BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
“Wọ́n Fẹ́ Kí Èmi Fúnra Mi wádìí Láti Mọ Ohun Tí Bíbélì Sọ”
-
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1982
-
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: DOMINICAN REPUBLIC
-
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: INÚ Ẹ̀SÌN MORMON NI WỌ́N BÍ MI SÍ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Ìlú Santo Domingo ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic ni wọ́n ti bí mi. Èmi ni àbíkẹ́yìn nínú àwa mẹ́rin tí àwọn òbí mi bí. Àwọn òbí mi kàwé dáadáa, ó sì wù wọ́n kí wọ́n tọ́ ọmọ wọn dàgbà láàárín àwọn tó jẹ́ ọmọlúwàbí. Ní ọdún mẹ́rin ṣáájú kí wọ́n tó bí mi, àwọn òbí mi pàdé àwọn míṣọ́nnárì ẹ̀sìn Mormon, ìyẹn ìjọ Church of Jesus Christ of Latter-day Saints. Bí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà ṣe múra dáadáa tí wọ́n sì hùwà ọmọlúwàbí wú àwọn òbí mi lórí. Ni wọ́n bá pinnu pé ìdílé wa máa wà lára àwọn tó máa kọ́kọ́ di ọmọ ìjọ Latter-day Saints, ìyẹn ìjọ Mormon, ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic.
Bí mo ṣe ń dàgbà, mo gbádùn oríṣiríṣi eré ìtura tí wọ́n máa ń ṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì wa. Ọwọ́ pàtàkì tí wọ́n fi mú ọ̀rọ̀ ìdílé àti ìwà rere sì wú mi lórí. Kódà, inú mi máa ń dùn pé mo jẹ́ ọmọ ìjọ Mormon, mo sì fẹ́ di míṣọ́nnárì níbẹ̀.
Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún méjìdínlógún, ìdílé wa ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí n lè lọ sí ilé ìwé gíga níbẹ̀. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, àbúrò màmá mi àti ọkọ rẹ̀ wá kí wa ní ìpínlẹ̀ Florida. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Wọ́n ní ká bá àwọn lọ sí àpéjọ kan tí wọ́n ti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì. Nígbà tí a wà ní àpéjọ yẹn, bí gbogbo àwọn tó yí mi ká ṣe ń ṣí Bíbélì wọn, tí wọ́n sì ń kọ àwọn kókó pàtàkì sílẹ̀ wú mi lórí. Èmi náà bá ní kí wọ́n fún mi ní gègé àti bébà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àkọsílẹ̀.
Lẹ́yìn àpéjọ yẹn, àbúrò màmá mi àti ọkọ rẹ̀ sọ pé níwọ̀n ìgbà tó ti wù mí kí n di míṣọ́nnárì, àwọn máa kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ nípa Bíbélì. Mo gbà bẹ́ẹ̀, torí nígbà yẹn ìwé ẹ̀sìn Mormon ni mo ń kà dáadáa, mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Àbúrò màmá mi àti ọkọ rẹ̀ máa ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ lórí fóònù. Wọ́n sì sábà máa ń gbà mí níyànjú pé kí n máa wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí wọ́n fi kọ́ mi ní ṣọ́ọ̀ṣì àti ohun tí Bíbélì sọ. Wọ́n fẹ́ kí èmi fúnra mi wádìí láti mọ ohun tí Bíbélì sọ.
Ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ń kọ́ni nínú ìsìn Mormon ni mo gbà gbọ́, àmọ́ mi ò mọ bí wọ́n ṣe bá Bíbélì mu. Àbúrò màmá mi wá fi ìwé ìròyìn Jí! November 8, 1995 lédè Gẹ̀ẹ́sì ránṣẹ́ sí mi. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ àwọn àpilẹ̀kọ kan wà nínú rẹ̀ tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn onísìn Mormon gbà gbọ́. Nígbà tí mo kà á, mo wá rí i pé àṣé ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn Mormon ni mi ò tiẹ̀ mọ̀. Mo wá lọ sórí ìkànnì àwọn ẹlẹ́sìn Mormon lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti wádìí bóyá òótọ́ ni ohun tí mo kà nínú ìwé ìròyìn Jí! náà. Bí ìwé ìròyìn yẹn ṣe sọ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ náà rí. Nígbà tí mo tún lọ ṣe ìwádìí ní ibi tí àwọn ẹlẹ́sìn Mormon ń kó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí ní ìpínlẹ̀ Utah, mo rí i pé òótọ́ ni gbogbo ohun tí mo kà nínú ìwé ìròyìn Jí! yẹn.
Èrò mi tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ni pé ìwé ẹ̀sìn Mormon àti Bíbélì kò ta ko ara wọn, pé ṣe ni wọ́n wọnú ara wọn. Ṣùgbọ́n bí mo ṣe wá ń fara balẹ̀ ka Bíbélì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí bí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn Mormon ṣe ta ko ohun tí Bíbélì sọ. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìsíkíẹ́lì 18:4, Bíbélì sọ pé ọkàn máa ń kú. Àmọ́ ìwé ẹ̀sìn Mormon, sọ nínú Alma 42:9 pé: “Ọ̀kan kì í kú.”
Yàtọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ìsìn Mormon kò bá Ìwé Mímọ́ mu, bí ẹ̀sìn náà ṣe máa ń gbin ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni sọ́kàn àwọn èèyàn tún kọ mí lóminú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ Mormon pé àgbègbè Jackson County, ní ìpínlẹ̀ Missouri ní Amẹ́ríkà ni ọgbà Édẹ́nì wà láyé àtijọ́. Àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì náà sì ń kọ́ni pé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Ọlọ́run yóò lò láti fi ṣàkóso ayé.
Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé, ‘tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè mi àti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù nígbà náà’? Mo dá ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀ lọ́jọ́ kan tí mo ń bá ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọ ìjọ Mormon sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Wọ́n ti ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ tó máa fi di míṣọ́nnárì. Mo bi í ní pàtó pé ṣé ó máa lè bá àwọn ọmọ ìjọ Mormon bíi tiẹ̀ jà tí orílẹ̀-èdè rẹ̀ bá ń bá tiwọn jagun. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tó dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni! Mo ṣèwádìí jinlẹ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ wa nínú ìsìn Mormon, mo sì béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn kan tó jẹ́ aṣáájú nínú ẹ̀sìn náà. Èsì tí wọ́n fún mi ni pé àdììtú ṣì ni àwọn nǹkan tí mo ń béèrè wọ̀nyẹn, pé tó bá yá, ó máa ṣe kedere sí wa bí òye wa bá ṣe ń pọ̀ sí i.
Èsì tí wọ́n fún mi yìí kò tẹ́ mi lọ́rùn. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í tún inú rò nìyẹn lórí ohun tí mo fẹ́ ṣe gan-an àti ohun tó mú kí n fẹ́ di míṣọ́nnárì ẹ̀sìn Mormon. Mo wá rí i pé ohun tó mú kí n fẹ́ di míṣọ́nnárì kò ju pé ó wù mí kí n máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Bí àwọn èèyàn ṣe máa ń fi ojú ẹni ọ̀wọ̀ wo àwọn míṣọ́nnárì sì tún wù mí. Mi ò ṣírò ti Ọlọ́run mọ́ ọ̀rọ̀ náà rárá, torí mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Ọlọ́run dáadáa. Lóòótọ́, mo ti ka Bíbélì gààràgà ní àwọn àsìkò kan rí, àmọ́ mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọyì rẹ̀. Mi ò sì mọ ète tí Ọlọ́run ní fún ilẹ̀ ayé àti àwa èèyàn.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wá ń yé mi. Lára àwọn nǹkan tí mo kọ́ ni orúkọ Ọlọ́run, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá kú àti ipa tí Jésù kó nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ. Inú mi dùn pé èmi náà ti wá ń mọ Bíbélì tó jẹ́ ìwé àtàtà yìí, ó sì ń dùn mọ́ mi láti máa ṣàlàyé ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí mo ti kọ́ fún àwọn míì. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ mi ò mọ̀ ju pé Ọlọ́run wà, àmọ́ ní báyìí, mo ti wá mọ Ọlọ́run bí ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ mi jù lọ tí mo lè máa bá sọ̀rọ̀ nínú àdúrà. Ní July 12, ọdún 2004, mo ṣe ìrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, mo di òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù.
Ọdún márùn-ún ni mo fi yọ̀ǹda ara mi láti ṣiṣẹ́ sìn ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Inú mi dùn gan-an ni bí mo ṣe ṣèrànwọ́ níbi tí wọ́n ti ń tẹ Bíbélì àti àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì jáde, èyí tí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn káàkiri ayé ń jàǹfààní rẹ̀. Mo sì ń gbádùn bí mo ṣe ń bá a lọ láti máa kọ́ àwọn míì nípa Ọlọ́run.