń gbé àwọn apẹ̀rẹ̀ ńlá sọ̀ kalẹ̀ látinú bọ́ọ̀sì, a máa ń sáré sọ̀ kalẹ̀ lórí àtẹ̀gùn márùndínláàádóje [125] yẹn láti bá wọn gbé àwọn ẹrù náà wọlé.
Igi ọ̀pẹ tó ga kan wà nínú ọgbà wa, àwọn ẹyẹ mynah kọ́ ìtẹ́ wọn sórí rẹ̀. A máa ń rí bí wọ́n ṣe ń fò lọ fò bọ̀, a sì máa ń gbọ́ bí wọ́n ṣe ń ké. Ìyá bàbá mi máa ń jókòó síbi àtẹ̀gùn tó wà ní ẹnu
ọ̀nà àbáwọlé, wọ́n á máa sọ onírúurú ìtàn fún wa nípa wọn, bí ẹni pé ohun tí àwọn ẹyẹ yẹn ń sọ ni wọ́n ń túmọ̀ fún wa. Ọ̀pọ̀ nǹkan alárinrin ni mo ṣì máa ń rántí nípa bí a ṣe ń gbé pọ̀ nígbà yẹn! A jọ máa ń rẹ́rìn-ín, a jọ ń sunkún, a jọ ń ṣeré, a sì jọ ń ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀. A gbádùn bí agbo ilé wa ṣe jọ ń gbé pa pọ̀ gan-an ni. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé inú ilé wa yìí ni a ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà, àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi.Kí a tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ojoojúmọ́ ni a máa ń ṣe oríṣiríṣi ètùtù nínú ẹ̀sìn Híńdù tá à ń ṣe. A tún máa ń ṣe onírúurú ọdún òrìṣà látìgbàdégbà, a máa ń pe àwọn àlejò wá síbẹ̀ láti wá júbà àwọn òrìṣà náà, ì báà jẹ́ ti akọ tàbí ti abo. Lásìkò àwọn ọdún náà, òòṣà máa ń gun ìyá mi àgbà nígbà míì, wọ́n á bọ́ sójú ìran, wọ́n á máa bá àwọn àǹjọ̀nnú sọ̀rọ̀, tó bá sì ti di ọ̀gànjọ́ òru wọ́n á fi ẹran rúbọ láti tù wọ́n lójú. Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ bàbá bàbá mi sí olójú àánú, torí wọ́n máa ń gbé owó sílẹ̀ fún kíkọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba àti àwọn ojúbọ ẹ̀sìn Híńdù àti mímójú tó wọn.
Bí A Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Nípa Jèhófà
Ní ọdún 1972, bàbá mi àgbà ṣàìsàn wọ́n sì kú. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, ìyàwó ọ̀kan nínú àwọn àbúrò bàbá mi, ìyẹn Indervathey tí àwọn èèyàn mọ̀ sí Jane, gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan. Ó dùn ún pé kò jẹ́ kí wọ́n wọlé láti wá bá òun sọ̀rọ̀. Ṣé ẹ rí i, tí àwọn Ẹlẹ́rìí bá ti wá sọ́dọ̀ wa, ṣe la máa ń ní kí wọ́n máa lọ. Àmọ́ nígbà tí wọ́n tún wá, ìyàwó àbúrò bàbá mi ní kí wọ́n wọlé, ó sì sọ ìṣòro ìdílé rẹ̀ fún wọn nípa bí ọkọ rẹ̀ ṣe máa ń mu ọtí àmujù. Àwọn aládùúgbò wa àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa ti sọ fún un pé kí ó kọ ọkọ yẹn sílẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà wá ṣàlàyé irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó. (Mátíù 19:6) Inú rẹ̀ dùn bó ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Bíbélì àti bí Ọlọ́run ṣe ṣèlérí pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dára lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. * Ó pinnu pé òun kò ní fi ọkọ òun sílẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Tí wọ́n bá ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nínú pálọ̀ ilé wa, àwọn ìyàwó ilé yòókù máa fetí sí ìjíròrò náà látinú yàrá wọn.
Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ìyàwó ilé yòókù náà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Àǹtí Jane máa ń sọ ohun tó kọ́ fún wa, ó tún máa ń ka àwọn ìtàn fún wa látinú ìwé Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na, * á sì ṣàlàyé rẹ̀ fún wa. Nígbà tí àwọn àbúrò bàbá mi mọ̀ pé àwọn ìyàwó wọn ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtakò sí wa. Ọ̀kan nínú wọn kó gbogbo àwọn ìwé wa, títí kan Bíbélì, ó sì dáná sún ún. Wọ́n máa ń bú wa, wọ́n sì máa ń lù wá torí pé a lọ sí ìpàdé. Bàbá mi nìkan ni kì í hu irú ìwà yìí sí wa, kódà wọn ò fìgbà kankan rí ta ko bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àmọ́ ṣá o, ìyàwó ilé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yẹn kò yéé lọ sí ìpàdé, wọ́n sì túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run sí i.
Ní ọdún 1974, àǹtí Jane ṣe ìrìbọmi, ó sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí màmá mi àti àwọn ìyàwó ilé tó kù náà fi ṣe ìrìbọmi. Nígbà tó yá, ìyá mi àgbà náà fi ẹ̀sìn Híńdù tó ń ṣe sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń tẹ̀ lé wọn lọ sí gbogbo ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n nígbà àpéjọ àgbègbè ńlá kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Shameela Rampersad béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ìgbà wo lo máa
ṣe ìrìbọmi?” Mo dáhùn pé, “Mi ò tíì lè ṣèrìbọmi torí kò sí ẹni tó tíì kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí.” Ló bá sọ pé òun á máa kọ́ mi. Ní àpéjọ àgbègbè tí a ṣe lẹ́yìn ìyẹn, ní December 16, ọdún 1977, mo sì ṣe ìrìbọmi. Nígbà tó yá, nínú àwa mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tí a jọ wà nínú agbo ilé wa, méjìdínlógún [18] ṣe ìrìbọmi. Àmọ́ títí dìgbà tí mo fi ṣe iṣẹ́ abẹ, ẹ̀sìn Híńdù ni bàbá mi Sonny Deva ṣì ń ṣe.“Ẹ Má Ṣe Máa Ṣàníyàn Nípa Ohunkóhun”
Ọ̀rọ̀ tó wà nínu Fílípì 4:6, 7 ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an, pàápàá lẹ́yìn ìgbà tí àyẹ̀wò fi hàn pé kókó ọlọ́yún ńlá kan wà nínú ọpọlọ mi. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Kò rọrùn kéèyàn má “ṣàníyàn nípa ohunkóhun,” pàápàá tí wọ́n bá sọ fún un pé ìgbàkígbà ló lè kú. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ sọ àbájáde àyẹ̀wò náà fún mi, ṣe ni mo kàn ń sunkún. Lẹ́yìn ìyẹn, mo gbàdúrà sí Jèhófà. Látìgbà náà ni mo ti rí i pé mo ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”
Mo lè sọ pé ṣe ni Jèhófà Ọlọ́run di ọwọ́ ọ̀tún mi mú, torí mo rí i pé ó ń ṣamọ̀nà mi lọ lóòótọ́. (Aísáyà 41:13) Ó mú kí n lè fi ìgboyà ṣàlàyé fún àwọn oníṣègùn yẹn pé mo ti pinnu láti pa àṣẹ Bíbélì mọ́, èyí tó sọ pé kí a ta kété sí ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Nítorí èyí, dókítà oníṣẹ́ abẹ náà àti oníṣègùn apàmọ̀lára kan gbà láti ṣe iṣẹ́ abẹ náà láìfa ẹ̀jẹ̀ sí mi lára. Níkẹyìn, dókítà oníṣẹ́ abẹ náà sọ pé àwọn ṣe àṣeyọrí àti pé wọ́n ti mú kókó ọlọ́yún náà kúrò pátápátá. Ó tún sọ pé òun kò tíì rí ẹni tí wọ́n ṣe irú iṣẹ́ abẹ inú ọpọlọ tó díjú báyẹn fún rí tí ara rẹ̀ sì tètè yá bíi tèmi.
Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnì kan látorí ibùsùn mi nínú ilé wa. Nígbà tó fi máa di ìparí ọ̀sẹ̀ keje, mo tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í wa ọkọ̀, mo ti ń jáde òde ẹ̀rí, mo sì tún ti ń lọ sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí a jọ ń lọ sóde ìwàásù ń ṣe fún mi. Wọ́n kì í jẹ́ kí n dá wà ní èmi nìkan, wọ́n sì tún máa ń rí i dájú pé mo dé ilé láìsí ìṣòro. Ó dá mi lójú pé bí mo ṣe máa ń tẹ́tí sí Bíbélì kíkà tí wọ́n gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ àti bí mo ṣe máa ń pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́ gan-an, ó sì jẹ́ kí ara mi tètè yá.
Inú mi tún dùn pé lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe fún mi, bàbá mi gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ṣe ìrìbọmi ní ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin [73], ó sì ń fi ìtara sin Jèhófà lọ báyìí. Ó ju ogójì [40] lára àwọn mọ̀lẹ́bí mi tí a ti jọ ń sin Jèhófà báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè fi ojú ọ̀tún mi ríran mọ́, àti pé irin ni wọ́n fi de eegun agbárí mi pa pọ̀, mo ń retí àsìkò tí Jèhófà máa sọ “ohun gbogbo di tuntun” nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀.—Ìṣípayá 21:3-5.
Ọlọ́run fi ọkọ onífẹ̀ẹ́ kan, tó jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà jíǹkí mi, àti ọmọbìnrin dáadáa tí mo bí, ìyẹn Clerista, tó ń ṣèrànlọ́wọ́ fún mi bí mo ṣe ń bá a lọ ní fífi àkókò tó pọ̀ ṣiṣẹ́ Ọlọ́run. Jèhófà ti fi ìbùkún sí iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe gan-an ni. Ní báyìí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mo ti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ràn lọ́wọ́ tó sì ti yí ìgbésí ayé wọn pa dà sí rere. Ó ju ọgbọ̀n [30] nínú wọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, tí wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi.
Mo ń fi gbogbo ọkàn retí ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run máa gbà wá lọ́wọ́ ètò búburú tó kún fún ìrora yìí, tí yóò sì mú wa wọ inú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.
^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé, ka orí 3 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́, a kò tẹ̀ ẹ́ mọ́.