KÓKÓ Ọ̀RỌ̀: ÀǸFÀÀNÍ TÍ ÀJÍǸDE JÉSÙ ṢE FÚN WA
Ṣé Òótọ́ Ni Pé Jésù Jíǹde?
ÒPÌTÀN tó ń jẹ́ Herodotus, ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó gbé láyé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún sẹ́yìn, sọ ìtàn kan nípa àwọn ará Íjíbítì ìgbà ayé rẹ̀. Ó ní: “Tí àwọn èèyàn bá jẹun tán níbi àpèjẹ àwọn ọlọ́rọ̀, ọkùnrin kan máa gbé pósí tí ère onígi kan wà nínú rẹ̀ hàn wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan. Ṣe ni wọ́n gbẹ́ ère yìí, tí wọ́n sì kùn ún kó lè jọ òkú èèyàn. Ó máa ń gùn tó nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà méjì sí mẹ́ta. Ọkùnrin náà á wá máa sọ fún àwọn tó ń gbé e hàn pé: ‘Mutí, kí o sì gbádùn ẹ̀mí ẹ, torí nígbà tí o bá kú, bí o ṣe máa wà nílẹ̀ bọrọgidi nìyí.’”
Kì í ṣe àwọn ará Íjíbítì nìkan ló ní irú èrò yìí nípa ìgbésí ayé èèyàn àti ikú. Lónìí bákan náà, àwọn èèyàn máa ń sọ pé, “Ẹ jẹ́ ká jẹ, ká mu, ká gbádùn ẹ̀mí wa o jàre.” Èrò wọn ni pé tó bá jẹ́ ikú ni òpin ìgbé ayé èèyàn, á dáa kéèyàn kúkú jayé orí ẹ̀ dọ́ba kó tó kú. Àbí kí nìdí téèyàn á fi máa yọ ara rẹ̀ lẹ́nu pé òun fẹ́ máa hùwà tó mọ́? Tó bá lọ jẹ́ pé ikú ni òpin ìgbésí ayé èèyàn, a jẹ́ pé ó bọ́gbọ́n mu nìyẹn téèyàn bá ń jayé orí ẹ̀ láìro tẹ̀yìn ọ̀la. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ̀rọ̀ nípa irú èrò táwọn èèyàn ní yìí. Ó ṣàpèjúwe ìwà àwọn tí kò gbà gbọ́ pé àjíǹde wà. Ó ní wọ́n máa ń sọ pé: “Bí a kò bá ní gbé àwọn òkú dìde, ‘ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.’”—1 Kọ́ríńtì 15:32.
Àmọ́ ṣá o, Pọ́ọ̀lù kò gbà pé téèyàn bá ti kú tiẹ̀ tán nìyẹn. Ó dá a lójú pé àwọn òkú máa jíǹde, wọ́n á sì lè wà láàyè títí lọ gbére. Àjíǹde * Kristi Jésù ló sì jẹ́ kó ní ìdánilójú yìí. Òótọ́ pọ́ńbélé ni àjíǹde Jésù yìí, ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì sì ni. Kódà, àjíǹde Jésù ni ìṣẹ̀lẹ̀ kan pàtàkì tó gbé ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ró jù.
Báwo ni àjíǹde Jésù ṣe ṣe wá láǹfààní? Báwo la tiẹ̀ ṣe mọ̀ pé ó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́? Ẹ jẹ́ ká wo àlàyé tí Pọ́ọ̀lù
ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó ń gbé ní ìlú Kọ́ríńtì.KÁ NÍ ỌLỌ́RUN Ò JÍ KRISTI DÌDE ŃKỌ́?
Ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa àjíǹde dà rú mọ́ àwọn Kristẹni kan ní ìlú Kọ́ríńtì lójú láyé àtijọ́. Àwọn míì kò sì gbà gbọ́ pé àjíǹde tiẹ̀ wà rárá. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá kọ ìwé kìíní sí àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀, ó sọ ohun tí ì bá yọrí sí ká ní kò sí àjíǹde lóòótọ́. Ó ní: “Ní tòótọ́, bí kò bá sí àjíǹde àwọn òkú, a jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde. Ṣùgbọ́n bí a kò bá tíì gbé Kristi dìde, dájúdájú, asán ni ìwàásù wa, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a rí wa pẹ̀lú ní ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run . . . Ìgbàgbọ́ yín jẹ́ aláìwúlò; ẹ ṣì wà nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín. Pẹ̀lúpẹ̀lù . . . àwọn tí ó sùn nínú ikú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ṣègbé.”—1 Kọ́ríńtì 15:13-18.
“Ó fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo . . . Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jákọ́bù, lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì; ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn gbogbo rẹ̀, ó fara han èmi pẹ̀lú.”—1 Kọ́ríńtì 15:6-8
Gbólóhùn tí Pọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní àríyànjiyàn kankan nínú. Ó ní tó bá jẹ́ pé kò sí àjíǹde, a jẹ́ pé Ọlọ́run kò jí Kristi tó kú dìde nìyẹn. Ká ní Ọlọ́run kò sì jí Kristi dìde, kí ni ì bá yọrí sí? A jẹ́ pé asán ni ìhìn rere tí à ń wàásù, irọ́ ńlá ni a sì ń pa. Ó ṣe tán, ọ̀kan lára òpómúléró ìgbàgbọ́ àwa Kristẹni ni àjíǹde Kristi jẹ́, torí kò sí bí a ṣe máa ṣàlàyé ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ inú Bíbélì, irú bí ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, orúkọ Ọlọ́run, Ìjọba rẹ̀ àti ìgbàlà wa tí kò ní mẹ́nu kan àjíǹde Jésù. Tó bá jẹ́ pé àjíǹde Jésù kò wáyé, a jẹ́ pé òfìfo ọ̀rọ̀ lásán ni Pọ́ọ̀lù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù kéde káàkiri.
Ìyẹn nìkan kọ́ o. Pọ́ọ̀lù tún fi hàn pé ká ní Kristi kò jíǹde, asán àti òfo ni ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni ì bá já sí, orí irọ́ ni ìgbàgbọ́ wọn ì bá sì dá lé. Á wá já sí pé irọ́ ni Pọ́ọ̀lù àti àwọn tó kù ń pa pé Jésù jíǹde àti pé wọ́n parọ́ mọ́ Jèhófà Ọlọ́run pé ó jí i dìde. Yàtọ̀ síyẹn, a jẹ́ pé irọ́ gbuu tún ni bí wọ́n ṣe sọ pé Kristi “kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.” Àbí, tí ẹni tí a mọ̀ sí Olùgbàlà fúnra rẹ̀ ò bá tíì bọ́ lọ́wọ́ ikú, báwo ló ṣe máa gba àwọn míì là? (1 Kọ́ríńtì 15:3) Ohun tí èyí máa túmọ̀ sí ni pé, ṣe ni àwọn Kristẹni tó kú, títí kan àwọn tó kú ikú ajẹ́rìíkú pàápàá, kàn fẹ̀mí ara wọn ṣòfò lásán, tí wọ́n rò pé àwọn máa jíǹde.
Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé nínú ìgbésí ayé yìí nìkan ni a ti ní ìrètí nínú Kristi, àwa ni ó yẹ láti káàánú jù lọ nínú gbogbo ènìyàn.” (1 Kọ́ríńtì 15:19) Bí àwọn Kristẹni yòókù ṣe jìyà náà ni Pọ́ọ̀lù ṣe jìyà. Ìgbàgbọ́ tó ní pé àjíǹde dájú àti pé ó máa ṣe aráyé láǹfààní kò jẹ́ kó mikàn bó ṣe pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, tó fojú winá inúnibíni, tó fara da ìṣòro, kódà tí wọ́n tún pa á. Gbogbo èyí ì bá já sí asán ká ní irọ́ pátápátá ni àjíǹde!
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÍ O GBÀ GBỌ́ PÉ ÀJÍǸDE WÀ
Pọ́ọ̀lù kò gbà rárá pé irọ́ ni ìgbàgbọ́ tí àwọn Kristẹni ní pé àjíǹde wà. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run jí Jésù dìde. Ó sì mẹ́nu ba àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ kó dá a lójú ní ṣókí fún àwọn ará Kọ́ríńtì. Ó ní: “Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé a sin ín, bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé ó fara han Kéfà, lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá * náà.” Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, púpọ̀ jù lọ nínú àwọn tí wọ́n ṣì wà títí di ìsinsìnyí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jákọ́bù, lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì; ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn gbogbo rẹ̀, ó fara han èmi pẹ̀lú.”—1 Kọ́ríńtì 15:3-8.
Ọ̀rọ̀ tó dá Pọ́ọ̀lù lójú ló fi bẹ̀rẹ̀ àlàyé rẹ̀ bó ṣe sọ pé Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, a sin ín, a sì gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta. Kí ló jẹ́ kó dá a lójú? Ìdí àkọ́kọ́ ni ẹ̀rí látọ̀dọ̀ àwọn tó fojú rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde. Ó fara han àwọn kan lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, títí kan Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀. Ó tún fara Lúùkù 24:1-11) Púpọ̀ nínú àwọn tó fojú rí Jésù ṣì wà láyé nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn èèyàn sì lè lọ bi wọ́n bóyá òótọ́ ni Jésù fara hàn wọ́n lẹ́yìn tó jíǹde. (1 Kọ́ríńtì 15:6) Àwọn èèyàn lè má ka ọ̀rọ̀ ẹnì kan tàbí méjì sí, àmọ́ ó máa ṣòro láti kó ọ̀rọ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta èèyàn tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ dà nù.
han àwùjọ kéékèèké. Kódà ó fara han èrò tí ó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500], tó sì jẹ́ pé púpọ̀ lára wọn ni kò kọ́kọ́ gbà gbọ́ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jésù ti jíǹde! (Tún kíyè sí i pé ẹ̀ẹ̀mejì ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ikú Jésù, bí wọ́n ṣe sin ín àti àjíǹde rẹ̀, rí “gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.” Ìdí ni pé bí nǹkan wọ̀nyẹn ṣe ṣẹlẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ní ìmúṣẹ. Èyí sì fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí.
Láìka ẹ̀rí látọ̀dọ̀ àwọn tó rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde àti àwọn ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì sí, àwọn kan kò gbà nígbà yẹn pé òótọ́ ni Jésù jíǹde. Kódà títí dòní pàápàá àwọn míì kò tíì gbà pé òótọ́ ni. Àwọn kan sọ pé ṣe ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù jí òkú rẹ̀ gbé, tí wọ́n wá ń sọ kiri pé àwọn rí i lẹ́yìn tó jíǹde. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò ní agbára tàbí ohunkóhun tí wọ́n lè ṣe tí wọ́n á fi lè borí àwọn ọmọ ogun Róòmù tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibojì Jésù. Àwọn míì tún sọ pé ìran lásán ni wọ́n kàn rí, tí wọ́n ń sọ pé àwọn rí Jésù tó jíǹde. Àmọ́ ìyẹn kò bọ́gbọ́n mu, torí bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló rí Jésù ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ fi hàn pé kò lè jẹ́ ojú ìran ni gbogbo wọn wà. Níwọ̀n bí Jésù sì ti yan ẹja fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní Gálílì lẹ́yìn tó jíǹde, tí wọ́n sì jẹ ẹ́, ó dájú pé ìyẹn náà kò lè jẹ́ ìran lásánlàsàn. (Jòhánù 21:9-14) Bákan náà, ǹjẹ́ ó lè jẹ́ pé ojú ìran náà ni gbogbo àwọn kan tó láwọn rí Jésù wà nígbà tó jẹ́ pé Jésù dìídì sọ pé kí wọ́n fọwọ́ kan òun?—Lúùkù 24:36-39.
Àwọn kan tún sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló hùmọ̀ ìtàn irọ́ tí wọ́n ń sọ kiri pé Jésù jíǹde. Àmọ́
kí ni wọ́n fẹ́ rí gbà nídìí ìyẹn? Torí pé bí wọ́n ṣe ń jẹ́rìí pé Jésù jíǹde, ṣe ni àwọn èèyàn ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà, tí wọ́n ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì pa àwọn míì lára wọn pàápàá. Ǹjẹ́ wọ́n á fẹ́ fi ẹ̀mí ara wọn wewu bẹ́ẹ̀, ká ní irọ́ lásán lọ̀rọ̀ yìí? Ohun kan tí kò sì yẹ ká gbàgbé ni pé Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti kọ́kọ́ kéde ọ̀rọ̀ yìí fáyé gbọ́, níbi tí àwọn tó kórìíra wọn wà, tí wọ́n sì ń wá ẹ̀sùn èyíkéyìí tí wọ́n á lè kà sí wọn lọ́rùn kí wọ́n lè pa wọ́n.Torí pé àjíǹde yìí wáyé ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ní ìgboyà láti jẹ́rìí nípa Olúwa wọn kódà lójú inúnibíni lílekoko. Àjíǹde wá di ọ̀kan pàtàkì lára ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni. Kì í ṣe torí ẹnì kan tó kàn jẹ́ olùkọ́ ọlọ́gbọ́n tí àwọn èèyàn pa ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe ń jẹ́rìí tí wọ́n wá ń fi ẹ̀mí ara wọn wewu o. Ohun tó mú kí wọ́n máa polongo àjíǹde Jésù láìkọ ikú ni pé, àjíǹde rẹ̀ jẹ́ kó dájú pé òun ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run, àti pé ó jẹ́ ẹni alágbára kan tó wà láàyè, tó ń tọ́ wọn sọ́nà, tó sì ń tì wọ́n lẹ́yìn. Bí Jésù ṣe jíǹde tún jẹ́ kó dá wọn lójú pé àwọn náà máa jíǹde tí wọ́n bá kú. Ní tòdodo, ká ní Jésù kò jíǹde ni, kò ní sí ẹ̀sìn Kristẹni. Àní sẹ́, ká ní Ọlọ́run kò jí Jésù dìde ni, ó ṣeé ṣe ká má tiẹ̀ gbọ́ nǹkan kan nípa rẹ̀ rárá.
Ṣùgbọ́n, àǹfààní wo ni àjíǹde Kristi ṣe fún wa lónìí?
^ ìpínrọ̀ 5 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “àjíǹde” lédè Yorùbá túmọ̀ sí pé kí ẹni tó kú tún pa dà wà láàyè, tòun ti gbogbo ohun tó mú kó yàtọ̀ sí ẹlòmíì. Kó má sì gbàgbé àwọn ohun tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nígbà ayé rẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 13 Àwọn “àpọ́sítélì” ni ẹsẹ Bíbélì yìí pè ní “àwọn méjìlá náà,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé mọ́kànlá ni wọ́n fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn ikú Júdásì Ísíkáríótù. Kódà ìgbà kan wà tí Tọ́másì kò sí láàárín wọn, tó jẹ́ pé mẹ́wàá péré lára wọn ni Jésù fara hàn, síbẹ̀ wọ́n ṣì pè wọ́n ní àwọn méjìlá.—Jòhánù 20:24.