Ní Gbẹ̀yìn Gbẹ́yín Mo Di Òmìnira!
Òṣìṣẹ́ kan ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tí a wà fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Kò kúkú sí ẹnì kankan tó wá béèrè ẹ̀yin ní tiyín. Ẹ máa ṣe ayé yín lọ níbí.” Ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ni wá, èèyàn jẹ́jẹ́ sì ni wá nínú ìdílé wa, a sì máa ń ṣiṣẹ́ kára. Báwo la ṣe wá dèrò ẹ̀wọ̀n ní orílẹ̀-èdè North Korea ní ọdún márùn-ún péré lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì?
ÀWỌN ìwé tí mo ní lọ́wọ́ fi hàn pé ọdún 1924 ni wọ́n bí mi. Ẹ̀rí sì fi hàn pé abúlé Shmakovka ni wọ́n bí mi sí. Ó wà ní ìkángun ìlà oòrùn ilẹ̀ Rọ́ṣíà, nítòsí ààlà ilẹ̀ Ṣáínà.
Lọ́jọ́ kan àwọn jàǹdùkú wá kó bàbá mi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin lọ. Ìgbà yẹn sì ni ìyá mi rí wọn mọ. Ó wá ku òun nìkan àti àwa ọmọ kéékèèké púpọ̀ sílé. Kò sì lè bọ́ gbogbo wa. Aládùúgbò wa kan sọ pé kó jẹ́ kí òun kó àwa tí a ṣì kéré lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ó ní òun á sọ fún wọn pé ìyá wa ti dà wá sílẹ̀.
Màmá mi gbà pé kí ó kó wa lọ, torí ká ní kò gbà ni, bóyá ebi ni ì bá pa àwa tí a ṣì kéré kú. Nísinsìnyí tí mo ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún, mo dúpẹ́ pé ìyá mi jẹ́ kí wọ́n kó wa lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí. Bóyá ohun tó ṣe yẹn ni kò jẹ́ ká ti kú nígbà yẹn. Síbẹ̀ náà, ohun tí ìyá mi ṣe yẹn ṣì máa ń dùn mí.
Ní ọdún 1941, mo kó lọ sí orílẹ̀-èdè Kòríà. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé ọkùnrin dáadáa kan, ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà, tó ń jẹ́ Ivan, a sì ṣe ìgbéyàwó. Ní ọdún 1942, a bí Olya ọmọ wa obìnrin àkọ́kọ́, ìlú Seoul tó wà lórílẹ̀-èdè Kòríà ni a bí i sí. Ibẹ̀ náà la tún ti bí Kolya ọmọ wa ọkùnrin ní ọdún 1945, àti àbúrò rẹ̀ Zhora ní ọdún 1948, ọkùnrin ni òun náà. A ní ṣọ́ọ̀bù kan tí ọkọ mi ti ń tajà, èmi sì máa ń ránṣọ. Torí pé àwọn ará ilẹ̀ Japan ló kún inú ìlú Seoul, èdè wọn ni àwọn ọmọ wa ń sọ bí wọ́n ṣe ń dàgbà, àmọ́ èdè Rọ́ṣíà la máa ń sọ nínú ilé. Títí di ọdún 1950, kò sí wàhálà láàárín àwọn ará ilẹ̀ Rọ́ṣíà, àwọn ará Amẹ́ríkà àti àwọn ọmọ ilẹ̀ Kòríà tó wà ní ìlú Seoul. Gbogbo wọn ló máa ń wá bá wa ra ọjà ní ilé ìtajà wa.
Àwọn Ọmọ Ogun North Korea Kó Wa
Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àfi bí gbogbo nǹkan ṣe yí pa dà ní ọdún 1950. Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ North Korea wá gba ìlú Seoul. Wọ́n ká wa mọ́ ibẹ̀, wọ́n sì kó wa mọ́ àwọn àjèjì yòókù tó wà níbẹ̀. Ọdún mẹ́ta ààbọ̀ ni wọ́n fi ń kó àwa, àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ti Faransé tí wọ́n mú lójú ogun káàkiri ilẹ̀ North Korea. Ibikíbi tí wọ́n bá ṣáà ti rí àyè ni wọ́n máa ń kó wa sí, a sì máa ń yẹra fún àwọn bọ́ǹbù.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń kó wa sí àwọn ilé tó ní nǹkan tó lè múlé móoru, wọ́n á fún wa ní oúnjẹ tí ó tó. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé jéró nìkan ni wọ́n rí fún wa jẹ, inú àwọn ilé tí àwọn èèyàn ti pa tì, tó tutù nini, la sì máa sùn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló kú láàárín wa torí àìrí oúnjẹ gidi jẹ àti àìrí ìtọ́jú. Ara ta mí gan-an nígbà tí mo rí bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn ọmọ mi. Ìgbà òtútù tètè bẹ̀rẹ̀ lọ́dún náà ní orílẹ̀-èdè North Korea. Mo rántí bí mo ṣe máa ń wà nídìí iná ní òru mọ́jú, tí màá máa kó òkúta síná kí n lè kó wọn sábẹ́ ibi tí àwọn ọmọ mi sùn sí.
Nígbà tí ojú ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í móoru, àwọn ará abúlé tó wà níbẹ̀ sọ àwọn ewébẹ̀ tó ṣeé jẹ fún wa. Torí náà a bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn ewébẹ̀, oríṣiríṣi àgbáyun, àjàrà, àti olú kiri nínú igbó. Ó hàn gbangba pé àwọn ará abúlé náà kò kórìíra wa rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni àánú wa ń ṣe wọ́n. Ibẹ̀ ni mo ti kọ́ bí wọ́n ṣe
ń mú àkèré, ká bàa lè máa rí nǹkan tí a ó fi kún oúnjẹ tí ò tó nǹkan tí à ń rí jẹ. Inú mi bà jẹ́ bí mo ṣe ń rí i pé àwọn ọmọ mi tiẹ̀ tún ń tọrọ àkèré.Ní oṣù October kan báyìí, wọ́n ní kí gbogbo wa fi ẹsẹ̀ rìn lọ sí ibì kan tí wọ́n ń pè ní Manp’o. Wọ́n ní wọ́n máa fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbé àwọn tí ara wọn kò yá àti àwọn ọmọ kéékèèké. Ọkọ mi àti Olya bá àwọn tó kù fi ẹsẹ̀ rìn. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni èmi àti àwọn àbúrò Olya méjèèjì fi ń wọ̀nà kí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà tó dé.
Wọ́n wá fún àwọn tí ara wọn kò yá pọ̀ sínú àwọn kẹ̀kẹ́ náà bí ìgbà tí wọ́n to àpò ìrẹsì. Áà, ó burú jáì! Mo gbé Zhora pọ̀n, mo wá ní kí n gbé Kolya sí ẹ̀gbẹ́ kan nínú ọ̀kan nínú àwọn kẹ́kẹ́ náà. Ṣùgbọ́n ńṣe ló bú sẹ́kún, tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Mọ́mì, Mọ́mì, ẹ jẹ́ kí n bá yín lọ! Ẹ jọ̀ọ́ ẹ má fi mí sílẹ̀!”
Bí Kolya ṣe tẹ̀ lé mi nìyẹn, tó fi ọwọ́ rẹ̀ kékeré di aṣọ mi mú, tó sì ń sá tẹ̀ lé mi. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni a fi rin ìrìn àrìnwọ́dìí yìí, àwọn tí ìbọn sì bà lára wa kò kéré. Àwọn ẹyẹ kannakánná ń fò tẹ̀ lé wa lẹ́yìn, wọ́n ń jẹ òkú àwọn tó kú lọ́nà. Nígbà tó yá, a dé ibi tí ọkọ mi àti Olya wà. Omijé ń bọ́ lójú wa, a sì dì mọ́ ara wa. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, mi ò sùn mọ́jú, òkúta ni mo ń kó síná. Àmọ́ bí mo tiẹ̀ ṣe rí gbogbo ọmọ mi sójú tí mo sì ń kó òkúta gbígbóná sábẹ́ ibi tí wọ́n sùn sí tún jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ lọ́tọ̀.
Ní 1953, a dé ẹ̀bá ààlà àárín North Korea àti South Korea, nǹkan sì rọrùn fún wa díẹ̀ bákan ṣá. Wọ́n fún wa ní aṣọ tó mọ́, bàtà àti búrẹ́dì, kódà wọ́n tún ń fún wa ní súìtì. Láìpẹ́ sígbà yẹn, wọ́n dá àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó wà láàárín wa sílẹ̀, lẹ́yìn ìyẹn wọ́n dá àwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ní tiwa, kò sẹ́ni tó kà wá kún ọmọ orílẹ̀-èdè kankan. Nígbà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù lọ tán, àwa nìkan ló kù síbẹ̀. Ìbànújẹ́ bá wa, a sunkún títí, ẹnu wa pàápàá kọ oúnjẹ. Ìgbà yẹn ni òṣìṣẹ́ kan ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ilẹ̀ Kòríà fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ bí mo ṣe sọ ní ìṣáájú.
Nǹkan Yí Pa Dà Nígbà Tí A Dé Amẹ́ríkà
Láìpẹ́ sígbà yẹn, wọ́n ṣàdédé kó wa gba àgbègbè tí àwọn ológun ò gbọ́dọ̀ dé, wọ́n sì kó wa wọ orílẹ̀-èdè South Korea. Ibẹ̀ ni
àwọn òṣìṣẹ́ ológun orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fi ọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò, wọ́n sì gbà kí a wá máa gbé ní Amẹ́ríkà. Bí a ṣe wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí ìlú San Francisco ní ìpínlẹ̀ California nìyẹn, tí ẹgbẹ́ aláàánú kan sì ràn wá lọ́wọ́ níbẹ̀. Nígbà tó yá, a lọ sí ìpínlẹ̀ Virginia, àwọn tí a sì mọ̀ níbẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ kí a lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ bùkátà ara wa. Nígbà tó yá, a lọ sí ìpínlẹ̀ Maryland. Ibẹ̀ ni a ti wá fìdí kalẹ̀ tí a tún bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé wa látilẹ̀.Ọ̀pọ̀ nǹkan ló jẹ́ tuntun sí wa nígbà yẹn, títí kan irú àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bí ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbálẹ̀. Torí pé ẹni tuntun la jẹ́ ní orílẹ̀-èdè yẹn, ọ̀pọ̀ wákàtí la máa fi ń ṣiṣẹ́, a sì ní láti ṣiṣẹ́ kára gan-an. Inú mi kì í dùn rárá bí mo ṣe ń rí bí àwọn tí nǹkan ti ń dáa fún ní àgbègbè tuntun yìí ṣe ń rẹ́ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé jẹ. Láìpẹ́ sígbà tí a dé ibẹ̀, a rí àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan. Ohun tó sọ ni pé: “Ilẹ̀ ìbùkún ni ẹ wà báyìí. Tí ẹ bá fẹ́ rọ́wọ́ mú, ẹ rí i dájú pé ẹ yẹra fún àwọn tí ẹ jọ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà.” Ohun tó sọ yìí yà mí lẹ́nu, ó sì rú mi lójú. Ṣé kò wá yẹ ká ran ara wa lọ́wọ́ ni?
Ní ọdún 1970 ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bernie Battleman wá sí ilé wa. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ọ̀rọ̀ nípa Bíbélì ni ó sì wá bá wa sọ. Irú èèyàn bíi tiwa ni. Ó lákíkanjú, kì í sì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Ọ̀pọ̀ wákàtí la fi jọ sọ̀rọ̀. Torí pé ibi tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ń tọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, mo ti mọ àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì sórí. Àmọ́ mi ò rò ó rí pé ó yẹ kí n ní Bíbélì tèmi! Bernie wá fún wa ní ọ̀kan, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ni mo mú Bíbélì yìí wá fún, torí mo nífẹ̀ẹ́ yín.” Ó tún mú Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Ben wá sọ́dọ̀ wa. Ọmọ ilẹ̀ Belarus ni, ó sì máa ń sọ èdè Rọ́ṣíà.
Ben àti ìyàwó rẹ̀ fi sùúrù dáhùn àwọn ìbéèrè mi látinú Bíbélì. Nígbà yẹn ṣe ni mo gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí ń lọ́ Ìwé Mímọ́ lọ́rùn. Nígbà tí mo kà á nínú ìwé wọn pé Màríà bí àwọn ọmọ míì lẹ́yìn Jésù, inú bí mi gan-an, torí èyí yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n kọ́ wa ní ṣọ́ọ̀ṣì.
Mo pe ọ̀rẹ́ mi kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Poland, mo ní kó wo Mátíù 13:55, 56 nínú Bíbélì tiẹ̀ lédè Polish. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tó kà á fún mi pé òótọ́ ni Jésù ní àwọn àbúrò ọkùnrin! Ọ̀rẹ́ mi yìí tún pe ẹnì kan tó mọ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìkówèésí ńlá kan tó ń jẹ́ Library of Congress ní ìlú Washington, D.C. Ó ní kó bá òun wo ẹsẹ Bíbélì yìí nínú gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì tó wà níbẹ̀. Ẹni náà sì sọ pé ohun kan náà ló wà nínú gbogbo wọn, ó ní gbogbo wọn ló sọ pé Jésù ní àbúrò lọ́kùnrin àti lóbìnrin!
Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló ń jà gùdù lọ́kàn mi. Irú bíi: Kí ló
dé tí àwọn ọmọdé fi ń kú? Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bá ara wọn jà? Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn kì í fi í yéra, kódà bí wọ́n tilẹ̀ ń sọ èdè kan náà? Ìdáhùn tí mo rí nínú Bíbélì wú mi lórí gan-an ni. Mo wá mọ̀ pé Ọlọ́run kò dá wa pé ká máa jìyà. Inú mi sì dùn nígbà tí mo gbọ́ pé mo máa tún pa dà rí àwọn èèyàn mi tí wọ́n pa nígbà ogun. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo wá mọ Jèhófà dáadáa.Lọ́jọ́ kan, èmi àti ọmọ mi ọkùnrin jọ wà ní iwájú àwọn ère, a jọ ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ọmọ mi yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ojú ogun Vietnam ni, ìdààmú ọkàn sì bá a gan-an. Ó kàn ṣáà sọ sí mi lọ́kàn pé kì í ṣe àwọn ère ló yẹ kí n máa gbàdúrà sí, Jèhófà Ọlọ́run alààyè ló yẹ kí n máa ké pè. Ni mo bá fa àwọn ère náà ya, igbà yẹn ni mo wá rí i pé ìdànǹdán aláràbarà lásán tiẹ̀ ni wọ́n. Ṣọ́ọ̀ṣì ni mo ti rà wọ́n, àmọ́ alẹ́ ọjọ́ yẹn ni mo kó wọn dà nù.
Kò rọrùn fún mi rárá láti fi ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti tọ́ mi dàgbà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, mo wá mọyì ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ju gbogbo ohun mìíràn lọ. Lọ́dún kan lẹ́yìn náà, èmi àti ọkọ mi àti ọmọ wa obìnrin jọ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà tí mo sọ lẹ́ẹ̀kan. Mo mú ìwé kan dání tí mo kọ àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì sí àti àwọn ẹsẹ Bíbélì tó jẹ mọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan. Bí mo ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì náà sókè, àlùfáà náà sọ pé, “Áà ìwọ yìí ti sọ nù pátápátá!” Ó wá sọ pé òun ò gbọ́dọ̀ rí ẹsẹ̀ wa lẹ́nu ọ̀nà òun mọ́.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà wọ Olya ọmọbìnrin mi lọ́kàn, tórí ó máa ń fẹ́ mọ ìdí tí nǹkan fi ń ṣẹlẹ̀. Òun náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í fara balẹ̀ ka Bíbélì, ó sì ń tẹ̀ lé mi lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọdún 1972, mo ṣe ìrìbọmi. Olya náà sì ṣe ìrìbọmi lọ́dún tó tẹ̀ lé e.
Àkọmọ̀nà Ìdílé Wa
Àkọmọ̀nà ìdílé wa ni, tòní ni kó o máa rò, fi tàná sílẹ̀. Torí náà, a kì í lọ́ra láti ṣe ohun tó bá tiẹ̀ jẹ́ tuntun sí wa, tó bá ṣáà ti dá wa lójú pé ohun tó tọ́ ni. Nígbà tí èmi àti ọmọ mi obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, ṣe ló ń wù wá ṣáá pé ká máa lọ sí ilé àwọn èèyàn ká sì máa sọ ohun tí a ń kọ́ fún wọn. Èmi gan-an alára rí i pé bí mo ṣe máa ń la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ àti bí mi kì í ṣe lè fi bí nǹkan ṣe rí lára mi pa mọ́, máa ń mú kí àwọn tí a bá jọ lọ wàásù fi ìfẹ́ àti ọgbọ́n ṣàtúnṣe ọ̀rọ̀ tí mo bá sọ sí àwọn tí a lọ wàásù fún. Àmọ́ nígbà tó yá, mo kọ́ bí mo ṣe lè máa bá àwọn èèyàn tó ní irú ìrírí bíi tèmi sọ̀rọ̀, torí pé onírúurú orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti gbé rí níbi tí wọ́n ti ń wá bí wọ́n á ṣe lè gbé ìgbé ayé tó sunwọ̀n.
Ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, èmi àti ọmọ mi pinnu pé tí ètò Ìṣèlú kan tí wọ́n fi ṣe ìdènà láàárín àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé bá ti kásẹ̀ nílẹ̀, a máa lọ sí Rọ́ṣíà ká lè lọ kọ́ àwọn míì bíi tiwa nípa Ọlọ́run. Láàárín ọdún 1990 sí 1993, ètò Ìṣèlú náà kásẹ̀ nílẹ̀. Olya sì ṣe ohun tí àwa méjèèjì sọ pé a máa ṣe. Ó kó lọ sí ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ọdún mẹ́rìnlá ló si fi lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kọ́ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ó tún wà lára àwọn tó túmọ̀ àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Rọ́ṣíà ni ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Rọ́ṣíà.
Ní báyìí, mi ò lè dìde lórí bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n ti ń tọ́jú mi mọ́. Àmọ́ àwọn ọmọ mi ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí nǹkan lè rọ̀ mí lọ́rùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà jẹ mí níbẹ̀rẹ̀, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó ti jẹ́ kí n gbé ìgbé ayé tó dáa. Mo ti wá rí bí ọ̀rọ̀ sáàmù tí Dáfídì tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn kọ ṣe ṣẹ sí mi lára níbi tó ti sọ pé: “[Ọlọ́run] ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa. Ó ń tu ọkàn mi lára. Ó ń ṣamọ̀nà mi ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.”—Sáàmù 23:2, 3. *
^ Maria Kilin kú ní March 1, 2010, nígbà tí a ń ṣètò bí a ṣe máa tẹ ìtàn tó kọ nípa ara rẹ̀ yìí jáde.