Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ayé Oníwà Ìbàjẹ́ Yìí?

Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ayé Oníwà Ìbàjẹ́ Yìí?

“A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—HÉBÉRÙ 13:18.

LÓÒÓTỌ́ ipa tí jíjẹ́ tí a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ayé búburú tí à ń gbé àti Sátánì Èṣù máa ń fẹ́ ní lórí wa lè pọ̀ gan-an, síbẹ̀ a lè má gbà fún wọn! Báwo la ṣe lè kọ̀? A lè ṣe èyí tí a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, tí ẹ̀rí ti fi hàn tipẹ́tipẹ́ pé ó wúlò. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì yìí ná.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Má ṣe máa hùwà bíi ti ayé tí ó yí ọ ká.”—Róòmù 12:2, New Jerusalem Bible.

Ìrírí ẹnì kan rèé: Guilherme jẹ́ oníṣòwò ńlá kan ní ilẹ̀ Brazil. Ó sọ pé kì í rọrùn láti jẹ́ olóòótọ́. Ó ní: “Oníṣòwò kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà àìṣòótọ́ nídìí òwò rẹ̀, bóyá torí kí ilé iṣẹ́ rẹ̀ lè dójú ìlà ohun tí wọ́n ń fẹ́ tàbí kí wọ́n lè máa rọ́wọ́ mú láwùjọ àwọn oníṣòwò yòókù tí wọ́n jọ wà lójú ọpọ́n. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ti gbà pé kò sí ohun tó burú nínú fífúnni ní ẹ̀gúnjẹ tàbí gbígba ẹ̀gúnjẹ. Téèyàn bá jẹ́ oníṣòwò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tó sì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti náwó sí, ó máa ń ṣòro láti jẹ́ olóòótọ́.”

Síbẹ̀síbẹ̀, Guilherme ṣì rí i dájú pé òun kò jẹ́ kí ohunkóhun sọ òun di aláìṣòótọ́. Ó sọ pé: “Kódà lágbo àwọn oníṣòwò tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ka ìwà àìṣòótọ́ sí ohun tó burú, èèyàn ṣì lè jẹ́ olóòótọ́. Ohun tó kàn gbà ni pé kéèyàn ti pinnu látọkàn wá pé òun kò ní lọ́wọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́. Bíbélì ti jẹ́ kí n rí àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ olóòótọ́. Olóòótọ́ èèyàn máa ń ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ó máa ń ní ìfọ̀kànbalẹ̀, ó sì máa ń níyì lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Irú èèyàn bẹ́ẹ̀ sì máa ń ní ipa tó dára lórí àwọn tó bá sún mọ́ ọn.”

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Àwọn tí wọ́n ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa ṣubú sinu ìdánwò; tàkúté a mú wọn. Wọ́n a dàníyàn fún ọpọlọpọ nǹkan tí kò mú ọgbọ́n àti àwọn tí ó lè pa eniyan lára; àwọn nǹkan tí ó ti mu kí àwọn miran jìn sinu ọ̀fìn ikú àti ìparun. Ìfẹ́ owó ìpìlẹ̀ gbogbo nǹkan buruku.”—1 Tímótì 6:9, 10, Ìròhìn Ayọ̀.

Ìrírí ẹnì kan rèé: André ní ilé iṣẹ́ kan tó máa ń bá àwọn èèyàn ṣe ẹ̀rọ ìdáàbòbò sí ara nǹkan. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ńlá kan jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn oníbàárà rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, André wá síbẹ̀ láti wá gba owó iṣẹ́ tí ó bá wọn ṣe, àmọ́ lásìkò yìí, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí eré bọ́ọ̀lù pàtàkì kan ni. Ọwọ́ àwọn tó ń bójú tó owó níbẹ̀ dí gan-an torí pé wọ́n ń ka owó tí wọ́n pa ní àwọn ibi tí wọ́n ti ń já tíkẹ́ẹ̀tì ìwòran fún àwọn èèyàn. Torí pé ọjọ́ ti lọ, ọ̀gá wọn fi ìkánjú sanwó fún àwọn tó báwọn ṣiṣẹ́, títí kan André.

André sọ pé: “Bí mo ṣe ń lọ sílé, mo ṣàkíyèsí pé ọ̀gá yẹn ti san owó lé fún mi. Mo mọ̀ pé bóyá ni ọ̀gá náà fi máa mọ ẹni tó sanwó lé fún. Mo sì mọ̀ pé owó ara rẹ̀ ni ẹni ẹlẹ́ni yìí fi máa rọ́ gbèsè náà san pa dà! Ni mo bá pa dà síbẹ̀. Mo torí bọ àárín èrò tó ń wọ́ jáde níbẹ̀ láti lọ bá a, mo sì dá èlé orí owó náà pa dà fún un. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún ọ̀gá náà, torí pé ẹnikẹ́ni kò dá owó pa dà fún un rí.”

André wá sọ pé: “Owó tí mo dá pa dà yẹn mú kí n di ẹni iyì lọ́wọ́ ọ̀gá yìí. Ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá báyìí, àmọ́ nínú gbogbo àwa tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà máa ń gbéṣẹ́ fún nígbà yẹn, èmi nìkan ló ṣẹ́ kù tí wọ́n ṣì ń gbéṣẹ́ fún títí di báyìí. Mo dúpẹ́ gan-an pé títẹ̀lé àwọn ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì ti jẹ́ kí n ní orúkọ rere.”

Ìṣírí ló máa ń jẹ́ fúnni láti mọ̀ pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a lè kọ̀ láti hùwà ìbàjẹ́. Àmọ́, kò sí bí ẹ̀dá èèyàn ṣe lè mú kí ìwà ìbàjẹ́ kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá, bó ti wù kí kálukú wa sápá tó. Ohun tó fà á ré kọjá ohun tí àwa èèyàn aláìpé lè dá yanjú fúnra wa. Ǹjẹ́ èyí wá fi hàn pé ìwà ìbàjẹ́ kò ní dópin láé? Èyí tó kẹ́yìn nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ìdáhùn tó tuni nínú látinú Bíbélì.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Bíbélì ti jẹ́ kí n rí àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ olóòótọ́.”—GUILHERME

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Mo dúpẹ́ gan-an pé títẹ̀lé àwọn ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì ti jẹ́ kí n ní orúkọ rere.”—ANDRÉ