SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ Jẹ Jèhófà Lógún Lóòótọ́?
Obìnrin kan tó ṣòro fún láti gbà pé ọ̀rọ̀ òun lè jẹ Jèhófà lógún sọ pé: “Èrò pé mi ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run ni mo fẹ́ẹ̀ lè sọ pé ó jẹ́ olórí ìṣòro tí mò ń gbìyànjú láti borí.” Ṣé irú èrò tí ìwọ náà ní nìyẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ Jèhófà bìkítà nípa àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó bìkítà! A rí ẹ̀rí pé Jèhófà dìídì nífẹ̀ẹ́ wa nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ.—Ka Jòhánù 6:44.
Kí ni Jésù, ẹni tó mọ ìwà Jèhófà lámọ̀dunjú, tó sì mọ ìfẹ́ inú Jèhófà dáadáa ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ sọ? (Lúùkù 10:22) Ó sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” Èyí fi hàn pé, a kò lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, tàbí ká di olùjọsìn Jèhófà, Baba wa ọ̀run, láìjẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ fà wá. (2 Tẹsalóníkà 2:13) Tí a bá lóye ọ̀rọ̀ Jésù, a máa rí ẹ̀rí tó lágbára pé ọ̀rọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ Ọlọ́run lógún.
Kí ló túmọ̀ sí pé kí Jèhófà fà wá? Kì í ṣe pé Jèhófà ń fi dandan mú wa pé ká sin òun. Ó fún wa ní òmìnira, torí náà kì í fi tipátipá fà wá. (Diutarónómì 30:19, 20) Jèhófà ń wo ọkàn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé, ó ń wá àwọn tó ń fẹ́ láti mọ òun. (1 Kíróníkà 28:9) Tó bá rí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ó máa ń fi ìfẹ́ fà wọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Báwo ló ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?
Jèhófà máa ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fa àwọn tó bá ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́” mọ́ra. (Ìṣe 13:48) Ọ̀nà méjì ni Jèhófà máa ń gbà ṣe èyí. Àkọ́kọ́ jẹ́ nípasẹ̀ ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì tó ń dé ọ̀dọ̀ olúkúlùkù wa. Èkejì jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Tí Jèhófà bá rí i pé ọkàn ẹnì kan ṣí sílẹ̀ láti gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ran ẹni yẹn lọ́wọ́, kó lè lóye òtítọ́ yìí, kó sì fi í sílò ní ìgbésí ayé rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 2:11, 12) Láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a kò lè di ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù, a kò sì ní lè fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà láéláé.
Jèhófà fún wa ní òmìnira, torí náà kì í fi tipátipá fà wá
Kí wá ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 6:44 kọ́ wa nípa Jèhófà Ọlọ́run? Ó kọ́ wa pé, Jèhófà máa ń fà wá torí ó rí ohun rere nínú ọkàn wa àti pé ọ̀rọ̀ olúkúlùkù wa jẹ ẹ́ lógún. Nígbà tí obìnrin tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí wá lóye òtítọ́ tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí, ó tù ú nínú. Obìnrin náà sọ pé: “Àǹfààní tó ga jù lọ téèyàn lè ní láyé yìí ni pé kó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Níwọ̀n bí Jèhófà sì ti yàn mí ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, á jẹ́ pé mo ṣeyebíye lójú rẹ̀ nìyẹn.” Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ bí o ṣe wá mọ̀ pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa mú kí o sún mọ́ ọn?
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún May Lúùkù 22-24–Jòhánù 1-16