Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Rí Ohun Tó Dára Jù

Wọ́n Rí Ohun Tó Dára Jù

ÀRÀÁDỌ́TA Ọ̀KẸ́ àwọn Kristẹni ni kì í ṣe ọdún Kérésìmesì. Báwo ni ìpinnu yìí ṣe rí lára wọn? Ǹjẹ́ ó ń ṣe wọ́n bíi pé wọ́n ń pàdánù nǹkan kan? Àwọn ọmọ wọn ńkọ́, ṣé kì í ṣe wọ́n bíi pé wọ́n ń fi ohun rere dù wọ́n? Gbọ́ nǹkan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri ayé sọ nípa kókó yìí.

Rírántí Jésù Kristi: “Kí n tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹsẹ̀ mi wọ́n ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ọjọ́ Kérésì tàbí ọjọ́ ọdún àjíǹde nìkan ni mo máa ń lọ. Tí mo bá sì jàjà lọ, mi kì í sábà ronú nípa Jésù Kristi. Ní báyìí, mi ò ṣe ọdún Kérésìmesì mọ́, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ni mo máa ń lọ sí ìpàdé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kódà mo tún ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù!”—EVE, LÁTI ỌSIRÉLÍÀ.

Rírí ayọ̀ látinú fífúnni lẹ́bùn: “Orí mi máa ń wú tí wọ́n bá fún mi ní ẹ̀bùn tí mi ò retí tẹ́lẹ̀. Mo fẹ́ràn kí nǹkan máa yà mí lẹ́nu! Mo sì tún fẹ́ràn kí n máa ṣe káàdì ìkíni tàbí kí n ya àwòrán tó dára kí n sì fún àwọn èèyàn. Inú àwọn tí mo bá fún máa ń dùn, inú tèmi náà sì máa ń dùn.”—REUBEN, LÁTI NORTHERN IRELAND.

Ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìní: “A fẹ́ràn ká máa se oúnjẹ lọ fún àwọn tí ara wọn kò yá. Nígbà míì, a máa ń lọ fún wọn ní òdòdó, kéèkì tàbí ẹ̀bùn kékeré kan kí wọ́n lè dára yá. Inú wa máa ń dùn láti ṣe èyí, torí kò sí ìgbà tí a kò lè ṣe é láàárín ọdún.”—EMILY, LÁTI ỌSIRÉLÍÀ.

Wíwá àyè láti fara mọ́ ìdílé: “Tí àwa àti àwọn ìbátan wa bá wà pa pọ̀ nígbà tí kì í ṣe àsìkò ọdún, ara máa ń tù wá, ó sì máa ń rọrùn fún àwọn ọmọ wa láti mọ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò wa, àwọn òbí wa àti àwọn ìbátan wa yòókù láìsí ìkánjú. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ìgbà tó bá wù wá la máa ń lọ kí wọn, tí kò di dandan kó jẹ́ ìgbà ọdún, a kì í da ara wa láàmú nítorí rẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí wa náà sì mọ̀ pé torí pé a fẹ́ràn àwọn ni a ṣe wá kí wọn.”—WENDY, LÁTI ERÉKÙṢÙ CAYMAN.

Àlàáfíà: “Ní àsìkò Kérésì, ohun tí àwọn èèyàn fẹ́ ṣe máa ń pọ̀ débi pé wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ronú nípa bí wọ́n ṣe máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Nísinsìnyí, tí mo ti wá mọ ìlérí tí Bíbélì ṣe fún aráyé, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Ó sì ti wá yé mi pé ayé ń bọ̀ wá dáa fún àwọn ọmọ mi lọ́jọ́ iwájú.”—SANDRA, LÁTI SÍPÉÈNÌ.