Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òtítọ́

Òtítọ́

Ibo lo ti lè rí i?

Báwo ni òtítọ́ ṣe lè ṣe ìwọ àti ìdílé rẹ láǹfààní?

A pè ọ́ tayọ̀tayọ̀ kí o wá gbọ́ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí ní àpéjọ ọlọ́jọ́-mẹ́ta tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe lọ́dún yìí.

ẸṢIN Ọ̀RỌ̀:

‘Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!’

a gbé e ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 17:17.

ÀWỌN OHUN TÍ A MÁA GBÁDÙN:

Àsọyé alárinrin kan tó máa ṣàlàyé ìdí tí a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àkòrí rẹ̀ ni “Kí Ni Òtítọ́?”

A máa wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ méjì tó máa jẹ́ kó dà bíi pé ìṣojú wa ni àwọn ìtàn Bíbélì ṣe ṣẹlẹ̀, tá á sì tún kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́.

ÀWỌN WO LA PÈ:

Gbogbo èèyàn la pè. Ọ̀fẹ́ ni, kò sí owó ìwọlé, a kì í sì í gbégbá ọrẹ.

ÀKÓKÒ ÀTI IBI TÍ A TI MÁA ṢE É:

Wá àpéjọ kan tó bá sún mọ́ ẹ, kí o sì wo fídíò tó dá lórí àwọn àpéjọ wa lórí ìkànnì www.pr418.com. (Wo abẹ́ NÍPA WA/ÀWỌN ÀPÉJỌ)

Lọ wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ yìí lórí ìkànnì www.pr418.com. (Wo Àbẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE/ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ)