Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀

Bí Àárín Àwọn Tó Tún Ìgbéyàwó Ṣe Àti Àwọn Ẹlòmí ì Ṣe Lè Tòrò

Bí Àárín Àwọn Tó Tún Ìgbéyàwó Ṣe Àti Àwọn Ẹlòmí ì Ṣe Lè Tòrò

NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ ỌSIRÉLÍÀ, OBÌNRIN KAN TÓ Ń JẸ́ MARGARET, * TÓ FẸ́ ỌKỌ MÍÌ sọ pé: “Ìyàwó tí ọkọ mi ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ‘Rántí fọ eyín ẹ’ lásán ni mo kàn sọ.” Margaret gbà pé ọgbọ́n màdàrú tí obìnrin yìí dá ló fa wàhálà sínú ìdílé òun.

Kì í sábà rọrùn fáwọn tó tún ìgbéyàwó ṣe láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹni tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ wọn tún lè má wọ̀ pẹ̀lú ẹni tí ọkọ tàbí aya wọn ń fẹ́ tẹ́lẹ̀, kódà pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí àti àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá. * Bí àpẹẹrẹ, ó di dandan kí ọkọ tàbí ìyàwó tuntun jọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí òbí yìí á máa wá wo ọmọ rẹ̀ àti bó ṣe yẹ kí wọ́n bá ọmọ rẹ̀ wí àti irú ìtọ́jú tí wọ́n máa fún un. Àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn mọ̀lẹ́bí ẹni tó lọ fẹ́ ẹlòmíì lè má tètè mọwọ́ ẹni tuntun tó wá kún wọn nínú ìdílé wọn. Tó o bá wà nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀, jẹ́ ká wo bí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro yìí.

ÀJỌṢE KÌÍNÍ: ÒBÍ TÍ KÒ SÌ PẸ̀LÚ ỌMỌ RẸ̀

Ní orílẹ̀-èdè Nàmíbíà, obìnrin kan tó ń jẹ́ Judith, tó fẹ́ ọkọ míì sọ pé: “Nígbà kan, ìyàwó tí ọkọ mi fẹ́ tẹ́lẹ̀ sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé ìyàwó bàbá wọn ni mo kàn jẹ́ àti pé ọmọ tí mo bá bí fún bàbá wọn kì í ṣe àbúrò wọn. Ohun tó sọ yìí dùn mí wọra torí pé ṣe ni mo mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí ọmọ tí mo bí.”

Àwọn ọ̀mọ̀ràn gbà pé ẹni tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìdílé ẹnì kejì tó lọ fẹ́ ẹlòmíì. Lọ́pọ̀ ìgbà, obìnrin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ wọlé àti èyí tó kúrò nílé máa ń gbé e gbóná fún ara wọn. Kí lọ́nà àbáyọ?

Ọ̀nà àbáyọ: Jẹ́ kí ààlà wà, àmọ́ fọgbọ́n ṣe é. Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ rẹ ni ọmọ ń gbé, má yọwọ́ òbí kejì pátápátá lọ́rọ̀ ọmọ náà. O lè kó ìbànújẹ́ bá ọmọ náà tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé ipa kékeré kọ́ ni òbí ń kó nínú ìgbésí ayé ọmọ “tí ó bí.” * (Òwe 23:22, 25) Síbẹ̀, tí o bá jẹ́ kí ẹni tí ẹ jọ kọ ara yín sílẹ̀ máa tojú bọ ọ̀rọ̀ ìdílé rẹ, inú lè bí ọkọ tàbí ìyàwó tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ tàbí kí o kó o sí ìdààmú. Torí náà, bí o ò tiẹ̀ ní ta òbí kejì nù pátápátá, jẹ́ kí ààlà wà, àmọ́ fọgbọ́n ṣe é, kí àárín ìwọ àti ẹni tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ má bàa dà rú.

ÌMỌ̀RÀN FÁWỌN ÒBÍ

  • Tí o bá ń bá ẹni tí o ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ ọmọ tó dà yín pọ̀ ni kí o jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa dá lé jù, kí ẹ sì dín ọ̀rọ̀ tí ẹ ó máa sọ lórí àwọn ọ̀ràn míì kù. Bí àpẹẹrẹ, o lè fọgbọ́n sọ fún un pé kí ẹ jọ fi àdéhùn sí àkókò kan pàtó tí ẹ lè máa pe ara yín lórí fóònù. Ìyẹn máa jẹ́ kí ẹ mọ ìgbà tó yẹ kí ẹ pe ara yín, dípò tí ẹ ó kàn máa pè nígbà tó bá ti wù yín ṣáà tàbí lóru.

  • Tí àwọn ọmọ rẹ kò bá sí lọ́dọ̀ rẹ, o lè pè wọ́n lórí fóònù, o lè kọ lẹ́tà, o sì lè fi fóònù tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn. Èyí á jẹ́ kó o lè máa bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ déédéé. (Diutarónómì 6:6, 7) O tiẹ̀ lè lo ẹ̀rọ ìgbàlódé táá jẹ́ kí ẹ rí ara yín bí ẹ ṣe jọ ń sọ̀rọ̀. Tí o bá ń bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀, wàá mọ bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ìgbésí ayé wọn, wàá sì mọ bí o ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

ÌMỌ̀RÀN FÁWỌN OBÌNRIN TÓ FẸ́ ỌKỌ MÍÌ

  • Máa fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn sí ẹni tí ọkọ rẹ fẹ́ tẹ́lẹ̀. Jẹ́ kó hàn sí i pé kì í ṣe pé o fẹ́ gba ipò rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀. (1 Pétérù 3:8) Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, máa jẹ́ kí ìyá wọn mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe sí. Dáadáa tí wọ́n ń ṣe ni kó o máa sọ jù. (Òwe 16:24) Ní kí òun náà sọ ìmọ̀ràn tiẹ̀ lórí àwọn ọ̀ràn kan, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

  • Má ṣe máa kó àwọn ọmọ tó o bá nílé mọ́ra jù lójú ìyá wọn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Beverly, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àwọn ọmọ ọkọ mi fẹ́ máa pè mí ní mọ́mì. Èmi àti ọkọ mi gbà pé ilé wa nìkan ni kí wọ́n ti máa ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ kí wọ́n má ṣe pè mí bẹ́ẹ̀ lójú Jane, ìyá wọn tàbí àwọn ẹbí ìyá wọn. Èyí tún mú kí àárín èmi àti ìyá wọn gún sí i. A wá mọwọ́ ara wa débi pé a jọ máa ń pàdé nílé ìwé àwọn ọmọ náà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ayẹyẹ tàbí eré ìdárayá.”

Ọwọ́ tó o bá fi mú àwọn ọmọ rẹ lè yí nǹkan pa dà gan-an nínú ilé ju bí o ṣe rò lọ

ÌMỌ̀RÀN TÓ MÁA JẸ́ KÁWỌN ÒBÍ TỌ̀TÚN-TÒSÌ MỌWỌ́ ARA WỌN

    Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ àti ọ̀wọ̀ máa ń jẹ́ kí àlàáfíà jọba

  • Tó o bá jẹ́ ìyàwó, rí i dájú pé o kì í sọ̀rọ̀ bàbá àwọn ọmọ rẹ tàbí ẹni tí ọkọ rẹ ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ láìdáa létí àwọn ọmọ. Èèyàn lè gbàgbéra kó ti máa sọ̀rọ̀ burúkú bẹ́ẹ̀, àmọ́ ṣe ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń ba àwọn ọmọdé nínú jẹ́. O ò sì mọ bí wọ́n ṣe máa tún ọ̀rọ̀ náà sọ létí òbí wọn àti ibi tí wọ́n ti máa sọ ọ́. (Oníwàásù 10:20) Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ kan bá wá fẹjọ́ sun ìwọ tó o jẹ́ ìyá rẹ̀ pé bàbá òun tàbí ìyàwó bàbá òun sọ ọ̀rọ̀ burúkú nípa rẹ. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ọmọ náà ni kí o wò. O lè wá sọ pé: “Máà bínú pé wọ́n sọ irú ọ̀rọ̀ yẹn sí ẹ. Inú ló bí wọn, o sì mọ̀ pé táwọn èèyàn bá ń bínú nígbà míì, wọ́n lè sọ nǹkan tó máa dun ẹlòmíì.”

  • Sapá láti má ṣe yí òfin àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan pa dà nínú ilé wọn. Àmọ́, tó bá pọn dandan pé kí o yí i pa dà, fi pẹ̀lẹ́tù ṣàlàyé, má sì sọ̀rọ̀ tó máa bu òbí wọn kù. Wo àpẹẹrẹ kan:

    Ìyàwó bàbá: Tọ́lá, jọ̀ọ́, wá lọ sá tówẹ̀lì tó o fi nu ara.

    Tọ́lá: Ilẹ̀ẹ́lẹ̀ la máa ń jù ú sí, mọ́mì wa ló máa ń bá wa sá a.

    Ìyàwó bàbá (ó fìbínú sọ̀rọ̀): Àkẹ́bàjẹ́ ni ìyá yín ń kẹ́ yín yẹn.

    Àmọ́ tó bá sọ báyìí ńkọ́:

    Ìyàwó bàbá (ó fohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀): Ó yé mi, àmọ́ ní báyìí fúnra wa ni a ó máa sá a.

  • Rí i pé o kì í fi nǹkan míì dí àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ nígbà tó bá tó àsìkò fún wọn láti wà pẹ̀lú òbí wọn kejì tí kò gbé pẹ̀lú yín. (Mátíù 7:12) Tí ohun tó o fẹ́ kí wọ́n ṣe kò bá ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, kọ́kọ́ tọrọ àyè lọ́wọ́ òbí kejì kó tó di pé o sọ fáwọn ọmọ nípa ètò tí o ṣe.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Nígbà míì tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya ẹni tí ò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ bá pàdé, o lè ṣe àwọn nǹkan yìí:

  1. Jẹ́ kójú yín ṣe mẹ́rin, kó o sì rẹ́rìn-ín músẹ́. Má ṣe máa pòṣé, má sì dápàárá tó ń kanni lábùkù tàbí kó o máa fojú burúkú wò ó.

  2. Kí onítọ̀hún tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.

  3. Jẹ́ kí òun náà dá sí ọ̀rọ̀ tí ẹ bá ń sọ.

ÀJỌṢE KEJÌ: ÀWỌN ỌMỌ TÓ TI DÀGBÀ

Ìwé kan tó ń jẹ́ Step Wars sọ ọ̀rọ̀ obìnrin kan tó sọ pé ọkọ òun máa ń gbè sẹ́yìn àwọn ọmọ rẹ̀ tó ti dàgbà, kì í sì í gbà tí òun bá sọ fún un pé àwọn ọmọ náà ń rí òun fín. Obìnrin náà sọ pé, “Ṣe ni inú mi máa ń ru ṣùṣù.” Kí lo lè ṣe tó ò fi ní jẹ́ kí ọwọ́ tó o fi ń mú àwọn ọmọ rẹ tó ti dàgbà kó bá ìgbéyàwó rẹ?

Ọ̀nà àbáyọ: Máa gba táwọn ẹlòmíì rò. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:24) Fi ara rẹ sí ipò àwọn ẹlòmíì, kí o le mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Àwọn ọmọ tó ti dàgbà tí bàbá tàbí ìyá wọn ti lọ fẹ́ ẹlòmíì máa ń bẹ̀rù pé àwọn ò ní rí ojú òbí àwọn nílẹ̀ mọ́. Ó sì lè máa ṣe wọ́n bíi pé ọ̀dàlẹ̀ ni àwọn táwọn bá fi tayọ̀tayọ̀ gba ìyàwó bàbá àwọn tàbí ọkọ ìyá àwọn. Àwọn òbí náà lè máa ronú pé, àwọn ọmọ lè máà fẹ́ sún mọ́ àwọn mọ́ táwọn bá lọ ń gbè sẹ́yìn ẹni táwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́.

Má fipá fa ojú àwọn ọmọ tó o bá nílé mọ́ra, jẹ́ kó wá látọkàn wọn. Kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn fipá mú ẹnì kan pé kó nífẹ̀ẹ́ ẹni tí kò wù ú. (Orin Sólómọ́nì 8:4) Torí náà, má retí pé ìyanu kan máa ṣẹlẹ̀ táá jẹ́ kí ìwọ àtàwọn ọmọ tó o bá nílé dédé mọwọ́ ara yín.

Tí àwọn ọmọ náà bá ń hùwà àìdáa sí ẹ, má ṣe sọ gbogbo ohun tí ò ń rò tàbí gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ. (Òwe 29:11) Tí kò bá rọrùn fún ẹ láti pa gbogbo ohun tójú ẹ ń rí mọ́ra, gbàdúrà bí Dáfídì Ọba ti ṣe. Ó gbàdúrà pé: “Jèhófà, yan ẹ̀ṣọ́ fún ẹnu mi; yan ìṣọ́ síbi ilẹ̀kùn ètè mi.”—Sáàmù 141:3.

Tó bá jẹ́ pé inú ilé tí àwọn ọmọ náà ti dàgbà lẹ jọ ń gbé, ó ṣeé ṣe kí o kíyè sí i pé wọn fẹ́ràn ilé náà gan-an. Torí náà, jẹ́ kí àwọn àyípadà tó o máa ṣe nínú ilé náà mọ níwọ̀n, pàápàá tó bá máa kan yàrá tí wọ́n ti ń gbé tipẹ́. Tí ẹ bá fẹ́, ẹ tiẹ̀ lè kó lọ sílé tuntun.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Tí àwọn ọmọ tó ti dàgbà tó o bá nílé ò bá jáwọ́ láti máa hùwà ọ̀yájú sí ẹ, tí wọ́n sì ń rí ẹ fín, sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún ọkọ tàbí aya rẹ. Àmọ́ má ṣe fúngun mọ́ ọn pé dandan ni kó bá wọn wí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí ẹ jọ gbọ́ ara yín yé. Ẹ lè jọ wá nǹkan ṣe sí ìṣòro náà, tí ẹ bá jọ ń ‘ronú ní ìfohùnṣọ̀kan.’—2 Kọ́ríńtì 13:11.

Rí i dájú pé gbogbo ọmọ tó wà nínú ilé lo nífẹ̀ẹ́

ÀJỌṢE KẸTA: ÀWỌN ẸBÍ ÀTÀWỌN Ọ̀RẸ́

Ní orílẹ̀-èdè Kánádà obìnrin kan tó ń jẹ́ Marion, tó fẹ́ ọkọ míì sọ pé: “Àwọn òbí mi máa ń fún àwọn ọmọ mi lẹ́bùn, àmọ́ wọn kì í fún àwọn ọmọ ọkọ mi. Èmi àti ọkọ mi máa ń wá nǹkan rà fún wọn, àmọ́ nígbà míì agbára wa kì í gbé e.”

Ọ̀nà àbáyọ: Kọ́kọ́ máa gbọ́ ti ìdílé rẹ tuntun. Sọ bí ọ̀rọ̀ ìdílé rẹ tuntun ṣe jẹ ọ́ lógún tó fún àwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ rẹ. (1 Tímótì 5:8) O kò lè retí pé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ tuntun máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ṣùgbọ́n o lè rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ṣe dáadáa sí ìdílé rẹ tuntun. Jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe máa dun àwọn ọmọ tó, tí ó bá dà bíi pé wọ́n pa wọ́n tì tàbí tí wọn ò ṣe dáadáa sí wọn.

Má ṣe yọ ọwọ́ àwọn òbí ẹni tí ò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ pátápátá lórí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ-ọmọ wọn. Abiyamọ kan tó ń jẹ́ Susan nílẹ̀ England sọ pé: “Mo fẹ́ ọkọ míì lẹ́yìn ọdún kan àtààbọ̀ tí ọkọ mi kú, àmọ́ ṣe ni àwọn òbí rẹ̀ kàn rọ́jú fọwọ́ sí ọkọ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ yìí. Inú wọn túbọ̀ yọ́ sí wa nígbà tá ò yọwọ́ wọn pátápátá lọ́rọ̀ àwọn ọmọ-ọmọ wọn, a máa ń ní káwọn ọmọ pè wọ́n lórí fóònù, a sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún ìtìlẹ́yìn wọn.”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Tó o bá kíyè sí i pé mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ kan wà tí ọ̀rọ̀ yín ò wọ̀, ìwọ àti ọkọ tàbí ìyàwó rẹ tuntun lè jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, kí àárín ìwọ àti ẹni náà lè tòrò.

Ohun tí àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ àtàwọn míì ń ṣe lè máa dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìdílé rẹ tuntun. Àmọ́ tó o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́, ìwọ àti ìdílé rẹ máa jọlá ìbùkún tí Bíbélì ṣèlérí. Ó ní: “Ọgbọ́n ni a ó fi gbé agbo ilé ró, nípa ìfòyemọ̀ sì ni yóò fi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”—Òwe 24:3.

^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 4 Tí o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọgbọ́n téèyàn lè dá sí àwọn ìṣòro yìí, lọ wo Ilé Ìṣọ́ March 1, 1999 tó ní àkòrí náà “Ìdílé Onígbeyàwó Àtúnṣe Bí Wọ́n Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ ìpínrọ̀ 8 Àmọ́ o, tí ọkọ tàbí aya tí ẹ jọ kọ ara yín sílẹ̀ bá ń halẹ̀ mọ́ ẹni tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ báyìí tàbí tó ń yájú sí i, ó lè gba pé kí o jẹ́ kó mọ ààlà rẹ̀, kí ilé rẹ lè tòrò.

BI ARA RẸ LÉÈRÈ . . .

  • Kí ni mo lè ṣe tí kò fi ní sí ìjà láàárín èmi àti ẹni tí ọkọ tàbí aya mi ń fẹ́ tẹ́lẹ̀?

  • Kí la lè ṣe tí àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa kò fi ní máa ṣe ohun tó máa dun àwọn tó wà nínú ìdílé wa láì mọ̀ọ́mọ̀?