Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ǹjẹ́ Ọlọ́run Yóò Fún Wa Ní Ìjọba Kan Tó Máa Ṣàkóso Gbogbo Ayé?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.
1. Kí nìdí tí aráyé fi nílò ìjọba kan tí yóò máa ṣàkóso gbogbo ayé?
Lóde òní, tí ìṣòro kan bá jẹyọ, ó sábà máa ń kárí ayé. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn èèyàn tó pọ̀ jù níbẹ̀ jẹ́ tálákà, wọ́n sì máa ń fojú wọn gbolẹ̀. Àmọ́ láwọn orílẹ̀-èdè míì, ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ní ànító àti àníṣẹ́kù. Èyí fi hàn pé ìjọba tí àkóso rẹ̀ kárí ayé nìkan ló máa lè pín ohun àmúṣọrọ̀ inú ayé kárí bó ṣe yẹ.—Ka Oníwàásù 4:1; 8:9.
2. Ta ni a lè fọkàn tán pé ó máa ṣàkóso ayé lọ́nà tó dára?
Ọ̀pọ̀ èèyàn kò gbà pé ó dára kí ẹnì kan ṣoṣo máa ṣàkóso àgbáyé, torí pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin tó máa lè ṣe é yanjú. Kò sí èèyàn tí wọ́n yàn tó máa tẹ́ gbogbo aráyé pátá lọ́rùn. Bákan náà, ọmọ aráyé wo ni agbára kò ní gùn tó bá dórí oyè? Tó bá wa lọ jẹ́ pé òṣìkà kan ni àkóso gbogbo ayé bọ́ sí lọ́wọ́, ǹjẹ́ kò ní fi imú gbogbo èèyàn fọn fèrè?—Ka Òwe 29:2; Jeremáyà 10:23.
Ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run ti yan Jésù Ọmọ rẹ̀, pé kó máa ṣàkóso aráyé títí láé. (Lúùkù 1:32, 33) Jésù ti gbé ayé rí, torí náà ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí fún wa ní ayé. Nígbà tó wà láyé, ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, ó sì fàyè sílẹ̀ láti gbọ́ ti àwọn ọmọdé. (Máàkù 1:40-42; 6:34; 10:13-16) Torí náà, Jésù ni ẹni tó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ Alákòóso ayé.—Ka Jòhánù 1:14.
3. Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ lè ṣeé ṣe kí ìjọba kan ṣoṣo máa ṣàkóso àgbáyé?
Ọlọ́run yan Ọmọ rẹ̀ pé kó máa ṣàkóso ayé láti ọ̀run. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Bí kò ti pọn dandan pé kí alákòóso orílẹ̀-èdè kan wà ní gbogbo ìlú tó ń ṣàkóso kó tó lè ṣàkóso wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni kò pọn dandan kí Jésù wà ní orí ilẹ̀ ayé kó tó lè ṣàkóso aráyé.—Ka Mátíù 8:5-9, 13.
Ǹjẹ́ gbogbo èèyàn ló máa gba Jésù ní Ọba wọn? Rárá o. Kìkì àwọn tó bá fẹ́ràn ohun rere ni yóò tẹ́wọ́ gbà á. Jèhófà yóò sì pa gbogbo àwọn tó bá kọ Ọba onífẹ̀ẹ́ àti olódodo tó yàn rẹ́ kúrò ní ayé.—Ka Mátíù 25:31-33, 46.
4. Kí ni Alákòóso ayé yẹn máa ṣe?
Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń kó àwọn àgùntàn rẹ̀ jọ pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jésù ṣe ń kó àwọn èèyàn ọlọ́kàn tútù jọ báyìí, tó sì ń kọ́ wọn ní bí wọ́n ṣe lè máa fi ìfẹ́ ṣe gbogbo nǹkan bíi ti Ọlọ́run. (Jòhánù 10:16; 13:34) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń dẹni tó ń fi tọkàntara kọ́wọ́ ti Jésù àti ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn. (Sáàmù 72:8; Mátíù 4:19, 20) Ní báyìí, kárí ayé, gbogbo àwọn tí wọ́n fi tọkàntọkàn jẹ́ ọmọ abẹ́ ìṣàkóso Jésù ń fi ìṣọ̀kan kéde pé Jésù ti di Ọba.—Ka Mátíù 24:14.
Jésù máa tó fi agbára rẹ̀ gba aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ìjọba oníwà ìbàjẹ́. Ó ti yan àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ ṣe ọba tí wọ́n jọ máa ṣe àkóso ayé láti ọ̀run. (Dáníẹ́lì 2:44; 7:27) Ìjọba Jésù yóò mú kí ìmọ̀ Jèhófà kún ilẹ̀ ayé, yóò sì mú kí irú Párádísè tí Ádámù jẹ́ kí aráyé pàdánù ní ìbẹ̀rẹ̀ tún pa dà wà lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Aísáyà 11:3, 9; Mátíù 19:28.