KÓKÓ Ọ̀RỌ̀: ÌGBÀ WO NI Ẹ̀TANÚ MÁA DÓPIN?
Ìwà Ẹ̀tanú—Ìṣòro Tó Kárí Ayé
ỌMỌ ilẹ̀ Kòríà ni àwọn òbí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jonathan, àmọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni wọ́n bí i sí. Nígbà tó wà lọ́mọdé, àwọn èèyàn máa ń ṣe ẹ̀tanú sí i torí ẹ̀yà tó ti wá. Nítorí náà, bó ṣe ń dàgbà, ó lọ ń gbé níbi tí àwọn èèyàn kò ti ní máa ṣe ẹ̀tanú sí i nítorí ẹ̀yà rẹ̀ tàbí ìrísí rẹ̀. Ó di dókítà, ó sì ń ṣiṣẹ́ ní ìlú kan lápá àríwá ìpínlẹ̀ Alaska, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìdí tó fi lọ síbẹ̀ ni pé ìrísí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó wá ń gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ rẹ̀ jọ tirẹ̀. Ó ronú pé bí òun ṣe rìn jìnnà yìí, òun á bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀tanú.
Ohun tí Jonathan ní lọ́kàn yìí wọmi nígbà tó tọ́jú obìnrin ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n kan. Obìnrin yìí ti dákú lọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ gbàrà tó lajú tó rí ojú Jonathan báyìí, orúkọ burúkú tí wọ́n máa ń pe àwọn tó bá wá láti ilẹ̀ Kòríà ló kọ́kọ́ jáde lẹ́nu rẹ̀. Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé nǹkan ẹlẹ́gbin ló ka àwọn ará Kòríà sí. Ó dun Jonathan wọra gan-an, pé pẹ̀lú gbogbo bí òun ṣe gbìyànjú tó, tí òun tún kó lọ sí àdúgbò ibòmíì kí òun lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tanú, pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jonathan yìí jẹ́ ká rí ohun kan tí kò dáa tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Kò sí ibi tí ẹ̀tanú ò sí. Ṣe ló dà
bíi pé níbikíbi tí àwọn èèyàn bá ti wà, ẹ̀tanú máa wà níbẹ̀.Láìka bí ẹ̀tanú ṣe gbilẹ̀ tó, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń yára ta ko àwọn tó bá ń hùwà ẹ̀tanú. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yìí ò só síni lẹ́nu tó tún buyọ̀ sí i báyìí? Àbí, báwo ni ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn kórìíra á tún ṣe wá gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Òótọ́ kan ni pé ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé àwọn kórìíra ìwà ẹ̀tanú ni kì í fura pé àwọn gan-an máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé bí ọ̀rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn?
GBOGBO WA LỌ̀RỌ̀ YÌÍ KÀN
Yálà a mọ̀ tàbí a kò mọ̀, kì í rọrùn fún wa láti gbà pé à ń ṣe ẹ̀tanú sí àwọn kan nínú ọkàn wa. Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ.” (Jeremáyà 17:9, Bíbélì Mímọ́) Torí náà, a lè máa tan ara wa tí a bá ń rò pé kò sí irú èèyàn tàbí ẹ̀yà tá ò lè bá da nǹkan pọ̀. A sì lè máa rò ó pé a ní ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó jẹ́ ká kórìíra àwọn ẹ̀yà kan.
Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó máa jẹ́ ká mọ bó ti ṣòro tó láti mọ̀ pé ó ṣeé ṣe ká ní ẹ̀tanú sí àwọn ẹ̀yà kan lọ́kàn wa láì fura. Ká sọ pé ò ń rìn lọ ní àdúgbò kan nínú òkùnkùn lálẹ́ ọjọ́ kan. O wá rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì kan tó ò mọ̀ rí tí wọ́n ń rìn bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. Wọ́n rí fìrìgbọ̀n, ó sì dà bí i pé nǹkan kan wà lọ́wọ́ ẹnì kan nínú wọn.
Ṣé o ò ní rò pé ṣe ni àwọn ọkùnrin yẹn fẹ́ ṣe ẹ́ ní jàǹbá? Ó ṣeé ṣe kí ohun kan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí mú kí o fẹ́ ṣọ́ra, àmọ́ ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí yẹn ti wá tó láti gbà pé eléwu èèyàn ni àwọn ọkùnrin méjì yẹn? Ìbéèrè kan tí yóò wádìí ọkàn rẹ ni pé, Ẹ̀yà wo ni o rò pé àwọn ọkùnrin yẹn máa jẹ́? Ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè yìí máa fi ohun tó wà lọ́kàn rẹ hàn. Ó lè jẹ́ kó o mọ̀ pé dé ìwọ̀n àyè kan, ẹ̀tanú díẹ̀díẹ̀ ti ń wà lọ́kàn rẹ.
Tí a kò bá ní tan ara wa, a máa gbà pé nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún, lọ́nà kan tàbí òmíràn gbogbo wa pátá la ní ẹ̀tanú sáwọn kan tàbí àwọn ẹ̀yà kan. Kódà Bíbélì mẹ́nu kan irú ẹ̀tanú kan tó wọ́pọ̀ jù lọ. Ó ní: “Ènìyàn a máa wo ojú.” (1 Sámúẹ́lì 16:7, Bíbélì Mímọ́) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo wa ni ẹ̀tanú ń bá fínra, tó sì jẹ́ pé kì í so èso rere, ǹjẹ́ ìrètí wà pé a lè borí ẹ̀tanú tàbí ká tiẹ̀ mú un kúrò pátápátá láyé wa? Ǹjẹ́ ìgbà kankan tiẹ̀ máa wà tí gbogbo ayé máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tanú?