Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ǹjẹ́ èèyàn lè lóye Bíbélì?
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì. Ńṣe ló dà bíi lẹ́tà tí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan kọ sí àwọn ọmọ rẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Nínú Bíbélì, Ọlọ́run ṣàlàyé bí a ṣe lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdí tó fi fàyè gba ìwà ibi àti ohun tó máa ṣe fún aráyé lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n, àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ti lọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́rùn, èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ rò pé àwọn kò lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì láéláé.—Ìṣe 20:29, 30.
Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ká mọ ẹni tí òun jẹ́ gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní ìwé kan tó rọrùn láti lóye.—Ka 1 Tímótì 2:3, 4.
Báwo ni o ṣe lè lóyè Bíbélì?
Yàtọ̀ sí pé Jèhófà fún wa ní Bíbélì, ó tún ṣe ọ̀nà bí a ṣe máa lóye rẹ̀. Ó rán Jésù pé kó wá kọ́ wa. (Lúùkù 4:16-21) Bí Jésù ṣe máa ń ṣàlàyé Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ mú kí àwọn tó n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lóye Bíbélì dáadáa.—Ka Lúùkù 24:27, 32, 45.
Jésù dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ nìṣó. (Mátíù 28:19, 20) Lónìí, àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Ọlọ́run. Tí o bá fẹ́ lóye ohun tí Bíbélì sọ, inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Ka Ìṣe 8:30, 31.