Kí Ló Mú Kí Ìgbésí Ayé Jésù Ládùn?
ǸJẸ́ ìgbésí ayé Jésù ládùn lóòótọ́? Inú ìdílé olówó kọ́ ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Títí tó sì fi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, Jésù ò kó àwọn nǹkan ìní jọ. Kódà, “kò ní ibì kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Lúùkù 9:57, 58) Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn èèyàn tún kórìíra rẹ̀, wọ́n sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa, àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì pa á níkẹyìn.
O lè máa dà á rò nínú ọkàn rẹ pé, ‘Irú ayé yẹn kọ́ lèmi máa kà sí ìgbé ayé tó ládùn ní tèmi o!’ Àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan wà tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò nípa ìgbésí ayé Jésù. Jẹ́ ká wo apá mẹ́rin nínú rẹ̀.
ÀKỌ́KỌ́: JÉSÙ NÍ NǸKAN GIDI TÓ FI AYÉ RẸ̀ ṢE, Ó FI ṢE ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN.
“Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 4:34.
Jésù máa ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà, * Baba rẹ̀ ọ̀run nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Inú Jésù máa ń dùn láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kódà ó fi wé oúnjẹ, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ẹsẹ Bíbélì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fà yọ yìí. Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ kí ó tó di pé Jésù ṣe ìfiwéra tó ṣe.
Nǹkan bí ọwọ́ ọ̀sán ni Jésù sọ ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn. (Jòhánù 4:6) Orí ìrìn ni Jésù wà látàárọ̀ bó ṣe ń gba àgbègbè olókè tó wà ní Samáríà kọjá, torí náà ó dájú pé ebi ti ń pa á. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tiẹ̀ ń rọ̀ ọ́ pé: “Rábì, jẹun.” (Jòhánù 4:31) Jésù fi hàn nínú ìdáhùn rẹ̀ pé tí òun bá ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun, ìyẹn máa ń fún òun ní okun àti agbára. Ǹjẹ́ ìyẹn kò fi hàn pé ẹni tó ní nǹkan gidi tó fi ayé rẹ̀ ṣe ni Jésù?
ÌKEJÌ: JÉSÙ NÍ ÌFẸ́ TÓ JINLẸ̀ SÍ BABA RẸ̀.
“Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.”—Jòhánù 14:31.
Jésù ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀run. Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jésù ní sí Ọlọ́run ló mú kó máa kọ́ àwọn èèyàn nípa Baba rẹ̀, kí wọ́n lè mọ orúkọ rẹ̀, àwọn ìwà rẹ̀ àti ohun tó fẹ́ ṣe. Gbogbo ọ̀nà ni Jésù fi jọ Baba rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, nínú ìṣe àti nínú ìwà rẹ̀. Kódà tí a bá ń kà nípa Jésù, ṣe ni ó máa ń dà bíi pé ọ̀rọ̀ nípa Baba rẹ̀ ni a ń kà. Abájọ tó fi jẹ́ pé, nígbà tí Fílípì béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Fi Baba hàn wá,” Jésù fèsì pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”—Jòhánù 14:8, 9.
Jésù nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ débi pé, ó ṣe tán láti ṣe ohun tó bá fẹ́ kó ṣe láìkọ ikú pàápàá. (Fílípì 2:7, 8; 1 Jòhánù 5:3) Irú ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jésù ní sí Ọlọ́run yìí, ló mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ ládùn.
ÌKẸTA: JÉSÙ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÈÈYÀN.
“Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 15:13.
A mọ̀ pé ìgbésí ayé àwa èèyàn máa kún fún ìdààmú lọ́jọ́ iwájú, torí pé a jẹ́ aláìpé. Bíbélì sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) A kò lè fúnra wa bọ́ lọ́wọ́ nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ ń fà, ìyẹn ikú.—Róòmù 6:23.
Inú wa dùn pé, Jèhófà pèsè ojútùú sí àwọn ohun tó ń bá aráyé fínra, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ó jẹ́ kí Jésù Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá pípé tí kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan wá jìyà, kí ó sì kú fún wa, kí ó lè tipa bẹ́ẹ̀ ra aráyé pa dà kúrò lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ìfẹ́ tí Jésù ní sí Baba rẹ̀ àti àwa èèyàn ló mú kó fi tinútinú gbà láti fi ẹ̀mí pípé rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwa èèyàn. (Róòmù 5:6-8) Irú ìfẹ́ tí kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan tó ní yìí fi hàn pé ìgbé ayé tó ládùn ló gbé. *
ÌKẸRIN: JÉSÙ MỌ̀ PÉ BABA ÒUN NÍFẸ̀Ẹ́ ÒUN, INÚ RẸ̀ SÌ DÙN SÍ ÒUN.
“Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”—Mátíù 3:17, Bíbélì Mímọ́.
Ìgbà tí Jésù ṣèrìbọmi ni Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí láti ọ̀run. Nípa báyìí, Jèhófà fi hàn ní gbangba pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù, Ọmọ òun, inú òun sì dùn sí i. Abájọ tí Jésù fi fi ìdánilójú sọ pé: ‘Baba nífẹ̀ẹ́ mi’! (Jòhánù 10:17) Torí Jésù mọ̀ pé Baba òun nífẹ̀ẹ́ òun àti pé inú rẹ̀ dùn sí òun, èyí mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ nígbà tí àwọn èèyàn ṣe àtakò sí i, tí wọ́n sì ṣàríwísí rẹ̀. Kódà, kò mikàn rárá, ẹ̀rù ò sì bà á nígbà tí wọ́n fẹ́ pa á. (Jòhánù 10:18) Kò sí iyè méjì pé bí Jésù ṣe mọ̀ pé Baba òun nífẹ̀ẹ́ òun àti pé inú rẹ̀ dùn sí òun jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ ládùn.
Dájúdájú ìgbésí ayé Jésù ládùn. Ó ṣe kedere pé, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni a rí kọ́ lára Jésù nípa bí ìgbé ayé wa ṣe lè ládùn. Àpilẹ̀kọ tí ó kàn máa ṣàlàyé àwọn ìmọ̀ràn tó ṣe kedere tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbé ayé wọn.
^ ìpínrọ̀ 6 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.
^ ìpínrọ̀ 15 Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa bí ikú Jésù ṣe rà wá pa dà, ka orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.