Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Sí Òǹkàwé Wa

Sí Òǹkàwé Wa

Oṣù July ọdún 1879 ni a bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí ò ń kà yìí. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, tí nǹkan ń yí pa dà náà là ń ṣe ìyípadà lóríṣiríṣi sí i. (Wo àwọn fọ́tò tó wà lókè.) Bẹ̀rẹ̀ látorí ẹ̀dà tí o mú dání yìí, o máa rí àwọn ìyípadà míì tá a ṣe sí ìwé ìròyìn náà. Kí ló máa yí pa dà nínú rẹ̀?

Káàkiri ayé ni àwọn èèyàn tó ń lọ wá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì túbọ̀ ń pọ̀ sí i, torí wọ́n rí i pé ọ̀nà yìí rọ àwọn lọ́rùn. Lọ́wọ́ kan wẹ́rẹ́ báyìí ni wọ́n ń rí àwọn ìsọfúnni tí wọ́n bá ń wá lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àti ìwé ìròyìn ni àwọn èèyàn sì máa ń lọ kà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn láti máa kàwé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, a ti ṣe ìyípadà sí ìkànnì www.pr418.com wa kó lè túbọ̀ fani mọ́ra, kí ó sì túbọ̀ rọrùn fún àwọn èèyàn láti máa wá ìsọfúnni níbẹ̀. Àwọn tó bá dé orí ìkànnì yìí lè rí ìtẹ̀jáde wa kà ní èdè tó ju irínwó ó lé ọgbọ̀n [430]. Láti oṣù yìí lọ, wọ́n tún lè máa rí àwọn àpilẹ̀kọ kan tí à ń tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn wa tẹ́lẹ̀, àmọ́ tó jẹ́ pé orí ìkànnì nìkan ni a ó ti máa gbé wọn jáde báyìí kà níbẹ̀. *

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé orí Íńtánẹ́ẹ̀tì nìkan ni a ó ti máa gbé àwọn àpilẹ̀kọ kan jáde, a ti dín ojú ìwé ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí ó wà fún fífi sóde kù láti méjìlélọ́gbọ̀n sí mẹ́rìndínlógún, bẹ̀rẹ̀ látorí ẹ̀dà yìí. Ní báyìí à ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ní igba ó lé mẹ́rin [204] èdè. Níwọ̀n bí iye ojú ìwé tí a ó máa tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn yìí ti dín kù báyìí, àwọn èdè tí a ó máa túmọ̀ rẹ̀ sí á lè pọ̀ sí i.

A nírètí pé ìyípadà yìí á jẹ́ ká lè mú ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń mú kí àwọn èèyàn rí ìyè dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sí i. A pinnu pé a ó máa bá a lọ láti máa pèsè ìsọfúnni tó kún rẹ́rẹ́, tó ń lani lóye tó sì fani mọ́ra sínú ìwé tí a ń tẹ̀ àti lórí ìkànnì wa, kí àwọn òǹkàwé wa tó ní ọ̀wọ̀ fún Bíbélì tí wọ́n sì fẹ́ mọ ohun tó ń kọ́ni gan-an lè jàǹfààní púpọ̀.

Àwa Òǹṣèwé

^ ìpínrọ̀ 5 Lára àwọn àpilẹ̀kọ tí yóò máa jáde lórí ìkànnì nìkan ni: “Abala Àwọn Ọ̀dọ́,” tó dá lórí onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì tí a dìídì ṣe fún àwọn ọ̀dọ́. Òmíràn ni “Ẹ̀kọ́ Bíbélì,” a ṣe èyí fún àwọn òbí kí wọ́n lè máa lò ó láti fi kọ́ àwọn ọmọ wọn tí kò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́ta lọ.