Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

“O Ti . . . Ṣí Wọn Payá fún Àwọn Ìkókó”

“O Ti . . . Ṣí Wọn Payá fún Àwọn Ìkókó”

Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ lóòótọ́, kó o mọ ohun tó fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́, kí o sì tún mọ àwọn ohun tó fẹ́ ṣe? Jèhófà Ọlọ́run sọ gbogbo òtítọ́ nípa ara rẹ̀ fún wa nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè ka Bíbélì kí wọ́n sì lóye òtítọ́ yẹn o. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn tí Ọlọ́run bá fún láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ nìkan ló lè lóye irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀, kì í sì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń ní àǹfààní yẹn. Jésù jẹ́ ká mọ irú àwọn tí òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè yé. Jẹ́ ká wo ohun tó sọ.—Ka Mátíù 11:25.

Bí ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí: “Ní àkókò yẹn, Jésù sọ ní ìdáhùnpadà pé.” Tí o bá wò ó, ó jọ pé ohun kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni Jésù fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí. Ṣe ni Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bá àwọn èèyàn ìlú ńlá mẹ́ta kan ní Gálílì wí nítorí pé ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńláǹlà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n kọ̀ láti di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mátíù 11:20-24) Ó lè máa yà ẹ́ lẹ́nu pé, ‘Báwo ni ẹnì kan ṣe máa rí adúrú iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yẹn, síbẹ̀ kó má gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó fi kọ́ni gbọ́ débi pé ó tiẹ̀ máa di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?’ Ohun tó fà á ni pé ọkàn àwọn èèyàn wọ̀nyẹn yigbì, ìyẹn ni wọ́n ṣe kọ̀ láti tẹ̀ lé Jésù.—Mátíù 13:10-15.

Jésù mọ̀ pé ká tó lè lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì a nílò ohun méjì, ìyẹn ni ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run àti ọkàn tó ṣe tán láti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù ṣàlàyé pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti fi nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” Ṣé o ti wá rí ìdí tí a fi lè sọ pé àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ni ẹni tó bá lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ní? Jèhófà ní ẹ̀tọ́ láti pinnu irú àwọn tó fẹ́ kó lóye òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé òun ni “Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Àmọ́ o, kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn ń fi ojúsàájú pinnu àwọn tí ó ń jẹ́ kó lóye òtítọ́. Kí ni Ọlọ́run fi ń pinnu àwọn tó máa jẹ́ kí òtítọ́ inú Bíbélì yé àti àwọn tí kò ní yé?

Àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà máa ń ṣe ojú rere sí, àwọn agbéraga kì í rí ojú rere rẹ̀. (Jákọ́bù 4:6) Ó máa ń fi òtítọ́ yìí pa mọ́ fún “àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye,” ìyẹn àwọn ọlọ́gbọ́n ayé yìí àti àwọn ọ̀mọ̀wé tí ìgbéraga ti wọ̀ lẹ́wù, tí wọ́n sì jọra wọn lójú débi pé wọ́n wò ó pé àwọn kò nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 1:19-21) Àwọn “ìkókó” ló máa ń fi òtítọ́ yìí hàn, ìyẹn àwọn tí wọ́n ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti ọmọdé tọ̀ ọ́ wá tọkàntọkàn. (Mátíù 18:1-4; 1 Kọ́ríńtì 1:26-28) Jésù Ọmọ Ọlọ́run bá irú àwọn àwùjọ méjèèjì yìí pàdé dáadáa. Ọ̀rọ̀ Jésù kò yé àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n mọ̀wé àmọ́ tí wọ́n jẹ́ agbéraga, ṣùgbọ́n àwọn apẹja tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni òye ọ̀rọ̀ rẹ̀ yé. (Mátíù 4:18-22; 23:1-5; Ìṣe 4:13) Ṣùgbọ́n o, àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn ọ̀mọ̀wé kan, tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ látọkàn wá di ọmọlẹ́yìn Jésù.—Lúùkù 19:1, 2, 8; Ìṣe 22:1-3.

Jẹ́ ká wá pa dà sórí ìbéèrè tí a béèrè ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ìyẹn: Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ lóòótọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, inú rẹ á dùn láti mọ̀ pé kì í ṣe àwọn tó ka ara wọn sí ọlọ́gbọ́n ayé yìí ni Ọlọ́run ń fún ní àǹfààní láti mọ òun. Àwọn tí àwọn ọlọ́gbọ́n ayé máa ń fojú pa rẹ́ ni Ọlọ́run máa ń fún ní àǹfààní yìí. Tó o bá ń fi ọkàn tí ó tọ́ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, o lè wà lára àwọn tí Jèhófà máa fún ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ yìí, kó jẹ́ kí o lóye òtítọ́ nípa òun. Tó o bá lóye òtítọ́ yìí, wàá máa gbé ìgbé ayé aláyọ̀ báyìí, ọwọ́ rẹ yóò sì lè tẹ “ìyè tòótọ́.” Ìyẹn ni pé wàá lè wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun, tí àwọn olódodo yóò máa gbé, tó ń bọ̀ láìpẹ́. *1 Tímótì 6:12, 19; 2 Pétérù 3:13.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún January

Mátíù 1-21

^ ìpínrọ̀ 7 Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti kọ́ ẹ ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tí ó fẹ́ ṣe fún aráyé. A máa ń lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? láti kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nílé wọn.